ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 2/15 ojú ìwé 13-18
  • Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímú Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú Kúrò
  • Kíkájú Ohun Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Ń Náni
  • “Ìràpadà Tí Ó Ṣe Rẹ́gí”
  • Ìtóye Ìwàláàyè Ẹ̀dá Ènìyàn Pípé
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Ìràpadà Kristi
  • Ìràpadà Jẹ́ Ìfihàn Ìfẹ́
  • Ìràpadà Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fún Wa
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Irapada Tí Ó Dọ́gba Rẹ́gífun Gbogbo Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 2/15 ojú ìwé 13-18

Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà

“Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—JÒHÁNÙ 3:16.

1, 2. Ṣàpèjúwe ipò ìṣòro tó ti bẹ́ sílẹ̀ fún ìran ènìyàn.

KÁ SỌ pé àìsàn kan ń ṣe ẹ́, tó dájú pé yóò gbẹ̀mí ẹ, àfi bí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ fún ẹ. Báwo ni yóò ti rí lára rẹ bí iye owó tí wọ́n fẹ́ gbà fún iṣẹ́ abẹ náà bá kọjá agbára rẹ? Bó bá jẹ́ pé gbogbo dúkìá ìdílé rẹ, mọ́ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kò lè kájú ẹ̀ ń kọ́? Kí èèyàn bá ara rẹ̀ nínú irú ipò tí kò ti mọ èyí tí yóò ṣe mọ́, nígbà tí ẹ̀mí olúwa rẹ̀ wà nínú ewu, mà burú o!

2 Èyí ṣàpèjúwe ipò kan tó ti dìde, èyí tí ìràn ènìyàn wà nínú rẹ̀. A ṣẹ̀dá Ádámù àti Éfà, àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ní ẹni pípé. (Diutarónómì 32:4) Wọ́n ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé àti láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ, pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ṣùgbọ́n o, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Àìgbọràn wọn mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí Ádámù àti Éfà tìkára wọn, ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o, ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún tún tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ tí wọn kò tíì bí. Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ nì, wí lẹ́yìn ìgbà náà, pé: “Ta ní lè mú ẹni tí ó mọ́ jáde láti inú ẹni tí kò mọ́? Kò sí ẹnì kankan.”—Jóòbù 14:4.

3. Báwo ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn?

3 Nípa báyìí, ẹ̀ṣẹ̀ dà bí àìsàn tó ti ran olúkúlùkù wa, nítorí Bíbélì sọ pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀.” Ipò yìí fi ẹ̀mí wa sínú ewu. Ní tòótọ́, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 3:23; 6:23) Kò sẹ́nì kankan nínú wa tó ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. Gbogbo ènìyàn ló ń dẹ́ṣẹ̀, fún ìdí yìí, gbogbo ènìyàn ló ń kú. Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, inú ipò ìṣòro yìí la bí wa sí. (Sáàmù 51:5) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ṣùgbọ́n èyí kò wá túmọ̀ sí pé a kò ní ìrètí ìgbàlà.

Mímú Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú Kúrò

4. Èé ṣe tí ẹ̀dá ènìyàn kò fi lè fúnra wọn mú àìsàn àti ikú kúrò?

4 Kí ni yóò gbà láti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí í ṣe àtúbọ̀tán rẹ̀ kúrò? Dájúdájú, ó ré kọjá ohun tí ènìyàn èyíkéyìí lè pèsè. Onísáàmù náà kédàárò pé: “Ohun tí a ó san fún ẹ̀mí ènìyàn ti pọ̀ jù. Kò sóhun tó lè san tó lè tó láé, tí kò fi ní wọ sàréè, tí yóò fi máa wà láàyè títí láé.” (Sáàmù 49:8, 9, Today’s English Version) A gbà pé ó ṣeé ṣe láti mú ẹ̀mí wa gùn fún ọdún díẹ̀ sí i, nípa jíjẹ oúnjẹ tí ń ṣara lóore àti nípa ìtọ́jú ìṣègùn, síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ìkankan nínú wa tó lè ṣèwòsàn ipò ẹ̀ṣẹ̀ táa ti jogún. Kò sí ìkankan nínú wa tó lè ṣe àyípadà kùjọ́kùjọ́ tí ọjọ́ ogbó ń sọni dà, kí ó sì mú ara wa padà bọ̀ sípò ìjẹ́pípé tí Ọlọ́run fi í sí níbẹ̀rẹ̀ pàá. Dájúdájú, àsọdùn kọ́ ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, nígbà tó kọ̀wé pé tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, ẹ̀dá ènìyàn ni a ti ‘tẹ̀ lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo’—tàbí gẹ́gẹ́ bí The Jerusalem Bible ti túmọ̀ rẹ̀, “ni a ti sọ di aláìlè dé orí ète rẹ̀.” (Róòmù 8:20) Àmọ́ ṣá o, inú wa dùn pé Ẹlẹ́dàá kò pa wá tì. Ó ti ṣètò láti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò pátápátá. Báwo?

