ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/15 ojú ìwé 15-20
  • Ọjọ́ Ìgbàlà Nìyí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ́ Ìgbàlà Nìyí!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àwa Ń Yí Àwọn Ènìyàn Lérò Padà”
  • Ìfẹ́ Kristi Ha Ń Mú Kí O Sọ Iṣẹ́ Ìwàásù Di Ọ̀ranyàn Bí?
  • “Ẹ Padà Bá Ọlọ́run Rẹ́”
  • ‘Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà Gan-an’
  • ‘Dídámọ̀ràn Ara Wa Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run’
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Ìgbàlà Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà
  • “Ìsinsìnyí Gan-an Ni Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Jẹ́ Kí “Ìrètí Ìgbàlà” Wà Lọ́kàn Rẹ Digbí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹ Jẹ́ Kí Aráyé Gbọ́ Ìhìn Rere Nípa Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìgbàlà Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-An
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/15 ojú ìwé 15-20

Ọjọ́ Ìgbàlà Nìyí!

“Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 6:2.

1. Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ wa láti lè ní ìdúró tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run àti Kristi?

JÈHÓFÀ ti dá ọjọ́ ìdájọ́ aráyé. (Ìṣe 17:31) Bí yóò bá jẹ́ ọjọ́ ìgbàlà fún wa, ó di dandan ká mú ìdúró tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú rẹ̀ àti lójú Jésù Kristi, Onídàájọ́ tí ó yàn. (Jòhánù 5:22) Irú ìdúró bẹ́ẹ̀ ń béèrè fún ìwà tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu àti ìgbàgbọ́ tí yóò sún wa láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti di ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

2. Èé ṣe tí ayé aráyé fi di àjèjì sí Ọlọ́run?

2 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, ayé aráyé ti di àjèjì sí Ọlọ́run. (Róòmù 5:12; Éfésù 4:17, 18) Fún ìdí yìí, àfi bí àwọn tí a ń wàásù fún bá padà bá Ọlọ́run rẹ́ nìkan ni wọ́n fi lè jèrè ìgbàlà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú èyí ṣe kedere nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò 2 Kọ́ríńtì 5:10–6:10, kí a lè gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìdájọ́, pípadà bá Ọlọ́run rẹ́, àti ìgbàlà.

“Àwa Ń Yí Àwọn Ènìyàn Lérò Padà”

3. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe “ń yí àwọn ènìyàn lérò padà,” èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?

3 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìdájọ́ àti ìwàásù bára tan nígbà tó kọ̀wé pé: “A gbọ́dọ̀ fi gbogbo wa hàn kedere níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí olúkúlùkù lè gba ìpín èrè tirẹ̀ fún àwọn ohun tí ó ti ṣe nínú ara, gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun tí ó ti fi ṣe ìwà hù, yálà ó jẹ́ rere tàbí búburú. Nítorí náà, ní mímọ ìbẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí àwọn ènìyàn lérò padà.” (2 Kọ́ríńtì 5:10, 11) Àpọ́sítélì náà “ń yí àwọn ènìyàn lérò padà” nípa wíwàásù ìhìn rere. Àwa ńkọ́? Níwọ̀n bí a ti dojú kọ òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ó yẹ kí a sa gbogbo ipá wa láti yí àwọn ènìyàn lérò padà kí wọ́n lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó pọndandan láti rí ìdájọ́ rere gbà lọ́dọ̀ Jésù, kí wọ́n sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà Ọlọ́run, Orísun ìgbàlà.

4, 5. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ ká máa ṣògo nípa àwọn àṣeyọrí wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣògo “fún Ọlọ́run”?

4 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká máa ṣògo nítorí pé Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ní Kọ́ríńtì, àwọn kan máa ń wú fùkẹ̀ tàbí kí wọ́n máa gbé àwọn ẹlòmíràn ga, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fa ìyapa nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 1:10-13; 3:3, 4) Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ipò yìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwa kò tún máa dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà yín mọ́, ṣùgbọ́n a ń fún yín ní ìsúnniṣe fún ìṣògo nípa wa, kí ẹ lè ní ìdáhùn fún àwọn tí ń ṣògo lórí ìrísí òde ṣùgbọ́n tí kì í ṣe lórí ọkàn-àyà. Nítorí bí orí wa bá yí, fún Ọlọ́run ni; bí orí wa bá pé, fún yín ni.” (2 Kọ́ríńtì 5:12, 13) Àwọn agbéraga kò bìkítà nípa ìrẹ́pọ̀ àti ipò tẹ̀mí ìjọ. Kí wọ́n máa ṣògo nínú ìrísí òde nìkan ni wọ́n mọ̀, dípò tí wọn ì bá fi máa ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti ní ọkàn-àyà rere níwájú Ọlọ́run. Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù bá ìjọ náà wí, ó sì sọ lẹ́yìn náà pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.”—2 Kọ́ríńtì 10:17.

