Tíkíkù—Ẹrú Ẹlẹgbẹ́ Ẹni Tí Ó Ṣeé Fọkàn Tán
Ọ̀PỌ̀ ìgbà ni Tíkíkù ti bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò, tí ó sì ṣe ońṣẹ́ rẹ̀. Ó jẹ́ ikọ̀ tí a lè fi owó àti ẹrù iṣẹ́ àbójútó lé lọ́wọ́. Níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ ti tẹnu mọ́ ìṣeégbẹ́kẹ̀lé rẹ̀—ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì fún gbogbo Kristẹni—bóyá ìwọ yóò fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀.
Pọ́ọ̀lù pe Tíkíkù ní “arákùnrin mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ àti ẹrú ẹlẹgbẹ́ mi nínú Olúwa.” (Kólósè 4:7) Èé ṣe tí àpọ́sítélì náà fi kà á sí irú èèyàn bẹ́ẹ̀?
Ètò Ìrànwọ́ fún Jerúsálẹ́mù
Àìní nípa tara dìde láàárín àwọn Kristẹni ní Jùdíà ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìjọ ní Yúróòpù àti Éṣíà Kékeré, Pọ́ọ̀lù ṣètò ìdáwó láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Tíkíkù, tí ó wá láti àgbègbè Éṣíà, kópa pàtàkì nínú ètò a-dín-ṣòro-kù náà.
Lẹ́yìn pípèsè ìtọ́ni nípa bí a ó ṣe ṣètò ìdáwó yìí, Pọ́ọ̀lù dá a lábàá pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n bá rí kó jọ rán àwọn arákùnrin tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé lọ sí Jerúsálẹ́mù tàbí kí àwọn jọ lọ. (1 Kọ́ríńtì 16:1-4) Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò gígùn náà láti Gíríìsì lọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn ọkùnrin mélòó kan bá a lọ, Tíkíkù sì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. (Ìṣe 20:4) Ó pọndandan láti kẹ́gbẹ́ rìn nítorí pé wọ́n gbé owó tí àwọn ìjọ mélòó kan fi lé wọn lọ́wọ́ dání. Ìdí pàtàkì fún èyí lè jẹ́ nítorí ààbò, níwọ̀n bí àwọn dánàdánà ti ń dá àwọn ènìyàn lọ́nà.—2 Kọ́ríńtì 11:26.
Níwọ̀n bí Àrísítákọ́sì àti Tírófímù ti bá Pọ́ọ̀lù lọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn kan ronú pé ó jọ pé Tíkíkù àti àwọn yòókù bá wọn lọ pẹ̀lú. (Ìṣe 21:29; 24:17; 27:1, 2) Nítorí pé Tíkíkù lọ́wọ́ nínú ètò a-dín-ṣòro-kù yìí, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mélòó kan tí a gbà pé a pè ní “arákùnrin” tí ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Títù ní Gíríìsì láti ṣètò ìdáwó náà, ẹni tí “ìjọ yàn . . . pé kí ó jẹ́ alájọrin ìrìn àjò [Pọ́ọ̀lù] ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn inú rere yìí.” (2 Kọ́ríńtì 8:18, 19; 12:18) Bí iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Tíkíkù ṣe bá jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ rẹ̀ kejì.
Láti Róòmù sí Kólósè
Ọdún márùn-ún tàbí mẹ́fà lẹ́yìn náà (60 sí 61 Sànmánì Tiwa), Pọ́ọ̀lù ń retí pé a óò tú òun sílẹ̀ nígbà tí a kọ́kọ́ fi í sẹ́wọ̀n ní Róòmù. Tíkíkù wà pẹ̀lú rẹ̀, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ilé rẹ̀. Wàyí o, Tíkíkù ń padà sí Éṣíà. Èyí jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ Kristẹni tó wà ní àgbègbè yẹn àti láti dá Ónẹ́símù, ìsáǹsá ẹrú Fílémónì, padà sí Kólósè. Ó kéré tán, Tíkíkù àti Ónẹ́símù kó lẹ́tà mẹ́ta tí ó jẹ́ apá kan ìwé Bíbélì nísinsìnyí—ọ̀kan sí àwọn ará Éfésù, ọ̀kan sí àwọn ará Kólósè, àti ọ̀kan sí Fílémónì. Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n fi lẹ́tà kan jíṣẹ́ fún ìjọ tó wà ní Laodíkíà, ìlú tó wà ní nǹkan bí kìlómítà 18 sí Kólósè.—Éfésù 6:21; Kólósè 4:7-9, 16; Fílémónì 10-12.
