ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/1 ojú ìwé 14-20
  • “Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ohun Ìríra” Lóde Òní
  • Ìkọlù Ní Ọjọ́ Iwájú
  • “Sá”—Sá Lọ Síbo?
  • Sísá Àsálà Lọ Sí Ibi Ààbò Kí “Ìpọ́njú Ńlá” Tó Dé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Sọ Fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/1 ojú ìwé 14-20

“Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”

“Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.”—MÁTÍÙ 24:15, 16.

1. Kí ni àbájáde tí ìkìlọ̀ Jésù tí a rí nínú Lúùkù 19:43, 44 ní?

JÍJẸ́ ẹni tó tètè fura pé àjálù ń bọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún un. (Òwe 22:3) Nítorí náà, ronú nípa ipò tí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù wà lẹ́yìn tí àwọn ará Róòmù kọ lu ìlú náà lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Jésù ti kìlọ̀ pé a óò yí ìlú náà ká, a óò sì pa á run. (Lúùkù 19:43, 44) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ló yínmú sí Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àjálù tó wáyé lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.

2, 3. Èé ṣe tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:15-21?

2 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó kàn wá lónìí, Jésù mẹ́nu kan àmì alápá púpọ̀ tó ní nínú, ogun, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àti inúnibíni tí a óò ṣe sí àwọn Kristẹni tí ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:4-14; Lúùkù 21:10-19) Jésù tún sọ ohun tó lè jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tètè fura pé òpin ti sún mọ́lé—ìyẹn ni, “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” (Mátíù 24:15) Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyẹn, láti lè mọ bí wọ́n ṣe kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti ní ọjọ́ ọ̀la.

3 Lẹ́yìn tó ti to àmì náà lẹ́sẹẹsẹ, Jésù wí pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀,) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá. Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí ilé láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì! Ẹ máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù, tàbí ní ọjọ́ sábáàtì; nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí.”—Mátíù 24:15-21.

4. Kí ló fi hàn pé Mátíù 24:15 nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?

4 Àkọsílẹ̀ ti Máàkù àti Lúùkù tún jẹ́ ká mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn. Ibi tí Mátíù ti lo gbólóhùn náà, “tí ó dúró ní ibi mímọ́,” Máàkù 13:14 sọ pé “tí ó dúró níbi tí kò yẹ.” Lúùkù 21:20 fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù náà kún un pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìmúṣẹ àkọ́kọ́ náà ní í ṣe pẹ̀lú bí àwọn ará Róòmù ṣe kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀—ibi tí àwọn Júù kà sí ibi mímọ́ ṣùgbọ́n tí Jèhófà kò kà sí ibi mímọ́ mọ́—ìkọlù tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Sísọ ọ́ dahoro pátápátá wáyé nígbà tí àwọn ará Róòmù pa ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Kí ni “ohun ìríra náà” nígbà náà lọ́hùn-ún? Báwo ló sì ṣe “dúró ní ibi mímọ́”? Ìdáhùn táa bá rí sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe nímùúṣẹ lóde òní.

5, 6. (a) Èé ṣe tí àwọn tó bá ka Dáníẹ́lì orí kẹsàn-án fi ní láti lo òye? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ohun ìríra” ṣe nímùúṣẹ?

5 Jésù rọ àwọn òǹkàwé láti lo òye. Ìwe wo ni wọ́n ń kà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé Dáníẹ́lì orí kẹsàn-án. Níbẹ̀ ni a ti rí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ń sọ ìgbà tí Mèsáyà náà yóò fara hàn, tó tún ń sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò ‘ké e kúrò’ lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Àti lórí ìyẹ́ apá ohun ìríra ni ẹni tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yóò wà; títí di ìparun pátápátá, ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí yóò máa dà jáde sórí ẹni tí ó wà ní ahoro pẹ̀lú.”—Dáníẹ́lì 9:26, 27; tún wo Dáníẹ́lì 11:31; 12:11.