5 Pọ́ọ̀lù alára kò ha ṣògo bí? Àwọn kan lè rò bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tó sọ nípa jíjẹ́ tí òun jẹ́ àpọ́sítélì. Ṣùgbọ́n ìṣògo rẹ̀, “fún Ọlọ́run ni.” Ó ṣògo nípa ẹ̀rí ìtóótun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, kí àwọn ará Kọ́ríńtì má bàa fi Jèhófà sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù ṣe èyí kí ó bàa lè mú wọn padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nítorí pé àwọn èké àpọ́sítélì ti kọrí wọn sígbó. (2 Kọ́ríńtì 11:16-21; 12:11, 12, 19-21; 13:10) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kò bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ṣe fọ́ńté sí gbogbo ènìyàn.—Òwe 21:4.

Ìfẹ́ Kristi Ha Ń Mú Kí O Sọ Iṣẹ́ Ìwàásù Di Ọ̀ranyàn Bí?

6. Ipa wo ló yẹ kí ìfẹ́ Kristi ní lórí wa?

6 Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì tòótọ́, Pọ́ọ̀lù kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa ẹbọ ìràpadà Jésù. Ó nípa lórí ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù, nítorí ó kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọ́n ti kú; ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Ìfẹ́ tí Jésù fi hàn nípa fífi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa mà ga o! Dájúdájú, ó yẹ kí ìfẹ́ yẹn jẹ́ agbára tí ń sún wa ṣiṣẹ́. Ìmọrírì fún fífi tí Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa yẹ kí ó sún wa láti máa fi tìtara-tìtara pòkìkí ìhìn rere ìgbàlà tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòhánù 3:16; fi wé Sáàmù 96:2.) “Ìfẹ́ tí Kristi ní” ha ń mú kí o sọ ọ́ di ọ̀ranyàn láti máa fi ìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí?—Mátíù 28:19, 20.

7. Kí ló túmọ̀ sí láti ‘má ṣe mọ ènìyàn kankan nípa ti ẹran ara’?

7 Nípa lílo ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Kristi ṣe fún wọn, àwọn ẹni àmì òróró ‘kò wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún un.’ Pọ́ọ̀lù wí pé: “Nítorí náà, láti ìsinsìnyí lọ, a kò mọ ènìyàn kankan nípa ti ẹran ara. Bí a tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ẹran ara, dájúdájú, a kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́ nísinsìnyí.” (2 Kọ́ríńtì 5:16) Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ máa fi ojú ti ẹran ara wo àwọn ènìyàn, bóyá kí wọ́n máa gbé àwọn Júù lékè àwọn Kèfèrí tàbí kí wọ́n máa gbé ọlọ́rọ̀ lékè tálákà. Àwọn ẹni àmì òróró “kò mọ ènìyàn kankan nípa ti ẹran ara,” nítorí pé ìbátan tẹ̀mí tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ló ṣe pàtàkì. Àwọn tó “mọ Kristi nípa ti ẹran ara” kì í wulẹ̀ ṣe kìkì àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó rí Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Àní bí àwọn kan tó ní ìrètí nínú Mèsáyà bá fìgbà kan rí ka Kristi sí ẹlẹ́ran ara, wọn kò gbọ́dọ̀ fojú yẹn wò ó mọ́. Ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà, a sì jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè. Àwọn yòókù tí a jí dìde sí ìyè ti ọ̀run yóò bọ́ ẹran ara wọn sílẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n rí Jésù Kristi rí nínú ẹran ara.—1 Kọ́ríńtì 15:45, 50; 2 Kọ́ríńtì 5:1-5.

8. Báwo ni àwọn kan ṣe wá wà “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi”?

8 Pọ́ọ̀lù ṣì ń bá àwọn ẹni àmì òróró sọ̀rọ̀, ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ìṣẹ̀dá tuntun ni ó jẹ́; àwọn ohun ògbólógbòó ti kọjá lọ, wò ó! àwọn ohun tuntun ti wá wà.” (2 Kọ́ríńtì 5:17) Láti “wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi” túmọ̀ sí láti gbádùn jíjẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. (Jòhánù 17:21) Ìbátan yìí di tonítọ̀hún nígbà tí Jèhófà fà á sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ bí onítọ̀hún. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí, ó ti di “ìṣẹ̀dá tuntun” pẹ̀lú ìrètí ṣíṣàjọpín Ìjọba ọ̀run pẹ̀lú Kristi. (Jòhánù 3:3-8; 6:44; Gálátíà 4:6, 7) A ti fún irúfẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ga lọ́lá.

