ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/15 ojú ìwé 23-28
  • Fífún Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífún Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lókun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run —Ìpìlẹ̀ Ìgbàgbọ́ Wa
  • Fara Wé “Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa”
  • Wà Láàyè Nítorí Ìgbàgbọ́
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ṣé Lóòótọ́ Lo Nígbàgbọ́ Nínú Ìhìn Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/15 ojú ìwé 23-28

Fífún Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lókun

ÀWỌN ènìyàn tí ó ti ka Bíbélì pọ̀ ju àwọn tí ó ti ka ìwé mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni mélòó ni ó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ rẹ̀? Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (Tẹsalóníkà Kejì 3:2) Ó ṣe kedere pé, a kò bí ìgbàgbọ́ mọ́ wa. A gbọ́dọ̀ mú un dàgbà. Àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ díẹ̀ pàápàá kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Ìgbàgbọ́ lè yìnrìn, kí ó sì kú. Nítorí náà, ó ń béèrè ìsapá láti jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 2:2.

Nítorí náà, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdí rere láti yan ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fún ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè wọn ti ọdún 1997 sí 1998. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn mìíràn ti tipa báyìí láǹfààní láti pé jọ pọ̀ láti fún ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lókun.

Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run —Ìpìlẹ̀ Ìgbàgbọ́ Wa

Èyí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn fún gbogbo àwọn tí ó wá. Wíwà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ẹ̀rí níní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì. Síbẹ̀, a gbé àwọn ìbéèrè tí ó gba àròjinlẹ̀ dìde nípa ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa: ‘A ha lè gbèjà ìgbàgbọ́ wa, ní lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ bí? A ha mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí, ni ṣíṣàìfọwọ́ yẹpẹrẹ mú Bíbélì, àwọn ìpàdé ìjọ, àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì bí? A ha ń dàgbà nínú ìfẹ́, ìmọ̀ pípéye, àti ìfòyemọ̀ bí?’ Olùbánisọ̀rọ̀ náà rọ gbogbo àwùjọ láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, ni sísọ pé a ṣètò “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ yìí láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ara wa fínnífínní, kí a sì gbé ìwọ̀n àti ìjójúlówó ìgbàgbọ́ tí a ní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò.”

Ẹṣin ọ̀rọ̀ lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni “Nípa Ìgbàgbọ́ Ni A Ń Rìn, Kì Í Ṣe Nípa Ohun Tí A Rí.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:7) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Ìgbàgbọ́ àwọn tí ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó! Ojúlówó ìgbàgbọ́ kò fọ́jú. A gbé e karí òtítọ́ gidi. Hébérù 11:1 sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà pẹ̀lú ìdánilójú fún àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé: “Bí a óò bá rìn nípa ìgbàgbọ́ ní tòótọ́, a nílò ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáradára.” Nítorí tí a ń rìn nípa ìgbàgbọ́, tí kì í ṣe nípa ohun tí a rí, a kò nílò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Jèhófà yóò ṣe mú gbogbo ète rẹ̀ ṣẹ àti ìgbà tí yóò ṣe é. Ohun tí a ti mọ̀ nípa rẹ̀ ń fún wa ní ìgbọ́kànlé pátápátá nínú agbára rẹ̀ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ lọ́nà onífẹ̀ẹ́ àti òdodo.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Àwọn Èwe Kristẹni—Apá Ṣíṣe Kókó Kan Nínú Ìjọ,” rán àwọn èwe létí bí wọ́n ṣe ṣeyebíye tó fún Jèhófà. A rọ̀ wọ́n láti dàgbà nípa tẹ̀mí nípa lílépa àwọn góńgó bíi kíka Bíbélì látòkè délẹ̀ àti kíkúnjú ìwọ̀n ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí. Ìlépa àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tí ẹnì kan yóò pinnu pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n bí a bá dáwọ́ lé e, ète rẹ̀ ni láti múni gbára dì nígbà gbogbo láti sin Ọlọ́run lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. Ẹ̀kọ́ ayé lè ṣiṣẹ́ fún ète tí ó ṣàǹfààní nígbà tí a bá “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” tí ó tan mọ́ ìgbàgbọ́ wa.—Fílípì 1:9, 10.

Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta tí ó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ta Ni Ìwọ Ń Tẹ̀ Lé?” ni ó tẹ̀ lé e. Ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún wa láti rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì. Àwọn Kristẹni ń ṣègbọràn sí òfin àti ìlànà Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ ṣí wa létí láti má ṣe lo ọ̀rọ̀ àlùfààṣá àti ọ̀rọ̀ èébú. (Éfésù 4:31, 32) Olùbánisọ̀rọ̀ náà béèrè pé: “Nígbà tí a bá mú ọ bínú tàbí mú ara kan ọ́, o ha máa ń ké rara ní rírọ̀jò èébú sórí alábàáṣègbéyàwó tàbí sórí àwọn ọmọ rẹ bí?” Dájúdájú, ìyẹn yóò jẹ́ ìwà tí kò yẹ Kristẹni. Ọlọ́run tún ní ọ̀pá ìdiwọ̀n lórí ìrísí wa. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni fi aṣọ “tí ó wà létòlétò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Tímótì Kíní 2:9, 10) Ọ̀rọ̀ náà, “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà,” ní ìtumọ̀ ọ̀wọ̀ ara ẹni, níní ìwà tí ó wuyì, níní àròjinlẹ̀ àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn ni ó ń sún wa, ìlànà Bíbélì àti òye ohun tí ó tọ́ sì ni ó ń darí wa.

Ọ̀rọ̀ àsọyé méjì tí ó tẹ̀ lé e ní gbígbé Hébérù 3:7-15 àti 4:1-16 yẹ̀ wò lẹ́sẹẹsẹ nínú. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí kìlọ̀ fún wa nípa ewu dídi ẹni tí ‘agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ sọ di aláyà líle.’ (Hébérù 3:13) Báwo ni a ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú ìjàkadì lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀? Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní tòótọ́, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè ó sì ń sa agbára ó sì . . . lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn àyà.”—Hébérù 4:12.

Ọ̀rọ̀ àsọparí ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà ni “Ìwé Kan fún Gbogbo Ènìyàn.” Ó tẹnu mọ́ ìjótìítọ́, ìpéye, àti ìṣeémúlò Bíbélì. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti gbọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ náà kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Ìwé Kan fún Gbogbo Ènìyàn! A ṣètò ìtẹ̀jáde yìí ní pàtàkì fún àwọn tí ó jẹ́ pé, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ọ̀mọ̀wé, wọn kò mọ ohun púpọ̀ nípa Bíbélì. Ọ̀rọ̀ àsọyé náà wá sí òpin pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Ó yẹ kí àwọn ènìyàn ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra wọn. A ní ìgbọ́kànlé pé bí wọ́n bá fúnra wọn ṣàyẹ̀wò, wọn yóò mọ̀ pé 7ìwé aláìlẹ́gbẹ́ yìí, Bíbélì, jẹ́ ìwé kan fún gbogbo ènìyàn ní tòótọ́!”

Fara Wé “Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa”

Ẹṣin ọ̀rọ̀ yí tí ó jẹ́ ti ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà pe àfiyèsí sórí Jésù Kristi, “Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.” Ó pọn dandan kí a “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (Hébérù 12:2; Pétérù Kíní 2:21) A sọ fún ọ̀pọ̀ tí ó wà nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù pé: ‘Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà!’ Ṣùgbọ́n ṣé gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ ń béèrè nìyẹn? Bíbélì polongo pé “ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Nítorí náà, yàtọ̀ sí gbígbàgbọ́ nínú Jésù, a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ tí òun ṣe, ní pàtàkì nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ dá lórí iṣẹ́ ajíhìnrere. Bíi Pọ́ọ̀lù, ó yẹ kí a hára gàgà láti polongo ìhìn rere ìgbàlà. (Róòmù 1:14-16) Jésù wàásù fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo. Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé tí a ń ṣe déédéé tilẹ̀ ń méso jáde, àwọn tí kì í sí nílé nígbà tí a bá kàn sí wọn ń pọ̀ sí i. (Ìṣe 20:20) Ọ̀pọ̀ máa ń wà nílé ẹ̀kọ́, lẹ́nu iṣẹ́, nílé ìrajà, tàbí kí wọ́n rìnrìn àjò. Nítorí náà, a tún ní láti wàásù ní àwọn ibi tí èrò ń pọ̀ sí àti ibikíbi tí a ti lè rí ènìyàn.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ẹ Ta Gbòǹgbò Kí Ẹ Sì Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Òtítọ́,” rán wa létí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí—ìpíndọ́gba 1,000 ènìyàn lọ́jọ́ kan! Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí ta gbòǹgbò, kí wọ́n sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́. (Kólósè 2:6, 7) Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé gbòǹgbò gidi ń fa omi àti èròjà láti inú ilẹ̀, nígbà tí ó sì ń gbé irúgbìn dúró. Bákan náà, nípasẹ̀ àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ dáradára àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ tí ó gbámúṣé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú òtítọ́.

