Ọjọ́ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Gẹ́gẹ́ Bí Ènìyàn
Ní ọjọ́rọ̀ Friday, Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni. Àwùjọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin kan fẹ́ sìnkú ọ̀rẹ́ wọn ọ̀wọ́n. Ọ̀kan lára wọn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nikodémù, ti mú èròjà atasánsán wá, kí ó lè fọ́n ọn sí òkú náà lára, kí wọ́n tó sin ín. Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù pẹ̀lú ti mú aṣọ funfun wá, tí wọn yóò fi di òkú náà, tí ara rẹ̀ ti dáranjẹ̀, tó sì lọ́gbẹ́ yánnayànna.
ÀWỌN wo ló dúró wọ̀nyí, òkú ta sì ni wọ́n ń sin? Gbogbo èyí ha kàn ọ́ bí? Láti lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, jẹ́ kí a padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ pàtàkì yẹn.
Ìrọ̀lẹ́ Thursday, Nísàn 14
Òṣùpá àrànmọ́jú tó ràn roro rọra ń yọ sórí Jerúsálẹ́mù. Rọ̀tìrọ̀tì ìlú náà ti ń rọlẹ̀ lẹ́yìn ìgbòkègbodò tí ó mú ọwọ́ àwọn èèyàn dí ní ọjọ́ yẹn. Nírọ̀lẹ́ yìí, ìtasánsán ọ̀dọ́ àgùntàn tí à ń yan ló gba gbogbo ìlú kan. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ń múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan—ayẹyẹ ọdọọdún ti Ìrékọjá.
Nínú yàrá ìgbàlejò ńlá kan, Jésù Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjèèjìlá jókòó yí tábìlì kan ká, táa ti ṣètò oúnjẹ sórí rẹ̀. Tẹ́tí sílẹ̀ o! Jésù ń sọ̀rọ̀. Ó wí pé: “Mo ti fẹ́ gidigidi láti jẹ ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà.” (Lúùkù 22:15) Jésù mọ̀ pé àwọn tí wọ́n torí ọ̀ràn ẹ̀sìn mú òun lọ́tàá ń gbìmọ̀ àtipa òun. Àmọ́ kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, ohun kan tó ṣe pàtàkì gidi máa ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ yìí.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣayẹyẹ Ìrékọjá tán, Jésù kéde pé: “Ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.” (Mátíù 26:21) Èyí kó ìdààmú bá àwọn àpọ́sítélì. Ta lolúwa ẹ̀? Lẹ́yìn ìjíròrò ráńpẹ́, Jésù sọ fún Júdásì Ísíkáríótù pé: “Ohun tí ìwọ ń ṣe túbọ̀ ṣe é kíákíá.” (Jòhánù 13:27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yòókù kò mọ̀, ọ̀dàlẹ̀ paraku ni Júdásì. Ó fibẹ̀ sílẹ̀, kó bàa lè lọ ṣe iṣẹ́ ibi tó jẹ́ ipa tirẹ̀ nínú rìkíṣí tí àwọn kan dì mọ́ Jésù.
Ayẹyẹ Àrà Ọ̀tọ̀
Wàyí o, Jésù dá ayẹyẹ kan tó jẹ́ tuntun pátápátá sílẹ̀—ọ̀kan tí a óò máa fi ṣèrántí ikú rẹ̀. Nígbà tí Jésù mú ègé búrẹ́dì kan, ó gbàdúrà ọpẹ́ sórí rẹ̀, ó sì bù ú. Ó pàṣẹ pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín.” Nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti jẹ nínú búrẹ́dì náà, ó mú ife wáìnì pupa kan, ó sì súre sí i. Jésù ṣàlàyé pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” Ó pàṣẹ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, àwọn mọ́kànlá tó ṣẹ́ kù, pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Mátíù 26:26-28; Lúùkù 22:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 11:24, 25.
Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù lo inú rere láti mú kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ adúróṣinṣin gbára dì fún ohun tó wà níwájú wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún wọn. Ó ṣàlàyé pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòhánù 15:13-15) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àpọ́sítélì mọ́kọ̀ọ̀kànlá ti fi hàn pé àwọn jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ nípa dídúró ti Jésù gbágbáágbá nínú àdánwò rẹ̀.