“Ẹ Padà Bá Ọlọ́run Rẹ́”

9. Kí ni Ọlọ́run ti ṣe láti mú pípadà bá òun rẹ́ ṣeé ṣe?

9 Ojú rere Jèhófà lórí “ìṣẹ̀dá tuntun” yìí mà pọ̀ o! Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun gbogbo wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó tipasẹ̀ Kristi mú wa padà bá ara rẹ̀ rẹ́, tí ó sì fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́, èyíinì ni, pé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi ń mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́, láìṣírò àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn, ó sì fi ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ náà lé wa lọ́wọ́.” (2 Kọ́ríńtì 5:18, 19) Aráyé ti di àjèjì sí Ọlọ́run láti ìgbà tí Ádámù ti ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ fa ojú wa mọ́ra nípa ṣíṣí ọ̀nà ìpadàrẹ́ sílẹ̀ nípasẹ̀ ẹbọ Jésù.—Róòmù 5:6-12.

10. Àwọn wo ni Jèhófà fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́ lé lọ́wọ́, kí sì ni wọ́n ti ṣe láti lè ṣe é parí?

10 Jèhófà ti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́ lé àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́, fún ìdí yìí Pọ́ọ̀lù lè sọ pé: “Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa. Gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’” (2 Kọ́ríńtì 5:20) Láyé àtijọ́, àwọn ikọ̀ ni a sábà máa ń rán nígbà tí gbúngbùngbún bá wáyé, láti rí i bóyá ogun ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. (Lúùkù 14:31, 32) Níwọ̀n bí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ ti di àjèjì sí Ọlọ́run, ó ti rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ ẹni àmì òróró láti lọ sọ fún àwọn ènìyàn nípa àwọn ohun tí òun lànà sílẹ̀ fún ìpadàrẹ́. Gẹ́gẹ́ bí adípò fún Kristi, àwọn ẹni àmì òróró ń bẹ̀bẹ̀ pé: “Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.” Ẹ̀bẹ̀ yìí jẹ́ àrọwà tí ń fi tàánú-tàánú rọni láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti láti tẹ́wọ́ gba ìgbàlà tí òun mú kí ó ṣeé ṣe nípasẹ̀ Kristi.

11. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà, àwọn wo níkẹyìn ni yóò jèrè ìdúró òdodo lójú Ọlọ́run?

11 Gbogbo ènìyàn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà lè padà bá Ọlọ́run rẹ́. (Jòhánù 3:36) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni náà [Jésù] tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀ ni òun [Jèhófà] sọ di ẹ̀ṣẹ̀ fún wa, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 5:21) Jésù, ọkùnrin pípé náà, ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ọmọ Ádámù tí a óò dá nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá. Wọ́n di “òdodo Ọlọ́run” nípasẹ̀ Jésù. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ló kọ́kọ́ rí òdodo, tàbí ìdúró òdodo yìí gbà níwájú Ọlọ́run. Nígbà Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé, àwọn ọmọ orí ilẹ̀ ayé ti Jésù Kristi, Baba Ayérayé, yóò rí ìdúró òdodo gbà. Òun yóò gbé wọn dé ìdúró òdodo nínú ìjẹ́pípé kí wọ́n bàa lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun.—Aísáyà 9:6; Ìṣípayá 14:1; 20:4-6, 11-15.

‘Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà Gan-an’

12. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ pàtàkì wo ni àwọn ikọ̀ àti aṣojú Jèhófà ń ṣe?

12 Láti lè rí ìgbàlà, a gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, pé: “Ní bíbá a [Jèhófà] ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀. Nítorí ó wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” (2 Kọ́ríńtì 6:1, 2) Àwọn ẹni àmì òróró ikọ̀ Jèhófà àti àwọn aṣojú rẹ̀, “àwọn àgùntàn mìíràn,” kò tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Baba wọn ọ̀run kí wọ́n sì wá tàsé ète rẹ̀. (Jòhánù 10:16) Nípa ìwà mímọ́ wọn àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ onítara wọn ní “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” yìí, wọ́n ń wá ojú rere Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ fún àwọn olùgbé ayé pé “ọjọ́ ìgbàlà” nìyí.

13. Kí ni kókó pàtàkì ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 49:8, báwo sì ni ó ṣe kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ?

