Ìjójúlówó Ìgbàgbọ́ Rẹ—A Ń dán an Wò Nísinsìnyí
“Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.”—JÁKỌ́BÙ 1:2, 3.
1. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi ní láti máa retí ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn?
LỌ́DỌ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́, ìyà kì í ṣe omi ọbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrora tàbí ìtẹ́nilógo kò bá wọn lára mu. Síbẹ̀, wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí, tí Jákọ́bù, iyèkan Jésù, kọ, sọ́kàn. Kristi mú kí ó ṣe kedere fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n lè máa retí inúnibíni àti àwọn ìṣòro mìíràn nítorí pé wọ́n rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run. (Mátíù 10:34; 24:9-13; Jòhánù 16:33) Síbẹ̀síbẹ̀, ìdùnnú lè ti inú irú àwọn ìdánwò bẹ́ẹ̀ wá. Lọ́nà wo?
2. (a) Báwo ni ìdánwò ìgbàgbọ́ wa ṣe lè yọrí sí ìdùnnú? (b) Báwo ni ìfaradà ṣe lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré nínú ọ̀ràn tiwa?
2 Ìdí pàtàkì tí a fi ń rí ìdùnnú nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò tàbí ìdánwò ni pé wọn lè so èso rere. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti sọ, fífaradà lábẹ́ ìdánwò tàbí ìṣòro “ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” A lè jàǹfààní láti inú mímú ànímọ́ Kristẹni náà tí ó ṣeyebíye dàgbà. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:4) Ìfaradà ní ohun kan, àní, ó ní “iṣẹ́” kan láti ṣe. Iṣẹ́ rẹ̀ ni láti mú wa pé pérépéré, kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ Kristẹni tí mùṣèmúṣè rẹ̀ dá múṣémúṣé. Nítorí náà, bí a bá jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un láìgbìdánwò láti lo àwọn ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti fòpin sí àdánwò náà lójijì, a óò dán ìgbàgbọ́ wa wò, a óò sì yọ́ ọ mọ́. Bí a kò bá ti ń ní sùúrù, ìyọ́nú, inú rere, tàbí ìfẹ́ tẹ́lẹ̀ nínú bí a ṣe ń kojú àwọn ipò tàbí nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, ìfaradà lè túbọ̀ jẹ́ kí a di pípé. Bẹ́ẹ̀ ni, bí ó ṣe tẹ̀ léra nìyí: Ìdánwò ń yọrí sí ìfaradà; ìfaradà ń mú ànímọ́ Kristẹni pọ̀ sí i; ìwọ̀nyí ní ń mú ìdùnnú wá.—1 Pétérù 4:14; 2 Pétérù 1:5-8.
3. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí ìbẹ̀rù àdánwò tàbí ìdánwò ìgbàgbọ́ wa mú wa fà sẹ́yìn?
3 Àpọ́sítélì Pétérù tún tẹnu mọ́ ìdí tí kò fi yẹ kí a bẹ̀rù ìdánwò ìgbàgbọ́ tàbí kí a fà sẹ́yìn. Ó kọ̀wé pé: “Nínú òtítọ́ yìí ni ẹ̀yin ń yọ̀ gidigidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín, kí ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín tí a ti dán wò, tí ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dá[n] an wò sí, lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pétérù 1:6, 7) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń fún wa níṣìírí ní pàtàkì nísinsìnyí nítorí pé “ìpọ́njú ńlá” náà—àkókò ìyìn, ògo, ọlá, àti lílàájá—ti sún mọ́lé ju bí àwọn kan ti lè rò lọ, ó sì sún mọ́lé ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́.—Mátíù 24:21; Róòmù 13:11, 12.
4. Kí ni ìmọ̀lára arákùnrin kan nípa ìdánwò tí òun àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mìíràn ti nírìírí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, a ṣàyẹ̀wò àwọn ìdánwò tí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró dojú kọ láti ọdún 1914 síwájú. Ìdí kankan ha wà fún ìdùnnú bí? A. H. Macmillan fúnni ní ojú ìwòye tí a gbé karí ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá pé: “Mo ti rí ọ̀pọ̀ àdánwò lílekoko tí ó dé bá ètò àjọ náà àti dídán ìgbàgbọ́ àwọn tí ń bẹ nínú rẹ̀ wò. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, ó là á já, ó sì ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Mo ti rí ọgbọ́n tí ó wà nínú fífi sùúrù dúró de Jèhófà láti mú òye wa nípa àwọn ohun tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣe kedere dípò bíbínú nítorí èrò tuntun. . . . Láìka àtúnṣe tí a ní láti ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan sí nípa ojú ìwòye wa, ìyẹn kò ní yí ìpèsè aláàánú ti ìràpadà àti ìlérí ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣe padà. Nítorí náà, kò sí ìdí kankan fún wa láti jẹ́ kí àwọn ìfojúsọ́nà tí kò tí ì ní ìmúṣẹ tàbí ìyípadà nínú ojú ìwòye sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ.”—Ile Iṣọ Na, August 15, 1966, ojú ìwé 504.
