Àkókò Tó Yẹ Ká Wà Lójúfò Nìyí!
“Ẹ MÁ ṣe àṣìṣe nípa àkókò tí a ń gbé; ó tó àkókò fún wa láti jí kúrò lójú oorun wa.” (Róòmù 13:11, Knox) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 14 kí òpin alájàálù tó dé bá ètò àwọn nǹkan Júù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Nítorí pé àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni wà lójúfò nípa tẹ̀mí, wọn kò sí ní Jerúsálẹ́mù ní àkókò lílekoko yẹn, wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ikú, a kò sì mú wọn lẹ́rú. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn kúrò ní ìlú náà?
Jésù Kristi ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọ̀tá yóò yí Jerúsálẹ́mù ká, wọn yóò sì fọ́ àwọn olùgbé inú rẹ̀ mọ́lẹ̀. (Lúùkù 19:43, 44) Lẹ́yìn náà, Jésù fún àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkópọ̀ àmì tí kò ṣòro láti dá mọ̀. (Lúùkù 21:7-24) Fún àwọn Kristẹni tí ń gbé Jerúsálẹ́mù, kíkúrò níbẹ̀ túmọ̀ sí fífi ilé àti iṣẹ́ sílẹ̀. Síbẹ̀, wíwà tí wọ́n wà lójúfò àti sísá tí wọ́n sá gbà wọ́n là.
Nígbà tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Nínú ìdáhùn tí Jésù fún wọn, ó fi wíwàníhìn-ín rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú wé àkókò tó ṣáájú Ìkún Omi àgbáyé ní ọjọ́ Nóà. Jésù tọ́ka sí i pé Àkúnya náà gbá gbogbo ẹni burúkú dà nù. (Mátíù 24:21, 37-39) Ó tipa bẹ́ẹ̀ tọ́ka sí i pé Ọlọ́run yóò tún dá sí ọ̀ràn aráyé lẹ́ẹ̀kan sí i. Báwo ni yóò ṣe pọ̀ tó? Dájúdájú, yóò pọ̀ débi pé, yóò mú ayé, tàbí ètò àwọn nǹkan búburú kúrò pátápátá lódindi! (Fi wé 2 Pétérù 3:5, 6.) Ǹjẹ́ ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa?
Ǹjẹ́ Ohun Gbogbo Ṣì Rí Bí Ó Ti Rí Tẹ́lẹ̀?
Àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní tó ronú pé a lè pa ìlú mímọ́ wọn, Jerúsálẹ́mù, run kò tó nǹkan. Irú àìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ló sábà máa ń gbilẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí ń gbé nítòsí òkè ayọnáyèéfín, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé irú òkè bẹ́ẹ̀ kò bú lójú wọn rí. Nígbà tí a bá ṣèkìlọ̀, ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé: “Nígbà ayé mi kọ́.” Onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín, Lionel Wilson, wí pé: “Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, ọ̀rúndún kejìkejì tàbí ẹ̀kẹtakẹta ni àwọn òkè ayọnáyèéfín máa ń bú. Ìdààmú lè bá ọ bí ìbúgbàù kan bá ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn òbí rẹ. Àmọ́, bó bá jẹ́ nígbà ayé àwọn òbí rẹ àgbà ló ṣẹlẹ̀, o kò lè fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n lára.”
Bí ó ti wù kí ó rí, níní ìsọfúnni pípéye lè mú kí a dá àwọn àmì ewu mọ̀, kí a sì fọwọ́ dan-indan-in mú wọn. Ọ̀kan nínú àwọn tó sá kúrò níbi Òkè Ńlá Pelée ti mọ̀ nípa àwọn òkè ayọnáyèéfín dunjú, ó sì mọ àwọn àmì tí ń tọ́ka ewu. A lóye irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀ bó ṣe yẹ nígbà tó kù díẹ̀ kí Òkè Ńlá Pinatubo bú gbàù. Àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín tí wọ́n baralẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn agbára tí kò ṣeé fojú rí, tí ń kóra jọ nínú òkè ńlá náà, ṣàlàyé kíkún tó mú kí àwọn ènìyàn sá kúrò ní àgbègbè náà.
Ó dájú pé, àwọn kan yóò sábà máa ṣàìka àmì ìkìlọ̀ kún, tí wọn yóò sì máa sọ pé nǹkan kan kò ní ṣẹlẹ̀. Wọ́n tilẹ̀ lè máa pẹ̀gàn àwọn tí ń gbégbèésẹ̀ pàtó. Àpọ́sítélì Pétérù sọ tẹ́lẹ̀ pé irú èrò bẹ́ẹ̀ yóò wọ́pọ̀ ní ọjọ́ wa. Ó wí pé: “Ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’”—2 Pétérù 3:3, 4.