13 Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Aísáyà 49:8, tó kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo ti dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́; mo sì ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ kí n lè pèsè rẹ gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti tún ilẹ̀ náà ṣe, láti mú kí a gba àwọn ohun ìní àjogúnbá tí ó ti di ahoro padà.’” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ nígbà tí a tú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní oko ẹrú Bábílónì, tí wọ́n sì padà lẹ́yìn náà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn tí kò lólùgbé.—Aísáyà 49:3, 9.

14. Báwo ni Aísáyà 49:8 ṣe ní ìmúṣẹ nínú ọ̀ràn Jésù?

14 Nínú ìmúṣẹ síwájú sí i ti àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Jèhófà fi Jésù “ìránṣẹ́” rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí ìgbàlà [Ọlọ́run] lè wá títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 49:6, 8; fi wé Aísáyà 42:1-4, 6, 7; Mátíù 12:18-21.) Ó ṣe kedere pé “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” náà ṣeé lò fún Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó gbàdúrà, Ọlọ́run sì ‘dá a lóhùn.’ Èyíinì jẹ́ “ọjọ́ ìgbàlà” fún Jésù nítorí pé ó pa ìwà títọ́ pípé mọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ “di ẹni tí ó ní ẹrù iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣègbọràn sí i.”—Hébérù 5:7, 9; Jòhánù 12:27, 28.

15. Láti ìgbà wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí ti sapá láti fi hàn pé àwọn yẹ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, pẹ̀lú ète wo sì ni?

15 Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 49:8 fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘má tàsé ète inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run’ nípa kíkùnà láti wá ojú rere rẹ̀ ní “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” àti ní “ọjọ́ ìgbàlà” tí òun mú kó ṣeé ṣe. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” (2 Kọ́ríńtì 6:2) Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí ti sapá láti fi hàn pé àwọn yẹ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” lè jẹ́ “ọjọ́ ìgbàlà” fún wọn.

‘Dídámọ̀ràn Ara Wa Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run’

16. Lábẹ́ àwọn ipò líle koko wo ni Pọ́ọ̀lù ti dámọ̀ràn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run?

16 Àwọn kan tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kọ́ríńtì kò yẹ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Wọ́n ba Pọ́ọ̀lù lórúkọ jẹ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ ba ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹra fún dídi “okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀.” Dájúdájú, ó dámọ̀ràn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run “nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, nípa àwọn ìṣòro, nípa lílù, nípa ẹ̀wọ̀n, nípa rúgúdù, nípa òpò, nípa àwọn òru àìlèsùn, nípa àwọn àkókò àìsí oúnjẹ.” (2 Kọ́ríńtì 6:3-5) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé bí àwọn alátakò òun bá jẹ́ òjíṣẹ́, òun alára jẹ́ bẹ́ẹ̀ “lọ́nà tí ó túbọ̀ ta yọ” nítorí pé òun jìyà jù wọ́n lọ, ì báà jẹ́ ní ti ìfinisẹ́wọ̀n, líluni, ìdojúkọ ewu, àti ìfi-nǹkan-duni.—2 Kọ́ríńtì 11:23-27.

17. (a) Nípa fífi àwọn ànímọ́ wo hàn ni a fi lè dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí ni “àwọn ohun ìjà òdodo”?

17 Bí Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, a lè dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Báwo? “Nípa ìmọ́gaara,” tàbí ìwà mímọ́, àti nípa híhùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye ti Bíbélì. A lè dámọ̀ràn ara wa “nípa ìpamọ́ra,” fífi sùúrù fara da ìwà àìtọ́ tí a hù síni tàbí ìmúnibínú, àti “nípa inú rere” bí a ti ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Síwájú sí i, a lè dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run nípa títẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí rẹ̀, níní “ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè,” sísọ òtítọ́ àti gbígbára lé e fún agbára láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa parí. Ó gba àfiyèsí pé Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé òjíṣẹ́ lòun “nípasẹ̀ àwọn ohun ìjà òdodo ní ọwọ́ ọ̀tún àti ní òsì.” Nígbà ogun láyé àtijọ́, ọwọ́ ọ̀tún ni a sábà fi ń mú idà, tí a ó sì wá fi ọwọ́ òsì di apata mú. Nínú ogun tẹ̀mí tí a ń bá àwọn olùkọ́ èké jà, Pọ́ọ̀lù kò lo àwọn ohun ìjà ti ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀—ìwà békebèke, ìwà àgálámàṣà, ìwà ẹ̀tàn. (2 Kọ́ríńtì 6:6, 7; 11:12-14; Òwe 3:32) Ó lo “àwọn ohun ìjà” òdodo tàbí ọ̀nà òdodo fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́. Ohun tó yẹ kí àwa náà máa lò nìyẹn.