Ní òru—bóyá lẹ́yìn tí ààjìn ti jìn—Jésù gbàdúrà kan tí wọn kò lè gbàgbé, lẹ́yìn èyí wọ́n kọ orin ìyìn sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, nínú òṣùpá àrànmọ́jú tó mọ́lẹ̀ roro, wọ́n jáde kúrò nínú ìlú náà, wọ́n sì sọdá Àfonífojì Kídírónì.—Jòhánù 17:1–18:1.
Nínú Ọgbà Gẹtisémánì
Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ dé ọgbà Gẹtisémánì. Jésù fi mẹ́jọ lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sẹ́nu ọ̀nà ọgbà náà, ó mú Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù wọ àárín àwọn igi ólífì lọ. Ó sọ fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 14:33, 34.
Àwọn àpọ́sítélì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dúró nígbà tí Jésù túbọ̀ rìn wọnú ọgbà náà lọ láti gbàdúrà. Pẹ̀lú ohùn rara àti omijé, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi.” Ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta ló já lé Jésù léjìká yìí. Ẹ wo bó ti bà á lọ́kàn jẹ́ tó láti ronú kan ohun tí àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò sọ, nígbà tí wọ́n bá rí i, tí a kan Ọmọ Rẹ̀ bíbí kan ṣoṣo mọ́gi, bí ẹni pé ọ̀daràn ni! Èyí tó tilẹ̀ tún dun Jésù jù ni ìrònú nípa ẹ̀gàn ńláǹlà tí yóò mú wá sórí Baba rẹ̀ ọ̀run ọ̀wọ́n, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé kò yege nínú ìdánwò ríroni lára gógó yìí. Jésù fi taratara gbàdúrà gan-an, ó sì bọ́ sínú ìrora tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí òógùn tó ń jáde lára rẹ̀ fi dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sílẹ̀.—Lúùkù 22:42, 44.
Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà tán lẹ́ẹ̀kẹta ni. Bẹ́ẹ̀ làwọn ọkùnrin tó gbé òtùfù àti fìtílà dání dé. Ta ni ì bá tún ṣáájú wọn, bí kì í bá ṣe Júdásì Ísíkáríótù, ọ̀dọ̀ Jésù tààrà ló kọrí sí. Ó fẹnu ko Jésù lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó wí pé: “Kú déédéé ìwòyí o, Rábì!” Jésù dá a lóhùn pé, “Júdásì, ìwọ ha fi ìfẹnukonu da Ọmọ ènìyàn?”—Mátíù 26:49; Lúùkù 22:47, 48; Jòhánù 18:3.
Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn àpọ́sítélì ti fura. Wọ́n mà ti fẹ́ mú Olúwa wọn àti ọ̀rẹ́ wọn ọ̀wọ́n nìyẹn kẹ̀! Ni Pétérù bá fa idà yọ, àfi féú, ó ti gé etí ẹrú àlùfáà àgbà sílẹ̀. Jésù tètè yáa ké gbàjarè pé: “Ẹ fi mọ sí ibi yìí.” Ó rìn kúṣẹ́ síwájú, ó wo ẹrú náà sàn, ó sì pàṣẹ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Lúùkù 22:50, 51; Mátíù 26:52) Àwọn òṣìṣẹ́ ọba àti àwọn ọmọ ogun gbá Jésù mú, wọ́n sì dè é. Jìnnìjìnnì bo àwọn àpọ́sítélì, ọkàn wọn sì dà rú, ni wọ́n bá fi Jésù sílẹ̀, wọ́n ki eré mọ́lẹ̀ ní ọ̀gànjọ́ òru.—Mátíù 26:56; Jòhánù 18:12.
Òwúrọ̀ Friday, Nísàn 14
Ó ti ń di ọwọ́ àfẹ̀mọ́jú ní ìdájí ọjọ́ Friday. Wọ́n kọ́kọ́ mú Jésù lọ sí ilé Àlùfáà Àgbà tẹ́lẹ̀ rí, Ánásì, ẹni tó ṣì ń lo àṣẹ àti agbára ńlá. Ánásì bi í ní ìbéèrè, lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n mú un lọ sí ilé Àlùfáà Àgbà, Káyáfà, níbi tí Sànhẹ́dírìn ti pé sí.