Ìmọ̀ràn yí yẹ ní pàtàkì fún àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí. Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́jọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà, a batisí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù. Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣamọ̀nà sí Batisí,” rán àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí létí pé rírì wọ́n bọmi pátápátá jẹ́ àmì yíyẹ ti dídì tí wọ́n di òkú sí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn onímọtara-ẹni-nìkan ti àtijọ́. Gbígbé tí a gbé wọn dìde láti inú omi dúró fún sísọ tí a sọ wọn di ààyè láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

A gbé ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ẹ Máa Ja Ìjà Líle fún Ìgbàgbọ́,” karí ìwé Júúdà inú Bíbélì. A rọ̀ wá láti dáàbò bo ìgbàgbọ́ wa nípa dídènà ipa tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, irú bí ìwà pálapàla, ìṣọ̀tẹ̀, àti ìpẹ̀yìndà. Lẹ́yìn ìyẹn, a fún àwọn òbí—ní pàtàkì àwọn bàbá—ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ nínú ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Pèsè fún Agbo Ilé Rẹ.” Pípèsè fún ìdílé nípa tẹ̀mí, nípa ti ara, àti ti ìmọ̀lára jẹ́ ojúṣe tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀. (Tímótì Kíní 5:8) Èyí ń béèrè àkókò, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, àti wíwà pa pọ̀. Ó dájú pé inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí iṣẹ́ takuntakun tí àwọn Kristẹni òbí ń ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú òtítọ́.

Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó tẹ̀ lé e, “Ẹ Jẹ́ Kí A Lọ sí Ilé Jèhófà,” gbé ìmọrírì ga fún àwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n ń pèsè ìsinmi kúrò nínú àníyàn ayé yìí. Nínú ìpàdé, a láǹfààní láti ṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí, a sì lè fi ìfẹ́ wa hàn fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. (Hébérù 10:24, 25) Ìpàdé tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú ìjáfáfá wa gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ pọ̀ sí i, wọ́n sì ń mú ìmọ̀ wa nípa ète Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i. (Òwe 27:17) Ǹjẹ́ kí a má ṣe ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ìjọ láé, kí a sì rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ pọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.”—Mátíù 18:20.

Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kẹ́yìn ní ọjọ́ yẹn ni “Ìjójúlówó Ìgbàgbọ́ Rẹ—A Ń Dán An Wò Nísinsìnyí.” A kò lè mọ bí ìgbàgbọ́ tí a kò dán wò ti rí, a kò mọ ìjójúlówó rẹ̀. Ó dà bí ìwé sọ̀wédowó tí a kò tí ì lọ gba owó rẹ̀. Ó ha níye lórí tó ohun ti a kọ sí i lórí bí? Bákan náà, a gbọ́dọ̀ dán ìgbàgbọ́ wa wò láti fi hàn pé ó fìdí múlẹ̀ àti pé ó jẹ́ ojúlówó. (Pétérù Kíní 1:6, 7) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Nígbà míràn, àwọn àlùfáà àti àwọn apẹ̀yìndà ti tan àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àti àwọn aláṣẹ nípa fífẹ̀sùn èké kàn wá, ní fífi ìgbàgbọ́ Kristẹni wa àti ọ̀nà ìgbésí ayé wa hàn lọ́nà tí kò tọ́. . . . A óò ha jẹ́ kí àwọn tí Sátánì ti fọ́ lójú dẹ́rù bà wá, kí wọ́n mú àyà wa pami, kí wọ́n sì mú kí a tijú ìhìn rere bí? A óò ha jẹ́ kí pípa tí wọ́n ń pa irọ́ nípa òtítọ́ ní ipa lórí lílọ sí ìpàdé déédéé àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wa bí? Tàbí a óò ha dúró gbọn-in, kí a sì ní ìgboyà, kí a sì túbọ̀ pinnu ju ti ìgbàkigbà rí lọ láti máa bá a nìṣó ní pípolongo òtítọ́ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ bí?”

Wà Láàyè Nítorí Ìgbàgbọ́

A gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ kẹta àpéjọpọ̀ náà karí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Ó hàn gbangba pé nípa òfin kò sí ẹni kankan tí a polongo ní olódodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ‘olódodo yóò wà láàyè nítorí ìgbàgbọ́.’” (Gálátíà 3:11) Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Alásọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì fún Ọjọ́ Wa,” jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà. Ìwé Jóẹ́lì tọ́ka sí àkókò wa, ó sì fi òye ìjẹ́kánjúkánjú sọ pé: “Págà fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” (Jóẹ́lì 1:15, NW) Lọ́nà tí ó bá ti eéṣú tí kì í ṣàárẹ̀ mu, àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró kò jẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́ pípolongo Ìjọba náà ní àkókò òpin yìí.