6 Àwọn Júù rò pé bíbà tí Áńtíókọ́sì Kẹrin ba tẹ́ńpìlì jẹ́ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú àkókò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ. Àmọ́ ṣá o, Jésù fi hàn pé ohun tí òun ń sọ yàtọ̀ pátápátá sí èrò ọkàn wọn, ó rọ̀ wọ́n láti lo òye nítorí pé “ohun ìríra náà” kò tí ì fara hàn, kò sì tí ì dúró ní “ibi mímọ́.” Ó ṣe kedere pé Jésù ń tọ́ka sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tí yóò wá lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa pẹ̀lú àwọn àsíá táa fi lè dá a mọ̀ yàtọ̀. Àwọn Júù, ka irú àsíá bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn ti ń lò tipẹ́tipẹ́ sí ère, wọ́n jẹ́ ohun ìríra sí wọn.a Ṣùgbọ́n, nígbà wo ni wọn yóò “dúró ní ibi mímọ́”? Ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù, pẹ̀lú àsíá wọn, kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, tí àwọn Júù kà sí ibi mímọ́. Àwọn ará Róòmù tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dá ihò lu sára ògiri tó yí àgbègbè tẹ́ńpìlì náà ká. Lóòótọ́, ohun tó ti jẹ́ ohun ìríra fún ìgbà pípẹ́ mà ti wá dúró sí ibi mímọ́ báyìí o!—Aísáyà 52:1; Mátíù 4:5; 27:53; Ìṣe 6:13.

“Ohun Ìríra” Lóde Òní

7. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo ló ń nímùúṣẹ lọ́jọ́ tiwa?

7 Láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, a ti rí ìmúṣẹ àmì tí Jésù sọ, tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún, lọ́nà gbígbòòrò. Síbẹ̀, rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mátíù 24:15, 16) Apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà tún gbọ́dọ̀ nímùúṣẹ tirẹ̀ ní àkókò tiwa yìí.

8. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ nípa “ohun ìríra” ti òde òní?

8 Nígbà tó ń fi ìgbọ́kànlé tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí hàn pé bó ti wù kó rí yóò nímùúṣẹ, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti January 1, 1921, (Gẹ̀ẹ́sì) darí àfiyèsí sí i ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé nígbà náà. Nígbà tó ṣe, nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti December 15, 1929, ojú ìwé 374, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) sọ ní pàtó pé: “Gbogbo ète Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni láti yí àwọn èèyàn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ Kristi, nítorí náà ohun ìsọdahoro ló jẹ́, ọ̀dọ̀ Sátánì ló ti wá, ohun ẹlẹ́gbin gbáà ló sì jẹ́ lójú Ọlọ́run.” Nítorí náà lọ́dún 1919 “ohun ìríra” náà yọ kúlẹ́. Nígbà tó ṣe, Ìmùlẹ̀ náà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ó ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tú ètò àjọ tí àwọn èèyàn gbé kalẹ̀ láti lè mú àlàáfíà wá yìí fó pé ó jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.

9, 10. Báwo ni òye táa kọ́kọ́ ní nípa ìpọ́njú ńlá ṣe nípa lórí ojú ìwòye wa nípa àkókò náà tí “ohun ìríra” yóò dúró ní ibi mímọ́?

9 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣàkópọ̀ èrò tó ṣe kedere nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ń bẹ nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkarùndínlọ́gbọ̀n. Ǹjẹ́ ó bójú mu láti ṣe àwọn àlàyé tó ṣe kedere nípa “ohun ìríra tó dúró ní ibi mímọ́”? Bẹ́ẹ̀ ni. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù sọ pé ‘dídúró ní ibi mímọ́’ ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́sílẹ̀ “ìpọ́njú” náà tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ohun kan so àwọn méjèèjì pọ̀. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ohun ìríra” náà ti wà tipẹ́, ìsopọ̀ tó wà láàárín ‘dídúró tó dúró sí ibi mímọ́’ àti ìpọ́njú ńlá yẹ kó nípa lórí ìrònú wa. Lọ́nà wo?