5. (a) Àwọn àǹfààní wo ni ó wá láti inú ìdánwò tí ó dé bá àṣẹ́kù náà? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ọ̀ràn ìdánwò fà wá lọ́kàn mọ́ra nísinsìnyí?
5 A dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí ó la àkókò ìdánwò ti ọdún 1914 sí 1919 já sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ agbára ayé yìí tí ń jẹ gàba léni lórí àti ọ̀pọ̀ ìṣe onísìn ti Bábílónì. Àṣẹ́kù náà tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a ti fọ̀ mọ́, tí a sì yọ́ mọ́, tí wọ́n ń fi tinútinú rúbọ ìyìn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ní ìdálójú pé ó tẹ́wọ́ gbà wọ́n. (Aísáyà 52:11; 2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Ìdájọ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run, ṣùgbọ́n a kò lè parí rẹ̀ ní sáà kan pàtó. Ìdánwò àti ìyọ́mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń bá a lọ. A tún ń dán ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ní ìrètí láti la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ yìí já gẹ́gẹ́ bí apá kan “ogunlọ́gọ̀ ńlá” wò. (Ìṣípayá 7:9, 14) A ń ṣe èyí ní àwọn ọ̀nà tí ó jọ irú èyí tí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró dojú kọ àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú.
Báwo Ni A Ṣe Lè Dán Ọ Wò?
6. Irú ìdánwò lílekoko wo ni ọ̀pọ̀ ti nírìírí?
6 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ti ronú nípa ìpèníjà ti fífarada ìdánwò tí ó bá wà gẹ́gẹ́ bí ìgbéjàkò tààràtà. Wọ́n rántí ìròyìn yìí: “[Àwọn aṣáájú Júù] fi ọlá àṣẹ pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyí bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 5:40, 41) Ìtàn òde òní ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run, pàápàá nígbà àwọn ogun àgbáyé, mú kí ó ṣe kedere pé àwọn olùṣenúnibíni lu ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tòótọ́, wọ́n sì hùwà mìíràn tí ó burú jáì sí wọn.
7. Báwo ni àwọn Kristẹni òde òní kan ti ṣe lọ jìnnà tó ní fífi ìgbàgbọ́ hàn?
7 Ní ti pé àwọn Kristẹni yóò jẹ́ ẹni tí a óò máa ṣe inúnibíni sí, ayé kò fi ìyàtọ̀ sáàárín àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Jòhánù 10:16) Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti dán àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ méjèèjì wò lọ́nà lílekoko nípasẹ̀ ìfisẹ́wọ̀n àti ṣíṣekúpani pàápàá nítorí ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ wọn nínú rẹ̀. Ẹgbẹ́ méjèèjì ti nílò ẹ̀mí Ọlọ́run, láìka ìrètí wọn sí. (Fi wé Ilé-Ìṣọ́nà June 15, 1996, ojú ìwé 31.) Ní àwọn ọdún 1930 àti 1940 ní Germany ti ìjọba Nazi, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà, títí kan àwọn ọmọdé, fi ìgbàgbọ́ tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn, àwọn tí a sì dán wò dé góńgó pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní àwọn àkókò àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn Jèhófà ti dojú kọ ìdánwò inúnibíni ní irú àwọn ilẹ̀ bí Burundi, Eritrea, Etiópíà, Màláwì, Mòsáńbíìkì, Rwanda, Singapore, àti Zaire. Irú àwọn ìdánwò wọ̀nyí sì ń bá a lọ.
8. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí arákùnrin kan ní Áfíríkà sọ ṣe fi hàn pé ìdánwò ìgbàgbọ́ wa ń béèrè ju fífarada inúnibíni ní ọ̀nà líluni lọ?
