ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 9/1 ojú ìwé 8-13
  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ètò Àjọ Jèhófà
  • A Dáàbò Bò Wá Nínú Ètò Àjọ Ọlọ́run—Lọ́nà Wo?
  • Àwọn Wo Ni Wọ́n Wà Nínú Ètò Àjọ Ọlọ́run?
  • Ìṣọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ayé
  • Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Bá Ètò Jèhófà Rìn Bó Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Jèhófà Ló Ń Darí Ètò Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Darí Ètò Rẹ̀?
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 9/1 ojú ìwé 8-13

Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run

“Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.”—ÒWE 18:10.

1. Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Jésù, ipò ìṣòro wo ni àwọn Kristẹni wà nínú rẹ̀?

KÉTÉ kí Jésù tó kú, ó gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Pẹ̀lú ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́, ó wí pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 17:14, 15) Jésù mọ̀ pé ayé yóò jẹ́ ibi eléwu fún àwọn Kristẹni. Ayé yóò fi hàn pé òun kórìíra wọn nípa píparọ́ mọ́ wọn àti ṣíṣe inúnibíni sí wọn. (Mátíù 5:11, 12; 10:16, 17) Yóò tún jẹ́ orísun ìwà ìbàjẹ́.—2 Tímótì 4:10; 1 Jòhánù 2:15, 16.

2. Ibo ni àwọn Kristẹni ti lè rí ààbò nípa tẹ̀mí?

2 Àwọn tí wọ́n sọ ara wọn dàjèjì sí Ọlọ́run àti àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ìdarí Sátánì ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ayé tí yóò kòrìíra àwọn Kristẹni. (1 Jòhánù 5:19) Ayé yìí tóbi ju ìjọ Kristẹni lọ dáadáa, Sátánì alára gan-an sì lágbára ju ènìyàn èyíkéyìí lọ dáadáa. Nítorí náà, ìkórìíra tí ayé ní jẹ́ ewu ní tòótọ́. Ibo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti lè rí ààbò nípa tẹ̀mí? Ọ̀rọ̀ kan nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1922, (Gẹ̀ẹ́sì) dáhùn ìbéèrè náà pé: “Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni a ń gbé yìí. Ìjà ń lọ lọ́wọ́ láàárín ètò àjọ Sátánì àti ètò àjọ Ọlọ́run. Ìjà ọ̀hún le kú.” Nínú ìjà yìí, ètò àjọ Ọlọ́run ni ibi ààbò nípa tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ náà “ètò àjọ” kò fara hàn nínú Bíbélì, bí a bá sí padà sí àwọn ọdún 1920, “ètò àjọ Ọlọ́run” jẹ́ èdè tuntun nígbà náà. Kí wá ni ètò àjọ yìí? Báwo sì ni a ṣe lè rí ààbò nínú rẹ̀?

Ètò Àjọ Jèhófà

3, 4. (a) Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan àti Ilé Ìṣọ́ ti sọ, ki ni ètò àjọ? (b) Lọ́nà wo ni a lè gbà pe ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ní ètò àjọ?

3 Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Concise Oxford Dictionary, ti sọ, ètò àjọ túmọ̀ sí “ẹgbẹ́ kan tí a ṣètò.” Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, a mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí àwọn àpọ́sítélì ti ṣètò àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sínú àwọn ìjọ àdúgbò lábẹ́ àbójútó ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù, ó tọ́ láti pe “ẹgbẹ́ àwọn ará” yẹn ní ètò àjọ kan. (1 Pétérù 2:17) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ní irú ìṣètò bẹ́ẹ̀. “Àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn,” àwọn bí “olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,” fún ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ti ọ̀rúndún kìíní lókun. Àwọn kan lára àwọn wọ̀nyí rìnrìn àjò láti ìjọ kan sí ìkejì, nígbà tí àwọn mìíràn sì jẹ́ alàgbà nínú àwọn ìjọ àdúgbò. (Éfésù 4:8, 11, 12; Ìṣe 20:28) Irú “àwọn ẹ̀bùn” bẹ́ẹ̀ ń fún ìṣọ̀kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lókun lónìí.