10 Nígbà kan rí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóye pé apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 àti pé apá tó kẹ́yìn yóò dé nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16; fi wé Ilé Ìṣọ́, April 1, 1939, (Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 110.) Nítorí náà, a lè lóye ìdí tí a fi ronú nígbà kan pé “ohun ìríra” ti òde òní ti dúró ní ibi mímọ́ ní kété tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí.

11, 12. Lọ́dún 1969, ojú ìwòye tuntun wo nípa ìpọ́njú ńlá la gbé kalẹ̀?

11 Ṣùgbọ́n, ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e a ti wá rí i pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ Thursday, July 10, 1969, níbi Àpéjọ Àgbáyé “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” táa ṣe ní New York City, ni F. W. Franz, tó jẹ́ igbá kejì ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, sọ àwíyé kan tó tani jí gidigidi. Nígbà tó ń ṣàgbéyẹ̀wó òye táa ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, Arákùnrin Franz wí pé: “A ti ṣàlàyé rẹ̀ nígbà kan pé ‘ìpọ́njú ńlá’ náà ti bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914 ti Sànmánì Tiwa àti pé a kò yọ̀ǹda fún un láti máa bá a nìṣó, ṣùgbọ́n pé Ọlọ́run mú Ogun Àgbáyé Kìíní wá sópin ní November ọdún 1918. Láti ìgbà náà wá, Ọlọ́run ń yọ̀ǹda àkókò kan fún ìgbòkègbodò àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe àwọn Kristẹni àyànfẹ́ kó tó di pé yóò jẹ́ kí apá tó kẹ́yìn nínú ‘ìpọ́njú ńlá’ náà bẹ̀rẹ̀ nínú ogun Amágẹ́dọ́nì.”

12 Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé kan tí a fi ṣàtúnṣe ojú ìwòye náà lọ́nà tó gba àfiyèsí gidigidi, àlàyé ọ̀hún lọ báyìí: “Láti lè bá àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní mu, . . . ‘ìpọ́njú ńlá’ amápẹẹrẹṣẹ kò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 Sànmánì Tiwa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù amápẹẹrẹṣẹ, ìyẹn ni ohun tó dúró fún un lóde òní, lọ́dún 1914 sí 1918 wulẹ̀ jẹ ‘ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà’ . . . ‘Ìpọ́njú ńlá’ náà tí irú rẹ̀ kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ ṣì wà níwájú, nítorí yóò jẹ́ ìparun ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé (títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù), èyí tí ‘ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè’ ní Amágẹ́dọ́nì yóò tẹ̀ lé.” Èyí túmọ̀ sí pé ìpọ́njú ńlá náà látòkèdélẹ̀ ṣì wà níwájú.

13. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí “ohun ìríra” náà tó “dúró ní ibi mímọ́”?

13 Èyí ní nǹkan ṣe ní tààràtà pẹ̀lú ìgbà tí “ohun ìríra” náà dúró ní ibi mímọ́. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn ará Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, àmọ́ wọ́n kógun wọn lọ láìròtẹ́lẹ̀, èyí tó fún “ẹran ara,” tí í ṣe àwọn Kristẹni, láǹfààní láti rí ìgbàlà. (Mátíù 24:22) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a retí pé kí ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́, ṣùgbọ́n a óò ké e kúrú nítorí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Ṣàkíyèsí kókó pàtàkì yìí: Nínú ìmúṣẹ ti ìgbàanì, a pe ‘ohun ìríra tó dúró ní ibi mímọ́’ náà ní kíkọlù tí àwọn ará Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ lábẹ́ Ọ̀gágun Gallus lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ìkọlù tòde òní tó jẹ́ aláfijọ tọjọ́sí—ìyẹn ni ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá—ṣì wà ní iwájú. Nítorí náà, “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro,” tó ti wà láti ọdún 1919, ti fi hàn gbangba pé òun kò tí ì dúró ní ibi mímọ́.b Báwo lèyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Báwo ni yóò sì ṣe kàn wá?

Ìkọlù Ní Ọjọ́ Iwájú

14, 15. Báwo ni Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí Amágẹ́dọ́nì?

