ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 3/1 ojú ìwé 20-24
  • Mo Dúpẹ́ Fún Ogún Kristẹni Lílágbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Dúpẹ́ Fún Ogún Kristẹni Lílágbára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtara Bàbá fún Òtítọ́ Bíbélì
  • Ìpèníjà Àwọn Ọdún Ìgbà Ogun
  • Múra Tán Láti Pèsè Ìdáhùn
  • Ìkésíni Tí A Kò Retí
  • Iṣẹ́ Àyànfúnni Míṣọ́nnárì
  • Ìyípadà Nínú Iṣẹ́ Àyànfúnni
  • Iṣẹ́ ní Nàìjíríà
  • Ìrètí Wa Mú Wa Dúró
  • Jèhófà Fún Wa Lókun Lákòókò Ogun àti Lákòókò Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jèhófà ni Ààbò àti Okun Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • DÍdúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà—Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 3/1 ojú ìwé 20-24

Mo Dúpẹ́ Fún Ogún Kristẹni Lílágbára

GẸ́GẸ́ BÍ GWEN GOOCH ṢE SỌ Ọ́

Ní ilé ẹ̀kọ́, mo kọrin tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ náà, ‘Jèhófà Ńlá gúnwà nínú ògo rẹ̀.’ Mo sábà máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Jèhófà yìí?’

ÀWỌN òbí mi àgbà jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, wọ́n dara pọ̀ mọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ tí a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà náà. Bàbá mi rí ṣe nídìí òwò, ṣùgbọ́n kò kọ́kọ́ tàtaré ogún Kristẹni tí a fún un sí àwa ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Ìgbà tí Bàbá fún èmi, ẹ̀gbọ́n mi, Douglas, àti àbúrò mi, Anne, ní àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí ó ní àkọlé náà, His Works àti Who Is God? ni mo tó mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́. (Sáàmù 83:18) Inú mi dùn gan-an! Ṣùgbọ́n, kí ni ó ta ìfẹ́ Bàbá jí?

Ní ọdún 1938, nígbà tí ó rí i tí àwọn orílẹ̀-èdè ń múra ogun, Bàbá wá mọ̀ pé ìsapá ènìyàn kò lè yanjú àwọn ìṣòro ayé rárá. Ìyá mi àgbà fún un ní ìwé náà, Awọn Ọta, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Láti inú kíkà á, ó kọ́ pé Sátánì Èṣù ni olórí ọ̀tá aráyé, àti pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó lè mú àlàáfíà ayé wá.a—Dáníẹ́lì 2:44; 2 Kọ́ríńtì 4:4.

Bí ogun ti ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ìdílé wa bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Wood Green, Àríwá London. Ní June ọdún 1939, a lọ sí Ààfin Alexandra tí ó wà nítòsí, láti gbọ́ àwíyé náà fún gbogbo ènìyàn, “Ìjọba àti Àlàáfíà,” tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, sọ. A fi rédíò gbé ọ̀rọ̀ tí Rutherford sọ ní Gbàgede Ọgbà Madison ní New York City sáfẹ́fẹ́, ní London, àti àwọn ìlú ńlá mìíràn. A lè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ketekete débi pé, nígbà tí àwùjọ èèyànkéèyàn dá rògbòdìyàn sílẹ̀ ní New York, mo wò yíká láti rí i bóyá inú gbọ̀ngàn ńlá tí a wà ni rògbòdìyàn náà ti ń ṣẹlẹ̀!

Ìtara Bàbá fún Òtítọ́ Bíbélì

Bàbá rin kinkin mọ́ ọn pé gbogbo ìrọ̀lẹ́ Saturday ni ìdílé wa gbọ́dọ̀ máa jókòó pa pọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìkẹ́kọ̀ọ́ wa dá lórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì nínú Ilé Ìṣọ́ tí a óò jíròrò ní ọjọ́ kejì. Ní ṣíṣàkàwé ipa tí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ní lórí mi, ìtàn nípa Jóṣúà àti sísàgati ìlú Áì, tí a jíròrò nínú Ile Iṣọ ti May 1, 1939, (Gẹ̀ẹ́sì) dáradára kò kúrò lọ́kàn mi títí di òní olónìí. Ìtàn yẹn ru mí lọ́kàn sókè tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi ṣàyẹ̀wò gbogbo ìtọ́kasí tí a ṣe nípa rẹ̀ nínú Bíbélì mi. Irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ gbádùn mọ́ mi—ó ṣì gbádùn mọ́ mi títí di ìsinsìnyí.