4 Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti November 1, 1922, (Gẹ̀ẹ́sì) sọ nípa ọ̀rọ̀ náà, “ètò àjọ” pé: “Ètò àjọ jẹ́ àgbájọ àwọn ènìyàn tí ó wà fún ète mímú ìwéwèé kan pàtó ṣẹ.” Ilé Ìṣọ́ ọ̀hún ń bá a lọ láti ṣàlàyé pé, pípe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ètò àjọ kan kò sọ wọ́n di “ẹ̀ya ìsìn ní ọ̀nà tí a gbà ń lo ọ̀rọ̀ yẹn, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ túmọ̀ sí pé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ń sakun láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ, kí wọ́n sì ṣe é bí Olúwa ti ń ṣe ohun gbogbo, létòlétò.” (1 Kọ́ríńtì 14:33) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé nígbà ayé rẹ̀ àwọn Kristẹni hùwà lọ́nà tí ó wà létòlétò bákan náà. Ó fi àjọṣe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé ara ènìyàn, tí ó ní ẹ̀yà púpọ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un kí ara náà bàa lè ṣiṣẹ́ dáadáa. (1 Kọ́ríńtì 12:12-26) Àkàwé títayọ lọ́lá ni ìyẹn mà jẹ́ nípa ètò àjọ kan o! Èé ṣe tí a fi ṣètò àwọn Kristẹni? Láti lè mú “ète Ọlọ́run” ṣẹ ni, láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà.

5. Kí ni ètò àjọ Ọlọ́run tí ó ṣeé fojú rí?

5 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ yóò wà ní ìṣọ̀kan lónìí, a óò mú gbogbo wọn wá sí “ilẹ̀” kan gẹ́gẹ́ bí “orílẹ̀-èdè” kan, níbi tí wọn yóò ti máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Aísáyà 66:8; Fílípì 2:15) “Orílẹ̀-èdè” tí a ṣètò yìí ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àbọ̀ báyìí. (Aísáyà 60:8-10, 22) Ṣùgbọ́n, ètò àjọ Ọlọ́run kò mọ síbẹ̀ yẹn. Àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú wà nínú rẹ̀.

6. Lọ́nà gbígbòòrò jù lọ, àwọn wo ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ètò àjọ Ọlọ́run?

6 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló wà. (Jẹ́nẹ́sísì 28:12; Dáníẹ́lì 10:12-14; 12:1; Hébérù 1:13, 14; Ìṣípayá 14:14-16) Nígbà náà, lọ́nà yíyẹ, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ May 15, 1925, (Gẹ̀ẹ́sì) wí pé: “Gbogbo áńgẹ́lì mímọ́ jẹ́ apá kan ètò àjọ Ọlọ́run.” Ní àfikún sí i, ó wí pé: “Olúwa Jésù Kristi [ni] orí ètò àjọ Ọlọ́run, tí gbogbo agbára àti ọlá àṣẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Mátíù 28:18) Nítorí náà, lọ́nà gbígbòòrò, àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ètò àjọ Ọlọ́run. (Wo àpótí.) Ẹ wo àǹfààní àgbàyanu tí ó jẹ́ láti jẹ́ apá kan èyí! Ẹ sì wo bí ó ti mú inú ẹni dùn tó láti máa fojú sọ́nà fún àkókò náà nígbà tí a óò ṣètò gbogbo ẹ̀dá alààyè, tọ̀run àti tayé, láti yin Jèhófà Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan! (Ìṣípayá 5:13, 14) Ṣùgbọ́n, ààbò wo ni ètò àjọ Ọlọ́run ń pèsè lónìí?

A Dáàbò Bò Wá Nínú Ètò Àjọ Ọlọ́run—Lọ́nà Wo?

7. Ọ̀nà wo ni ètò àjọ Ọlọ́run gbà ń dáàbò bò wá?

7 Ètò àjọ Ọlọ́run lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ Sátánì àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀. (Éfésù 6:11) Sátánì ń gbógun, ó ń ṣenúnibíni, ó ń dán àwọn olùjọsìn Jèhófà wò pẹ̀lú góńgó kan ṣoṣo lọ́kàn: láti fà wọ́n kúrò ‘lójú ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n máa rìn.’ (Aísáyà 48:17; fi wé Mátíù 4:1-11.) A kò lè yẹra pátápátá fún àwọn àtakò wọ̀nyẹn nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Àmọ́ ṣá o, níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti ètò àjọ rẹ̀ ń fún wa lókun, ó ń dáàbò bò wá, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní “ọ̀nà [náà].” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a kò ní pàdánù ohun tí a ń retí.

8. Báwo ni ètò àjọ Jèhófà tí a kò lè fojú rí ṣe ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn?

8 Báwo ni ètò àjọ Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bò wá? Lákọ̀ọ́kọ́, a ní ìtìlẹyìn tí kì í yẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, ìránṣẹ́ Jèhófà. Nígbà tí Jésù kojú pákáǹleke tí ó lékenkà, áńgẹ́lì kan ṣe ìránṣẹ́ fún un. (Lúùkù 22:43) Nígbà tí ikú fẹjú mọ́ Pétérù, áńgẹ́lì kan yọ ọ́ lọ́nà ìyanu. (Ìṣe 12:6-11) Bí kò tilẹ̀ sí irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ mọ́ lónìí, a ṣèlérí irú ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn Jèhófà nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wọn. (Ìṣípayá 14:6, 7) Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ní okun ní ìwọ̀n tí ó ju ti ẹ̀dá lọ nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìṣòro. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ní àfikún sí i, wọ́n mọ̀ pé “áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7.

9, 10. Ọ̀nà wo ni a lè gbà sọ pé “orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára,” báwo sì ni ìlànà yìí ṣe kan ètò àjọ Ọlọ́run lápapọ̀?

9 Ètò àjọ Jèhófà tí ó ṣeé fojú rí tún jẹ́ ààbò. Lọ́nà wo? Nínú Òwe 18:10, a kà pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Èyí kò wulẹ̀ túmọ̀ sí pé wíwulẹ̀ máa pé orúkọ Ọlọ́run ṣáá yóò pèsè ààbò. Kàkà bẹ́ẹ̀, sísá tí a sádi orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fúnra rẹ̀. (Sáàmù 20:1; 122:4) Ó túmọ̀ sí kíkọ́wọ́ ti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, gbígbé òfin àti ìlànà rẹ̀ lárugẹ, àti níní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀. (Sáàmù 8:1-9; Aísáyà 50:10; Hébérù 11:6) Ó kan fífún Jèhófà ní ìjọsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé. Kìkì àwọn tí ń jọ́sìn Jèhófà ní ọ̀nà yìí ni ó lè sọ bí ti onísáàmù náà pé: “Ọkàn-àyà wa ń yọ̀ nínú [Jèhófà]; nítorí tí a gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.”—Sáàmù 33:21; 124:8.

10 Gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ètò àjọ Ọlọ́run tí a lè fojú rí ń sọ pẹ̀lú Míkà nísinsìnyí pé: “Àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tí Bíbélì pè ní “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” jẹ́ apá pàtàkì ètò àjọ ti òde òní. (Gálátíà 6:16; Ìṣe 15:14; Aísáyà 43:6, 7; 1 Pétérù 2:17) Nítorí náà, wíwà nínú ètò àjọ Jèhófà túmọ̀ sí wíwà nínú àwọn tí ń wá ààbò ní orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń rí i gbà.

11. Àwọn ọ̀nà pàtó wo ni ètò àjọ Jèhófà gbà ń pèsè ààbò fún àwọn tí wọ́n wà nínú rẹ̀?

11 Ní àfikún sí i, ètò àjọ Ọlọ́run tí a lè fojú rí jẹ́ àwùjọ àwọn onígbàgbọ́, ẹgbẹ́ àwọn onígbàgbọ́ tí ń gbé ara wọn ró, tí wọ́n sì ń fún ara wọn níṣìírí. (Òwe 13:20; Róòmù 1:12) Ó jẹ́ ibì kan tí àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ti ń bójú tó àwọn àgùntàn, tí wọ́n ti ń fún àwọn tí ń ṣàìsàn àti àwọn tí ó sorí kọ́ ní ìṣírí, tí wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti mú àwọn tí ó ti ṣubú padà bọ̀ sípò. (Aísáyà 32:1, 2; 1 Pétérù 5:2-4) “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nípasẹ̀ ètò àjọ náà. (Mátíù 24:45) “Ẹrú” yẹn, tí ó jẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ń pèsè àwọn ohun tí ó dára jù lọ nínú ohun tẹ̀mí—ìmọ̀ pípéye tí a gbé ka Bíbélì tí ó lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Nípasẹ̀ ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ “ẹrú” náà, a ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere, kí wọ́n sì “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí [wọ́n] jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà” nínú àgbègbè eléwu tí ó yí wọn ká. (Mátíù 10:16) Ìgbà gbogbo sì ni a ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa,” tí ìyẹn fúnra rẹ̀ jẹ́ ààbò lílágbára.—1 Kọ́ríńtì 15:58.