Tíkíkù kì í kàn-án ṣe a-kó-lẹ́tà. Ońṣẹ́ tí a fọkàn tán ni, nítorí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn àlámọ̀rí mi ni Tíkíkù, arákùnrin mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ àti ẹrú ẹlẹgbẹ́ mi nínú Olúwa, yóò sọ di mímọ̀ fún yín. Fún ète náà gan-an pé kí ẹ lè mọ àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wa àti pé kí òun lè tu ọkàn-àyà yín nínú, ni mo ṣe ń rán an sí yín”—Kólósè 4:7, 8.
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, E. Randolph Richards, fi hàn pé ẹni tí a fi lẹ́tà rán “sábà máa ń ṣojú fún ẹni tí ó kọ lẹ́tà àti ẹni tí a kọ ọ́ sí, ní àfikún sí ìwé tí ó pa wọ́n pọ̀. . . . [Ìdí kan] tí ó fi pọndandan láti fi rán ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni [pé] a sábà máa ń fún un ní àfikún ìsọfúnni. Lẹ́tà kan lè ṣe àlàyé ṣókí nípa ọ̀ràn kan, tí ó sábà máa ń jẹ́ bí ọ̀ràn náà ti rí lójú ẹni tó kọ lẹ́tà, ṣùgbọ́n a retí pé kí ẹni tí ó mú lẹ́tà wá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé fún ẹni tó mú lẹ́tà wá fún.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́tà kan lè dálé ọ̀ràn ẹ̀kọ́ àti ọ̀ràn kánjúkánjú, ońṣẹ́ tí a fọkàn tán ni yóò sọ àwọn nǹkan yòókù.
Àwọn lẹ́tà tí a kọ sí àwọn ará Éfésù, Kólósè, àti Fílémónì kò sọ púpọ̀ nípa ipò àlàáfíà Pọ́ọ̀lù. Nípa báyìí, Tíkíkù ti ní láti sọ ohun tí ó mọ̀, kí ó ṣàlàyé ipò Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, kí ó sì mòye ipò tó wà nínú àwọn ìjọ, kí ó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti pèsè ìṣírí. Kìkì àwọn tí a fọkàn tán pé wọn yóò fi ìṣòtítọ́ ṣojú ẹni tó rán wọn ni a ń fún ní irú àwọn ìhìn àti ẹrù iṣẹ́ báwọ̀nyí. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni Tíkíkù.
Iṣẹ́ Àbójútó Nílẹ̀ Jíjìnnà Réré
Lẹ́yìn tí a fòpin sí sísé Pọ́ọ̀lù mọ́lé ní Róòmù, ó ronú nípa rírán Tíkíkù tàbí Átémásì lọ bá Títù ní erékùṣù Kírétè. (Títù 1:5; 3:12) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù lẹ́ẹ̀kejì (bóyá ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa), àpọ́sítélì náà tún rán Tíkíkù lọ sí Éfésù, bóyá láti lọ rọ́pò Tímótì, kí ó lè wá dúró ti Pọ́ọ̀lù.—2 Tímótì 4:9, 12.
Bóyá Tíkíkù lọ sí Kírétè àti Éfésù lákòókò yìí kò ṣe kedere. Síbẹ̀síbẹ̀, irú ìtọ́ka báwọ̀nyí fi hàn pé ó ń bá a lọ ní jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù tímọ́tímọ́ títí di àwọn ọdún tó gbẹ̀yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ àpọ́sítélì náà. Bí Pọ́ọ̀lù bá ń ronú láti rán an lọ ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì tó sì nira, dípò kí ó rán Tímótì àti Títù, ó ṣe kedere pé Tíkíkù ti di Kristẹni alábòójútó tó dàgbà dénú. (Fi wé 1 Tímótì 1:3; Títù 1:10-13.) Ìmúratán rẹ̀ láti rìnrìn àjò àti láti gbà pé kí a lo òun fún àwọn iṣẹ́ àyànfúnni tó jìnnà jẹ́ kí ó wúlò fún Pọ́ọ̀lù àti ìjọ Kristẹni lápapọ̀.
Lónìí, àwọn Kristẹni olùfara-ẹni-rúbọ ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ní àwọn ìjọ àdúgbò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tàbí wọn ń yọ̀ǹda ara wọn fún gbígbé ire Ìjọba náà ga níbòmíràn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àyànfúnni gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì, alábòójútó arìnrìn àjò, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ní ilẹ̀ òkèèrè, ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Watch Tower Society, tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Tíkíkù, wọn kì í ṣe gbajúmọ̀, ṣùgbọ́n òṣìṣẹ́ kára ni wọ́n, ‘àwọn olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́’ tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run, tí àwọn Kristẹni yòókù sì nífẹ̀ẹ́ bí ‘àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ ẹni’ tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ‘nínú Olúwa.’