Wàyí o, àwọn aṣáájú ìsìn ń gbìyànjú láti wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò rí ẹ̀sùn wé mọ́ Jésù lẹ́sẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rí tí àwọn ẹlẹ́rìí èké ọ̀hún pàápàá jẹ́ kò bára mu. Gbogbo èyí táàá ń wí yìí, Jésù kò gbin. Ni Káyáfà bá yí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ padà, ló bá pàṣẹ pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run!” Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro lèyí jẹ́, nítorí náà Jésù fi ìgboyà fèsì pé: “Èmi ni; ẹ ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yóò sì máa bọ̀ nínú àwọsánmà ọ̀run.”—Mátíù 26:63; Máàkù 14:60-62.
Káyáfà kígbe, ó wí pé: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí ni a tún nílò àwọn ẹlẹ́rìí fún?” Bí àwọn kan ṣe ń kó ìgbájú bo Jésù, bẹ́ẹ̀ làwọn kan ń tutọ́ sí i lára. Àwọn mìíràn kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì rọ̀jò èébú lé e lórí. (Mátíù 26:65-68; Máàkù 14:63-65) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ọ̀yẹ̀ ti là ní ọjọ́ Friday, Sànhẹ́dírìn tún jókòó, bóyá kó lè dà bí ẹni pé òfin ṣètìlẹ́yìn fún ìgbẹ́jọ́ aláìbófinmu tí wọ́n fòkùnkùn bojú ṣe. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún fi ìgboyà sọ pé òun ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.—Lúùkù 22:66-71.
Lẹ́yìn èyí, àwọn olórí àlùfáà àti àgbà ọkùnrin mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù, gómìnà Róòmù ti Jùdíà, kó wá lọ jẹ́jọ́ níbẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn kan Jésù pé, ó fẹ́ dojú orílẹ̀-èdè náà dé, ó ń ka sísan owó orí fún Késárì léèwọ̀, ó sì “ń sọ pé òun fúnra òun ni Kristi ọba.” (Lúùkù 23:2; fi wé Máàkù 12:17.) Lẹ́yìn bíbèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù, Pílátù kéde pé: “Èmi kò rí ìwà ọ̀daràn kankan nínú ọkùnrin yìí.” (Lúùkù 23:4) Nígbà tí Pílátù gbọ́ pé ará Gálílì ni Jésù, ó ní kí wọ́n mú un lọ́ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù Áńtípà, alákòóso Gálílì, tó wá sí Jerúsálẹ́mù fún Ìrékọjá. Hẹ́rọ́dù ní tìrẹ kò fẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ó kàn fẹ́ rí i kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu ni. Ìgbà tó sì jẹ́ pé Jésù kò ṣe ohun tó ń fẹ́, tí kò tilẹ̀ gbin, ni Hẹ́rọ́dù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́, Hẹ́rọ́dù sì fi í ránṣẹ́ padà sí Pílátù.
Pílátù tún béèrè pé: “Ohun búburú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí nǹkan kan nínú rẹ̀ tí ó yẹ fún ikú; nítorí náà, ṣe ni èmi yóò nà án, tí n ó sì tú u sílẹ̀.” (Lúùkù 23:22) Ó bẹ̀rẹ̀ sí fi kòbókò aláwẹ́ púpọ̀ na Jésù, gbogbo ẹ̀yìn rẹ̀ sì bẹ́ yánnayànna. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ ogun fi adé ẹ̀gún dé e lórí. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣẹlẹ́yà, wọ́n fi esùsú tó ki pọ́pọ́ lù ú, wọ́n tẹ adé ẹ̀gún náà mọ́ ọn lórí, kó lè wọnú agbárí rẹ̀ dáadáa. Bí ìrora àti èébú tí kò ṣeé fẹnu sọ ti pọ̀ tó nì, Jésù kò mà bara jẹ́, ó ṣe bí ọkùnrin lọ́nà tó kàmàmà.
