Ìbí Jésù—Òkodoro Rẹ̀
RONÚ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí tàgbàtèwe mọ̀ nípa orílẹ̀-èdè rẹ. Àkọsílẹ̀ rẹ̀ péye, kì í sì í ṣe òpìtàn kan ṣoṣo ló kọ̀wé nípa rẹ̀. Wàyí o, bí ẹnì kan bá wá sọ fún ọ pé nǹkan yẹn kò ṣẹlẹ̀ rí ńkọ́, pé àròsọ lásán ni? Àbí, ká kúkú mú àpẹẹrẹ ìwọ alára wá, bí ẹnì kan bá sọ pé irọ́ pátá ni púpọ̀ nínú ohun tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ ti sọ fún ọ nípa bí a ṣe bí baba ńlá rẹ àti àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ ńkọ́? Èyí tó wù kó jẹ́ nínú àpèjúwe méjèèjì yìí, ọ̀rọ̀ náà lè mú ọ bínú. Ó dájú pé, o kò wulẹ̀ ní gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́ láìrí ẹ̀rí tó dájú!
Síbẹ̀síbẹ̀, lónìí, àwọn aṣelámèyítọ́ kò gba àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere tí Mátíù àti Lúùkù kọ nípa ìbí Jésù gbọ́. Wọ́n ní àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí takora pátápátá, pé kò tilẹ̀ sí bí a ṣe lè mú wọn bára mu, wọ́n tún sọ pé irọ́ ńláńlá pẹ̀lú àṣìṣe rẹpẹtẹ ló kún inú àkọsílẹ̀ méjèèjì fọ́fọ́. Ṣóòótọ́ ni wọ́n ń sọ? Kàkà tí a óò fi wulẹ̀ gba irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ gbọ́, ẹ jẹ́ ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere náà. Lẹ́nu àyẹ̀wò ọ̀hún, ẹ jẹ́ ká rí ẹ̀kọ́ tí wọ́n lè kọ́ wa lónìí.
Ète Táa fi Kọ Wọ́n
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó dára bí a bá lè rántí ètè táa fi kọ àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí. Wọn kì í ṣe ìwé ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan; ìwé Ìhìn Rere ni wọ́n jẹ́. Ìyàtọ̀ yẹn ṣe pàtàkì. Nínú ìwé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹnì kan, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ojú ìwé lè kún fún bí òǹkọ̀wé náà ṣe ń sapá láti fi bí ẹni ìtàn náà ṣe di ẹni tó gbajúmọ̀ hàn. Nípa báyìí, àwọn òǹkọ̀wé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹnì kan máa ń lo ọ̀pọ̀ ojú ìwé láti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn òbí onítọ̀hún, bí a ṣe bí i, àti ohun tó ṣe nígbà tó wà lọ́mọdé. Ti àwọn ìwé Ìhìn Rere kò rí bẹ́ẹ̀. Nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí a ní, Ìhìn Rere ti Mátíù àti Lúùkù nìkan ló sọ nípa ìbí Jésù àti ìgbà ọmọdé rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ète wọn kì í ṣe láti fi bí Jésù ṣe di irú ènìyàn tó dà hàn. Rántí pé, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni ó jẹ́ ní ọ̀run tẹ́lẹ̀, kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 8:23, 58) Nítorí náà, Mátíù àti Lúùkù kò ṣatótónu nípa ìgbà ọmọdé Jésù kí wọ́n bàa lè sọ irú ènìyàn tó dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ète àwọn ìwé Ìhìn Rere náà mu.
