ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/15 ojú ìwé 8-9
  • Dáríúsì—Ọba Onídàájọ́ Òdodo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáríúsì—Ọba Onídàájọ́ Òdodo
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌBA KAN TÍ ÌTÀN RẸ̀ KÒ KÚN
  • A ṢOJÚ RERE SÍ DÁNÍẸ́LÌ
  • A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Wọ́n Ju Dáníẹ́lì Sínú Ihò Kìnnìún
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Dáníẹ́lì Fi Ìdúró Gbọn-in Ṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/15 ojú ìwé 8-9

Dáríúsì—Ọba Onídàájọ́ Òdodo

NÍGBÀ tí ọba olókìkí kan ń sọ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó dáwọ́ lé, ó ṣògo pé: “Nígbà kíkọ́ odi Bábílónì mo mọ odi lílágbára sí ìhà ìlà oòrùn. Mo gbẹ́ yàrà kan . . . mo fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti bíríkì kọ́ odi tí ó dà bí òkè ńlá, tí a kò lè ṣí nípò.” Bẹ́ẹ̀ ni, Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì dáwọ́ lé iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá kan, ó sì ṣiṣẹ́ kára láti rí i pé mìmì kan kò lè mi olú ìlú ilẹ̀ ọba rẹ̀. Ṣùgbọ́n Bábílónì kò jẹ́ ibi àìlè-kógun-wọ̀ tí ó lérò pé yóò jẹ́.

Ẹ̀rí èyí fara hàn ní October 5, 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Kírúsì Kejì, olùṣàkóso Páṣíà nígbà náà, pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà ṣẹ́gun Bábílónì, ó sì pa Bẹliṣásárì, olùṣàkóso Kálídíà. Ta ni yóò wá di olùṣàkóso àkọ́kọ́ nínú ìlú tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́gun yìí? Dáníẹ́lì, wòlíì Ọlọ́run, tí òun alára wà nínú ìlú náà nígbà tí a ṣẹ́gun rẹ̀, kọ̀wé pé: “Dáríúsì ará Mídíà sì gba ìjọba, ó jẹ́ ẹni nǹkan bí ọdún méjì-lé-lọ́gọ́ta.”—Dáníẹ́lì 5:30, 31.

Ta ni Dáríúsì? Irú olùṣàkóso wo ni ó jẹ́? Ìwà wo ni ó hù sí wòlíì Dáníẹ́lì, tí ó ti wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì fún ohun tí ó lé ní 70 ọdún?

ỌBA KAN TÍ ÌTÀN RẸ̀ KÒ KÚN

Ìtàn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípa Dáríúsì ará Mídíà kò kún. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ará Mídíà kò fi àkọsílẹ̀ kankan sílẹ̀. Ní àfikún sí i, ìtàn tí kò kún tó ni ó wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún wàláà tí a gbẹ́ nǹkan sí lára tí a wú jáde ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó kò tó nǹkan, nǹkan bí ọ̀rúndún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n sì fi jìnnà sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan Dáríúsì.

Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé lẹ́yìn tí Kírúsì Kejì, olùṣàkóso Páṣíà, ti gba Ecbatana, olú ìlú Mídíà, ó ṣeé ṣe fún un láti jèrè ìdúróṣinṣin àwọn ará Mídíà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà para pọ̀ jagun lábẹ́ ìdarí rẹ̀. Òǹṣèwé Robert Collins ṣàpèjúwe ìbátan tí ó wà láàárín wọn, nínú ìwé rẹ̀, The Medes and Persians, pé: “Ní ti àlàáfíà, àárín àwọn ará Mídíà àti Páṣíà gún gan-an. A sábà máa ń yàn wọ́n sí ipò gíga nínú ètò ìṣèlú àti ipò aṣáájú nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Páṣíà. Ará Mídíà àti Páṣíà ni àwọn àjèjì máa ń pè wọ́n, wọn kì í fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tí a ṣẹ́gun àti àwọn tí ó ṣẹ́gun.” Nípa báyìí, Mídíà àti Páṣíà para pọ̀ di Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà.—Dáníẹ́lì 5:28; 8:3, 4, 20.

Ó dájú pé àwọn ará Mídíà kó ipa pàtàkì nínú gbígba agbára lọ́wọ́ Bábílónì. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé “Dáríúsì ọmọkùnrin Ahasuwérúsì, tí ó jẹ́ irú-ọmọ àwọn ará Mídíà” ni olùṣàkóso àkọ́kọ́ ní Ilẹ̀ Ọba Mídíà àti Páṣíà, tí Bábílónì jẹ́ apá kan rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún. (Dáníẹ́lì 9:1) Lára agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ni, gbígbé àwọn ìlànà kalẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà, èyí tí a kì í wọ́gi lé.” (Dáníẹ́lì 6:8) Ohun tí Bíbélì sọ nípa Dáríúsì tún jẹ́ kí a túbọ̀ mọ irú ẹni tí ó jẹ́ àti ìdí pàtàkì tí kò fi sí ìsọfúnni nípa rẹ̀ nínú àwọn ìwé mìíràn.