Àwọn Wo Ni Wọ́n Wà Nínú Ètò Àjọ Ọlọ́run?

12. Àwọn wo ni a mọ̀ pé wọ́n wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run ti òkè ọ̀run?

12 Níwọ̀n bí ààbò yìí ti wà fún àwọn tí wọ́n wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run, àwọn wo ni èyí ní nínú? Ní ti ètò àjọ ti òkè ọ̀run, ìdáhùn ìbéèrè yìí kò fa iyèméjì. Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ kò sí lọ́run mọ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́ ṣì wà níbẹ̀ “ní àpéjọ gbogbogbòò.” Àpọ́sítélì Jòhánù rí i pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” àwọn kérúbù (“àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin”), àti “ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì” yóò sún mọ́ ìtẹ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí. Àwọn alàgbà 24—tí ó dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọnnì tí wọ́n ti wọnú ògo ogún wọn ti ọ̀run—yóò sì wà pẹ̀lú wọn. (Hébérù 12:22, 23; Ìṣípayá 5:6, 11; 12:7-12) Ó ṣe kedere pé, gbogbo wọn pátá wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, láàárín ènìyàn, ọ̀ràn náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere.

13. Báwo ni Jésù ṣe fi àwọn tí ó wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò sí nínú rẹ̀ hàn?

13 Jésù sọ nípa àwọn kan tí yóò máa sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé e pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:22, 23) Bí ẹnì kan bà jẹ́ oníwà àìlófin, ó dájú pé kò sí nínú ètò àjọ Ọlọ́run, ohun yòówù tí ì báà sọ pé òun jẹ́, ibi yòówù tí ì báà sì sọ pé òun ti ń jọ́sìn. Jésù tún fi bí a ṣe lè dá ẹni tí ó wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run mọ̀ hàn. Ó wí pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.”—Mátíù 7:21.

14. Apá wo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run ni ó pọndandan fún àwọn tí ó wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run?

14 Nítorí náà, láti wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run—èyí tí “ìjọba ọ̀run” jẹ́ apá pàtàkì rẹ̀—onítọ̀hún gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kí wá ni ìfẹ́ rẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ apá pàtàkì kan nínú rẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “ó jẹ́ ìfẹ́ [Ọlọ́run] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Bí ẹnì kan bá ń fẹ́ láti ní ìmọ̀ pípéye láti inú Bíbélì ní tòótọ́, tí ó fẹ́ lò ó nínú ìgbésí ayé rẹ̀, tí ó sì fẹ́ mú un dé ọ̀dọ̀ “gbogbo onírúurú ènìyàn,” ó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 28:19, 20; Róòmù 10:13-15) Ìfẹ́ Ọlọ́run tún ni pé kí a bọ́ àwọn àgùntàn Jèhófà, kí a sì tọ́jú wọn. (Jòhánù 21:15-17) Àwọn ìpàdé Kristẹni ń kó ipa pàtàkì nínú èyí. Ẹnì kan tí ó lómìnira láti máa lọ sí irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò kà á sí, kò mọrírì ipò rẹ̀ nínú ètò àjọ Ọlọ́run.—Hébérù 10:23-25.

Ìṣọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ayé

15. Ìkìlọ̀ wo ni Jákọ́bù fún àwọn ìjọ ní ọjọ́ rẹ̀?

15 Ní nǹkan bí 30 ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú, Jákọ́bù, iyèkan rẹ̀, mẹ́nu kan àwọn kókó kan tí ó lè wu ipò ẹni nínú ètò àjọ Ọlọ́run léwu. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Dájúdájú, ẹni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run kò sí nínú ètò àjọ rẹ̀. Nígbà náà, kí ni ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé? A ti ṣàlàyé rẹ̀ pé ó lè jẹ́ onírúurú ọ̀nà, bí fífẹ́ láti máa kó ẹgbẹ́ búburú àti ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn. Ní àfikún sí i, Jákọ́bù darí àfiyèsí sí ohun kan pàtó—ẹ̀mí ìrònú òdì tí ń yọrí sí ìwà àìtọ́.

16. Kí ni àyíká ọ̀rọ̀ Jákọ́bù pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run?

16 Nínú Jákọ́bù 4:1-3, a kà pé: “Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín? Wọn kì í ha ṣe láti orísun yìí, èyíinì ni, láti inú àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara èyí tí ń bá ìforígbárí nìṣó nínú àwọn ẹ̀yà ara yín? Ẹ ń fẹ́, síbẹ̀ ẹ kò ní. Ẹ ń bá a lọ ní ṣíṣìkàpànìyàn àti ní ṣíṣojúkòkòrò, síbẹ̀ ẹ kò lè rí gbà. Ẹ ń bá a lọ ní jíjà, ẹ sì ń ja ogun. Ẹ kò ní nítorí tí ẹ kì í béèrè. Ẹ ń béèrè, síbẹ̀ ẹ kò rí gbà, nítorí tí ẹ ń béèrè fún ète tí kò tọ́, kí ẹ lè lò ó lórí àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.” Lẹ́yìn tí Jákọ́bù ti kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kìlọ̀ nípa ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé.

17. Lọ́nà wo ni “ogun” àti “ìjà” fi wà nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní?

17 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tí Jákọ́bù ti kú, àwọn èké Kristẹni bá ara wọn jagun, wọ́n sì pa ara wọn ní ti gidi. Àmọ́ ṣá o, àwọn mẹ́ńbà “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ọ̀rúndún kìíní, tí yóò jẹ́ ‘àlùfáà àti ọba’ ti ọ̀run, ni Jákọ́bù ń kọ̀wé sí. (Ìṣípayá 20:6) Wọn kò pa ara wọn ní ti gidi, wọn kò sì gbẹ̀mí ara wọn nínú ogun. Èé ṣe tí Jákọ́bù fi wá ń sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni? Tóò, àpọ́sítélì Jòhánù pe ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ní apànìyàn. Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú sọ pé gbúngbùngbún àti aáwọ̀ nínú ìjọ jẹ́ “ìjà” àti “gbọ́nmi-si omi-ò-to.” (Títù 3:9; 2 Tímótì 2:14; 1 Jòhánù 3:15-17) Pẹ̀lú èyí, ó ṣe kedere pé ohun tí Jákọ́bù ní lọ́kàn ni kíkọ̀ láti nífẹ̀ẹ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni. Àwọn Kristẹni ń bá ara wọn lò bí àwọn ẹni ayé ṣe ń bá ara wọn lò.

18. Kí ni ó lè fa àwọn ìwà àti èrò àìnífẹ̀ẹ́ láàárín àwọn Kristẹni?

18 Èé ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni? Nítorí ẹ̀mí ìrònú òdì, bí ojúkòkòrò àti “àwọn ìfàsí-ọkàn . . . fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.” Ìgbéraga, owú, àti ìfẹ́ fún ipò ńlá lè ba ìkẹ́gbẹ́pọ̀ onífẹ̀ẹ́ ti Kristẹni tí ó wà nínú ìjọ jẹ́. (Jákọ́bù 3:6, 14) Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń sọni di ọ̀rẹ́ ayé, tí yóò sì túmọ̀ sí dídi ọ̀tá Ọlọ́run. Kò sí ẹnì kan tí ó ní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀, tí a lè kà sí pé ó wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run.

19. (a) Ta ni ó yẹ kí a dá lẹ́bi gan-an bí Kristẹni kan bá rí i pé ìrònú búburú ń dàgbà ní ọkàn-àyà òun? (b) Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè borí ìrònú òdì?

19 Ta ni a lè dá lẹ́bi bí ẹ̀mí búburú bẹ́ẹ̀ bá ń dàgbà nínú ọkàn-àyà wa? Ṣé Sátánì ni? Dé àyè kan, bẹ́ẹ̀ ni. Òun ni “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́” ti ayé yìí, inú èyí tí irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ti tàn kálẹ̀. (Éfésù 2:1, 2; Títù 2:12) Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí ń fa ìrònú òdì wà nínú ẹran ara àìpé wa. Lẹ́yìn kíkìlọ̀ nípa ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Tàbí lójú yín, ó ha dà bí ẹni pé lásán ni ìwé mímọ́ wí pé: ‘Ó jẹ́ pẹ̀lú ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara ni ẹ̀mí tí ń gbé inú wa fi ń yán hànhàn’?” (Jákọ́bù 4:5) Gbogbo wa ni a bí ìtẹ̀sí láti ṣe búburú mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 7:18-20) Ṣùgbọ́n, a lè gbéjà ko ìtẹ̀sí náà bí a bá mọ àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wa, tí a sì gbára lé ìrànwọ́ Jèhófà láti borí wọn. Jákọ́bù sọ pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí [Ọlọ́run] fi fúnni tóbi [ju ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara tí a bí mọ́ wa].” (Jákọ́bù 4:6) Nípasẹ̀ ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti ìtìlẹ́yìn àwọn arákùnrin Kristẹni olóòótọ́, àti nípa ìtóye ẹbọ ìràpadà Jésù, àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó ti ẹran ara kò borí àwọn Kristẹni olóòótọ́. (Róòmù 7:24, 25) Wọ́n wà láìsewú nínú ètò àjọ Ọlọ́run, ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ ayé.

20. Àwọn ìbùkún jìngbìnnì wo ni àwọn tí ó jẹ́ apá kan ètò àjọ Ọlọ́run ń gbádùn?

20 Bíbélì ṣèlérí pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi okun fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi àlàáfíà bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Sáàmù 29:11) Ní tòótọ́, bí a bá wà nínú “orílẹ̀-èdè” òde òní ti Jèhófà, ètò àjọ rẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí, a óò gbà nínú okun tí ń fúnni, a óò sì gbádùn àlàáfíà tí ó fi ń bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀. Lóòótọ́, ayé Sátánì tóbi gan-an ju ètò àjọ Jèhófà tí ó ṣeé fojú rí lọ, Sátánì pàápàá sì lágbára gan-an jù wá lọ. Ṣùgbọ́n Jèhófà ni Olódùmarè. Ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ kò ṣeé ṣẹ́gun. Àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára pẹ̀lú wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa nínú sísin Ọlọ́run. Nípa báyìí, láìfi ìkórìíra tí a dojú kọ pè, a lè dúró gbọn-in. Bí Jésù, a lè ṣẹ́gun ayé.—Jòhánù 16:33; 1 Jòhánù 4:4.

Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?

◻ Kí ni ètò àjọ Ọlọ́run tí a lè fojú rí?

◻ Àwọn ọ̀nà wo ni ètò àjọ Ọlọ́run gbà ń pèsè ààbò?

◻ Àwọn wo ni apá kan ètò àjọ Ọlọ́run?

◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún dídi ọ̀rẹ́ ayé?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Kí Ni Ètò Àjọ Ọlọ́run?

Nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀nà mẹ́ta ni a ń gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ètò àjọ Ọlọ́run.”

1 Ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run tí a kò lè fojú rí, tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóòótọ́ jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀. Èyí ni a pè ní “Jerúsálẹ́mù ti òkè” nínú Bíbélì.—Gálátíà 4:26.

2 Ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí, ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Lónìí, èyí ní àwọn ẹni àmì òróró, tí ogunlọ́gọ̀ ńlá dara pọ̀ mọ́ nínú.

3 Ètò àjọ àgbáyé ti Jèhófà. Lónìí, èyí ní nínú ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run àti àwọn ẹni àmì òróró, tí a gbà ṣọmọ lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ní ìrètí tẹ̀mí. Nígbà tí ó bá tó àkókò, yóò ní àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí a sọ di pípé lórí ilẹ̀ ayé nínú pẹ̀lú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ètò àjọ Jèhófà ni ó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí ó dára jù lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́