14 Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe ìkọlù apanirun kan tí yóò dé sórí ìsìn èké lọ́jọ́ ọ̀la. Orí kẹtàdínlógún ṣàlàyé ìdájọ́ Ọlọ́run tí yóò dé sórí “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó”—ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá pàtàkì nínú rẹ̀, ó sì ń sọ pé òun ti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú. (Fi wé Jeremáyà 7:4.) Ó ti pẹ́ ti àwọn ìsìn èké, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù, ti ń bá “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” da nǹkan pọ̀, ṣùgbọ́n èyí yóò dópin nígbà ìsọdahoro àwọn ìsìn wọ̀nyẹn. (Ìṣípayá 17:2, 5) Ọwọ́ ta ni ìsọdahoro náà yóò ti wá?

15 Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan” tó ti wà fún sáà kan, tí a kò tún gbúròó rẹ̀ mọ́, tó tún padà yọ kúlẹ́. (Ìṣípayá 17:3, 8) Àwọn alákòóso ayé ni wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ẹranko ẹhànnà yìí. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ táa pèsè nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ yìí gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ tí a pète láti mú àlàáfíà wá, èyí tó wá sójútáyé lọ́dún 1919 gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (“ohun ìríra”) tí a sì wá mọ̀ nísinsìnyí sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìṣípayá 17:16, 17 fi hàn pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò fi í sí ọkàn-àyà àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn kan tí wọn kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú àjọ tó dúró fún “ẹranko ẹhànnà” yìí láti sọ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé dahoro. Kíkọlù tí yóò kọ lù ú yẹn ni yóò sàmì sí ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá.

16. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gba àfiyèsí wo ló ń wáyé nípa ẹ̀sìn báyìí?

16 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà ṣì wà níwájú, ṣé ‘dídúró ní ibi mímọ́’ náà ṣì wà lọ́jọ́ iwájú ni? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ohun ìríra” náà ti fara hàn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, yóò dúró “ní ibi mímọ́” lọ́nà tí yóò pabanbarì, ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́. Bó ṣe jẹ́ pé ṣe ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ọ̀rúndún kìíní ní láti fara balẹ̀ kí wọ́n sì ṣàkíyèsí bí ‘dídúró ní ibi mímọ́’ náà ṣe wáyé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tí ń bẹ lóde òní gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ láti rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, sùúrù la óò ní láti lè rí ìmúṣẹ náà gan-an, ká sì mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ fún àfiyèsí pé ní àwọn ilẹ̀ kan ṣá o, ẹ̀tanú ẹ̀sìn kàn ń pọ̀ sí i ṣáá ni. Àwọn olóṣèlú kan, tí wọ́n ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti kúrò nínú ẹ̀sìn tòótọ́, làwọn tí ń gbé ẹ̀tanú dìde sí ẹ̀sìn ní gbogbo gbòò, pàápàá jù lọ àwọn ló ń gbé ẹ̀tanú dìde sí àwọn Kristẹni tòótọ́. (Sáàmù 94:20, 21; 1 Tímótì 6:20, 21) Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, àwọn agbára ìṣèlú pàápàá nísinsìnyí ‘ń bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun,’ gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 17:14 sì ti fi hàn, ìjà yìí ṣì máa gbóná sí i o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wọn kò lè tẹ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run—Jésù Kristi táa ti gbé ga sí ipò ológo—wọn yóò túbọ̀ gbé àtakò wọn dìde sí àwọn olùjọsìn tòótọ́ ti Ọlọ́run, pàápàá “àwọn ẹni mímọ́” rẹ̀. (Dáníẹ́lì 7:25; fi wé Róòmù 8:27; Kólósè 1:2; Ìṣípayá 12:17.) Ọlọ́run ti mú un dá wa lójú pé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ni yóò borí nínú ìjà náà.—Ìṣípayá 19:11-21.