Ṣíṣàjọpín ohun tí a ń kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn mú kí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. Ní ọjọ́ kan, Bàbá gbé ohun èlò agbóhùnjáde, tí a ti ka ìwàásù tí a gbé ka Bíbélì sí fún mi, ó tún fún mi ní ìwé pẹlẹbẹ kan tí a fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti àdírẹ́sì màmá àgbàlagbà kan. Lẹ́yìn náà, ó ní kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Mo béèrè pé: “Kí ni n óò sọ, kí ni n óò sì ṣe?”

Bàbá fèsì pé: “Gbogbo rẹ̀ wà nínú rẹ̀. Ṣáà ti gbé rẹ́kọ́ọ̀dù yẹn sí i, ka àwọn ìbéèrè jáde, jẹ́ kí onílé ka ìdáhùn, lẹ́yìn náà kí o sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́.”

Mo ṣe bí ó ti wí, bí mo ṣe kọ́ bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Nípa lílo Ìwé Mímọ́ lọ́nà yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, mo wá túbọ̀ lóye rẹ̀.

Ìpèníjà Àwọn Ọdún Ìgbà Ogun

Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1939, mo sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi láti sin Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e. Ọmọ ọdún 13 péré ni mi nígbà náà. Nígbà yẹn, mo pinnu láti di aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Mo fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ ní ọdún 1941, mo sì dara pọ̀ mọ́ Douglas nínú ìgbòkègbodò ìwàásù alákòókò kíkún nígbà àpéjọpọ̀ Leicester.

Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a ju Bàbá sẹ́wọ̀n fún kíkọ̀ láti jagun nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Àwa ọmọ rọ̀gbà yí màmá wa ká, a ràn án lọ́wọ́ láti tọ́jú ilé wa ní àkókò tí kò fara rọ, tí ogun ń jà yẹn. Lẹ́yìn náà, kò pẹ́ tí a dá Bàbá sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ni a pe Douglas fún iṣẹ́ ológun. Àkọlé ìwé ìròyìn àdúgbò kan kà pé, “Ìdí Tí Ọmọ Fi Yan Ọ̀gbà Ẹ̀wọ̀n Bí Ti Bàbá Rẹ̀.” Ó yọrí sí ìjẹ́rìí tí ó jíire, níwọ̀n bí ó ti pèsè àǹfààní láti ṣàlàyé ìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í lọ́wọ́ nínú pípa ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn.—Jòhánù 13:35; 1 Jòhánù 3:10-12.

Ní àwọn ọdún tí ogun fi jà yẹn, ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé sí ilé wa, mi ò sì lè gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ gbígbéniró tí a gbé karí Bíbélì, tí wọ́n máa ń sọ láéláé. John Barr àti Albert Schroeder, tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí, wà lára àwọn Kristẹni arákùnrin olóòótọ́ wọ̀nyí. Àwọn òbí mi ní aájò àlejò gan-an, wọ́n sì kọ́ wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.—Hébérù 13:2.

Múra Tán Láti Pèsè Ìdáhùn

Kété lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà, mo bá Hilda pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Ó fi ìbínú sọ pé: “Ọkọ mi wà lójú ogun, tí ó ń jà fún àwọn ènìyàn bí tìrẹ! Èé ṣe tí o kò fi ṣe ohun kan láti fi ti ogun náà lẹ́yìn?”

Mo béèrè pé: “Kí ni o mọ̀ nípa ohun tí mò ń ṣe? Ìwọ ha mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá bí?”

Ó fèsì pé: “Ó dára, wọlé, kí o sọ ọ́ fún mi.”

Ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣàlàyé pé a ń pèsè ìrètí tòótọ́ fún àwọn ènìyàn tí ń jìyà nítorí àwọn ìwà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń hù—lọ́pọ̀ ìgbà lórúkọ Ọlọ́run. Hilda fetí sílẹ̀ dáradára, ó sì di akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àkọ́kọ́. Ó ti jẹ́ ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí fún ohun tí ó lé ní 55 ọdún nísinsìnyí.