Bóyá Pílátù rò pé lílù tí wọ́n ti lu Jésù dáadáa yóò jẹ́ kí àwọn èèyàn ṣàánú rẹ̀ ni, ló bá tún mú un wá síwájú àwọn èrò náà. Pílátù ké ní ohùn rara pé: “Wò ó! Mo mú un wá sóde fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí àléébù kankan nínú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà kígbe, pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!” (Jòhánù 19:4-6) Nígbà tó di pé àwọn èrò náà ṣáà fàáké kọ́rí pé àfi kí wọ́n pa Jésù dandan-ǹ-dan, ní Pílátù bá kúkú fara mọ́ ọn, ló bá fà á lé wọn lọ́wọ́.
Ikú Oró
Ní báyìí ó ti ń dọwọ́ ìyálẹ̀ta, ó jọ pé ọjọ́ ti fẹ́ kàtàrí. Wọ́n mú Jésù lọ sẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù, ní ibì kàn tí a ń pè ní Gọ́gọ́tà. Wọ́n fi ìṣó gbàǹgbà kan ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Jésù mọ òpó igi oró. Ẹnu á kọ̀ròyìn táa bá ní ká máa sọ ìrora tí Jésù jẹ nígbà tí wọ́n gbé òpó igi oró náà nàró, tí ọ̀ọ̀rìn òun alára sì mú kí ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti kàn án mọ́gi fà ya. Àwọn èrò pé jọ láti wo bí wọ́n ṣe kan Jésù àti àwọn ọ̀daràn méjì mọ́gi. Ọ̀pọ̀ sọ̀rọ̀ èébú sí Jésù. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn mìíràn fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kò lè gba ara rẹ̀ là!” Àní àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọ̀daràn méjì tí wọ́n kan àwọn pẹ̀lú mọ́gi fi Jésù tayín.—Mátíù 27:41-44.
Lójijì, ní ọjọ́kanrí, lẹ́yìn tí Jésù ti wà lórí igi fún ìgbà díẹ̀, òkùnkùn biribiri tó kó jìnnìjìnnì báni, tí ó ní ọwọ́ Ọlọ́run nínú, ṣú bo ilẹ̀ náà fún wákàtí mẹ́ta.a Àfàìmọ̀ ni kò fi jẹ́ pé èyí ló mú kí ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn náà bá èkejì rẹ̀ wí. Tó sì wá yíjú sí Jésù lẹ́yìn náà, tó wá bẹ̀ ẹ́ pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Irú ìgbàgbọ́ tó ní nígbà tí ikú rẹ̀ sún mọ́lé yìí mà ga o! Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:39-43.
Ní nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán, Jésù nímọ̀lára pé àkùkọ ti fẹ́ kọ lẹ́yìn ọmọkùnrin. Ó wí pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí.” Lẹ́yìn náà, ó ké ní ohùn rara pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn náà ti rí lára Jésù, ṣe ló dà bíi pé Baba òun kò dáàbò bo òun mọ́ nítorí kí a lè dán ìwà títọ́ òun wò dé góńgó, ìdí nìyẹn tó fi fa àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì wọ̀nyẹn yọ. Ẹnì kan fi kànrìnkàn tí wáìnì kíkan ti rin gbingbin sí Jésù lẹ́nu. Lẹ́yìn ti Jésù mu díẹ̀ nínú wáìnì náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀kà ikú, ó wí pé: “A ti ṣe é parí!” Lẹ́yìn èyí ló kígbe pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé,” ó tẹ orí ba, ó sì gbẹ́mìí mì.—Jòhánù 19:28-30; Mátíù 27:46; Lúùkù 23:46; Sáàmù 22:1.
Níwọ̀n bí ó ti ń di ọjọ́rọ̀, wọ́n yára ṣètò àtisin Jésù kó tó di Sábáàtì (Nísàn 15), tí yóò bẹ̀rẹ̀ tí oòrùn bá ti wọ̀. Jósẹ́fù ará Arimatíà, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn táa mọ̀ bí ẹní mowó, tó sì ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ní bòókẹ́lẹ́, gba àṣẹ láti lọ sìnkú rẹ̀. Nikodémù, tóun pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn tó ti sọ pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù ní bòókẹ́lẹ́ fi òjíá àti àwọn álóè bí ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n pọ́n-ùn ṣèrànwọ́. Ní jẹ́jẹ́-ǹ-jẹ́jẹ́, wọ́n tẹ́ Jésù sínú ibojì tuntun tí ń bẹ nítòsí.
Ó Padà Wà Láàyè!