Kí sì ni ète táa fi kọ wọ́n? Iṣẹ́ kan náà ni àwọn ọkùnrin méjèèjì jẹ́—pé Jésù ni Mèsáyà tí a ṣèlérí, tàbí Kristi; pé ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé; àti pé a jí i dìde sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n ipò àtilẹ̀wá àwọn òǹkọ̀wé méjèèjì yàtọ̀ síra gidigidi, àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni wọ́n kọ̀wé fún. Mátíù, tó jẹ́ agbowó òde, kọ̀wé tirẹ̀ ní pàtàkì fún àwọn Júù. Lúùkù, tó jẹ́ oníṣègùn, kọ̀wé sí “Tìófílọ́sì ẹni títayọlọ́lá jù lọ”—ẹni tó ṣeé ṣe kó wà ní ipò gíga—ní àfikún, a tún lè sọ pé ó kọ̀wé náà fún àwọn àwùjọ mìíràn bí àwọn Júù àti Kèfèrí. (Lúùkù 1:1-3) Òǹkọ̀wé kọ̀ọ̀kan yan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí òun gbà pé ó ṣe pàtàkì jù lọ, tó sì gbà pé ó lè tètè yí àwọn tí ó kọ̀wé sí lọ́kàn padà. Nípa báyìí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó ṣẹ sí Jésù lára ni àkọsílẹ̀ Mátíù tẹnu mọ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Lúùkù ní tirẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀nà tí àwọn ará ìgbàanì gbà ń sọ ìtàn wọn, irú èyí tí ó lè tètè yé àwọn tí kì í ṣe Júù tí ó kọ̀wé náà fún.
Abájọ tí àkọsílẹ̀ wọn fi yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ méjèèjì kò takora, gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣelámèyítọ́ ti sọ. Ṣe ni èkíní wulẹ̀ ṣe àṣekún èkejì, kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò sí nínú ìkan ń bẹ nínú èkejì, kí ọ̀rọ̀ wọn lè péye.
Ìbí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Mátíù àti Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ńláǹlà kan nípa ìbí Jésù—wúńdíá ló bí i. Mátíù fi hàn pé iṣẹ́ ìyanu yìí mú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Aísáyà ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ṣẹ. (Aísáyà 7:14; Mátíù 1:22, 23) Lúùkù ṣàlàyé pé a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nítorí tí ètò ìforúkọsílẹ̀ tí Késárì gbé kalẹ̀, mú kó pọndandan fún Jósẹ́fù àti Màríà láti rìnrìn àjò lọ síbẹ̀. (Wo àpótí lójú ewé 7.) Bíbí tí a bí Jésù sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe pàtàkì gan-an. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, wòlíì Míkà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú kan tí kò lókìkí nítòsí Jerúsálẹ́mù, ni Mèsáyà náà yóò ti wá.—Míkà 5:2.
Alẹ́ ọjọ́ ìbí Jésù ti wá di ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún Àwòrán Ìbí Jésù. Ṣùgbọ́n, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an yàtọ̀ sí ohun tí a sábà ń rí nínú àwòrán náà. Òpìtàn náà, Lúùkù, tó sọ fún wa nípa ètò ìkànìyàn tó gbé Jósẹ́fù àti Màríà wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tún sọ fún wa nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà ní gbangba ìta pẹ̀lú agbo ẹran wọn ní alẹ́ mánigbàgbé yẹn. Àwọn ipò méjèèjì yìí ti mú kí àwọn olùwádìí Bíbélì parí èrò sí pé, kò lè jẹ́ oṣù December ni a bí Jésù. Wọ́n tọ́ka sí i pé kò lè jẹ́ ìgbà òtútù àti ìgbà òjò yẹn ni Késárì pàṣẹ pé kí àwọn Júù, tó jẹ́ pé adárútúrútú ni wọ́n, máa fẹsẹ̀ rìn lọ sí ìlú wọn, níwọ̀n bí wọ́n sì ti ń dáná ọ̀tẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí lè túbọ̀ mú inú bí wọn. Bákan náà, àwọn ọ̀mọ̀wé ọ̀hún tún sọ pé, kò lè jẹ́ irú àkókò ojú ọjọ́ tí kò bára dé bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa wà ní gbangba ìta pẹ̀lú agbo ẹran wọn.—Lúùkù 2:8-14.