Ǹjẹ́ ìwọ gbà pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí? Nínú ìwé The Columbia History of the World, John A. Garraty àti Peter Gay béèrè pé: “Ṣé ọ̀làjú wa ń wó palẹ̀ lójú wa ni?” Àwọn òpìtàn wọ̀nyí wá ṣàtúpalẹ̀ àwọn ìṣòro ìjọba, bí ìwà ọ̀daràn àti àìgbọràn ará ìlú ṣe ń pọ̀ sí i kárí ayé, bí ìgbésí ayé ìdílé ṣe ń dojú rú, bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe kùnà láti tán ìṣòro aráyé, ìṣòro tó tan mọ́ àṣẹ, àti ìbàjẹ́ tó karí ayé nínú ọ̀ràn ìwà rere àti ìsìn. Wọ́n parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Bí ìwọ̀nyí kì í bá ṣe àwọn àmì òpin dídájú kan, wọ́n jọ ọ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.”
A ní ìdí dídájú láti gbà pé “òpin” ti dé tán. A kò ní láti bẹ̀rù pé ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀ á dópin, nítorí pé Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Síbẹ̀, ó yẹ kí a retí òpin ètò àwọn nǹkan burúkú tó ti fa ọ̀pọ̀ ìnira fún ènìyàn láìpẹ́. Èé ṣe? Nítorí pé, a lè rí ọ̀pọ̀ àmì tí ń tọ́ka sí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan yìí, gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe là wọ́n lẹ́sẹẹsẹ. (Wo àpótí “Díẹ̀ Nínú Àmì Tí Ń Tọ́ka sí Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn.”) Èé ṣe tí o kò fi àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ wé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó lọ́gbọ́n nínú fún ara rẹ àti ìdílé rẹ. Àmọ́, kí ló fà á tí o fi ní láti ṣe nǹkan kan nísinsìnyí?
Ó Yẹ Láti Wà Lójúfò Gan-an
Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tilẹ̀ ń mọ̀ nígbà tí ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín kan bá ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, wọn kò lè sọ ìgbà tí yóò ṣẹlẹ̀ ní pàtó. Lọ́nà kan náà, Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Níwọ̀n bí a kò ti mọ ìgbà tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yóò dópin ní pàtó, Jésù kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn [Jésù] ń bọ̀.”—Mátíù 24:43, 44.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ wọ̀nyí fi hàn pé òpin oníjàábá ti ètò nǹkan yìí yóò bá ayé yìí lójijì. Kódà, bí a bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, a ní láti “wà ní ìmúratán.” Ipò tí a wà dà bí ti onílé kan tí a lè bá lójijì láìsí ìmúratẹ́lẹ̀, nítorí pé kò mọ ìgbà tí olè yóò wá fọ́ ilé rẹ̀.
Lọ́nà kan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà pé: “Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. . . . Ẹ̀yin, ará, ẹ kò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn yóò fi dé bá yín lójijì gẹ́gẹ́ bí yóò ti dé bá àwọn olè.” Pọ́ọ̀lù tún rọni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:2, 4, 6, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Kí ló túmọ̀ sí láti “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́”?
Sísá tí àwa ń sá lọ síbi ààbò yàtọ̀ sí ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Jerúsálẹ́mù ní ti pé, a kò ní sá kúrò ní ìlú kan pàtó. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Róòmù níyànjú láti jí lójú oorun, ó rọ̀ wọ́n láti “bọ́ àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn kúrò,” kí wọ́n sì “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀.” (Róòmù 13:12, 14) Nípa títẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, a óò fi hàn pé a mọ àkókò tí a wà dunjú, ìwàlójúfò tẹ̀mí yìí yóò sì mú kí a lè ní ààbò àtọ̀runwá, nígbà tí ètò àwọn nǹkan burúkú yìí bá lọ sópin.—1 Pétérù 2:21.
Àwọn tí ń tẹ̀ lé Jésù Kristi ń gbádùn ìgbésí ayé tó ní ète, tó sì ń tẹ́ni lọ́run. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ẹrù jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ ti inú rere, ó sì tuni lára. (Mátíù 11:29, 30, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn ni ‘gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti ẹni tí ó rán jáde, Jésù Kristi, sínú.’ (Jòhánù 17:3) Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣèbẹ̀wò sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Inú wọn yóò dùn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé rẹ. Bí o bá sì ti ń ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i, ó dájú pé yóò dá ìwọ náà lójú pé àkókò tí a wà yìí yàtọ̀. Dájúdájú, ó tó àkókò fún wa láti jí lójú oorun!