8 Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí tẹ́lẹ̀, a tún ń dán ìgbàgbọ́ wa wò ní àwọn ọ̀nà mìíràn tí a kò lè tètè fura sí. Àwọn kan lára àwọn ìdánwò náà kò ṣe tààràtà, kò sì rọrùn láti tètè mọ̀ wọ́n. Ronú nípa bí ìwọ yóò ṣe hùwà padà sí díẹ̀ nínú ìwọ̀nyí. Arákùnrin kan ní Àǹgólà tí ó ní ọmọ mẹ́wàá wà ní ìjọ kan tí ó jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin tí a fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti kàn sí fún àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe fún àwọn mìíràn láti bẹ ìjọ náà wò. A béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe ń rọ́gbọ́n dá láti bọ́ ìdílé rẹ̀. Kò rọrùn fún un láti dáhùn, kìkì ohun tí ó lè sọ ni pé ipò nǹkan kò rọrùn. Ó ha ṣeé ṣe fún un láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ bí? Ó fèsì pé: “Tóò, ekukáká ni. A ti kọ́ láti jẹ́ kí ohun tí a bá ní tẹ́ wa lọ́rùn.” Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ohùn tí ó fi ìdánilójú hàn, ó wí pé: “Ṣùgbọ́n kì í ha ṣe ohun tí a ń retí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí nìyí bí?” Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ pabanbarì nínú ayé, ṣùgbọ́n kò ṣàjèjì láàárín àwọn Kristẹni adúróṣinṣin, tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé kíkún pé a óò mú àwọn ìlérí Ìjọba náà ṣẹ.
9. Báwo ni a ṣe ń dán wa wò ní ìbámu pẹ̀lú 1 Kọ́ríńtì 11:3?
9 A tún ń fi àwọn ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run dán ogunlọ́gọ̀ ńlá náà wò. Ìlànà àtọ̀runwá àti ọ̀pá ìdiwọ̀n ti ìṣàkóso Ọlọ́run ni a fi ń darí ìjọ Kristẹni kárí ayé. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, èyí túmọ̀ sí pé kí a mọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú, ẹni tí a yàn fi ṣe Orí Ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 11:3) A ń fi hàn pé a fi tinútinú juwọ́ sílẹ̀ fún òun àti Baba rẹ̀ nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ìyànsípò tí a gbé ka ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run àti ìpinnu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú fífi ìṣọ̀kan ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Síwájú sí i, nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, a ní àwọn ọkùnrin tí a yàn láti mú ipò iwájú. Wọ́n jẹ́ ènìyàn aláìpé tí a lè tètè rí àṣìṣe wọn; síbẹ̀ a rọ̀ wá láti bọ̀wọ̀ fún irú àwọn alábòójútó bẹ́ẹ̀, kí a sì tẹrí ba fún wọn. (Hébérù 13:7, 17) Ìwọ ha máa ń ri pé ìyẹn jẹ́ ìpèníjà nígbà mìíràn bí? Èyí ha jẹ́ ìdánwò fún ọ ní ti gidi bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ ha ń jàǹfààní láti inú ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ?
10. Ìdánwò wo ni a dojú kọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá?
10 A tún ń fi àǹfààní àti ohun àbéèrèfún láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé dán wa wò. Kí a lè yege ìdánwò yìí, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé nínípìn-ín lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń béèrè ju wíwàásù fún àkókò díẹ̀ lásán lọ. Rántí ọ̀rọ̀ rere tí Jésù sọ nípa òtòṣì opó náà tí ó fi gbogbo ohun tí ó ní fúnni. (Máàkù 12:41-44) A lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Ní ti ọ̀ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá mo ha ń yọ̀ǹda ara mi bákan náà bí?’ Gbogbo wa gbọ́dọ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbo ọjọ́, kí a múra tán láti lo gbogbo àǹfààní tí a bá ní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn.—Mátíù 5:16.
11. Báwo ni àwọn ìyípadà nínú òye wa tàbí ìmọ̀ràn lórí ìwà ṣe lè jẹ́ ìdánwò?
11 Ìdánwò mìíràn tí a lè dojú kọ ní í ṣe pẹ̀lú bí a ti ní ìmọrírì tó fún ìmọ́lẹ̀ tí ó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sórí òtítọ́ Bíbélì àti fún ìmọ̀ràn tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà pèsè. (Mátíù 24:45) Nígbà mìíràn, èyí ń béèrè fún àtúnṣe nínú ìwà ẹni, irú bí nígbà tí ó ṣe kedere pé àwọn tí ń mu tábà ní láti jáwọ́ nínú rẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ máa wà nínú ìjọ.a (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ìdánwò náà sì lè jẹ́ láti tẹ́wọ́ gba ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìyípadà nínú orin tí a nífẹ̀ẹ́ sí tàbí àwọn eré ìnàjú mìíràn.b A óò ha kọminú sí ọgbọ́n tí ó wà nínú ìmọ̀ràn tí a fún wa bí? Àbí a óò jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run tún èrò inú wa ṣe, kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àkópọ̀ ìwà Kristẹni wọ̀?—Éfésù 4:20-24; 5:3-5.
12. Kí ni a nílò láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun lẹ́yìn tí ẹnì kan ti ṣe batisí?
12 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń pọ̀ sí i, lẹ́yìn batisí wọn, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa fún ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà lókun. Èyí ní nínú ju wíwulẹ̀ lọ sí àpéjọ Kristẹni, lílọ sí àwọn ìpàdé kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, tàbí lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ. Láti ṣàkàwé: Ẹnì kan lè wà lẹ́yìn òde Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ṣùgbọ́n ó ha ti fi í sílẹ̀ ní tòótọ́ bí? Ó ha ṣì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn nǹkan tí ń fi ẹ̀mí Bábílónì Ńlá hàn—ẹ̀mí tí ń fojú tín-ín-rín ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run? Ó ha ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú sísá fún ìwà pálapàla àti jíjẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni? Ó ha ń tẹnu mọ́ ire ti ara rẹ̀ àti ọrọ̀ àlùmọ́nì ju ire tẹ̀mí bí? Àní, ó ha ti wà láìlábàwọ́n nínú ayé bí?—Jákọ́bù 1:27.
Jàǹfààní Láti Inú Ìgbàgbọ́ Tí A Dán Wò
13, 14. Kí ni àwọn kan ti ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ti wà lójú ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́?
13 Bí a bá ti sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá ní tòótọ́, tí a sì ti jáde kúrò nínú ayé, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa wo ohun tí ó wà lẹ́yìn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a rí nínú Lúùkù 9:62, bí ẹnikẹ́ni nínú wa bá bojú wẹ̀yìn ó lè túmọ̀ sí pípàdánù jíjẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Jésù wí pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.”
14 Ṣùgbọ́n àwọn kan tí ó di Kristẹni ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ti ń tẹ̀ lé àṣà ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Wọn kò dènà ẹ̀mí ayé. (2 Pétérù 2:20-22) Àwọn ohun ayé tí ń fa ìpínyà ọkàn ti gba ọkàn àti àkókò wọn, ó sì tipa báyìí dí ìtẹ̀síwájú wọn lọ́wọ́. Kàkà tí wọn yóò fi pa èrò inú àti ọkàn-àyà wọn pọ̀ sórí Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀, kí wọ́n fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé, wọ́n ti yí padà láti máa lépa góńgó ọrọ̀ àlùmọ́nì. Wọ́n wà nínú ewu pípàdánù ipò ìbátan wọn ṣíṣeyebíye pẹ̀lú Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀, àyàfi bí a bá sún wọn láti mọ ipò ìgbàgbọ́ ahẹrẹpẹ àti onílọ̀ọ́wọ́ọ́wọ́ tí wọ́n wà, kí wọ́n sì yí ipa ọ̀nà wọn padà nípa wíwá ìmọ̀ràn àtọ̀runwá.—Ìṣípayá 3:15-19.
15. Kí ni ó ń béèrè láti wà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?
15 Rírí wa gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, tí ó sì wà ní ojú ìlà fún líla ìpọ́njú ńlá tí ń yára bọ̀ kánkán yìí já sinmi lórí wíwà ní mímọ́ tónítóní, ‘fífọ aṣọ wa nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ (Ìṣípayá 7:9-14; 1 Kọ́ríńtì 6:11) Bí a kò bá pa ìdúró òdodo mímọ́ tónítóní níwájú Ọlọ́run mọ́, iṣẹ́ ìsìn wa kò ní ṣe ìtẹ́wọ́gbà. Dájúdájú, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yẹ kí ó mọ̀ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ tí a dán wò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà, kí a sì yẹra fún fífa ìbínú Ọlọ́run.
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni irọ́ fi lè jẹ́ ìdánwò ìgbàgbọ́ wa?