18. Bí ó bá ṣe pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wá, báwo ni a ó ṣe máa ṣe?

18 Bí ó bá ṣe pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wá, bí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ làwa náà yóò máa ṣe. A ó máa hu ìwà Kristẹni, yálà a pọ́n wa lé tàbí a tàbùkù sí wa. Ìròyìn búburú nípa wa kì yóò dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní bẹ̀rẹ̀ sí ṣògo bí wọ́n bá ròyìn wa ní rere. A óò máa sọ òtítọ́, àwọn ènìyàn sì lè mọ̀ wá mọ àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run tí a ń ṣe. Nígbà tí ìkọlù ọ̀tá tó lè gbẹ̀mí ẹni bá dojú kọ wá, a óò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A ó sì fọpẹ́ gba ìbáwí.—2 Kọ́ríńtì 6:8, 9.

19. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe láti “sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀” nípa tẹ̀mí?

19 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń parí ìjíròrò rẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́, ó sọ pé òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun rí “bí ẹni tí ó kárí sọ ṣùgbọ́n tí ń yọ̀ nígbà gbogbo, bí òtòṣì ṣùgbọ́n tí ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 6:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òjíṣẹ́ náà ní ìdí láti banújẹ́ nítorí ìpọ́njú tó dé bá wọn, wọ́n ní ìdùnnú ọkàn. Wọ́n tòṣì nípa ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n “sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀” nípa tẹ̀mí. Ká sòótọ́, wọ́n “ní ohun gbogbo” nítorí pé ìgbàgbọ́ wọn sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí—títí kan àǹfààní dídi ọmọ Ọlọ́run lókè ọ̀run. Wọ́n gbé ìgbé-ayé gbígbámúṣé àti aláyọ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni òjíṣẹ́. (Ìṣe 20:35) Bí tiwọn, a lè “sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀” nípa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́ nísinsìnyí—ní ọjọ́ ìgbàlà yìí!

Gbẹ́kẹ̀ Lé Ìgbàlà Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà

20. (a) Kí ni ìfẹ́ àtọkànwá Pọ́ọ̀lù, èé sì ti ṣe tí kò gbọ́dọ̀ sí fífi àkókò ṣòfò? (b) Kí ló sàmì sí ọjọ́ ìgbàlà tí a ń gbé nísinsìnyí?

20 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ló kù fún ètò àwọn nǹkan Júù. Àpọ́sítélì náà fi taratara fẹ́ pé kí àwọn Júù àti Kèfèrí padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ Kristi. Ọjọ́ ìgbàlà ni wọ́n wà, wọn kò sì gbọ́dọ̀ fàkókò ṣòfò. Tóò, àwa náà ti wà ní ìparí ètò àwọn nǹkan láti ọdún 1914. Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé báyìí ń sàmì sí àkókò yìí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìgbàlà.

21. (a) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdọọdún wo ni a ti yàn fún ọdún 1999? (b) Kí ló yẹ ká máa ṣe ní ọjọ́ ìgbàlà yìí?

21 Ó pọndandan kí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa ìpèsè Ọlọ́run fún ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Kristi. A kò gbọ́dọ̀ fi nǹkan falẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” Ọ̀rọ̀ wọnnì láti inú 2 Kọ́ríńtì 6:2 ni yóò jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 1999 fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó mà bá a mu o, nítorí pé a dojú kọ ohun kan tó tún burú ju ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀! Òpin gbogbo ètò àwọn nǹkan yìí, tí yóò kan gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ti sún mọ́lé gírígírí. Ìsinsìnyí ló yẹ ká gbégbèésẹ̀, kì í ṣe ọ̀la. Bí a bá gbà pé ti Jèhófà ni ìgbàlà, bí a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí a sì fojú ribiribi wo ìyè ayérayé, a kò ní tàsé ète inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá láti bọlá fún Jèhófà, àwa yóò fi hàn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe pé ó tọkàn wa wá nígbà tí a polongo pé: “Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Èé ṣe tí pípadà bá Ọlọ́run rẹ́ fi ṣe kókó?

◻ Àwọn wo ni ikọ̀ àti aṣojú tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́?

◻ Báwo ni a ṣe lè dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run?

◻ Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 1999 ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ sí fún ọ?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bí Pọ́ọ̀lù, o ha ń fi ìtara wàásù, tí o sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti padà bá Ọlọ́run rẹ́?

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ilẹ̀ Faransé

Cote d’Ivoire

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ní ọjọ́ ìgbàlà yìí, ǹjẹ́ o wà lára àwọn ògìdìgbó tí ń padà bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́