Ìwé Jóẹ́lì tún fún wa nírètí, ní sísọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32, NW) Èyí ń béèrè ju wíwulẹ̀ lo orúkọ Jèhófà lọ. Ó ń béèrè ìrònúpìwàdà àtọkànwá, èyí sì ní kíkẹ̀yìn wa sí ìwà àìtọ́ nínú. (Jóẹ́lì 2:12, 13) Kò sí àyè fún ìjáfara nítorí pé láìpẹ́ Jèhófà yóò múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè, àní bí ó ti ṣe sórí Móábù, Ámónì, àti ẹkùn olókè ti Séírì ní àwọn ọjọ́ Ọba Jèhóṣáfátì ti Júdà.—Kíróníkà Kejì 20:1-30; Jóẹ́lì 3:2, 12.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ẹ Fi Ìgbàgbọ́ Hàn Nípa Dídúró De Jèhófà,” fún gbogbo àwùjọ níṣìírí. Nísinsìnyí tí a ti rìn jìnnà wọnú àkókò òpin náà, a lè bojú wẹ̀yìn wo ìmúṣẹ ọ̀pọ̀ àwọn ìlérí Jèhófà, kí a sì lọ́kàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú àwọn ohun tí kò tí ì nímùúṣẹ. Àwọn ènìyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti mú sùúrù, ní rírántí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò ṣẹ.—Títù 2:13; Pétérù Kejì 3:9, 10.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ wá sí òpin pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan.” Àwòkẹ́kọ̀ọ́ nípa bí nǹkan ṣe rí gan-an yìí fún wa níṣìírí láti yẹ ẹ̀mí ìrònú wa nípa ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́nì wò. Láìka ibi tí a ń gbé sí, bí a bá fẹ́ kí ìgbésí ayé wa bọ́ lọ́wọ́ àníyàn, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù láti jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, kí ó máa wo Ìjọba Ọlọ́run ní kedere.—Mátíù 6:22.

Àwíyé fún gbogbo ènìyàn ní ẹṣin ọ̀rọ̀ arùmọ̀lárasókè náà pé, “Ìgbàgbọ́ àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ.” Ó fúnni ní ẹ̀rí pé àwọn aṣáájú ènìyàn kò lè yanjú àwọn ìṣòro ayé. (Jeremáyà 10:23) Ìtàn ènìyàn ń tún ara rẹ̀ sọ—lọ́nà púpọ̀ sí i, tí ó sì túbọ̀ ń ba nǹkan jẹ́ sí i. Kí ni èrò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa ọjọ́ ọ̀la? A gbà gbọ́ pé aráyé olùṣòtítọ́ ní ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 5:5) Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ fún àǹfààní gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí ó rọni pé: “Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i, ẹ pè é, nígbà tí ó wà nítòsí.”—Aísáyà 55:6.

Jésù béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pẹ̀lú ọjọ́ wa lọ́kàn. Ó béèrè pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé, òun yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Lúùkù 18:8) Ọ̀rọ̀ àsọparí ṣàtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà, ó sì fi bí ó ṣe fi ẹ̀rí lílágbára hàn pé ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bẹ, bí a tilẹ̀ ń gbé nínú ayé aláìnígbàgbọ́ àti aláìlẹ́mìí-ìsìn.

Síbẹ̀, a lè bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan léèrè pé, ‘Mo ha wà lára àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ tí ó dúró gbọn-in nínú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí?’ Ó yẹ kí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí ìbéèrè yẹn. Ẹ sì wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó sí Jèhófà fún fífún ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀ àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí, Bíbélì, lókun!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ọ̀pọ̀ olùyọ̀ǹda-ara-ẹni fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ láti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó wá wọ̀ sílé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

L. A. Swingle ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń mú ìwé pẹlẹbẹ tuntun jáde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

A lo àwọn pápá ìṣeré ìdárayá ńláńlá bí irú èyí ní ọ̀pọ̀ ibi káàkiri ayé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀pọ̀ ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn tí ó wá sí àpéjọpọ̀ fi tayọ̀tayọ̀ kọrin Ìjọba. Àwòrán inú àkámọ́: àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́