Báwo La Ṣe Lè Pẹ́ Tó Láyé?
Lápapọ̀, ṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń pẹ́ láyé sí i, èyí sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo la ṣe lè pẹ́ tó láyé?’
GẸ́GẸ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica (1995), ti wí, tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Pierre Joubert ni wọ́n sọ pé ó pẹ́ jù lọ láyé. Ọdún 1814 ló kú, lẹ́ni ọdún mẹ́taléláàádọ́fà [113]. A tún gbọ́ pé àwọn mìíràn ti pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé, ṣùgbọ́n kò sí àkọọ́lẹ̀ tó ṣeé gbára lé nípa ọjọ́ orí wọn. Àmọ́ o, àkọọ́lẹ̀ tó péye ti fi hàn pé àwọn èèyàn mélòó kan ti pẹ́ láyé ju Pierre Joubert lọ.
Ní February 21, 1875, a bí Jeanne Louise Calment ní ìlú Arles, ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Òkìkí kàn jákèjádò nígbà tóbìnrin yìí kú ní August 4, 1997—ó lé lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́fà [122] lókè eèpẹ̀. Lọ́dún 1986, Shigechiyo Izumi ará Japan kú lẹ́ni ọgọ́fà [120] ọdún. Ìwé náà, Guinness Book of Records 1999, sọ pé Sarah Knauss, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́fà [118] ló dàgbà jù lọ lọ́dún tí wọ́n ń ṣe ìwé yẹn. September 24, 1880 ni a bí i ní ìlú Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí Marie-Louise Febronie Meilleur láti ìpínlẹ̀ Quebec, ní Kánádà, kú lọ́dún 1998, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́fà [118] ní í ṣe, ṣùgbọ́n ó fi ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ṣàgbà Sarah.
Lóòótọ́ ni iye àwọn tí ń darúgbó gan-an ti pọ̀ sí i lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Wọ́n fojú bù ú pé iye àwọn tó pé ọgọ́rùn-ún ọdún láyé yóò tó ohun tó lé ní àádọ́fà ọ̀kẹ́ láàárín àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún tí ń bọ̀ yìí! Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, iye àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n tó ọgọ́rin ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, lọ sókè láti nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lọ́dún 1970 dé mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́ta lọ́dún 1998. Èyíinì jẹ́ ìlọsókè tó jẹ́ ìlọ́po mẹ́tàdínláàádọ́jọ [147] nínú ọgọ́rùn-ún, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpíndọ́gba ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún tí àròpọ̀ àwọn olùgbé ayé fi pọ̀ sí i.
Ọ̀ràn pé àwọn èèyàn túbọ̀ ń pẹ́ láyé nìkan kọ́. Àní ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó wọ̀nyí tún ń ṣe bẹbẹ, wọ́n ń ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ ogún ọdún kò lè ṣe. Lọ́dún 1990, John Kelley ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin parí eré ẹlẹ́mìí ẹṣin—eré tó lé ní kìlómítà méjìlélógójì—ní wákàtí márùn-ún àti ìṣẹ́jú márùn-ún. Lọ́dún 1991, Mavis Lindgren, ìyá àgbà ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, sá eré yẹn ní wákàtí méje àti ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án. Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún sá eré ẹlẹ́mìí ẹṣin ti New York City parí!
Èyí kò wá túmọ̀ sí pé àwọn àgbàlagbà láyé àtijọ́ kò pitú kankan. Lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, Ábúráhámù baba ńlá ìgbàanì táa mẹ́nu kàn nínú Bíbélì “bẹ̀rẹ̀ sí sáré láti pàdé” àwọn àlejò rẹ̀. Lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́rin, Kálébù kéde pé: “Bí agbára mi ti rí nígbà yẹn [lọ́dún márùnlélógójì sẹ́yìn], bẹ́ẹ̀ ni agbára mi rí nísinsìnyí fún ogun, láti jáde lọ àti láti wọlé.” Bíbélì sì sọ nípa Mósè pé nígbà tó jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún, “ojú rẹ̀ kò di bàìbàì, okun agbẹ́mìíró rẹ̀ kò sì pòórá.”—Jẹ́nẹ́sísì 18:2; Jóṣúà 14:10, 11; Diutarónómì 34:7.
Jésù Kristi sọ pé lóòótọ́ ni ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, àti Nóà tó kan ọkọ̀ áàkì, gbé ayé rí. (Mátíù 19:4-6; 24:37-39) Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Ádámù ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé ọgbọ̀n ọdún [930] láyé, Nóà sì ṣe ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín àádọ́ta [950] láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5; 9:29) Ṣé lóòótọ́ làwọn èèyàn pẹ́ tó yẹn láyé? Ǹjẹ́ a lè pẹ́ láyé ju báyẹn lọ, bóyá ká tilẹ̀ wà láàyè títí láé? Dákun gbé ẹ̀rí tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.