Nígbà tí ogun náà parí, mo gba iṣẹ́ àyànfúnni tuntun ti aṣáájú ọ̀nà sí Dorchester, ìlú kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn England. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí n óò fi ilé sílẹ̀. Ìjọ wa kékeré máa ń pàdé ní ilé àrójẹ kan, ilé kan tí a ń pè ní “Ilé Tíì Àtijọ́,” tí a ti kọ́ láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. A ní láti tún tábìlì àti àga tò fún ìpàdé wa kọ̀ọ̀kan. Ó yàtọ̀ pátápátá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó ti mọ́ mi lára. Síbẹ̀síbẹ̀, a ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí kan náà àti ìfararora onífẹ̀ẹ́ ti àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin.

Láàárín àkókò náà, àwọn òbí mi ṣí lọ sí Tunbridge Wells, ní gúúsù London. Mo padà sílé kí èmi, Bàbá, àti Anne lè ṣe aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀. Kò pẹ́ tí ìjọ wa fi gbèrú láti orí Ẹlẹ́rìí 12 sí 70, nítorí náà, a ní kí ìdílé wa ṣí lọ sí Brighton, ní gúúsù etíkun, níbi tí àìní fún olùpòkìkí Ìjọba náà gbé pọ̀. Ọ̀pọ̀ fi ìtara dara pọ̀ ní wíwàásù pẹ̀lú ìdílé wa tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, a sì rí i tí Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa jìngbìnnì. Kò pẹ́ ti ìjọ kan ṣoṣo yẹn fi di mẹ́ta!

Ìkésíni Tí A Kò Retí

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1950, ìdílé wa wà lára 850 àyànṣaṣojú láti Britain, tí wọ́n lọ sí Àpéjọ Àgbáyé ti Ìbísí Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York City. A fi fọ́ọ̀mù àtilọ sí Watchtower Bible School of Gilead, tí ó wà nítòsí Gúúsù Lansing, ní New York, ṣọwọ́ sí ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà tí yóò wá sí àpéjọpọ̀ yẹn láti òkè òkun. Èmi, Douglas, àti Anne, wà lára wọn! Mo rántí ríronú nígbà tí mo ń ju fọ́ọ̀mù tí mo kọ̀rọ̀ kún náà sínú àpótí lẹ́tà, pé, ‘Ó ti ṣẹlẹ̀ wàyí o! Báwo ni ìgbésí ayé mi yóò ṣe wá rí?’ Síbẹ̀, ìpinnu mi ni pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Inú mi dùn jọjọ nígbà tí mo rí ìkésíni gbà láti dúró lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà láti lọ sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead, pa pọ̀ pẹ̀lú Douglas àti Anne. Gbogbo wa pátá ni a mọ̀ pé a lè rán wa jáde gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì sí apá ibikíbi lágbàáyé.

Lẹ́yìn gbígbádùn àpéjọpọ̀ náà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, àkókò tó fún àwọn òbí wa láti padà sí England—ní àwọn nìkan. Àwa ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta juwọ́ sí wọn pé ó dìgbòóṣe bí wọ́n ti ń rìnrìn àjò òkun padà sílé nínú ọkọ̀ Mauritania. Ẹ wo irú ìmọ̀lára ìfira-ẹni-sílẹ̀ tí ó jẹ́!

Iṣẹ́ Àyànfúnni Míṣọ́nnárì

Ọgọ́fà akẹ́kọ̀ọ́ láti apá ibi gbogbo lágbàáyé, títí kan àwọn tí wọ́n jìyà ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Nazi, ni ó wà ní kíláàsì kẹrìndínlógún ti Gilead. Níwọ̀n bí a ti kọ́ kíláàsì wa ní èdè Spanish, a retí kí a rán wa lọ́ sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Spanish ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ẹ wo bí ẹnu ti yà wá tó ní ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa, láti gbọ́ pé a yan Douglas sí Japan, tí a sì yan èmi àti Anne sí Síríà. Nítorí náà, àwa obìnrin ní láti kọ́ èdè Lárúbáwá, èyí sì jẹ́ òtítọ́ àní nígbà tí a yí ibi tí a yàn wá sí padà sí Lẹ́bánónì. Nígbà tí a ń retí ìwe àṣẹ ìwọ̀lú tí a óò lo, a gba ẹ̀kọ́ lórí èdè Lárúbáwá nígbà méjì lọ́sẹ̀ láti ọ̀dọ̀ George Shakashiri, òǹtẹ̀wé Watch Tower Society fún Ilé Ìṣọ́ Lárúbáwá.

Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ni tó láti máa lọ sí ilẹ̀ Bíbélì tí a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú kíláàsì! Keith àti Joyce Chew, Edna Stackhouse, Olive Turner, Doreen Warburton, àti Doris Wood lọ pẹ̀lú wa síbẹ̀. Ẹ wo irú ìdílé míṣọ́nnárì aláyọ̀ tí a wá jẹ́! Ẹlẹ́rìí àdúgbò kan bẹ ilé míṣọ́nnárì wa wò láti ràn wá lọ́wọ́ síwájú sí i nínú èdè náà. Ní àkókò ìtọ́ni wa ojoojúmọ́, a óò fi ìgbékalẹ̀ ṣókí dánra wò, lẹ́yìn èyí tí a óò jáde lọ láti lò ó nínú iṣẹ́ ìwàásù wa.

A lo àwọn ọdún wa àkọ́kọ́ ní Tripoli, níbi tí ìjọ kan tí a ti dá sílẹ̀ wà. Èmi, Joyce, Edna, Olive, Doreen, Doris, àti Anne, ṣèrànwọ́ fún àwọn aya àti ọmọbìnrin Àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìpàdé àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fun gbogbo ènìyàn. Títí di igbà yẹn, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa, ní títẹ̀lé àṣà àdúgbò, kì í jókòó pa pọ̀ ní ìpàdé, àwọn Kristẹni arábìnrin wọ̀nyí kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá láti ilé dé ilé. A nílò ìrànlọ́wọ́ wọn ní ti èdè náà nínú wíwàásù fún gbogbo ènìyàn, a sì fún wọn níṣìírí láti fúnra wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí.

Lẹ́yìn náà, a yan èmi àti Anne láti ran àwùjọ kékeré ti Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú ìgbàanì ti Sídónì lọ́wọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, a ní kí a padà sí olú ìlú náà, Beirut. A ti gbin irúgbìn òtítọ́ Bíbélì sáàárín àwùjọ tí ń sọ èdè Armenian níbẹ̀, nítorí náà a kọ́ èdè náà láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ìyípadà Nínú Iṣẹ́ Àyànfúnni

Mo ti bá Wilfred Gooch pàdé ki n tó fi England sílẹ̀. Ó jẹ́ arákùnrin onítara, aláájò, tí ó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti London. Wilf jẹ́ mẹ́ńbà kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dógún ti Gilead, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ yege nígbà àpéjọpọ̀ tí a ṣe ni Pápá Ìṣeré Yankee ní ọdún 1950. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Nàìjíríà, ni ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn án sí, a sì ń kọ̀wé síra wa fún àkókò kan. Ní ọdún 1955, àwa méjèèjì lọ sí àpéjọpọ̀ “Ìjagunmólú Ìjọba” ní London, kété lẹ́yìn náà, a ṣàdéhùn láti fẹ́ra wa. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a ṣègbéyàwó ní Gánà, mo sì dara pọ̀ mọ́ Wilf nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn fún un ní Èkó, Nàìjíríà.

Lẹ́yìn tí mo fi Anne sílẹ̀ ní Lẹ́bánónì, Kristẹni arákùnrin àtàtà kan tí ó ti kọ́ òtítọ́ Bíbélì ní Jerúsálẹ́mù, fẹ́ ẹ. Kò ṣeé ṣe fún àwọn òbí mi láti wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó wa, níwọ̀n bí èmi, Douglas, àti Anne ti ṣègbéyàwó ní apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ayé. Síbẹ̀, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti mọ̀ pé gbogbo wa pátá ń fi ayọ̀ sin Jèhófà, Ọlọ́run wa.

Iṣẹ́ ní Nàìjíríà

Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Èkó, a yàn mí sí títọ́jú iyàrá àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé ẹ̀ka wa, kí n gbọ́únjẹ fún wọn, kí n sì fọṣọ wọn. Ṣe ni ó dà bí ẹni pé kì í ṣe ọkọ nìkan ni mo ní, ṣùgbọ́n mo tún ní ìdílé tí ó sún mọ́ mi gan-an!

