Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń Yí Ìsìn Wọn Padà
Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, orúkọ lásán ni ìsìn jẹ́. Ó lè fi ibi tí ẹnì kan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ Sunday, ibi tí ó ti ṣègbéyàwó, àti ibi tí a óò sin ín sí, hàn. Ṣùgbọ́n kì í sọ irú ẹni tí onítọ̀hún jẹ́ tàbí ohun tí ó mọ̀, tí ó sì gbà gbọ́. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí kan fi hàn pé ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ni kò mọ ẹni tí ó ṣe Ìwàásù Orí Òkè. Họ́wù, kódà ìlúmọ̀ọ́ká, aṣáájú ilẹ̀ Íńdíà náà, Mohandas Gandhi, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, mọ̀ ọ́n!
Ó HA yani lẹ́nu pé àwọn ènìyàn ń sú lọ kúrò nínú ìsìn nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn kó mọ ohunkóhun nípa ìsìn wọn? Rárá o, kò yani lẹ́nu. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ó sábà máa ń ya àwọn tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìrànwọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu láti rí bí wọ́n ti jàǹfààní tó. Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.
Kí ni ó yẹ kí àwọn tí kò rí nǹkan ṣe sí ebi tẹ̀mí tí ń pa wọ́n ṣe? Wọn kò ní láti juwọ́ sílẹ̀ nínú sísin Ọlọ́run! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n yẹ Bíbélì wò, kí wọ́n sì rí ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn.
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Tí Ó Takókó
Ní ọmọ ọdún méje, níṣojú Bernd kòrókòró ni ìyá rẹ̀ ṣe kú.a Jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, ó ń kọminú pé, ‘Ìyá mi dà? Èé ṣe tí mo fi ní láti dàgbà láìníyàá?’ Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, Bernd jẹ́ ògbóṣáṣá mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì kan. Nítorí tí ó ń ṣàníyàn nípa ìyà tí ń jẹ aráyé, ó ní in lọ́kàn láti di apèsè ìrànwọ́ ní ilẹ̀ òkèèrè. Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ kò lè dáhùn lọ́nà tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn kó ìdààmú ńláǹlà bá a.
Lẹ́yìn náà, Bernd bá ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Ọ̀dọ́ yìí fi han Bernd láti inú Bíbélì pé ìyá rẹ̀ kò mọ nǹkan kan mọ́, ó ti sùn nínú ikú. Bernd kọ́ nípa ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tí ó ṣàlàyé èyí, irú bí Oníwàásù 9:5: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Nítorí náà, Bernd kò ní ìdí kankan láti dààmú nípa bóyá ìyá rẹ̀ ń jìyà nínú pọ́gátórì kan—tàbí bóyá ohun tí ó burú ju ìyẹn lọ ń ṣẹlẹ̀ sí i. Bí wọ́n tilẹ̀ ń fi ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn kọ́ni nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn, Bernd rí i nínú Bíbélì pé ènìyàn kan ni ó jẹ́ ọkàn kan. Nígbà tí ẹni náà bá sì ti kú, ọkàn rẹ̀ pẹ̀lú ti kú. “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4.
Bernd tún kọ́ nípa ìfojúsọ́nà àgbàyanu fún àwọn òkú. Ó fúnra rẹ̀ kà á nínú ìwé Ìṣe nínú Bíbélì pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ẹ wo bí inú rẹ̀ ti dùn tó láti mọ̀ pé àjíǹde yìí yóò ṣẹlẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, tí Ọlọ́run yóò sọ di párádísè!—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.