Ṣàkíyèsí pé kì í ṣe àwọn ọ̀mọ̀wé àti ògúnná gbòǹgbò aṣáájú ẹ̀sìn àkókò náà ni Jèhófà yàn láti kéde ìbí Ọmọ rẹ̀ fún, bí kò ṣe àwọn alágbàṣe lásánlàsàn tó jẹ́ ìta gbangba nilé wọn. Kò dájú pé àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn, àwọn tí ipò iṣẹ́ wọn kò jẹ́ kí wọ́n ráyè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin àtẹnudẹ́nu. Ṣùgbọ́n, lọ́nà tó buyì kún wọn, Ọlọ́run fojú rere hàn sí àwọn ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n tún jẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyí—ọ̀wọ́ àwọn áńgẹ́lì tí a yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú wá sọ fún wọn pé a ti bí Mèsáyà náà, tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti ń retí láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni wọ́n bẹ Màríà àti Jósẹ́fù wò, tí wọ́n sì rí ọmọ ọwọ́ jòjòló tí kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn náà ní ibùjẹ ẹran, kì í ṣe “àwọn ọba mẹ́ta” bí wọ́n ṣe sábà ń fi wọ́n hàn nínú Àwòrán Ìbí Jésù.—Lúùkù 2:15-20.
Jèhófà Ń Fojú Rere Hàn sí Àwọn Tí Ń Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Wá Òtítọ́
Ọlọ́run máa ń fojú rere hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń hára gàgà láti rí ìmúṣẹ ète rẹ̀. Èyí ni kókó tó hàn léraléra nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yí ìbí Jésù ká. Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn ìgbà tí a ti bí i, Jósẹ́fù àti Màríà gbé e lọ sí tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè ṣègbọràn sí Òfin Mósè, wọ́n sì fi “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” rúbọ. (Lúùkù 2:22-24) Lóòótọ́, àgbò ni Òfin ní kí wọ́n mú wá, àmọ́ bí ẹnì kan bá jẹ́ ẹni tí kò rí jájẹ, òfin náà yọ̀ǹda pé kó mú ohun tí kò gbówó lórí púpọ̀ wá. (Léfítíkù 12:1-8) Rò ó wò ná. Jèhófà Ọlọ́run, Ọba Aláṣẹ àgbáyé, kò yan ìdílé ọlọ́rọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yan ìdílé tálákà gẹ́gẹ́ bí agbo ilé tí a óò ti tọ́ Ọmọ rẹ̀ bíbí kan ṣoṣo dàgbà, ọmọ tó fẹ́ràn gidigidi. Bí o bá jẹ́ òbí, ó yẹ kí èyí rán ọ létí pé ẹ̀bùn dídára jù lọ tí o lè fún àwọn ọmọ rẹ—ẹ̀bùn tó dára ju ohun ìní ti ara tàbí ẹ̀kọ́ ìwé tó yanjú—ni ìdílé tó fi ohun tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́.
Nínú tẹ́ńpìlì náà, Jèhófà tún ṣojú rere sí àwọn méjì mìíràn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ olùjọsìn, tí wọ́n sì tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Ánà, opó ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, tí “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” (Lúùkù 2:36, 37) Ẹnì kejì ni àgbàlagbà kan tó jẹ́ olóòótọ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síméónì. Àwọn méjèèjí ni àǹfààní tí Ọlọ́run fún wọn dùn mọ́ nínú gidigidi—kí wọ́n tó kú, wọ́n fojú ara wọn rí ẹni náà tí yóò di Mèsáyà tí a ti ṣèlérí. Síméónì sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan sórí ọmọ náà. Ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó kún fún ìrètí, àmọ́ tí ó múni sorí kọ́ lọ́nà kan. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé, lọ́jọ́ ọjọ́ kan ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ìyá àbúrò yìí, Màríà, yóò ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ yìí tó fẹ́ràn jọjọ.—Lúùkù 2:25-35.
Ọmọ Kan Tó Wà Nínú Ewu
Àsọtẹ́lẹ̀ Síméónì jẹ́ ìránnilétí bíbani nínú jẹ́ pé ọmọ tí kò lẹ́ṣẹ̀ lọ́rùn yìí yóò di ẹni tí àwọn èèyàn kórìíra. Kò tilẹ̀ tí ì já lẹ́nu ọmú tí ìkórìíra yìí ti bẹ̀rẹ̀. Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá, Jósẹ́fù, Màríà, àti Jésù ń gbé nínú ilé kan ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì wá bẹ̀ wọ́n wò. Láìka ohun tí ọ̀pọ̀ Àwòrán Ìbí Jésù fi hàn, Mátíù kò sọ ní pàtó iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí tó wá, bẹ́ẹ̀ sì ni kò pè wọ́n ni “amòye,” ká má tilẹ̀ wá sọ pé “àwọn ọba mẹ́ta.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, maʹgoi, tó túmọ̀ sí “awòràwọ̀” ló lò. Èyí nìkan gan-an ti tó fún òǹkàwé láti lóye pé ẹni ibi kan ló wà nídìí ọ̀ràn yìí, nítorí pé ìwòràwọ̀ jẹ́ iṣẹ́ kan tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà léèwọ̀, àwọn Júù olóòótọ́ sì máa ń yàgò pátápátá fún un.—Diutarónómì 18:10-12; Aísáyà 47:13, 14.