A ṢOJÚ RERE SÍ DÁNÍẸ́LÌ

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Dáríúsì gba agbára ní Bábílónì, Bíbélì sọ pé ó fi ‘ọgọ́fà baálẹ̀, tí yóò wà lórí gbogbo ìjọba náà, jẹ lórí ìjọba náà, wọ́n sì ní àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga mẹ́ta lórí wọn, lára àwọn tí Dáníẹ́lì jẹ́ ọ̀kan.’ (Dáníẹ́lì 6:1, 2) Ṣùgbọ́n, àwọn onípò àṣẹ yòókù ń fapá jánú nítorí ipò gíga tí Dáníẹ́lì wà. Láìsí àní-àní, ìwà títọ́ rẹ̀ dènà ìwà ìbàjẹ́, ó sì ṣeé ṣe kí èyí ti fa ìbínú. Ìlara pẹ̀lú ti lè nípa lórí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga náà, níwọ̀n bí ọba ti ṣojú rere sí Dáníẹ́lì, tí ó sì ti ń ronú àtisọ ọ́ di olórí ìjọba.

Láti lè fòpin sí èyí, àwọn onípò àṣẹ méjì náà àti àwọn baálẹ̀ gbìmọ̀ láti fi òfin mú un. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì ní kí ó fọwọ́ sí òfin kan tí ó ka ‘títọrọ nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí’ yàtọ̀ sí Dáríúsì léèwọ̀ fún 30 ọjọ́. Wọ́n ṣòfin pé a óò ju ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ òfin náà lójú sínú ihò kìnnìún. Wọ́n mú kí Dáríúsì gbà gbọ́ pé gbogbo lọ́gàá lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ni inú wọn dùn sófin náà, àti pé òfin náà jẹ́ fífi hàn pé tọba làwọ́n ń ṣe.—Dáníẹ́lì 6:1-3, 6-8.

Dáríúsì fọwọ́ sí òfin náà, kò sí pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi wá rí àbájáde rẹ̀ kòrókòró. Dáníẹ́lì ni ó kọ́kọ́ rú òfin náà, níwọ̀n bí kò ti lè ṣe kí ó má gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. (Fi wé Ìṣe 5:29.) A ju Dáníẹ́lì olóòótọ́ sínú ihò kìnnìún láìka ìsapá ọba náà sí láti wá ọ̀nà àtiyí àṣẹ náà padà. Dáríúsì fi ìgbọ́kànlé sọ pé Ọlọ́run Dáníẹ́lì ní agbára láti pa wòlíì náà mọ́ láàyè.—Dáníẹ́lì 6:9-17.

Lẹ́yìn alẹ́ tí ó fi gbààwẹ̀ láìfojú ba oorun, kíá ni Dáríúsì forí lé ibi ihò kìnnìún náà. Inú rẹ̀ mà dùn o láti rí Dáníẹ́lì tí ó wà láàyè, láìsì ìpalára kankan! Kí ẹ̀san lè tètè ké, ojú ẹsẹ̀ ni ọba pàṣẹ pé kí a ju àwọn olùfisùn Dáníẹ́lì àti ìdílé wọn sínú ihò kìnnìún. Ó tún pàṣẹ pé ‘ní gbogbo àgbègbè ìṣàkóso ìjọba òun, kí àwọn ènìyàn máa wárìrì, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì.’—Dáníẹ́lì 6:18-27.

Ó ṣe kedere pé, Dáríúsì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì àti ẹ̀sìn rẹ̀, ó sì hára gàgà láti ṣe ẹ̀tọ́. Síbẹ̀, fífìyà jẹ àwọn olùfisùn Dáníẹ́lì ti gbọ́dọ̀ ru kèéta àwọn onípò àṣẹ yòókù sókè. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìkéde Dáríúsì tí ó fi pàṣẹ pé kí gbogbo ẹni tó wà lábẹ́ ìjọba “bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì” ti gbọ́dọ̀ dá ìkùnsínú ńláǹlà sílẹ̀ láàárín àwọn abọrẹ̀ Bábílónì. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí nípa lórí àwọn akọ̀wé òfin, kò lè yani lẹ́nu nígbà náà bí a bá yí àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé ìtàn padà láti yọ ẹ̀rí tí ó tan mọ́ Dáríúsì kúrò. Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ ṣókí ti inú ìwé Dáníẹ́lì fi Dáríúsì hàn gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso kan tí kì í ṣe ojúsàájú, tí ó sì jẹ́ onídàájọ́ òdodo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́