5. Báwo ni Òfin tí a fi fún Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé ojú ribiribi la fi wo ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo?

5 Jèhófà jẹ́ “olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 33:5) Òfin tó fún Ísírẹ́lì fi hàn pé ojú ribiribi ló fi ń wo ọ̀ràn ìdájọ́ àìṣègbè àti ìdájọ́ tí kò ṣojúsàájú. Fún àpẹẹrẹ, nínú òfin yìí, a kà pé ‘a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí dí ẹ̀mí.’ Lédè mìíràn, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn, ó ní láti fi ẹ̀mí rẹ̀ dí ẹ̀mí ẹni tó pa. (Ẹ́kísódù 21:23; Númérì 35:21) Nípa báyìí, ohun tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run béèrè fún ni a óò mú ṣẹ.—Fi wé Ẹ́kísódù 21:30.

6. (a) Lọ́nà wo la fi lè pe Ádámù ní apànìyàn? (b) Irú ìwàláàyè wo ni Ádámù pàdánù, irú ẹbọ wo sì ni a nílò láti mú ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè fún ṣẹ?

6 Nígbà tí Ádámù ṣẹ̀, ó di apànìyàn. Lọ́nà wo? Ní ti pé yóò kó ipò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—tí yóò yọrí sí ikú—ran gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Torí àìgbọràn Ádámù ló fi jẹ́ pé lọ́wọ́ táa wà yìí, ara wa ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, tó sì forí lé sàréè. (Sáàmù 90:10) Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù tilẹ̀ ní ipa tó tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ jẹ́ ká rántí pé ohun tí Ádámù pàdánù fún ara rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kì í kàn-án ṣe ìwàláàyè àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún lásán. Ó pàdánù ìwàláàyè pípé—àní, ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, bí a óò bá ‘fi ẹ̀mí dí ẹ̀mí,’ irú ẹ̀mí wo ni a óò ní láti fi lélẹ̀ kí a tó lè sọ pé a ti ṣe ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀ràn yìí? Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé ló gbọ́dọ̀ jẹ́—ìwàláàyè tó jẹ́ pé, bíi ti Ádámù, ó lè mú àwọn ọmọ tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn pípé jáde. Báa bá fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rúbọ, yóò mú ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè fún ṣẹ, ṣùgbọ́n ní àfikún, yóò tún mú kí ó ṣeé ṣe láti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí í ṣe àtúbọ̀tán rẹ̀ kúrò pátápátá.

Kíkájú Ohun Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Ń Náni

7. Ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìràpadà.”

7 Iye tí rírà wá padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò ná wa ni Bíbélì pè ní “ìràpadà.” (Sáàmù 49:7) Lédè Yorùbá, ọ̀rọ̀ yìí lè tọ́ka sí iye tí ajínigbé kan máa ń béèrè kí ó tó lè tú ẹni tó jí gbé sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìràpadà tí Jèhófà pèsè kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú jíjínigbé. Ṣùgbọ́n èròǹgbà sísan ohun kan ṣì wà níbẹ̀. Àní, ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí a tú sí “ìràpadà,” báa bá tú u lóréfèé, ó túmọ̀ sí “láti kájú.” Kí ìràpadà tó lè ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, ó gbọ́dọ̀ bára mu rẹ́gí pẹ̀lú ohun táa fẹ́ fi kájú—èyíinì ni ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé ti Ádámù.

8. (a) Ṣàlàyé ìlànà ìtúnrà. (b) Báwo ni ìlànà ìtúnrà ṣe kàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀?

8 Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà kan táa rí nínú Òfin Mósè—èyíinì ni ìlànà ìtúnrà. Bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá bá ara rẹ̀ ní ipò òṣì, tó sì ta ara rẹ̀ ṣe ẹrú fún ẹnì kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ẹbí rẹ̀ kan lè tún un rà (tàbí, rà á padà) nípa sísan ohun tí a bá kà sí ọgbọọgba pẹ̀lú ẹrú náà. (Léfítíkù 25:47-49) Bíbélì sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀” ni wá. (Róòmù 6:6; 7:14, 25) Kí ni yóò gbà láti tún wa rà? Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ìpàdánù ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé yóò béèrè fún sísan ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé—kò gbọ́dọ̀ dín, kò gbọ́dọ̀ lé.