Láìpẹ́, a fi ojúlówó ìmọ̀ Bíbélì tẹ́ àìní Bernd nípa tẹ̀mí lọ́rùn. Bernd kò pa ìsìn tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ṣọ́ọ̀ṣì tí kò lè pòùngbẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì tẹ́wọ́ gba irúfẹ́ ìjọsìn tí a gbé ka Bíbélì lọ́nà tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Ó sọ pé: “Ìyẹn jẹ́ ní ọdún 14 sẹ́yìn, n kò sì kábàámọ̀ gbígbé ìgbésẹ̀ náà. Wàyí o, mo mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kì í mú ìyà báni. Sátánì ni ọlọ́run ètò yìí, òun sì ni ó lẹ̀bi àwọn ipò tí ó yí wa ká. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe gbogbo ìpalára tí ayé Sátánì ti ṣe. Ìyá mi pẹ̀lú yóò padà wá nínú àjíǹde. Ẹ wo irú ayọ̀ ńlá tí ìyẹn yóò jẹ́!”
Lọ́nà kan ṣáá, Bernd ti lé góńgó rẹ̀ ti ṣíṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, bá. Ó ń ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè kan, níbi tí ó ti ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ojútùú tòótọ́ fún ipò ìnira wọn. Gẹ́gẹ́ bí Bernd, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run yóò mú òpin dé bá ìyà tí ń jẹ ènìyàn láìpẹ́. Inú wọn dùn láti mọ̀ pé ìsìn kan ń bẹ tí ń tẹ́ àwọn àìní tẹ̀mí wọn lọ́rùn.—Mátíù 5:3.
Kí Ni Ète Ìgbésí Ayé?
Bí apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé ṣe túbọ̀ ń di èyí tí kò ka ìsìn sí ohun pàtàkì mọ́, ọ̀pọ̀ ń béèrè pé, ‘Kí ni ète ìgbésí ayé?’ A óò rí ìdáhùn rẹ̀ nínú Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí Michael ti ṣàwárí rẹ̀. Ní àárín gbùngbùn àwọn ọdún 1970, Michael fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ apániláyà kan. Ète kan ṣoṣo ni ó ní nínú ìgbésí ayé rẹ̀—láti fojú àwọn tí òun gbà pé wọ́n ń ṣokùnfà àìsídàájọ́ òdodo nínú ètò ìjọba olówò bòńbàtà rí màbo. Ó wí pé: “N kì í jáde nílé láìmú ìbọn mi dání. Ète mi ni láti pa àwọn aṣáájú òṣèlú àti olówò bòńbàtà púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ǹ bá ti fi ẹ̀mí mi dí ète yìí.”
Michael kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà tí ó lè ṣàlàyé ohun tí ó jẹ́ ète ìgbésí ayé gan-an. Nítorí náà, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i ní ilé rẹ̀, tí wọ́n sì fi àwọn ìdáhùn tí Bíbélì ní sí ìbéèrè rẹ̀ hàn án, Michael tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé fún ìjọsìn nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò.
Àwọn ọ̀rẹ́ Michael ń tọpinpin ìfẹ́ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní nínú Bíbélì. Michael rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ wá sí ìpàdé ní ọjọ́ Sunday tí ń bọ̀ yìí. Ẹ jókòó fún ìgbà díẹ̀. Bí ẹ kò bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ẹ ń gbọ́, ẹ lè máa lọ sílé.” Lóòótọ́, lẹ́yìn àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú 45, tí a gbé ka Bíbélì, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi gbọ̀ngàn náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn—Susan—kò lọ. Ohun tí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin yìí gbọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn Michael àti Susan ṣègbéyàwó, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Michael sọ pé: “Wàyí o, mo mọ ìdí tí a fi wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà ni ó dá wa. Ète wa gan-an nínú ìgbésí ayé ni láti mọ̀ ọ́n, kí a sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Èyí ni ó ń mú ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ wá!”
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní irú ìgbàgbọ́ lílágbára tí Michael ní. Wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì náà sọ́kàn pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.
Kíkojú Àwọn Ìṣòro Ìgbésí Ayé
Gbogbo wa ni a ń nírìírí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a rí nínú 2 Tímótì 3:1: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” Àwọn ìṣòro “àwọn àkókò lílekoko” wọ̀nyí kò yọ ẹnì kankan sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lè kojú wọn.
