ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 7/1 ojú ìwé 30-31
  • Ará Samáríà Kan Jẹ́ Aládùúgbò Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ará Samáríà Kan Jẹ́ Aládùúgbò Rere
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ará Samáríà Oníyọ̀ọ́nú
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ “Aláàánú Ará Samáríà”?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ará Samaria Aládùúgbò Rere Kan
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ará Samáríà Kan Fi Hàn Pé Òun Láàánú
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ìfẹ́ Aládùúgbò Ṣeéṣe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 7/1 ojú ìwé 30-31

Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Ará Samáríà Kan Jẹ́ Aládùúgbò Rere

NÍ ỌJỌ́ Jésù, kèéta tí a kò fi bò wà láàárín àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí. Nígbà tí ó ṣe, ìwé Mishnah ti àwọn Júù tilẹ̀ tún fi òfin kan kún un, tí ó kà á léèwọ̀ fún àwọn obìnrin, tí í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, láti gbẹ̀bí fún àwọn tí kì í ṣe Júù bí wọ́n bá ń rọbí, níwọ̀n bí èyí yóò ti wulẹ̀ ṣèrànwọ́ láti mú Kèfèrí mìíràn wá sí ayé.—Abodah Zarah 2:1.

Àwọn ará Samáríà bá àwọn Júù tan ju àwọn Kèfèrí lọ, ní ti ìsìn àti ní ti ẹ̀yà ìran. Síbẹ̀, ojú àtọ̀húnrìnwá ni wọ́n fi ń wo àwọn náà. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Àwọn Júù kì í ní ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.” (Jòhánù 4:9) Ní tòótọ́, Talmud kọ́ni pé “ègé búrẹ́dì kan tí ará Samáríà bá fúnni kún fún àìmọ́ ju ẹran ẹlẹ́dẹ̀ lọ.” Àwọn Júù kan tilẹ̀ lo ọ̀rọ̀ náà “ará Samáríà” gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ìṣáátá.—Jòhánù 8:48.

Bí ọ̀ràn náà ṣe wá rí yìí, ọ̀rọ̀ tí Jésù bá ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú òfin àwọn Júù sọ kún fún ẹ̀kọ́. Ọkùnrin náà tọ Jésù wá, ó sì bi í pé: “Olùkọ́, nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ní fífèsì, Jésù pe àfiyèsí rẹ̀ sí Òfin Mósè, tí ó pàṣẹ pé kí a ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, gbogbo ọkàn, gbogbo okun, àti gbogbo èrò inú,’ kí a sì ‘nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ Amòfin náà wá bi Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” (Lúùkù 10:25-29; Léfítíkù 19:18; Diutarónómì 6:5) Gẹ́gẹ́ bí àwọn Farisí ti sọ, àwọn tí ń pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù mọ́ ni a lo ọ̀rọ̀ náà “aládùúgbò” fún—dájúdájú kì í ṣe fún àwọn Kèfèrí tàbí àwọn ará Samáríà. Bí amòfin atọpinpin yìí bá rò pé Jésù yóò kín ojú ìwòye yẹn lẹ́yìn, ohun tí yóò gbọ́ yóò yà á lẹ́nu.

Ará Samáríà Oníyọ̀ọ́nú

Jésù dáhùn ìbéèrè ọkùnrin náà nípa lílo àkàwé kan.a Ó wí pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò.” Nǹkan bí kìlómítà 23 ni ó wà láàárín Jerúsálẹ́mù àti Jẹ́ríkò. Àwọn kọ́nà kọrọdọ àti àwọn àpáta gbágungbàgun tí ó yọ gọnbu pọ̀ lójú ọ̀nà tí ó so ìlú méjèèjì yìí pọ̀, èyí tí ó mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn olè láti máa rí ibi fara pa mọ́ sí, kí wọ́n tibẹ̀ kọ luni, kí wọ́n sì sá lọ. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá rí, arìnrìn àjò nínú àkàwé Jésù “bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán.”—Lúùkù 10:30.

Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní ìṣekòńgẹ́, àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ojú ọ̀nà yẹn, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ. Bákan náà, ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó sọ̀ kalẹ̀ dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ.” (Lúùkù 10:31, 32) Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì jẹ́ olùkọ́ Òfin—títí kan òfin ìfẹ́ fún aládùúgbò. (Léfítíkù 10:8-11; Diutarónómì 33:1, 10) Dájúdájú, àwọn gan-an ni ó yẹ kí ó kà á sí ojúṣe wọn láti ṣaájò arìnrìn àjò tí a ṣe léṣe náà.

Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ará Samáríà kan tí ó ń rin ìrìn àjò gba ojú ọ̀nà náà ṣàdédé bá a pàdé.” Kò sí iyèméjì pé mímẹ́nukan ará Samáríà ru ìfẹ́ ìtọpinpin amòfin náà sókè. Jésù yóò ha tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye òdì ti àwọn ẹ̀yà ìran rẹ̀ bí? Ní òdì-kejì, nígbà tí ó rí arìnrìn àjò tí ó rin àrìnfẹsẹ̀sí náà, “àánú ṣe” ará Samáríà náà. Jésù wí pé: “Nítorí náà, ó sún mọ́ ọn, ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn. Lẹ́yìn náà, ó gbé e gun orí ẹranko tirẹ̀, ó sì gbé e wá sí ilé èrò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀.b Ó sì mú owó dínárì méjì jáde ní ọjọ́ kejì, ó fi fún olùtọ́jú ilé èrò náà, ó sì wí pé, ‘Tọ́jú rẹ̀, ohun yòówù tí ìwọ bá sì ná ní àfikún sí èyí, èmi yóò san án padà fún ọ nígbà tí mo bá padà wá síhìn-ín.’”—Lúùkù 10:33-35.

Jésù wá bi ẹni tí ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò pé: “Lójú tìrẹ, ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” Amòfin náà mọ ìdáhùn, síbẹ̀ ó jọ pé ó lọ́ tìkọ̀ láti sọ pé “ará Samáríà.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wulẹ̀ fèsì pé: “Ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú.” Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.”—Lúùkù 10:36, 37.

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n

Ọkùnrin tí ń bi Jésù ní ìbéèrè ṣe bẹ́ẹ̀ láti lè “fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo.” (Lúùkù 10:29) Bóyá ó rò pé Jésù yóò gbóríyìn fún òun fún rírọ̀ tí òun rọ̀ pinpin mọ́ Òfin Mósè. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí ọ̀gbẹ́ni tí ó jọ ara rẹ̀ lójú yìí mọ̀ pé òtítọ́ ni òwe Bíbélì tí ó sọ pé: “Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dúró ṣánṣán lójú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà ni ó ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà.”—Òwe 21:2.

Àkàwé Jésù fi hàn pé ẹni tí ó dúró ṣánṣán ní tòótọ́ ni ẹni tí kì í ṣe pé ó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n, tí ó tún ń fara wé àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Éfésù 5:1) Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) A ha ń fara wé Ọlọ́run lọ́nà yìí bí? Àkàwé Jésù tí ó ru ìmọ̀lára sókè fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀ràn orílẹ̀-èdè, àṣà ìbílẹ̀, àti ìsìn dí ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́. Ní tòótọ́, a fún àwọn Kristẹni ní ìtọ́ni láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn”—kì í ṣe sí kìkì àwọn ènìyàn tí a jọ wà ní ipò kan náà ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ẹ̀ya ìran, tàbí orílẹ̀-èdè, kì í sì í ṣe sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nìkan.—Gálátíà 6:10.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń làkàkà láti tẹ̀ lé ìṣílétí Ìwé Mímọ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjábá ti ìṣẹ̀dá bá ṣẹlẹ̀, bí wọ́n ti ń nawọ́ ìrànwọ́ afẹ́dàáfẹ́re sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń nà án sí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.c Ní àfikún sí i, wọ́n ń pawọ́ pọ̀ lo wákàtí tí ó lé ní bílíọ̀nù kan lọ́dọọdún láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti wá ní ìmọ̀ tí ó jíire nípa Bíbélì. Wọ́n ń làkàkà láti mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ ẹni gbogbo, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4; Ìṣe 10:35.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àkàwé máa ń kúrú, lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń jẹ́ ìtàn àròsọ nínú èyí tí a ti lè fa òtítọ́ ti ìwà rere tàbí ohun tẹ̀mí jáde.

b Ní ọjọ́ Jésù, kì í ṣe ibi ibùwọ̀ nìkan ni àwọn ilé èrò máa ń pèsè, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń pèsè oúnjẹ àti àwọn nǹkan mìíràn. Ó lè jẹ́ irú ibùwọ̀ yìí ni Jésù ní lọ́kàn, nítorí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a lò níhìn-ín yàtọ̀ sí èyí tí a lò fún “yàrá ibùwọ̀” nínú Lúùkù 2:7.

c Fún àpẹẹrẹ, wo Ilé Ìṣọ́, December 1, 1996, ojú ìwé 3 sí 8, àti January 15, 1998, ojú ìwé 3 sí 7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́