Ilẹ̀ kò tí ì mọ́ rárá ní ìdájí ọjọ́ Sunday tí Màríà Magidalénì àti àwọn obìnrin kan ti wá sẹ́nu ibojì Jésù. Áà, nǹkan ti ṣẹlẹ̀ o! Wọ́n ti yí òkúta tó wà lẹ́nu ibojì náà kúrò. Págà, ibojì náà ti ṣófo! Ni Màríà Magidalénì bá sáré lọ sọ fún Pétérù àti Jòhánù. (Jòhánù 20:1, 2) Kò pẹ́ tó lọ ni áńgẹ́lì kan yọ sí àwọn obìnrin tó kù. Ó wí pé: “Ẹ má bẹ̀rù.” Ó tún rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ . . . lọ ní kíákíá, kí ẹ sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú.”—Mátíù 28:2-7.
Bí wọ́n ti ń yára lọ, kò sí ẹlòmíràn tí wọ́n pàdé ju Jésù alára lọ! Ó wí fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi.” (Mátíù 28:8-10) Lẹ́yìn èyí, ibi ibojì náà ni Màríà Magidalénì wà tó ti ń sunkún, ni Jésù bá yọ sí i. Màríà kò lè pa ìdùnnú rẹ̀ mọ́ra, kíá ló sáré lọ sọ ìròyìn ìyanu náà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. (Jòhánù 20:11-18) Àní, ìgbà márùn-ún ni Jésù tí a jí dìde fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọjọ́ Sunday mánigbàgbé yẹn, kò jẹ́ kí wọ́n ṣiyè méjì rárá pé òun tún ti padà wà láàyè!
Bó Ṣe Kàn Ọ́
Báwo wá ni àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹgbàá ọdún dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [1,966] sẹ́yìn ṣe lè kàn ọ́ nígbà táa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ọ̀rúndún kọkànlélógún tán yìí? Ẹnì kan tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòhánù 4:9, 10.
Lọ́nà wo ni ikú Kristi gbà jẹ́ “ẹbọ ìpẹ̀tù”? Ó jẹ́ ìpẹ̀tù nítorí pé ó mú kí níní ìbátan tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run ṣeé ṣe. Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tàtaré ogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà láti fi tán ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí aráyé ti jogún, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí Ọlọ́run rí ìdí kan tó fi lè nawọ́ àánú àti ojú rere síni. (1 Tímótì 2:5, 6) Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù rú, a lè dá ọ sílẹ̀ kúrò nínú ipò ìdálẹ́bi tí o ti jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12; 6:23) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, èyí ṣí àǹfààní àgbàyanu sílẹ̀ fún ọ láti ní ìbátan pẹ̀lú Baba rẹ ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run. Láìfọ̀rọ̀ gùn, ẹbọ gígalọ́lá ti Jésù yìí lè túmọ̀ sí ìyè tí kò nípẹ̀kun fún ọ.—Jòhánù 3:16; 17:3.
Ìwọ̀nyí àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tó so mọ́ ọn ni a óò jíròrò ní ìrọ̀lẹ́ Thursday, April 1, ní ẹgbẹẹgbàarùn-ún ibi káàkiri àgbáyé, nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn bá pé jọ láti ṣèrántí ikú Jésù Kristi. A ké sí ọ láti wà níbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè rẹ yóò láyọ̀ láti sọ ibi tí wọn yóò ti ṣe é àti ìgbà tí àwọn yóò ṣe é fún ọ. Ó dájú pé bóo bá wà níbẹ̀, ìmọrírì rẹ yóò pọ̀ sí i fún ohun tí Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ àti Ọmọ rẹ ọ̀wọ́n ṣe lọ́jọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kò lè jẹ́ oòrùn ló ṣíji bo òṣùpá, tó sì wá mú kí òkùnkùn biribiri yìí ṣú, nítorí pé, àkókò òṣùpá àrànmọ́jú ni Jésù kú. Tí oòrùn bá sì ṣíji bo òṣùpá, ìṣẹ́jú díẹ̀ lòkùnkùn fi máa ń ṣú, èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí oṣù bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lé, nígbà tí òṣùpá bá wà láàárín ayé àti oòrùn.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