Èmi àti Wilf kọ́ àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì díẹ̀ ní èdè Yorùbá, a sì san èrè fún ìsapá wa. Ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan tí a kàn sí nígbà yẹn ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin kan nísinsìnyí tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ńlá ti Nàìjíríà, tí ó ní nǹkan bí 400 mẹ́ńbà.

Ní ọdún 1963, Wilf ri ìkésíni gbà láti lọ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́wàá kan ti ìtọ́ni àkànṣe ní Brooklyn, New York. Lẹ́yìn tí ó parí rẹ̀, láìrò ó tẹ́lẹ̀, a rán an padà sí England. Èmi ṣì wà ní Nàìjíríà, wọ́n sì fún mi ní ìfitónilétí ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlá péré láti bá Wilf ní London. Mo lọ pẹ̀lú ayọ̀ àti ẹ̀dùn ọkàn, níwọ̀n bí mo ti rí ayọ̀ gidigidi nínú iṣẹ́ àyànfúnni mi ní Nàìjíríà. Lẹ́yìn sísìn fún ọdún 14 nílẹ̀ òkèèrè, ó gba àkókò láti lè mú ara mi bá ipò ìgbésí ayé ní England mú. Ṣùgbọ́n, inú wa dùn láti wà nítòsí àwọn òbí wa tí ń darúgbó lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ó sì ṣeé ṣe fún wa láti tọ́jú wọn.

Ìrètí Wa Mú Wa Dúró

Láti ọdún 1980, mo láǹfààní láti bá Wilf lọ bí ó ti ń rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá. Ní pàtàkì, mo máa ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí a óò padà ṣèbẹ̀wò sí Nàìjíríà. Lẹ́yìn náà, a tún lọ sí Scandinavia, West Indies, àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn—títí kan Lẹ́bánónì. Ayọ̀ arà ọ̀tọ̀ ni ó jẹ́ láti tún rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ àti láti rí àwọn tí mo ti mọ̀ nígbà tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́langba, tí wọ́n ti wá di Kristẹni alàgbà.

Ó bà mí nínú jẹ́ pé, ọkọ mi ọ̀wọ́n kú ní ìgbà ìrúwé ọdún 1992. Ẹni ọdún 69 péré ni. Nítorí tí ó ṣẹlẹ̀ lójijì, ó gbò mí gidigidi. Lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún 35, ó gba àkókò láti lè mú ara mi bọ̀ sípò. Ṣùgbọ́n mo ti rí ọ̀pọ̀ ìrànwọ́ àti ìfẹ́ gbà láti ọ̀dọ̀ ìdílé Kristẹni ti mo ní kárí ayé. Mo ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí aláyọ̀ tí mo lè máa ronú lé lórí.

Àwọn òbí mi fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ fun mi ní ti ìwà títọ́ Kristẹni. Màmá kú ní ọdún 1981, Bàbá sì kú ní ọdún 1986. Douglas àti Anne ń bá a nìṣó láti máa fi òótọ́ sin Jèhófà. Douglas àti aya rẹ̀, Kam, ti padà sí London, níbi ti wọ́n fìdí kalẹ̀ sí lẹ́yìn tí wọ́n ti tọ́jú Bàbá tán. Anne àti ìdílé rẹ̀ wà ní United States. Gbogbo wa pátá mọrírì ìrètí àti ogún tí Ọlọ́run fún wa gidigidi. A óò máa bá a nìṣó láti “fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn,” ní fífojúsọ́nà fún àkókò náà, nígbà tí àwọn alààyè, àti àwọn olólùfẹ́ wọn tí a jí dìde, yóò sìn pa pọ̀ títí láé gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìdílé Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé.—Ìdárò 3:24.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ìgbésí ayé bàbá mi, Ernest Beavor, fara hàn nínú Ilé-Ìṣọ́ Naa September 15, 1980.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún:

Gwen ní ọmọ ọdún 13 tí ó ń ṣàṣefihàn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Enfield

Ìdílé míṣọ́nnárì ní Tripoli, Lẹ́bánónì, ọdún 1951

Gwen àti Wilf, ọkọ rẹ̀ tí ó ti dolóògbé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́