9. Ìpèsè wo ni Jèhófà ti ṣe láti kájú ẹ̀ṣẹ̀ wa?

9 Ṣùgbọ́n o, aláìpé ni a bí àwa ẹ̀dá ènìyàn. Kò sí ìkankan nínú wa tó jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú Ádámù; kò sí ìkankan nínú wa tó lè san ìràpadà tí ìdájọ́ òdodo béèrè fún. Gẹ́gẹ́ bí a ti wí níbẹ̀rẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni pé àìsàn kan tó fẹ́ gbẹ̀mí wa ń ṣe wá, tí a kò sì lágbára àtisan owó iṣẹ́ abẹ tó lè wò wá sàn. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a ò ní mọrírì rẹ̀, bí ẹnì kan bá bá wa dá sí ọ̀ràn náà, tó sì sanwó náà? Ohun tí Jèhófà ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn! Ó ti ṣètò láti tún wa rà padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, lẹ́ẹ̀kan láìtún tún un ṣe mọ́ láé. Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe tán láti fún wa ní ohun tí agbára àwa fúnra wa kò lè gbé láé. Lọ́nà wo? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Jòhánù pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n san ìràpadà.

“Ìràpadà Tí Ó Ṣe Rẹ́gí”

10. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa “irú-ọmọ” kan ṣe darí àfiyèsí sí Jósẹ́fù àti Màríà?

10 Kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà ní Édẹ́nì, Jèhófà kéde ète rẹ̀ láti pèsè “irú-ọmọ” kan, tí yóò ra aráyé padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Nípasẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn ìṣípayá látọ̀runwá, Jèhófà fi ìlà ìdílé tí yóò bí irú-ọmọ náà hàn. Bí àkókò ti ń lọ, ìṣípayá wọ̀nyí wá darí àfiyèsí sí Jósẹ́fù àti Màríà, ẹni méjì tí ń fẹ́ ara wọn sọ́nà ní ilẹ̀ Palẹ́sínì. Lójú àlá, a sọ fún Jósẹ́fù pé Màríà ti lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”—Mátíù 1:20, 21.

11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ṣètò bíbí tí a bí Ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀dá ènìyàn pípé? (b) Èé ṣe tí Jésù fi lè pèsè “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí”?

11 Oyún yìí kì í ṣe oyún lásán, torí pé Jésù ti wà ní ọ̀run tẹ́lẹ̀ ká tó bí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. (Òwe 8:22-31; Kólósè 1:15) Jèhófà tipasẹ̀ agbára àgbàyanu rẹ̀ fi ìwàláàyè rẹ̀ ránṣẹ́ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, ó jẹ́ kí a bí Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. (Jòhánù 1:1-3, 14; Fílípì 2:6, 7) Jèhófà ṣe gbogbo rẹ̀ lọ́nà tó fi jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kò ta bá Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni pípé la bí Jésù. Nípa báyìí, ó ní ohun tí Ádámù pàdánù—ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ẹ̀dá ènìyàn kan ló dé yìí tó lè kájú ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ń náni! Ìyẹn gẹ́lẹ́ sì ni Jésù ṣe ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ní ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, Jésù yọ̀ǹda ara rẹ̀, kí àwọn ọ̀tá fikú pa òun, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí.”—1 Tímótì 2:6.

Ìtóye Ìwàláàyè Ẹ̀dá Ènìyàn Pípé

12. (a) Ṣàlàyé ìyàtọ̀ pàtàkì tó wà láàárín ikú Jésù àti ikú Ádámù. (b) Báwo ni Jésù ṣe di “Baba Ayérayé” fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn?

12 Ìyàtọ̀ wà láàárín ikú Jésù àti ikú Ádámù—ìyàtọ̀ tó pàfiyèsí sí ìtóye ìràpadà náà. Ikú tọ́ sí Ádámù, torí pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ikú kò tọ́ sí Jésù rárá, torí pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22) Fún ìdí yìí, nígbà tí Jésù kú, ó ní ohun kan tí ìtóye rẹ̀ pabanbarì, èyí tí Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní nígbà ikú rẹ̀—ẹ̀tọ́ sí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé. Nípa báyìí, ikú Jésù ní ìtóye ẹbọ. Nígbà tó gòkè re ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, ó gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ síwájú Jèhófà. (Hébérù 9:24) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Jésù tún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ rà padà, ó sì di Baba wọn tuntun, ó rọ́pò Ádámù. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Àbájọ táa fi ń pe Jésù ní “Baba Ayérayé.” (Aísáyà 9:6) Sáà ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí! Ádámù, baba tó ní ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn, tan ikú dé ọ̀dọ̀ gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Jésù, Baba pípé, lo ìtóye ẹbọ rẹ̀ láti fi fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn ní ìyè ayérayé.