17. Láìlẹ́mìí pé ohun táa ti mọ̀ náà la ó rinkinkin mọ́, kí la lè sọ nípa bí “ohun ìríra” náà yóò ṣe dúró ní ibi mímọ́?

17 A mọ̀ dájú pé ìsọdahoro ń dúró de ìsìn èké. Bábílónì Ńlá ti “mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́” ó sì ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọbabìnrin, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè yẹ ìparun rẹ̀. Agbára àìmọ́ tó ti lò lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé yóò yí padà lójijì bí àjọṣe wọn ti máa yí padà bírí, nígbà tí ‘ìwo mẹ́wàá àti ẹranko ẹhànnà náà’ bá kórìíra rẹ̀ pátápátá. (Ìṣípayá 17:6, 16; 18:7, 8) Nígbà tí “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” bá kọ lu ẹ̀sìn tó ti ya aṣẹ́wó kalẹ̀ yìí, “ohun ìríra” náà yóò dúró ní ibi tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń pè ní ibi mímọ́, lọ́nà tí yóò fi hàn pé ewu ń bọ̀.c Nítorí náà, ìsọdahoro náà yóò bẹ̀rẹ̀ lórí Kirisẹ́ńdọ̀mù aláìgbàgbọ́, tí ń fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́.

“Sá”—Sá Lọ Síbo?

18, 19. Kí ni àwọn ìdí táa fún wa tó fi hàn pé ‘sísa lọ sórí òkè ńlá’ kò ní túmọ̀ sí títi inú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn?

18 Lẹ́yìn tó ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ‘dídúró tí ohun ìríra náà yóò dúró ní ibi mímọ́,’ Jésù kìlọ̀ fún àwọn olóye láti máà jáfara. Ṣé ohun tí ó ń sọ ni pé nígbà tí àkókò ti lọ tán yẹn—nígbà tí “ohun ìríra” ti “dúró ní ibi mímọ́”—ọ̀pọ̀ èèyàn yóò sá kúrò nínú ìsìn èké lọ sínú ìsìn tòótọ́? Kò dájú. Ṣàgbéyẹ̀wò ìmúṣẹ àkọ́kọ́. Jésù wí pé: “Kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá. Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀, tàbí kí ó wọlé lọ mú ohunkóhun jáde kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ni ọjọ́ wọnnì! Ẹ máa gbàdúrà kí ó má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù.”—Máàkù 13:14-18.

19 Jésù kò sọ pé kìkì àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù nìkan ló ní láti sá, kó wá dà bí ẹni pé kókó ohun tó ń sọ ni pé wọ́n ní láti kúrò ní ibi tí ó jẹ́ ojúkò fún ìjọsìn àwọn Júù; bẹ́ẹ̀ sì ni ìkìlọ̀ rẹ̀ kò mẹ́nu kan títi inú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn—ìyẹn ni sísa kúrò nínú ẹ̀sìn èké, kí a sì gba ẹ̀sìn tòótọ́. Lóòótọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò nílò ìkìlọ̀ kankan nípa sísá láti inú ẹ̀sìn kan sínú òmíràn; wọ́n kúkú ti di Kristẹni tòótọ́ ná. Kíkọlù tí a sì kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa kò sún àwọn ẹlẹ́sìn Júù tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù àtàwọn tó wà jákèjádò Jùdíà láti pa ẹ̀sìn wọn tì, kí wọ́n sì wá tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni. Ọ̀jọ̀gbọ́n Heinrich Graetz sọ pé àwọn tó gbá tẹ̀ lé àwọn ará Róòmù tí wọ́n fẹsẹ̀ fẹ tún padà wá sínú ìlú náà, ó sọ pé: “Àwọn Onítara Ìsìn, tí wọ́n ń fi ohùn rara kọrin ogun kiri ìgboro, gbogbo wọn ló padà wá sí Jerúsálẹ́mù (lọ́jọ́ kẹjọ oṣù October), tí wọ́n ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ìdáǹdè àti òmìnira wọn ti dé. . . . Ǹjẹ́ Ọlọ́run kò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ báyìí bí Ó ti ran àwọn baba ńlá wọn lọ́wọ́? Digbídigbí lọkàn Àwọn Onítara Ìsìn náà balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.”

20. Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ṣe dáhùn padà sí ìkìlọ̀ tó fún wọn nípa sísá lọ sí àwọn òkè ńlá?

20 Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo làwọn àyànfẹ́ tí wọ́n kéré níye gan-an nígbà náà lọ́hùn-ún ṣe wá ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn Jésù? Nípa fífi Jùdíà sílẹ̀ àti sísá tí wọn sá lọ sórí àwọn òkè níkọjá Jọ́dánì, wọ́n fi hàn pé àwọn kì í ṣe apá kan ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù, ì báà jẹ́ ní ti ìṣèlú o, tàbí ní ti ẹ̀sìn. Wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀, wọn ò tiẹ̀ kó dúkìá tí wọ́n ní sílé pàápàá. Nítorí pé wọ́n nígbọ̀ọ́kànlé pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn, àti pé yóò pèsè fáwọn, wọ́n fi ìjọsìn rẹ̀ ṣáájú ohunkóhun tó lè jọ pé ó ṣe pàtàkì.—Máàkù 10:29, 30; Lúùkù 9:57-62.

21. Kí ni kò yẹ ká máa retí nígbà tí “ohun ìríra” náà bá ṣe ìkọlù rẹ̀?

21 Wàyí o, wá gbé ìmúṣẹ rẹ̀ títóbi jù yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún la ti ń rọ àwọn èèyàn láti jáde kúrò nínú ìsìn èké, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìsìn tòótọ́. (Ìṣípayá 18:4, 5) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù kò fi hàn pé gbàrà tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ́ sílẹ̀, àwọn èèyàn yóò wá yíjú sí ìjọsìn mímọ́ gaara; ó dájú pé ìyípadà irú-wá-ògìrì-wá bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Júù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni yóò mú àwọn Kristẹni tòótọ́ lórí yá láti fi ìkìlọ̀ Jésù sílò, kí wọ́n sì sá.

22. Kí ni fífi táa bá fi ìmọ̀ràn Jésù nípa sísálọ sórí òkè sílò lè ní nínú?

22 Ní báyìí, a kò lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá, ṣùgbọ́n ó bọ́gbọ́n mu fún wa láti dé ìparí èrò pé ní tiwa, sísá tí Jésù sọ kò ní jẹ́ sísá láti àgbègbè kan lọ sí àgbègbè mìíràn. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà káàkiri àgbáyé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí wọn ò sí. Ṣùgbọ́n o, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé, nígbà tó bá pọndandan pé kí àwọn Kristẹni sá, sísá wọn yóò jẹ́ bíbá a nìṣó láti di ìdúró wọn gédégbé mú ní ti pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ètò ìsìn èké. Ó tún ṣe pàtàkì pé Jésù kìlọ̀ pé kéèyàn má padà lọ sílé rẹ̀ torí pé ó fẹ́ lọ mú ẹ̀wù àwọ̀lékè tàbí torí àwọn ẹrù mìíràn tó fẹ́ gbé. (Mátíù 24:17, 18) Nítorí náà, àdánwò lè wà níwájú nípa ojú táa fi ń wo ọrọ̀ àlùmọ́nì; ṣé àwọn nǹkan yẹn la kà sí ohun to ṣe pàtàkì jù lọ, àbí ìgbàlà tí yóò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá? Bẹ́ẹ̀ ni, sísá wa lè ní àwọn ìnira àti ìṣòro kan nínú. A ní láti múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn akẹgbẹ́ wa ní ọ̀rúndún kìíní ti ṣe, àwọn tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà lọ sí Pèríà, níkọjá Jọ́dánì.

23, 24. (a) Ibo ni ibì kan ṣoṣo táa ti lè rí ààbò? (b) Ipa wo ló yẹ kí ìkìlọ̀ Jésù nípa “ohun ìríra, tí ó dúró ní ibi mímọ́” ní lórí wa?