Ìràwọ̀ kan láti ìlà oòrùn ni àwọn awòràwọ̀ wọ̀nyí tẹ̀ lé wá, wọ́n sì mú ẹ̀bùn lọ́wọ́ tí wọn fẹ́ fún “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù.” (Mátíù 2:2) Àmọ́ ìràwọ́ náà kò mú wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Jerúsálẹ́mù, lọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù Ńlá, ló mú wọn lọ. Kò sẹ́ni bẹ́ẹ̀ ní ayé yìí tó ní agbára, tó sì tún ní èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn láti ṣèpalára fún ọmọ kékeré náà Jésù. Ọkùnrin apànìyàn, ọlọ́kàn gíga yìí ti pa ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ ìbátan rẹ̀ pàápàá, tí ó kà sí ewu.a Nítorí tí gbígbọ́ nípa ìbí ẹni tí yóò di “ọba àwọn Júù” lọ́jọ́ iwájú kó ìdààmú bá a, ó rán àwọn awòràwọ̀ láti wá Onítọ̀hún rí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Bí wọ́n ti ń lọ, ohun àràmàǹdà kan ṣẹlẹ̀. Ó mà dà bí pé “ìràwọ̀” tí wọ́n rí, tó mú kí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, ń sún síwájú!—Mátíù 2:1-9.
Wàyí o, bóyá ìmọ́lẹ̀ gidi lójú ọ̀run ni èyí jẹ́ ni o, tàbí ìran kan ni o, a kò mọ̀. Àmọ́ ohun kan tó dá wa lójú ni pé “ìràwọ̀” yìí, kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí ète ibi tó wà lẹ́yìn rẹ̀, kò ṣe méní, kò ṣe méjì, ó mú àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyí lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù—ọmọ kékeré tí kò lè gbèjà ara rẹ̀, tí kò sì lè dáàbò bo ara rẹ̀, tó jẹ́ pé káfíńtà lásán àti aya rẹ̀ ló ń dáàbò bò ó. Àwọn awòràwọ̀, tí Hẹ́rọ́dù ti ponú wọ́n pọ̀ yìí ì bá padà wá ròyìn fún ọba tó fẹ́ gbẹ̀san náà, èyí ì bá sì yọrí sí pípa ọmọ náà. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àlá Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà, ó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà mìíràn padà sílé. Nítorí náà, irin iṣẹ́ Sátánì, ọ̀tá Ọlọ́run ni “ìràwọ̀” náà, ẹni tí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó bá rí láti pa Mèsáyà náà. Ẹ kò rí bí fífi tí Àwòrán Ìbí Jésù fi “ìràwọ̀” àti àwọn awòràwọ̀ náà hàn bí aṣojú Ọlọ́run ti jẹ́ irọ́ pátápátá tó!—Mátíù 2:9-12.
Síbẹ̀, Sátánì kò dẹ́kun iṣẹ́ ibi rẹ̀. Ẹni tó lò láti mú ète rẹ̀ ṣẹ nínú ọ̀ràn yìí, Ọba Hẹ́rọ́dù, pàṣẹ pé kí a pa gbogbo ọmọ ọwọ́ tí kò tí ì pé ọmọ ọdún méjì tó bá wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àmọ́, Sátánì kò lè borí Jèhófà. Mátíù sọ pé, tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti mọ̀ pé pípa àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì nípakúpa báyìí yóò wáyé. Jèhófà tún gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ sí Sátánì lẹ́ẹ̀kan sí i, ó lo áńgẹ́lì kan láti kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé kí ó wá ààbò lọ sí Íjíbítì. Mátíù ròyìn pé, nígbà tó ṣe díẹ̀, Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ tí kò tóbi púpọ̀ tún ṣí kúrò níbẹ̀, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n wá fìdí kalẹ̀ sí Násárétì, níbi tí Jésù pẹ̀lú àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin dàgbà sí.—Mátíù 2:13-23; 13:55, 56.