13. (a) Ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe pa gbèsè tí Ádámù jẹ rẹ́. (b) Èé ṣe tí ẹbọ Jésù kò fi kájú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́?

13 Àmọ́ ṣá o, báwo ni ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè kájú ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn? (Mátíù 20:28) Nínú àpilẹ̀kọ kan lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, a ṣàpèjúwe ìràpadà lọ́nà yìí: “Ká sọ pé ilé iṣẹ́ ńlá kan ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́. Máníjà ilé iṣẹ́ náà kówó jẹ, èyí sì mú kí ilé iṣẹ́ náà wọko gbèsè; ni ilé iṣẹ́ náà bá kógbá sílé. Ni iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́, wọn kò sì lè san gbèsè tí wọ́n jẹ. Àtìyàwó àtọkọ wọn, àtàwọn ọmọ wọn, àti gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè pàápàá wá ń jìyà nítorí ìwàkiwà ọkùnrin yẹn! Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni ọlọ́rọ̀ kan tí ń fi owó rẹ̀ ṣàánú dé, tó san gbogbo gbèsè ilé iṣẹ́ náà, tó sì tún ilé iṣẹ́ náà ṣí. Sísan tí ọlọ́rọ̀ yẹn san gbèsè ọ̀hún, ló mú ìtura kíkún wá bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìdílé wọn, àti àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ máníjà àkọ́kọ́ yẹn yóò nípìn-ín nínú aásìkí tuntun tó wọlé dé yìí? Ó tì o, torí pé ó ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, iṣẹ́ sì ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ títí lọ gbére! Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, sísan táa san gbèsè Ádámù mú èrè wá fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀—ṣùgbọ́n Ádámù kò ní bá wọn pín nínú èrè náà.”

14, 15. Èé ṣe tí a fi lè pe Ádámù àti Éfà ni ẹlẹ́ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, báwo sì ni ipò tiwa ṣe yàtọ̀ sí tiwọn?

14 Èyí tọ́. Ẹ jẹ́ ká rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ni Ádámù àti Éfà. Wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ni. Ní òdìkejì, ṣe ni a bí wa sínú ẹ̀ṣẹ̀. A ò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. Bó ti wù ká fi torí-tọrùn ṣe tó, kò sí báa ṣe lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá. (1 Jòhánù 1:8) Nígbà mí-ìn, ìmọ̀lára wa lè dà bí ti Pọ́ọ̀lù, tó kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi. Èmi abòṣì ènìyàn!”—Róòmù 7:21-24.

15 Síbẹ̀, nítorí ìràpadà, a ní ìrètí! Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí, Jésù ni irú-ọmọ tí ‘gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún ara wọn.’ (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Róòmù 8:20) Ẹbọ Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn àǹfààní àgbàyanu fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ nínú irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.

Jíjàǹfààní Láti Inú Ìràpadà Kristi

16. Láìka ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa sí, àwọn àǹfààní wo la lè gbádùn nísinsìnyí nítorí ìràpadà Jésù?

16 Òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jákọ́bù, gbà pé “a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jákọ́bù 3:2) Ṣùgbọ́n o, nítorí ìràpadà Kristi, a lè dárí àwọn ìṣìnà wa jì wá. Jòhánù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ jọ̀gọ̀nù fún ẹ̀ṣẹ̀. (Júúdà 4; fi wé 1 Kọ́ríńtì 9:27.) Síbẹ̀síbẹ̀, báa bá ṣi ẹsẹ̀ gbé, a lè tú gbogbo ọkàn-àyà wa jáde fún Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5; 130:3, 4; Aísáyà 1:18; 55:7; Ìṣe 3:19) Nípa báyìí, ìràpadà náà ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fi ẹ̀rí ọkàn mímọ́ sin Ọlọ́run, ó sì ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà lórúkọ Jésù Kristi.—Jòhánù 14:13, 14; Hébérù 9:14.