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
DÍẸ̀ NÍNÚ ÀMÌ TÍ Ń TỌ́KA SÍ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
“Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè”; ‘a óò mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé.’ (Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:4)
Àwọn ogun àgbáyé méjèèjì tó jà ní ọ̀rúndún yìí, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ogun mìíràn ti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé. Òpìtàn John Keegan kọ̀wé pé “Ogun Àgbáyé Kìíní—àti Èkejì—wá yàtọ̀ sí gbogbo ogun tí a ti jà ṣáájú, wọ́n yàtọ̀ ní ti bí wọ́n ṣe gbilẹ̀ tó, bí wọ́n ṣe le tó, bí wọ́n ṣe gbòòrò tó, àti iye ohun ìní àti ènìyàn tó ṣègbé. . . . Àwọn Ogun Àgbáyé náà ju àwọn ogun ìṣáájú lọ ní ti iye ènìyàn tó kú, dúkìá tó ṣègbé àti ìjìyà tó dá sílẹ̀ ní ibi púpọ̀ lágbàáyé.” Nísinsìnyí, ogun ń pa àwọn obìnrin àti ọmọdé ju àwọn jagunjagun lọ. Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣírò pé, láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, mílíọ̀nù méjì ni àwọn ọmọdé tó bógun lọ.
“Àìtó oúnjẹ” (Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:5, 6, 8)
Ní 1996, ọkà wheat àti àgbàdo gbówó lórí gan-an. Kí ló fà á? Iye oúnjẹ wọ̀nyí tí a ní nípamọ́ lágbàáyé ti lọ sílẹ̀ dé orí ìwọ̀n tí a lè lò tán ní 50 ọjọ́, kò kéré tó bẹ́ẹ̀ rí. Bí iye owó àwọn oúnjẹ kòṣeémánìí ṣe ń ròkè túmọ̀ sí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tálákà lágbàáyé—tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ọmọdé—ní ń sùn lébi.
“Ìsẹ̀lẹ̀ . . . láti ibì kan dé ibòmíràn” (Mátíù 24:7)
Láàárín 2,500 ọdún tó kọjá, ìsẹ̀lẹ̀ mẹ́sàn-án péré ti pa ènìyàn tó lé ní 100,000. Mẹ́rin lára ìsẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ló ṣẹlẹ̀ láti 1914 wá.
“Pípọ̀ sí i ìwà àìlófin” (Mátíù 24:12)
Bí ọ̀rúndún ogún ti ń parí lọ, ìwà àìlófin, tàbí ìwà ìrúfin, ti gbilẹ̀. Àwọn apániláyà tí ń gbéjà ko àwọn aráàlú, àwọn apànìyàn láìláàánú, àti pípa ènìyàn lápalù wà lára àwọn àmì búburú ti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn oníwà ipá wọ̀nyí.
“Àjàkálẹ̀ àrùn . . . láti ibì kan dé ibòmíràn” (Lúùkù 21:11)
Ó ṣeé ṣe kí ikọ́ ẹ̀gbẹ pa 30 mílíọ̀nù ènìyàn láàárín àwọn ọdún 1990. Àwọn egbòogi kò ran àwọn bakitéríà tí ń tan àrùn kiri mọ́. Lọ́dọọdún ni àrùn aṣekúpani mìíràn, ibà, ń mú ènìyàn 300 mílíọ̀nù sí 500 mílíọ̀nù, ó sì ń pa iye tí a fojú bù sí mílíọ̀nù 2. Nígbà tí ẹ̀wádún yìí bá fi parí, a retí pé àrùn AIDS yóò máa pa 1.8 mílíọ̀nù ènìyàn lọ́dún. Ìwé State of the World 1996 sọ pé: “Lónìí, aráyé ń kojú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà rànyìn.”
“A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14)
Ní 1997, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò ju bílíọ̀nù kan wákàtí lọ ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ló ń mú ìsọfúnni yìí tọ àwọn ènìyàn lọ déédéé ní 232 ilẹ̀.
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò FAO/B. Imevbore
Fọ́tò U.S. Coast Guard
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Àwọn Kristẹni sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù nítorí pé wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí