ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/15 ojú ìwé 8-13
  • Jerúsálẹ́mù—“Ìlú Ńlá Ti Ọba Ńlá Náà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jerúsálẹ́mù—“Ìlú Ńlá Ti Ọba Ńlá Náà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tí “Ìtẹ́ Jèhófà” Wà
  • Láti Orí Àlàáfíà sí Ìsọdahoro
  • Àwọn Onísìn Èké Alámùúlégbè Wọn Ta Kò Wọ́n
  • Mèsáyà Náà Fara Hàn!
  • Títọ́ Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wò
  • Jerusalemu ti Ilẹ̀-Ayé ní Ìfiwéra Pẹlu Jerusalemu ti Òkè-Ọ̀run
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Jerúsálẹ́mù Kan Tí Orúkọ Rò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kí Ni Jerúsálẹ́mù Tuntun?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìlú Ológo
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/15 ojú ìwé 8-13

Jerúsálẹ́mù—“Ìlú Ńlá Ti Ọba Ńlá Náà”

‘Má ṣe fi Jerúsálẹ́mù búra, nítorí pé ìlú ńlá ti Ọba ńlá náà ni.’—MÁTÍÙ 5:34, 35.

1, 2. Kí ní lè rú àwọn kan lójú nípa Jerúsálẹ́mù?

JERÚSÁLẸ́MÙ—orúkọ rẹ̀ gan-an ń ru ìmọ̀lára lílágbára sókè nínú àwọn ènìyàn tí ó wá láti inú onírúurú ẹ̀sìn. Ní tòótọ́, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí kò ka ìlú ìgbàanì yìí sí, nígbà tó kúkú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ń mẹ́nu kàn án nínú ìròyìn. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìròyìn fi hàn pé, Jerúsálẹ́mù kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ibi àlàáfíà.

2 Èyí lè rú àwọn kan tí ń ka Bíbélì lójú. Nígbà àtijọ́, ìkékúrú orúkọ Jerúsálẹ́mù ni Sálẹ́mù, tí ó túmọ̀ sí “àlàáfíà.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:18; Sáàmù 76:2; Hébérù 7:1, 2) Nítorí náà, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí àlàáfíà kò sí nínú ìlú tí ó ní irú orúkọ yìí?’

3. Níbo ni a ti lè rí ìsọfúnni tí ó ṣeé gbára lé nípa Jerúsálẹ́mù?

3 Láti lè dáhùn ìbéèrè yẹn, a ní láti yẹ ìtàn ìgbà láéláé wò, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jerúsálẹ́mù ti ìgbàanì. Ṣùgbọ́n, àwọn kan lè ronú pé, ‘Kò sí àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtàn ìgbàanì.’ Síbẹ̀síbẹ̀, ìmọ̀ pípéye nípa ìtàn ìjímìjí ti Jerúsálẹ́mù ṣeyebíye fún gbogbo wa. Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti sọ ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ìmọ̀ Bíbélì nípa Jerúsálẹ́mù lè tù wá nínú—àní, ó lè mú kí a ní ìrètí pé kì í ṣe nínú ìlú yẹn nìkan ní àlàáfíà yóò wà, ṣùgbọ́n pé yóò wà jákèjádò ayé.

Ibi Tí “Ìtẹ́ Jèhófà” Wà

4, 5. Báwo ni ọ̀ràn ṣe kan Dáfídì nípa ríran Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ láti kó ipa pàtàkì nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ?

4 Ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣááju Sànmánì Tiwa, òkìkí Jerúsálẹ́mù kàn káàkiri gẹ́gẹ́ bí olú ìlú orílẹ̀-èdè kan tí ó fini lọ́kàn balẹ̀, tí ó sì ní àlàáfíà. Jèhófà Ọlọ́run mú kí a fi òróró yan ọ̀dọ́mọkùnrin kan, Dáfídì, gẹ́gẹ́ bí ọba lórí orílẹ̀-èdè ìgbàanì náà—Ísírẹ́lì. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jerúsálẹ́mù ni ibùjókòó ìjọba wà, Dáfídì àti àwọn ọba tí ó jẹ́ tẹ̀ lé e jókòó sórí “ìtẹ́ àkóso Jèhófà,” tàbí “ìtẹ́ Jèhófà.”—1 Kíróníkà 28:5; 29:23.

5 Dáfídì, olùbẹ̀rù Ọlọ́run—ọmọ Ísírẹ́lì kan láti ẹ̀yà Júdà—gba Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ àwọn ará Jébúsì abọ̀rìṣà. Nígbà náà lọ́hùn-ún, òkè kan tí a ń pè ní Síónì ni ó wà ní ìlú náà, ṣùgbọ́n ohun kan náà ni orúkọ òkè yẹn àti Jerúsálẹ́mù túmọ̀ sí. Nígbà tó yá, Dáfídì mú kí a gbé àpótí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì dá lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí a ti pàgọ́ fún un. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yìí, Ọlọ́run ti bá wòlíì rẹ̀ Mósè sọ̀rọ̀ láti inú àwọsánmà tí ó wà lórí Àpótí mímọ́ náà. (Ẹ́kísódù 25:1, 21, 22; Léfítíkù 16:2; 1 Kíróníkà 15:1-3) Àpótí náà dúró fún wíwà tí Ọlọ́run wà níbẹ̀, nítorí Jèhófà ni Ọba Ísírẹ́lì gan-an. Nítorí náà, ọ̀nà méjì ni a lè gbà sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ń ṣàkóso láti Jerúsálẹ́mù.

6. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa Dáfídì àti Jerúsálẹ́mù?

6 Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ìlà ìdílé ọba tirẹ̀, tí Síónì tàbí Jerúsálẹ́mù dúró fún, kò ní dópin láé. Èyí túmọ̀ sí pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì kan yóò jogún ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso títí láé, gẹ́gẹ́ bí Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run—Mèsáyà, tàbí Kristi.a (Sáàmù 132:11-14; Lúùkù 1:31-33) Bíbélì tún fi hàn pé kì í ṣe Jerúsálẹ́mù nìkan ni ajogún “ìtẹ́ Jèhófà” títí láé yìí yóò ṣàkóso, ṣùgbọ́n, yóò ṣàkóso lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.—Sáàmù 2:6-8; Dáníẹ́lì 7:13, 14.

7. Báwo ni Dáfídì Ọba ṣe gbé ìjọsìn mímọ́ gaara lárugẹ?

7 Gbogbo akitiyan láti yẹ àga mọ́ ẹni àmì òróró Ọlọ́run, Dáfídì Ọba, nídìí ló já sí òtúbáńtẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a tẹ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá lórí ba, a sì mú àwọn ààlà Ilẹ̀ Ìlérí gbòòrò dé ibi jíjìnnà réré tí Ọlọ́run pinnu pé kí ó dé. Dáfídì lo ipò yìí láti gbé ìjọsìn mímọ́ gaara lárugẹ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ sì gbé Jèhófà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba tòótọ́ ni Síónì.—2 Sámúẹ́lì 8:1-15; Sáàmù 9:1, 11; 24:1, 3, 7-10; 65:1, 2; 68:1, 24, 29; 110:1, 2; 122:1-4.

8, 9. Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù ṣe gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Ọba?

8 Nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì, ìjọsìn Jèhófà gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Sólómọ́nì mú kí Jerúsálẹ́mù gbòòrò sí ìhà àríwá dé òkè Mòráyà (àgbègbè tí Ilé Olórùlé Rìbìtì Orí Àpáta wà lónìí). Ó láǹfààní láti kọ́ tẹ́ńpìlì ńlá kan sórí òkè téńté yìí, sí ìyìn Jèhófà. A sì gbé àpótí májẹ̀mú sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ti tẹ́ńpìlì náà.—1 Àwọn Ọba 6:1-38.

9 Àlàáfíà wà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bí wọ́n ti ń fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn Jèhófà, tí a gbé kalẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Ìwé Mímọ́ ń ṣàpèjúwe ipò náà lọ́nà fífanimọ́ra, ó wí pé: “Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà lẹ́bàá òkun nítorí tí wọ́n jẹ́ ògìdìgbó, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀. . . . Àlàáfíà pàápàá sì jẹ́ ti [Sólómọ́nì] ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀ rẹ̀ yí ká. Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 4:20, 24, 25.

10, 11. Báwo ni ìwalẹ̀pìtàn ṣe jẹ́rìí sí ohun tí Bíbélì sọ nípa Jerúsálẹ́mù nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàkóso?

10 Àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn kín àkọsílẹ̀ ìṣàkóso aláásìkí ti Sólómọ́nì yìí lẹ́yìn. Nínú ìwé rẹ̀, The Archaeology of the Land of Israel, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yohanan Aharoni sọ pé: “Ọrọ̀ tí a ń kó wọ ààfin ọba láti ìhà gbogbo, àti ètò ìṣòwò tí ó búrẹ́kẹ́ . . . mú kí ìyípadà nínú gbogbo ìlọsíwájú àti aásìkí nípa ti ara yá kánkán. . . . Kì í ṣe nínú àwọn ohun amáyédẹrùn nìkan ní a ti rí ìyípadà nínú ìlọsíwájú àti aásìkí nípa ti ara . . . , ṣùgbọ́n a tún rí i nínú àwọn ohun àfamọ̀ṣe pàápàá. . . . Ìjójúlówó àwọn ohun àfamọ̀ṣe àti ọ̀nà ìfiná-sun-wọ́n tún sunwọ̀n sí i gidigidi.”

11 Bákan náà, Jerry M. Landay kọ̀wé pé: “Lábẹ́ Sólómọ́nì, ìlọsíwájú àti aásìkí nípa ti ara tí ó dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sunwọ̀n sí i láàárín ọgbọ̀n ọdún ju bí ó ti rí ní igba ọdún tí ó ṣáájú. Níbi tí a ti rí àwọn ohun ìtàn nípa Sólómọ́nì, a rí àwọn àwókù ọlọ́jọ́ pípẹ́, àwọn ìlú ńláńlá olódi gìrìwò, àwọn ilé gbígbé tí wọ́n pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ pẹ̀lú àwọn ilé alákọ̀ọ́pọ̀ rèǹtèrente tí ó jẹ́ ti àwọn tí ó rí já jẹ láwùjọ, a rí ìtẹ̀síwájú gíga nínú òye iṣẹ́ àwọn amọ̀kòkò àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà mọ ọ́n. Pẹ̀lúpẹ̀lú, a tún rí àwókù àwọn iṣẹ́ ọnà tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ jíjìnnà réré, ìwọ̀nyí jẹ́ àmì ìṣòwò àti káràkátà tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kárí ayé.”—The House of David.

Láti Orí Àlàáfíà sí Ìsọdahoro

12, 13. Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé a kò gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ mọ́ ní Jerúsálẹ́mù?

12 Nígbà náà lọ́hùn-ún, àlàáfíà àti aásìkí Jerúsálẹ́mù, ìlú tí ibùjọsìn Jèhófà wà, jẹ́ ohun tí ó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà fún. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ẹ béèrè fún àlàáfíà Jerúsálẹ́mù. Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ ìlú ńlá, yóò bọ́ lọ́wọ́ àníyàn. Kí àlàáfíà máa bá a lọ nínú ohun àfiṣe-odi rẹ, àti òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ. Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi ni èmi yóò ṣe sọ̀rọ̀ wàyí pé: ‘Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.’” (Sáàmù 122:6-8) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fún Sólómọ́nì ní àǹfààní láti kọ́ tẹ́ńpìlì ńlá náà sínú ìlú alálàáfíà yẹn, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó lọ fẹ́ ọ̀pọ̀ aya tí wọ́n jẹ́ abọ̀rìṣà. Ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, wọ́n tì í sínú gbígbé ìjọsìn àwọn ọlọ́run èké ti àwọn ọjọ́ wọnnì lárugẹ. Ìpẹ̀yìndà yìí ní ipa búburú lórí gbogbo orílẹ̀-èdè náà, ó gba ojúlówó àlàáfíà mọ́ òun àti àwọn olùgbé rẹ̀ lọ́wọ́.—1 Àwọn Ọba 11:1-8; 14:21-24.

13 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Rèhóbóámù, ọmọ Sólómọ́nì, ẹ̀yà mẹ́wàá ṣọ̀tẹ̀, wọ́n dá ìjọba àríwá Ísírẹ́lì sílẹ̀. Nítorí ìbọ̀rìṣà wọn, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Asíríà dojú ìjọba náà bolẹ̀. (1 Àwọn Ọba 12:16-30) Ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà tí ó wà ní gúúsù ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí àwọn pẹ̀lú fi yí padà kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ gaara, nítorí náà, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí àwọn ará Bábílónì pa ìlú oníwàkiwà náà run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àádọ́rin ọdún ni ojú fi pọ́n àwọn Júù gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn ní Bábílónì. Lẹ́yìn náà, nípasẹ̀ àánú Ọlọ́run, a gbà kí wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò.—2 Kíróníkà 36:15-21.

14, 15. Báwo ni Jerúsálẹ́mù ṣe padà di ipò pàtàkì mú lẹ́yìn ìgbèkùn ní Bábílónì, ṣùgbọ́n ìyípadà wo ni ó mú wá?

14 Lẹ́yìn 70 ọdún ìsọdahoro, ó dájú pé igbó yóò ti kún bo àwọn ilé tí ó ti di òkìtì àlàpà. Odi Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀, àyè gbayawu wá rọ́pò àwọn ẹnubodè àti òpó tí a fi gbé wọn ró. Síbẹ̀, àwọn Júù tí wọ́n padà dé náà kò mikàn. Wọ́n kọ́ pẹpẹ kan síbi tí tẹ́ńpìlì àtijọ́ wà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ ojoojúmọ́ sí Jèhófà.

15 Ìbẹ̀rẹ̀ tí ó fi hàn pé nǹkan yóò ṣẹnuure lèyí jẹ́, àmọ́ ṣá o, Jerúsálẹ́mù tí a mú padà bọ̀ sípò yẹn kò tún ní jẹ́ olú ìlú ìjọba kan tí yóò ní àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba lórí ìtẹ́ mọ́ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, gómìnà kan tí àwọn ará Bábílónì tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn Júù yàn ni ó ń ṣàkóso wọn, wọ́n sì ní láti san owó orí fún àwọn ọ̀gá wọn tí wọ́n jẹ́ ará Páṣíà. (Nehemáyà 9:34-37) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jerúsálẹ́mù wà ní ipò “ìtẹ̀mọ́lẹ̀,” nígbà náà lọ́hùn-ún, ní gbogbo ayé, òun ṣì ni ìlú kan tí Jèhófà Ọlọ́run ṣojú rere sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Lúùkù 21:24) Gẹ́gẹ́ bí ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn mímọ́ gaara, ó tún ń ṣojú fún ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lórí ayé nípasẹ̀ àtọmọdọ́mọ kan láti ọ̀dọ̀ Ọba Dáfídì.

Àwọn Onísìn Èké Alámùúlégbè Wọn Ta Kò Wọ́n

16. Báwo ni àwọn Júù tí wọ́n padà dé láti Bábílónì ṣe jáwọ́ nínú ìmúpadàbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù?

16 Láìpẹ́, àwọn Júù tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn sí Jerúsálẹ́mù fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun lélẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn onísìn èké alámùúlégbè wọn kọ lẹ́tà tí ó kún fún ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí Atasásítà Ọba Páṣíà, wọ́n sọ pé àwọn Júù ń dìtẹ̀. Látàrí èyí, Atasásítà pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ ilé kíkọ́ ní Jerúsálẹ́mù dúró. Ká ní ò ń gbé nínú ìlú náà nígbà yẹn, ìwọ ì bá ti máa ronú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, àwọn Júù dáwọ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà dúró, lílépa ọrọ̀ àlùmọ́nì sì gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá.—Ẹ́sírà 4:11-24; Hágáì 1:2-6.

17, 18. Ọ̀nà wo ni Jèhófà lò láti rí i pé a tún Jerúsálẹ́mù kọ́?

17 Ní nǹkan bí ọdún 17 lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé, Ọlọ́run gbé wòlíì Hágáì àti Sekaráyà díde láti tún ìrònú àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe. Nígbà tí a sún àwọn Júù láti ronú pìwà dà, wọ́n dáwọ́ lé iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Láàárín àkókò náà, Dáríúsì ti di ọba Páṣíà. Ó rí àrídájú àṣẹ tí Kírúsì Ọba pa pé kí a tún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù kọ́. Dáríúsì kọ lẹ́tà kan sí àwọn alámùúlégbè àwọn Júù, ó kìlọ̀ fun wọn láti ‘jìnnà sí Jerúsálẹ́mù,’ kí wọ́n sì mú nínú owó orí ọba ṣe ìtìlẹ́yìn, kí iṣẹ́ náà bàa lè parí.—Ẹ́sírà 6:1-13.

18 Àwọn Júù parí tẹ́ńpìlì náà ní ọdún kejìlélógún tí wọ́n padà dé. Ìwọ pẹ̀lú lè rí i pé ìyípadà pàtàkì yìí jẹ́ ohun kan tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣayẹyẹ rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà. Síbẹ̀, dé ìwọ̀n kan, òkìtì àlàpà Jerúsálẹ́mù àti àwókù odi rẹ̀ ṣì wà níbẹ̀. “Ní ọjọ́ Nehemáyà gómìnà àti Ẹ́sírà àlùfáà, tí í ṣe adàwékọ,” a fún ìlú náà ní àfiyèsí tí ó yẹ. (Nehemáyà 12:26, 27) Ẹ̀rí fi hàn pé, nígbà tí ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa fi máa parí, a ti tún Jerúsálẹ́mù kọ́ pátápátá gẹ́gẹ́ bí ìlú ńlá kan ní ayé ìgbàanì.

Mèsáyà Náà Fara Hàn!

19. Ọ̀nà wo ni Mèsáyà gbà sọ ipò àrà ọ̀tọ̀ tí Jerúsálẹ́mù wà?

19 Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí a fo àwọn ọ̀rúndún díẹ̀ kọjá sí àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ kárí ayé ṣẹlẹ̀, ìyẹn ni ìbí Jésù Kristi. Áńgẹ́lì Jèhófà Ọlọ́run ti sọ fún wúńdíá náà tí í ṣe ìyá Jésù pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, . . . kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù ṣe Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, èyí tí a mọ̀ bí ẹni mowó. Nínú ìwàásù náà, ó fúnni ní ìṣírí, ó sì gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti mú ẹ̀jẹ́ wọn fún Ọlọ́run ṣẹ, ṣùgbọ́n kí wọ́n ṣọ́ra fún fífi ìbúra ṣeré. Jésù wí pé: “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra láìmúṣẹ, ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’ Bí ó ti wù kí ó rí, èmi wí fún yín pé: Má ṣe búra rárá, yálà fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni; tàbí ilẹ̀ ayé, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀ ni; tàbí Jerúsálẹ́mù, nítorí pé ìlú ńlá ti Ọba ńlá náà ni.” (Mátíù 5:33-35) Ó yẹ fún àfiyèsí pé Jésù sọ ipò àrà ọ̀tọ̀ tí Jerúsálẹ́mù wà—èyí tí ó ti wà nínú rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Bẹ́ẹ̀ ni, ó jẹ́ “ìlú ńlá ọba ńlá náà,” Jèhófà Ọlọ́run.

20, 21. Ìyípadà agbàfiyèsí wo ni ó wáyé nínú ìṣarasíhùwà ọ̀pọ̀ àwọn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù?

20 Nígbà tí ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ń lọ sópin, Jésù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn tí a fòróró yàn. Ní fífi ìmọ̀lára wọn hàn fún ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ yẹn, ọ̀pọ̀ fi ìdùnnú kígbe pé: “Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà! Alábùkún ni ìjọba Dáfídì baba wa tí ń bọ̀!”—Máàkù 11:1-10; Jòhánù 12:12-15.

21 Ṣùgbọ́n, kò tó ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, tí àwọn èèyàn náà fi yọ̀ǹda kí àwọn aṣáájú ìsìn Jerúsálẹ́mù mú wọn kẹ̀yìn sí Jésù. Ó kìlọ̀ pé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo orílẹ̀-èdè náà yóò pàdánù ipò ojú rere wọn níwájú Ọlọ́run. (Mátíù 21:23, 33-45; 22:1-7) Bí àpẹẹrẹ, Jésù polongo pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:37, 38) Nígbà Àjọ Ìrékọjá ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn alátakò Jésù mú kí a pa á lọ́nà tí kò tọ́, lẹ́yìn òde Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà jí Ẹni Àmì Òróró rẹ̀ dìde, ó sì fi ẹ̀mí ìyè àìleèkú nínú Síónì ti ọ̀run ṣe é lógo, àṣeparí kan tí gbogbo wa lè jàǹfààní nínú rẹ̀.—Ìṣe 2:32-36.

22. Lẹ́yìn ikú Jésù, ìmúṣẹ wo ni ọ̀pọ̀ ìtọ́kasí nípa Jerúsálẹ́mù ní?

22 Láti ìgbà náà lọ, a lè lóye rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Síónì, tàbí Jerúsálẹ́mù tí kò tí ì nímùúṣẹ, ni ó ti ń nímùúṣẹ sórí àwọn ìṣètò ti òkè ọ̀run tàbí sára àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù. (Sáàmù 2:6-8; 110:1-4; Aísáyà 2:2-4; 65:17, 18; Sekaráyà 12:3; 14:12, 16, 17) Lọ́nà tí ó ṣe kedere, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun ìtọ́kasí nípa “Jerúsálẹ́mù” tàbí “Síónì” tí a kọ́ lẹ́yìn ikú Jésù ní ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ, kò sì ní í ṣe pẹ̀lú ìlú ńlá náà gan-an tàbí ibi tí ó wà. (Gálátíà 4:26; Hébérù 12:22; 1 Pétérù 2:6; Ìṣípayá 3:12; 14:1; 21:2, 10) Ẹ̀rí ìkẹyìn pé Jerúsálẹ́mù kì í ṣe “ìlú ńlá ti ọba ńlá náà” mọ́ wáyé ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù sọ ọ́ dahoro, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì àti Jésù Kristi ti sọ tẹ́lẹ̀. (Dáníẹ́lì 9:26; Lúùkù 19:41-44) Kò sí ẹnì kan lára àwọn tí ó kọ Bíbélì tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ iwájú pé ìlú náà yóò padà rí ojú rere àrà ọ̀tọ̀ ti Jèhófà Ọlọ́run, èyí tí ó ti gbádùn nígbà kan rí, Jésù alára pàápàá kò sọ bẹ́ẹ̀.—Gálátíà 4:25; Hébérù 13:14.

Títọ́ Àlàáfíà Pípẹ́ Títí Wò

23. Èé ṣe tí a ṣì fi fẹ́ mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù?

23 Lẹ́yìn gbígbé ìtàn ìgbàanì nípa Jerúsálẹ́mù ilẹ̀ ayé yẹ̀ wò, kò sí ẹni tí ó lè jiyàn pé orúkọ náà—“Níní [tàbí, Ìpìlẹ̀] Àlàáfíà Alápá Méjì”—kò ro ìlú náà nígbà ìṣàkóso alálàáfíà ti Sólómọ́nì Ọba. Síbẹ̀, ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò àlàáfíà àti aásìkí tí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé tí a sọ di párádísè, yóò gbádùn láìpẹ́.—Lúùkù 23:43.

24. Kí ní a lè rí kọ́ nípa ipò tó gbilẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì jọba?

24 Sáàmù kejìléláàádọ́rin fi ipò tí ó gbilẹ̀ nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì Ọba hàn. Ṣùgbọ́n orin adùnyùngbà yẹn jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìbùkún tí yóò wà fún aráyé lábẹ́ ìṣàkóso ọ̀run ti Mèsáyà náà, Jésù Kristi. Onísáàmù náà kọrin nípa rẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. . . . Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:7, 8, 12-14, 16.

25. Èé ṣe tí a fi fẹ́ kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jerúsálẹ́mù?

25 Ẹ wo irú ìtùnú àti ìrètí tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn pèsè fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù tàbí níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé! Ìwọ lè wà lára àwọn wọnnì tí yóò gbádùn àlàáfíà kárí ayé lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. Ohun tí a ti mọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù ìgbàanì lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ète Ọlọ́run fún aráyé. Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò darí àfiyèsí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní àádọ́rin àti ọgọ́rin ọdún lẹ́yìn tí àwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì. Èyí jẹ́ ìtùnú fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Ńlá náà, lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn orúkọ oyè náà “Mèsáyà” (tí a yá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù) àti “Kristi” (láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì) túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.”

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Báwo ni Jerúsálẹ́mù ṣe wá di ibi tí “ìtẹ́ Jèhófà” wà?

◻ Ipa pàtàkì wo ni Sólómọ́nì kó nínú mímú ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú?

◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù kò jẹ́ ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn Jèhófà mọ́?

◻ Èé ṣe tí a fi fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa Jerúsálẹ́mù?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìlú Ńlá Dáfídì wà ní apá Gúúsù, àmọ́ Sólómọ́nì mú kí ìlú náà gbòòrò dé àríwá, ó sì kọ́ tẹ́ńpìlì síbẹ̀

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́