IKÚ ÀTI ÀJÍǸDE JÉSÙ
NÍSÀN 33 SÀNMÁNÌ TIWA ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ ỌKÙNRIN TÍTÓBILỌLA JÙ LỌ*
14 Ìrọ̀lẹ́ Thursday Ayẹyẹ Ìrékọjá; Jésù wẹ ẹsẹ̀ 113, ìpínrọ̀ 2 sí
àwọn àpọ́sítélì rẹ̀; Júdásì 117, ìpínrọ̀ 1
jáde lọ láti da Jésù; Kristi
dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀
(Thursday, April 1, la óò ṣe
é lọ́dún yìí, lẹ́yìn tí oòrùn
bá wọ̀); ó sọ̀rọ̀ ìyànjú tó fi mú
àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gbára dì
fún àtilọ rẹ̀; àdúrà ìparí àti
orin ìyìn
Ọ̀gànjọ́ òru títí Lẹ́yìn àdúrà àti orin ìyìn, 117 sí 120
di fẹ̀ẹ̀rẹ̀-kílẹ̀ẹ́mọ́ Jésù àti àwọn àpọ́sítélì lọ sí
ọgbà Gẹtisémánì; Jésù fi ohùn
rara àti omijé gbàdúrà; Júdásì
Ísíkáríótù dé pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ,
ó sì da Jésù; àwọn àpọ́sítélì
fẹsẹ̀ fẹ nígbà tí wọ́n de Jésù, tí
wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ánásì; wọ́n mú
Jésù lọ sọ́dọ̀ Káyáfà olórí àlùfáà,
kó lè fara hàn níwájú Sànhẹ́dírìn;
wọ́n dájọ́ ikú fún un; wọ́n sọ̀rọ̀ èébú
sí i, wọ́n sì hùwà ìkà sí i; Pétérù
sẹ́ Jésù nígbà mẹ́ta
Òwúrọ̀ Friday Bí ọ̀yẹ̀ ti ń là, Jésù tún wá 121 sí 124
síwájú Sànhẹ́dírìn; wọ́n mú un lọ
síwájú Pílátù; Pílátù fi ránṣẹ́ sí
Hẹ́rọ́dù; wọ́n mú un padà sọ́dọ̀ Pílátù;
Wọ́n na Jésù, wọ́n bú u, wọ́n sì hùwà
ìkà sí i; wọ́n fipá mú Pílátù láti fa
Jésù lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lọ kàn án
mọ́gi; nígbà tó ń dọwọ́ ìyálẹ̀ta wọ́n mú
un lọ sí Gọ́gọ́tà láti pa
Ọjọ́kanrí sí ọwọ́ Wọ́n kàn án mọ́gi kó tó di ọjọ́kanrí; 125, 126
ọ̀sán ganrínganrín òkùnkùn ṣú láti ọjọ́kanrí títí di
nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán, nígbà tí
Jésù kú; ìsẹ̀lẹ̀ lílágbára ṣẹlẹ̀; aṣọ
ìkélé tẹ́ńpìlì ya sí méjì
Ọjọ́rọ̀ A sin Jésù sí ibojì kan nínú ọgbà 127,
kí Sábáàtì tó bẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ 1-7
15 Ìrọ̀lẹ́ Friday Sábáàtì bẹ̀rẹ̀
Saturday Pílátù gbà kí àwọn ẹ̀ṣọ́ wà ní 127,
ibojì Jésù ìpínrọ̀ 8, 9
16 Sunday Ní ìdájí a rí i pé ibojì Jésù 127, ìpínrọ̀
ti ṣófo; Jésù tí a jí dìde fara 10 sí 129,
han (1) àwùjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ìpínrọ̀ 10
wọ́n jẹ́ obìnrin, títí kan Sàlómẹ̀,
Jòánà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù;
(2) Màríà Magidalénì;
(3) Kíléópà àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀;
(4) Símónì Pétérù;
(5) àwùjọ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn
ọmọ ẹ̀yìn yòókù
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Àwọn nọ́ńbà wọ̀nyí tí a tò lẹ́sẹẹsẹ síhìn-ín ń tọ́ka sí àwọn àkòrí nínú ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Tí o bá fẹ́ wo ṣáàtì tó ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtọ́kasí nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó ṣe kẹ́yìn, wo ìwé náà, “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” ojú ìwé 290. Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ ìwé wọ̀nyí jáde