Ìbí Kristi—Ohun Tó Túmọ̀ Sí fún Ọ
Ǹjẹ́ àkópọ̀ yìí nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yí ìbí Jésù àti ìgbà ọmọdé rẹ̀ ká ha yà ọ́ lẹ́nu? Ó ń ya ọ̀pọ̀ lẹ́nu. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí i pé àkọsílẹ̀ náà bára mu, ó sì péye, láìka àwọn èèyàn kan sí tí ń pariwo ẹnu kiri pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti mọ̀ pé a ti sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Ó sì yà wọ́n lẹ́nu pé àwọn kókó pàtàkì kan nínú àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí àwọn ìtàn tí a sábà ń gbọ́ nípa ìbí Jésù àti Àwòrán Ìbí rẹ̀ tí a sábà ń rí fi kọ́ni.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí tó yani lẹ́nu jù lọ ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ayẹyẹ tí ń bá Kérésìmesì rìn ti sọ àwọn kókó pàtàkì inú ìtàn Ìhìn Rere nù. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí kókó náà pé, Jèhófà Ọlọ́run ni Baba Jésù—kì í ṣe Jósẹ́fù. Ìwọ náà fojú inú wo irú ìmọ̀lára tí yóò ní fún fífi Ọmọ rẹ̀ tó fẹ́ràn gidigidi síkàáwọ́ Jósẹ́fù àti Màríà láti tọ́ ọ dàgbà, kí wọ́n sì gbọ́ bùkátà rẹ̀. Tún ronú lórí ìrora ọkàn tí Baba rẹ̀ lókè ọ̀run yóò ní nítorí jíjẹ́ kí Ọmọ òun dàgbà nínú ayé kan tí ọba kan tí ìkà kún inú rẹ̀, yóò ti gbìmọ̀ láti pa ọmọ náà, àní nígbà tó ṣì wà ní ọmọ pínníṣín! Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní fún aráyé ló mú kí ó ṣe ìrúbọ yìí.—Jòhánù 3:16.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni Jésù alára ti di ẹni tí a gbàgbé nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì. Họ́wù, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ó sọ ọjọ́ ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀rí kankan pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe àyájọ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀.
Jésù kò pàṣẹ ṣíṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ọjọ́ ikú rẹ̀—àti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ nínú ìtàn—ni ó pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa ṣe. (Lúùkù 22:19, 20) Rárá o, Jésù kò sọ pé kí a máa rántí òun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́ tí kò lè gbèjà ara rẹ̀ tó wà ní ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí ní ipò yẹn mọ́ báyìí. Ní ohun tó ju ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí a pa Jésù, ó fi ara rẹ̀ hàn nínú ìran fún àpọ́sítélì Jòhánù bí Ọba alágbára tí ń gẹṣin lọ sójú ogun. (Ìṣípayá 19:11-16) Ipa tó ń kó yìí, gẹ́gẹ́ bí Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, ló yẹ ká fi máa rántí Jésù lónìí, nítorí òun jẹ́ Ọba tí yóò yí ayé padà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àní, Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì sọ pé ó sàn kí èèyàn jẹ́ ẹlẹ́dẹ̀ Hẹ́rọ́dù ju kí onítọ̀hún jẹ́ ọmọ Hẹ́rọ́dù.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣé Irọ́ ni Lúùkù Pa?
BÁWO ni Jésù tó gbé Násárétì dàgbà, tí gbogbo ayé mọ̀ sí ará Násárétì, ṣe wá di ẹni tí a bi ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà sí Násárétì? Lúùkù ṣàlàyé pé: “Wàyí o, ní ọjọ́ wọnnì [ká tó bí Jésù] àṣẹ àgbékalẹ̀ kan jáde lọ láti ọ̀dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé forúkọ sílẹ̀; (ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà Síríà;) gbogbo ènìyàn sì ń rin ìrìn àjò lọ láti forúkọ sílẹ̀, olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀.”—Lúùkù 1:1; 2:1-3.