16 Nígbà mìíràn, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn aláṣẹ ayé ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn ènìyàn Ọlọ́run, wọ́n ń gbé ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni àti ọ̀nà ìgbésí ayé wa kalẹ̀ lọ́nà òdì. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí Jésù fi hàn ní kedere pé ‘ayé yóò kórìíra wa nítorí pé àwa kì í ṣe apá kan rẹ̀.’ (Jòhánù 17:14) A óò ha yọ̀ǹda kí àwọn tí Sátánì fọ́ lójú mú wa láyà pami, kí wọ́n mú wa sọ̀rètí nù, kí wọ́n sì mú kí ìhìn rere náà máa tì wá lójú bí? A óò ha fàyè gba irọ́ tí a ń pa mọ́ òtítọ́ láti nípa lórí wíwá sí ìpàdé wa déédéé àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wa bí? Àbí a óò ha dúró gbọn-in, kí a mọ́kàn le, kí a sì túbọ̀ pinnu ju ti ìgbàkigbà rí lọ láti máa bá pípolongo òtítọ́ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ nìṣó?
17. Ìdánilójú wo ni ó lè ru wá sókè láti máa bá fífi ìgbàgbọ́ hàn lọ?
17 Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí a ti mú ṣẹ, nísinsìnyí, a ń gbé ní àkókò tí ó ti wọnú àkókò òpin gan-an. Ó dájú pé àwọn ìfojúsọ́nà wa tí a gbé karí Bíbélì fún ayé tuntun òdodo yóò ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́, tí yóò sì gbádùn mọ́ni. Títí di ọjọ́ náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa lo ìgbàgbọ́ tí kò lè mì nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì fi ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wa hàn nípa ṣíṣàìjuwọ́ sílẹ̀ nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà yíká ayé. Ronú nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tí a ń batisí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìyẹn kò ha tó ìdí fún wa láti mọrírì pé sùúrù Jèhófà nípa mímú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lè yọrí sí ìgbàlà ènìyàn púpọ̀ sí i bí? Inú wa kò ha dùn pé Ọlọ́run ti yọ̀ǹda kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba agbẹ̀mílà máa bá a lọ bí? Inú wa kò ha sì dùn pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà, tí wọ́n sì ń fi ìgbàgbọ́ wọn hàn bí?
18. Kí ni ìpinnu rẹ ní ti sísin Jèhófà?
18 A kò lè sọ bí ìdánwò ìgbàgbọ́ wa ti ìsinsìnyí yóò ti gùn tó. Ṣùgbọ́n ohun kan dájú pé: Jèhófà ní ọjọ́ kan pàtó tí àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé burúkú ti ìsinsìnyí yóò jíhìn. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti fara wé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ tí a dán wò tí Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù, fi hàn. Ẹ sì jẹ́ kí a tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí wọ́n ti ń darúgbó àti ti àwọn mìíràn tí wọ́n ń fi ìgboyà sìn láàárín wa.
19. Kí ni ó dá ọ lójú pé yóò ṣẹ́gun ayé yìí?
19 Ó yẹ kí a pinnu láti polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun náà láìdábọ̀ fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ahọ́n, àti ènìyàn ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú áńgẹ́lì tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run. Ẹ jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìpolongo áńgẹ́lì náà pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.” (Ìṣípayá 14:6, 7) Nígbà tí a bá mú ìdájọ́ àtọ̀runwá náà ṣẹ, kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ ní ti ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa tí a dán wò? Kò ha ní jẹ́ ìjagunmólú ológo—ìdáǹdè kúrò nínú ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí sínú ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run bí? Nípa fífarada ìdánwò ìgbàgbọ́ wa, a óò lè sọ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ti sọ pé: “Èyí . . . ni ìṣẹ́gun tí ó ti ṣẹ́gun ayé, ìgbàgbọ́ wa.”—1 Jòhánù 5:4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ile-Iṣọ Na ti February 1, 1974, ojú ìwé 77-83, àti March 1, 1974, ojú ìwé 149 sí 151.
b Wo Ile-Iṣọ Naa ti January 15, 1984, ojú ìwé 18 sí 22.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni ìdánwò ìgbàgbọ́ wa ṣe lè jẹ́ ìdí fún ayọ̀?
◻ Kí ni díẹ̀ nínú ìdánwò ìgbàgbọ́ wa tí a kò lè tètè fura sí?
◻ Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní pípẹ́ títí nípa bíborí ìdánwò ìgbàgbọ́ wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
A. H. Macmillan (níwájú lápá òsì) ní àkókò tí a fi òun àti àwọn òṣìṣẹ́ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́
Ó jẹ́ àyànṣaṣojú sí àpéjọpọ̀ ní Detroit, Michigan, 1928
Ní àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, Arákùnrin Macmillan ṣì ń fi ìgbàgbọ́ hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gẹ́gẹ́ bí ìdílé yìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni ní Áfíríkà ti fi ìjójúlówó ìgbàgbọ́ tí a dán wò hàn