Gbé ọ̀ràn Steven àti Olive, tọkọtaya kan, yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ti àwọn mìíràn, àwọn pẹ̀lú ní ìṣòro ìdílé. Steven ṣàlàyé pé: “Ṣe ni olúkúlùkù wa ń ṣe tirẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Góńgó wa àti ọkàn-ìfẹ́ wa yàtọ̀ síra.” Kí ní ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé papọ̀? Steven ń bá a nìṣó pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi bí a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa hàn wá. Fún ìgbà àkọ́kọ́, a kọ́ ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan àti agbatẹnirò. Fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò so wá pọ̀. Wàyí o, a ń gbádùn ìgbéyàwó aláyọ̀, tí ó dúró gbọn-in.”
Ipò Ìbátan Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìíkiri èrò ara ìlú tí a ṣe láìpẹ́ yìí ti fi hàn, ìpín 96 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà ni ó gba Ọlọ́run gbọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sì ń gbàdúrà sí i. Síbẹ̀, ìwádìí mìíràn fi hàn pé iye àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àti sínágọ́gù ti lọ sílẹ̀ gidigidi ní ìlàjì ọ̀rúndún kan. Nǹkan bí ìpín 58 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà sọ pé ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ni àwọn ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, tàbí kó má tilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ rárá. Kò sí àní-àní pé, ìsìn kò tí ì fà wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run. Ìṣòro yìí kò sì mọ sí United States nìkan.
Bavaria ni Linda dàgbà sí. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ní í ṣe, ó sì máa ń gbàdúrà déédéé. Ní ọwọ́ kan náà, ọjọ́ ọ̀la kò fi í lọ́kàn balẹ̀ rárá. Kò mọ ohunkóhun nípa ète Ọlọ́run fún ènìyàn. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 14 péré, Linda pàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ròyìn pé: “Ohun tí wọ́n sọ fà mí mọ́ra púpọ̀, nítorí náà mo tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì, mo sì yára kà wọ́n.” Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, Linda bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wí pé: “Gbogbo ohun tí mo kọ́ nípa Ọlọ́run láti inú Bíbélì pátá ni ó bọ́gbọ́n mu.” Linda kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọmọ ọdún 18.
Kí ní sún Linda láti yí ìsìn rẹ̀ padà? Ó ṣàlàyé pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì mi ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé Ọlọ́run ń bẹ, mo sì kọ́ láti gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n lójú mi kì í ṣe ẹni gidi, ó sì jìnnà sí mi. Kì í ṣe pé ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nínú Bíbélì jẹ́rìí sí ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ràn mí lọ́wọ́ láti wá mọ̀ ọ́n, kí n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nísinsìnyí, mo ní ipò ìbátan ara ẹni tí ó ṣeyebíye pẹ̀lú Ọlọ́run, ohun kan tí ó ṣeyebíye ju ohunkóhun mìíràn lọ.”
Ìsìn Tòótọ́ Tó Bẹ́ẹ̀, Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ!
Ìsìn rẹ ha ń fún ọ ní ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí, tí ó sì fi bí Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé hàn ọ́ bí? Ó ha ń fi ìrètí Bíbélì fún ọjọ́ ọ̀la kọ́ni bí? Ó ha mú kí o ni ipò ìbátan tímọ́tímọ́, tí a gbé ka ìmọ̀ pípéye nínú Bíbélì, pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá bí? Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Kàkà tí ìwọ yóò fi pa ìsìn tì, wá ìjọsìn kan tí a gbé ka Bíbélì lọ́nà tí ó dúró gbọn-in rí. Nígbà náà, ìwọ yóò dà bí àwọn tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn nínú ìwé Aísáyà inú Bíbélì pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: ‘Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun . . . Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu . . . Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.’”—Aísáyà 65:13, 14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn kan lára àwọn orúkọ tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti wá mọ Ọlọ́run, kí a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