ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/1 ojú ìwé 8
  • Lílo Gbogbo Àǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílo Gbogbo Àǹfààní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkíìjọba Ròyìn

Lílo Gbogbo Àǹfààní

A MỌ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fún iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí Bíbélì tí wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n wọ́n tún ń ṣe àwọn ètò mìíràn tí ń ṣe àwùjọ láǹfààní. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí láti Ecuador ti fi hàn, àwọn ènìyàn ti fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re yìí.

◻ Àwọn alákòóso ilé iṣẹ́ gíláàsì kan fẹ́ ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù nínú ìdílé fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn. Olùdarí gbogbo òṣìṣẹ́ ké sí àwọn àlùfáà Kátólíìkì mélòó kan láti wá kópa nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò wá. Àlùfáà kan sọ fún un pé, ó ṣeé ṣe kí ó máà sí ẹnikẹ́ni lárọ̀ọ́wọ́tó nítorí pé ìwọ̀nba àlùfáà díẹ̀ ni ó tóótun láti sọ̀rọ̀ lórí kókó náà. Ní gbígbọ́ èyí, òṣìṣẹ́ kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣètò fún arákùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ ní àgbègbè ìpínlẹ̀ iṣẹ́ ajé láti ṣèbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ náà.

Ní ọjọ́ kejì gan-an, Ẹlẹ́rìí náà mú ìlapa èrò lórí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà tọ olùdarí gbogbo òṣìṣẹ́ lọ. Ó kọ àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ jáde láti inú onírúurú ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Ó wú olóòtú náà lórí. Ó yan ẹṣin ọ̀rọ̀ mẹ́ta fún ìjíròrò—ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ìlànà ìwà híhù níbi iṣẹ́, àti ìlànà ìwà híhù nínú ìdílé. Wọ́n ṣètò láti jíròrò ìsọfúnni náà pẹ̀lú gbogbo òṣìṣẹ́ pátá.

Wọ́n pín àwọn òṣìṣẹ́ náà sí ìsọ̀rí méje, 30 ènìyàn ni ó wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin mẹ́ta tí ó tóótun gbé ìsọfúnni náà kalẹ̀ fún wọn. Kí ni ó yọrí sí? Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ní kí a kàn sí àwọn nílé, a sì fi 216 ìwé àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sóde. Inú àwọn alákòóso ilé iṣẹ́ náà dùn débi pé wọ́n béèrè bóyá Àwọn Ẹlẹ́rìí náà yóò lè ṣètò ọ̀wọ́ ìjíròrò mìíràn.

◻ Láìpẹ́ yìí, Ecuador gbé òfin kan jáde tí ó fàyè gba kíkọ́ni ní ọ̀ràn ìsìn ní ilé ẹ̀kọ́. Arábìnrin kan tí ó jẹ́ míṣọ́nnárì bi ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan bí òfin tuntun náà ṣe gbéṣẹ́ tó. Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé pé wọ́n gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ètò kan lórí ìjọsìn Màríà ṣùgbọ́n kò mú èrè kankan wá. Nígbà tí arábìnrin náà sọ pé irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ lè jẹ́ ìṣòro fún àwọn ọmọ tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ọ̀gá náà gbà pé ó lè rí bẹ́ẹ̀. Míṣọ́nnárì náà wí pé: “Ẹ̀wẹ̀, a ní ètò kan fún kíkọ́ni ní àwọn ìlànà ìwà híhù láti inú Bíbélì, kò sì fi òté lé e pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ìsìn kan pàtó.” Ọ̀gá náà fèsì pé: “Nígbà wo ni o lè ráyè wá? Ṣé o lè wà ní ọ̀túnla?” Lẹ́yìn tí míṣọ́nnárì náà fi ìwé náà, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, hàn án, wọ́n pinnu pé àwọn yóò gbé orí náà, “Alayọ Li Awọn Ẹni Alafia,” yẹ̀ wò.

Nígbà tí ó padà dé, míṣọ́nnárì náà lo wákàtí mẹ́ta láti bẹ kíláàsì méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò, ọ̀gá náà sì tẹ́tí sí i. Lẹ́yìn àkókò ìjókòó kan pẹ̀lú kíláàsì karùn-ún, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wí pé: “Omidan, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rí i pé ẹ bẹ kíláàsì kẹfà wò. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń fẹ́ nà wá, kí wọ́n sì bá wa jà!” Olùkọ́ kan sọ pé: “Ìwà ipá jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì. A nílò àkókò púpọ̀ sí i láti jíròrò ọ̀ràn yìí.”

A ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà láti jíròrò àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ bí ìgbọràn àti irọ́ pípa. Títí di ìsinsìnyí, ìyọrísí rẹ̀ dára gan-an. Nísinsìnyí tí arábìnrin tí ó jẹ́ míṣọ́nnárì yìí bá ń lọ nígboro, àwọn ọmọ náà máa ń sáré lọ kí i, wọ́n a sì máa béèrè ìbéèrè Bíbélì lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn mìíràn máa ń fi tayọ̀tayọ̀ sọ fun àwọn òbí wọn pé olùkọ́ àwọn rèé. Ní àfikún sí i, a ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́