23 A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ tó dà bí òkè ńlá ni yóò máa jẹ́ ibi ìsádi wa. (2 Sámúẹ́lì 22:2, 3; Sáàmù 18:2; Dáníẹ́lì 2:35, 44) Ibẹ̀ yẹn la ti lè rí ààbò! Ẹ má ṣe jẹ́ ká fara wé àwọn èèyàn ayé tí wọn yóò sá lọ sínú “àwọn hòrò” tí wọn yóò lọ fara pamọ́ “sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá”—àwọn ètò àjọ tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀ tó ṣeé ṣe kó wà fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti sọ Bábílónì Ńlá dahoro. (Ìṣípayá 6:15; 18:9-11) Lóòótọ́, nǹkan lè máà rọrùn—bó ti ṣeé ṣe kó rí fún àwọn aboyún tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà tàbí àwọn kan tí wọ́n ní láti rìnrìn àjò nígbà òtútù tàbí ní àkókò àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n a lè nígbàgbọ́ pé lágbára Ọlọ́run a óo là á já. Àní láti ìsinsìnyí lọ, ẹ jẹ́ kí a máa fún ìgbàgbọ́ táa ní nínú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ lókun, Ọmọ rẹ̀ tí ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba náà.

24 Kò sídìí kankan fún wa láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun nígbà yẹn bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ kí àwa pẹ̀lú máa fòyà báyìí tàbí ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀. Ó ta wá lólobó torí kí a bàa lè múra ọkàn-àyà àti ìrònú wa sílẹ̀. Ó ṣe tán, a kò ní fìyà jẹ àwọn Kristẹni onígbọràn nígbà tí ìparun bá dé sórí ìsìn èké àti ìyókù ètò búburú yìí. Wọn yóò lo òye, wọn yóò sì kọbi ara sí ìkìlọ̀ nípa “ohun ìríra tí ó dúró ni ibi mímọ́.” Ìgbàgbọ́ wọn tí kò lè yẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n gbégbèésẹ̀ láìjáfara. Ǹjẹ́ kí a má gbàgbé ìlérí Jésù yìí láé pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Máàkù 13:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Nínú tẹ́ńpìlì Róòmù, ọ̀wọ̀ ńlá tó wà fún nǹkan ẹ̀sìn ni wọ́n fún àsíá àwọn ará Róòmù; bí àwọn èèyàn wọ̀nyí sì ṣe gbà pé wọ́n lọ́lá ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe gbé àsíá ilẹ̀ wọn gẹ̀gẹ̀ tó . . . [Lójú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ náà], kò sóhùn tó tún ṣe pàtàkì tó o lágbàáyé. Àsíá náà wà lára àwọn ohun tí ọmọ ogun Róòmù fi máa ń búra.”—The Encyclopædia Britannica, Ìtẹ̀jáde kọkànlá.

b Ó yẹ ká kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí wọn yóò ṣe nímùúṣẹ nígbà ìpọ́njú ńlá, ìmúṣẹ méjèèjì kò lè rí bákan náà nítorí pé àwọn ìmúṣẹ náà ṣẹlẹ̀ nínú ipò tó yàtọ̀ síra.

c Jọ̀wọ́ wo Ile Iṣọ Na, October 15, 1976, ojú ìwé 617 sí 623.

Ǹjẹ́ O Rántí?

◻ Báwo ni “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro” ṣe fi ara rẹ̀ hàn ní ọ̀rúndún kìíní?

◻ Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé ó ṣì di ọjọ́ ọ̀la kí “ohun ìríra” ti òde òní tó dúró ní ibi mímọ́?

◻ Ìkọlù wo táa ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá ni “ohun ìríra” náà yóò ṣe?

◻ Irú ‘sísá’ wo ni a ṣì lè sọ pé kí a sá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

A pe Bábílónì Ńlá ni “ìyá àwọn aṣẹ́wó”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò inú ìwé Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún ni “ohun ìríra” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yóò kọ lu ẹ̀sìn lọ́nà tí yóò fi sọ ọ́ dahoro

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́