17. Nítorí ìràpadà náà, àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú wo ló ṣeé ṣe?

17 Ìràpadà Kristi ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìmúṣẹ ète Ọlọ́run—pé kí ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù].” (2 Kọ́ríńtì 1:20) Òtítọ́ ni, ikú ti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.” (Róòmù 5:17) Ìràpadà pèsè ìpìlẹ̀ fún Ọlọ́run láti pa “ọ̀tá ìkẹyìn” yìí run. (1 Kọ́ríńtì 15:26; Ìṣípayá 21:4) Ìràpadà Jésù lè ṣàǹfààní fún àwọn tó ti kú pàápàá. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [ohùn Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 15:20-22.

18. Ìyọrísí bíbaninínújẹ́ wo ni ẹ̀ṣẹ̀ ti ní lórí ẹ̀dá ènìyàn, báwo sì ni a ó ṣe ṣàtúnṣe èyí nínú ayé tuntun Ọlọ́run?

18 Sáà ronú bí yóò ti mọ́kàn yọ̀ tó láti máa gbádùn ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bó ti yẹ kó rí—láìsí hílàhílo tí ń dẹ́rù pa wá lóde òní! Ẹ̀ṣẹ̀ ti yà wá nípa sí Ọlọ́run, ìyẹn nìkan kọ́, ó tún ti yà wá nípa sí èrò inú, ọkàn-àyà, àti ara àwa tìkára wa. Àmọ́ o, Bíbélì ṣèlérí pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, kò “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, àìsàn ti ara ìyára àti ti èrò ìmọ̀lára kì yóò fojú aráyé gbolẹ̀ mọ́. Èé ṣe? Aísáyà dáhùn pé: “Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.”—Aísáyà 33:24.

Ìràpadà Jẹ́ Ìfihàn Ìfẹ́

19. Báwo ló ṣe yẹ ká dáhùn padà lẹ́nìkọ̀ọ̀kan sí ìràpadà Kristi?

19 Ìfẹ́ ló sún Jèhófà láti rán Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n wá. (Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 4:9) Ẹ̀wẹ̀, ìfẹ́ ló sún Jésù láti “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn.” (Hébérù 2:9; Jòhánù 15:13) Nítorí ìdí gúnmọ́ yìí ni Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa . . . Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Báa bá mọrírì ohun tí Jésù ṣe fún wa, a óò dáhùn padà. Ó ṣe tán, ìràpadà náà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ikú! Dájúdájú, a ò ní máa hùwà lọ́nà tí yóò fi dà bí ẹni pé a ń fojú yẹpẹrẹ wo ẹbọ Jésù.—Hébérù 10:29.

20. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà táa gbà ń pa “ọ̀rọ̀” Jésù mọ́?

20 Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún ìràpadà náà? Ní gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó mú Jésù, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” (Jòhánù 14:23) “Ọ̀rọ̀” Jésù wé mọ́ àṣẹ rẹ̀, pé ká máa fi ìtara nípìn-ín nínú ṣíṣe iṣẹ́ tó fi rán wa, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19) Ìgbọràn sí Jésù tún ń béèrè pé ká fìfẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí.—Jòhánù 13:34, 35.

21. Èé ṣe tó fi yẹ ká wà níbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní April 1?

21 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ táa lè gbà fi ìmọrírì hàn fún ìràpadà náà ni nípa wíwà níbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, tí a ó ṣe ní April 1 lọ́dún yìí.a Èyí pẹ̀lú jẹ́ ara “ọ̀rọ̀” Jésù, torí pé nígbà tó ń dá ayẹyẹ yìí sílẹ̀, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Báa bá wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí, tí a sì fiyè sí gbogbo ohun tí Kristi pa láṣẹ kínníkínní, a ó fi hàn pé lóòótọ́ ló dá wa lójú hán-ún-hán-ún pé ìràpadà Jésù ni ọ̀nà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ fún ìgbàlà. Lóòótọ́, “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.”—Ìṣe 4:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́dún yìí, April 1 ni Nísàn 14, ọjọ́ tí Jésù kú ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, bọ́ sí. Wádìí lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ nípa àkókò ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí àti ibi tí wọn yóò ti ṣe é.

O Ha Lè Rántí Bí?

◻ Èé ṣe tí ẹ̀dá ènìyàn kò fi lè ṣètùtù fún ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn?

◻ Lọ́nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí”?

◻ Báwo ni Jésù ṣe lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ fún ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé fún àǹfààní wa?

◻ Àwọn ìbùkún wo ni aráyé rí gbà nítorí ìràpadà Kristi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kìkì ẹ̀dá ènìyàn pípé—tó jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú Ádámù—ló lè mú ohun tí ìdájọ́ òdodo béèrè fún ṣẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Níwọ̀n bí Jésù ti ní ẹ̀tọ́ sí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé, ikú rẹ̀ ní ìtóye ẹbọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́