Àwọn aṣelámèyítọ́ máa ń tako àyọkà yìí gidigidi, wọ́n ní àṣìṣe gbáà ni, àwọn mìíràn tilẹ̀ sọ pé irọ́ gbuu ni. Wọn ò gbà póòótọ́ lọ́rọ̀ yìí, wọ́n ní ọdún 6 tàbí 7 ti Sànmánì Tiwa ni ìkànìyàn yìí wáyé àti pé ìgbà yẹn ní Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà. Bó bá lọ jẹ́ pé òótọ́ ní ohun tí wọ́n sọ yìí, èyí yóò mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyè méjì gidigidi nípa àkọsílẹ̀ Lúùkù, nítorí ẹ̀rí fi hàn pé ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa la bí Jésù. Ṣùgbọ́n, àwọn aṣelámèyítọ́ wọ̀nyí kò ka kókó pàtàkì méjì sí. Àkọ́kọ́, Lúùkù gbà pé ìkànìyàn tó wáyé kì í ṣe ẹyọ kan ṣoṣo—ṣàkíyèsí pé ó sọ pé “ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí.” Ó mọ̀ pé ìforúkọsílẹ̀ mìíràn wáyé. (Ìṣe 5:37) Ìkànìyàn mìíràn yìí náà ni òpìtàn Josephus sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èyí tó wáyé ní ọdún 6 ṣááju Sànmánì Tiwa. Èkejì, ìgbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà kò fi dandan túmọ̀ sí pé ìgbà yẹn gan-an la bí Jésù. Èé ṣe? Ìdí ni pé, ó hàn gbangba pé, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Kúírínọ́sì ṣe gómìnà. Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé ló gbà pé nǹkan bí ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa ni ti ìgbà àkọ́kọ́.
Àwọn aṣelámèyítọ́ kan sọ pé, Lúùkù fúnra rẹ̀ ló hùmọ̀ ìkànìyàn yìí, kí ó bàa lè rí nǹkan fi tì í lẹ́yìn pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù la bí Jésù sí, kí àsọtẹ́lẹ̀ Míkà 5:2 bàa lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ. Wọ́n ní àbá èrò orí yìí sọ Lúùkù di òpùrọ́ paraku, àmọ́ kò sí aṣelámèyítọ́ kan tó lè fìdí ẹ̀sùn tí a fi kan òpìtàn tí kì í ṣe oníwàdùwàdù yìí múlẹ̀, ẹni tó jẹ́ pé òun ló kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù àti ìwé Ìṣe.
Ohun mìíràn tí kò sí aṣelámèyítọ́ kankan tó lè ṣàlàyé rẹ̀ tún rèé: Ìkànìyàn náà gan-an tún mú àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ! Ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa alákòóso kan tí yóò “mú kí afipámúni la ìjọba ọlọ́lá ńlá náà kọjá.” Ǹjẹ́ èyí kan Ọ̀gọ́sítọ́sì àti àṣẹ tó pa láti kànìyàn ní Ísírẹ́lì? Ó dáa, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ ní sísọ pé nígbà ìṣàkóso ẹni tí yóò gbapò lọ́wọ́ alákòóso yìí, a óò “ṣẹ́” Mèsáyà náà, tàbí “Aṣáájú májẹ̀mú náà.” Lóòótọ́, wọ́n “ṣẹ́” Jésù, wọ́n pa á, nígbà ìṣàkóso ẹni tó gbapò lọ́wọ́ Ọ̀gọ́sítọ́sì, ìyẹn ni Tìbéríù.—Dáníẹ́lì 11:20-22.
[Àwọn àwòrán]
Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì (27 B.C.E.–14 C.E.)
Késárì Tìbéríù (14-37 C.E.)
[Àwọn Credit Line]
Musée de Normandie, Caen, France
Fọ́tò tí a yà pẹ̀lú àṣẹ British Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Áńgẹ́lì Jèhófà fi ìhìn rere nípa ìbí Kristi ṣojú rere sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