Mímọrírì “Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn”
“Ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, . . . kí ẹ sì máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:12, 13.
1. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 20:35 ti wí, agbára wo ni fífúnni ní? Ṣàpèjúwe.
“AYỌ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ǹjẹ́ o lè rántí ìgbà tí ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyẹn ṣẹ sí ẹ lára gbẹ̀yìn? Ó lè jẹ́ ìgbà tóo fún ẹnì kan tóo fẹ́ràn gan-an ní ẹ̀bùn kan. O fara balẹ̀ ṣàṣàyàn ẹ̀bùn náà, torí pé o fẹ́ kó jẹ́ ohun kan tí yóò wu ẹni náà gan-an. Nígbà tóo wojú onítọ̀hún, tóo rí pé inú rẹ̀ dùn—inú ìwọ náà wá dùn gan-an! Nígbà táa bá fúnni ní nǹkan látọkànwá, ó jẹ́ ìfihàn ìfẹ́, fífìfẹ́hàn sì máa ń fún wa láyọ̀.
2, 3. (a) Èé ṣe táa fi lè sọ pé kò sẹ́ni tó láyọ̀ tó Jèhófà, báwo sì ni ìpèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ṣe lè máa mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀? (b) Kí ni kò yẹ ká ṣe sí ẹ̀bùn tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá?
2 Ta ló wá lè láyọ̀ tó Jèhófà, Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere”? (Jákọ́bù 1:17; 1 Tímótì 1:11) Ìfẹ́ ló ń sún un láti fúnni ní gbogbo ẹ̀bùn tó ń fúnni. (1 Jòhánù 4:8) Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lọ̀ràn rí ní ti ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi fún ìjọ nípasẹ̀ Kristi—èyíinì ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfésù 4:8) Pípèsè àwọn alàgbà láti máa bójú tó agbo jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ àtọkànwá tí Ọlọ́run ní fún àwọn èèyàn rẹ̀. Ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ la fi ń yan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí—wọ́n gbọ́dọ̀ dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9) Wọ́n mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ máa “fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo,” torí pé ìyẹn ni yóò mú kí àwọn àgùntàn mọrírì irú àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 20:29; Sáàmù 100:3) Nígbà tí Jèhófà bá rí i pé àwọn àgùntàn òun ní ọkàn-àyà tó kún fún irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ọkàn-àyà òun alára yóò kún fún ayọ̀!—Òwe 27:11.
3 Ó dájú pé a kò ní fẹ́ fojú yẹpẹrẹ wo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run bá fún wa; bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní fẹ́ ṣàìmọrírì àwọn ẹ̀bùn rẹ̀. Ìbéèrè méjì wá tipa báyìí dìde: Ojú wo ló yẹ káwọn alàgbà máa fi wo ipa tí wọ́n ń kó nínú ìjọ? Báwo sì ni ìyókù agbo ṣe lè fi hàn pé àwọn mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”?
‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Yín Ni Àwa Jẹ́’
4, 5. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ìjọ wé, èé sì ti ṣe tí èyí fi jẹ́ àpèjúwe tó ṣe wẹ́kú? (b) Kí ni àpèjúwe Pọ́ọ̀lù fi hàn nípa ojú tó yẹ ká máa fi wo ara wa, àti bó ṣe yẹ ká máa bá ara wa lò?
4 Jèhófà ti fún “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ní ọlá àṣẹ dé àyè kan nínú ìjọ. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, àwọn alàgbà kì í fẹ́ ṣi ọlá àṣẹ wọn lò, torí wọ́n mọ̀ pé ó rọrùn gidigidi fún ẹ̀dá aláìpé láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ojú wo ló wá yẹ kí wọ́n máa fi wo bí wọ́n ti jẹ́ sí ìyókù agbo? Gbé àpèjúwe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò yẹ̀ wò. Lẹ́yìn jíjíròrò ìdí táa fi pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.” (Éfésù 4:15, 16) Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù fi ìjọ, àti àwọn alàgbà àti àwọn mẹ́ńbà yòókù, wé ara ènìyàn. Èé ṣe tí àpèjúwe yìí fi bá a mu?
5 Ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹ̀yà ara ni ènìyàn ní, ṣùgbọ́n orí kan ṣoṣo ló ní. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò sóhun tí kò wúlò nínú ara—ì báà ṣe iṣu ẹran ara, tàbí iṣan, tàbí òpó ẹ̀jẹ̀ inú ara. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló wúlò, tó sì níṣẹ́ tó ń ṣe fún ìlera àti ẹwà gbogbo ara. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìjọ jẹ́ àpapọ̀ ọ̀kan-kò-jọ̀kan mẹ́ńbà, ṣùgbọ́n mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan—ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, ì báà jẹ́ abarapá tàbí ẹni tára rẹ̀ kò ṣe ṣámúṣámú—gbogbo wọn ni wọ́n níṣẹ́ tí wọ́n lè ṣe fún ìlera àti ẹwà tẹ̀mí ìjọ lódindi. (1 Kọ́ríńtì 12:14-26) Kò sídìí fún ẹnikẹ́ni láti máa ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan rárá. Ṣùgbọ́n ní ìdà kejì, kò tún wá yẹ kí ẹnikẹ́ni máa lérò pé òun lọ́lá ju àwọn yòókù lọ, torí pé gbogbo wa—àti olùṣọ́ àgùntàn àti àgùntàn—jẹ́ apá kan ara, orí kan ṣoṣo ló sì wà, ìyẹn Kristi. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù ṣe àpèjúwe tó wọni lọ́kàn nípa ìfẹ́, àbójútó, àti ọ̀wọ̀ tó yẹ ká ní fún ẹnì kìíní kejì. Mímọ èyí ń jẹ́ kí àwọn alàgbà ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ipa tí wọ́n ń kó nínú ìjọ.
6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní ọlá àṣẹ àpọ́sítélì, báwo ló ṣe fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn?
6 “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí kì í wá ọ̀nà láti jẹgàba lórí ìgbésí ayé tàbí ìgbàgbọ́ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́ríńtì 1:24) Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ láti jẹgàba lórí ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà ìgbé-ayé àwọn arákùnrin rẹ̀. Àní, kò rídìí fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó sọ pé ọkàn òun balẹ̀ pé olùṣòtítọ́ ni wọ́n, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àti pé wọ́n wà nínú ètò àjọ Jèhófà nítorí pé ó tinú ọkàn wọn wá láti máa ṣe ohun tó tọ́. Fún ìdí yìí, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ àti Tímótì, tí wọn jọ ń rìnrìn àjò, ohun tó jọ pé ó ń sọ ni pé: ‘Ojúṣe wa ni láti máa ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín kí ẹ lè máa fayọ̀ sin Ọlọ́run nìṣó.’ (2 Kọ́ríńtì 1:1) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ náà mà kúkú pọ̀ o!
7. Kí ni àwọn alàgbà onírẹ̀lẹ̀ mọ̀ nípa ipa iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, ọkàn wọn sì balẹ̀ pé àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn yóò ṣe kí ni?
7 Ojúṣe kan náà ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” lónìí ní. Wọ́n jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú wa.’ Àwọn alàgbà onírẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé iṣẹ́ àwọn kọ́ ni láti máa pinnu ohun tí agbára àwọn èèyàn gbé láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Wọ́n mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn lè máa fún àwọn èèyàn níṣìírí láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i tàbí láti mú un sunwọ̀n sí i, iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ti inú ọkàn-àyà wá. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Ọkàn wọn balẹ̀ pé bí àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn bá jẹ́ aláyọ̀, wọn yóò ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe. Fún ìdí yìí, ìfẹ́ àtọkànwá wọn ni láti ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ láti máa “fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà.”—Sáàmù 100:2.
Ríran Gbogbo Àwọn Ará Lọ́wọ́ Láti Máa Fayọ̀ Sìn
8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí àwọn alàgbà fi lè ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sin Jèhófà?
8 Ẹ̀yin alàgbà, báwo lẹ ṣe lè ran àwọn ará lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sìn? Ẹ lè máa fúnni níṣìírí nípasẹ̀ àpẹẹrẹ. (1 Pétérù 5:3) Ẹ jẹ́ kí ìtara àti ayọ̀ yín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ hàn gbangba, ó sì lè gún ọkàn àwọn mìíràn ní kẹ́ṣẹ́ láti máa fara wé àpẹẹrẹ yín. Ẹ máa gbóríyìn fún àwọn èèyàn fún ìsapá àtọkànwá wọn. (Éfésù 4:29) Fífi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà àti tọkàntọkàn gbóríyìn fún àwọn èèyàn máa ń jẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé wọ́n wúlò àti pé a kà wọ́n sí. Ó máa ń fún àwọn àgùntàn níṣìírí láti sa gbogbo ipá wọn láti sin Ọlọ́run. Ẹ yẹra fún ṣíṣe àwọn ìfiwéra tí kò bára dé. (Gálátíà 6:4) Irú ìfiwéra bẹ́ẹ̀ lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, dípò kí ó sún àwọn èèyàn láti tẹ̀ síwájú. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn àgùntàn Jèhófà—ipò kálukú yàtọ̀, agbára kálukú ò sì rí bákan náà. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ kí àwọn arákùnrin yín mọ̀ pé ẹ lè gba ẹ̀rí wọn jẹ́. Ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́,” nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbà gbọ́ pé àwọn arákùnrin wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé wọ́n fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù ú. (1 Kọ́ríńtì 13:7) Nígbà táa bá ‘bu ọlá fún àwọn ẹlòmíràn,’ èyí yóò mú kí wọn túbọ̀ sa gbogbo ipá wọn. (Róòmù 12:10) Ó dájú pé nígbà táa bá fún àwọn àgùntàn níṣìírí, tí a sì mára tù wọ́n, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn yóò ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe ní sísin Ọlọ́run, wọn yóò sì láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn náà.—Mátíù 11:28-30.
9. Ojú ìwòye wo nípa àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ ẹni ni yóò ran alàgbà kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sìn?
9 Fífi tí o bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa sìn tayọ̀tayọ̀, yóò sì jẹ́ kí o mọrírì ẹ̀bùn aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ ní. Alàgbà kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀bùn àbínibí àti ìmọ̀ tó lè lò fún àǹfààní ìjọ. (1 Pétérù 4:10) Ọ̀kan lè lẹ́bùn ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Òmíràn lè mọ ètòó ṣe. Síbẹ̀, òmíràn lè ṣeé sún mọ́ nítorí ọ̀yàyà àti ìyọ́nú rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, kò sí alàgbà tó ní gbogbo ẹ̀bùn ní ìwọ̀n kan náà. Ǹjẹ́ níní ẹ̀bùn kan pàtó—bóyá ká sọ pé, ẹ̀bùn ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́—wá sọ alàgbà kan di ẹni tó lọ́lá ju alàgbà mìíràn bí? Rárá o! (1 Kọ́ríńtì 4:7) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò sídìí láti máa ṣe ìlara ẹ̀bùn tí ẹlòmíràn ní, tàbí láti máa rò pé àwa ò kúkú tóótun nígbà táwọn èèyàn bá ń gbóríyìn fún alàgbà kan nítorí ẹ̀bùn tó ní. Rántí o, ìwọ alára ní àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà rí lára rẹ. Ó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyẹn dàgbà, kí o sì lò wọ́n fún àǹfààní àwọn arákùnrin rẹ.—Fílípì 4:13.
‘Ẹ Jẹ́ Onígbọràn àti Ẹni Tí Ń Tẹrí Ba’
10. Èé ṣe tó fi bójú mu pé ká fìmọrírì hàn fún “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”?
10 Táa bá rí ẹ̀bùn gbà, ó bójú mu pé ká fìmọrírì hàn. Kólósè 3:15 sọ pé: “Ẹ . . . fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” Nípa “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wá ńkọ́ o, tí í ṣe ẹ̀bùn níníyelórí tí Jèhófà fún wa? Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, a ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Olùfúnni-Lẹ́bùn láìṣahun. Ṣùgbọ́n “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” náà tìkára wọn ńkọ́? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì wọn?
11. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? (b) Kí ni ìjẹ́pàtàkì àwọn gbólóhùn náà “jẹ́ onígbọràn” àti “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba”?
11 A lè fi ìmọrírì wa hàn fún “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” nípa títaraṣàṣà láti tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn àti ìpinnu tí wọ́n gbé ka Bíbélì. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” (Hébérù 13:17) Ṣàkíyèsí pé kì í ṣe kìkì pé a gbọ́dọ̀ “jẹ́ onígbọràn” nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ní láti “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba” fún àwọn tí ń mú ipò iwájú. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa lò fún “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba,” táa bá tú u ní ṣáńgílítí, ó túmọ̀ sí “jíjẹ́ ẹni tó ṣe tán láti ṣe ohunkóhun táa bá ní kó ṣe.” Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì nì, R. C. H. Lenski, ń ṣàlàyé àwọn gbólóhùn náà “jẹ́ onígbọràn” àti “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba,” ó sọ pé: “Èèyàn máa ń ṣègbọràn bí olúwarẹ̀ bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí wọ́n ní kó ṣe, bó bá gbà pé ó tọ̀nà, pé ó ṣàǹfààní; àmọ́ èèyàn máa ń fara mọ́ nǹkan bó bá tilẹ̀ ní èrò tó yàtọ̀.” Nígbà táa bá lóye, táa sì fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn tí ń mú ipò iwájú, kíá la máa ń ṣègbọràn. Ṣùgbọ́n, bí a kò bá mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe ìpinnu kan pàtó ńkọ́?
12. Èé ṣe tó fi yẹ ká jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, tàbí tí ń juwọ́ sílẹ̀, kódà nígbà tí a kò bá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdí tí wọ́n fi ṣe ìpinnu kan pàtó?
12 Ìhín yìí lọ̀ràn jíjẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, tàbí ẹni tí ń juwọ́ sílẹ̀, ti wáyé. Èé ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ire wa làwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí wọ̀nyí ń wá. Ó ṣe tán, wọ́n mọ̀ lámọ̀dunjú pé wọn yóò jíhìn fún Jèhófà nípa àwọn àgùntàn tó fi sábẹ́ àbójútó wọn. (Jákọ́bù 3:1) Ní àfikún, ó yẹ ká máa rántí pé a lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú wọn ṣe ìpinnu olóye tí wọ́n ṣe.—Òwe 18:13.
13. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba nígbà tó bá dọ̀ràn ìpinnu ìdájọ́ táwọn alàgbà ṣe?
13 Jíjẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba nígbà tó bá dọ̀ràn ìpinnu ìdájọ́ ńkọ́? A ò jiyàn, òótọ́ ni pé èyí lè má rọrùn, pàápàá jù lọ bí ìpinnu wọn bá jẹ́ láti yọ ẹnì kan táa nífẹ̀ẹ́ lẹ́gbẹ́—bóyá ẹbí wa tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ lonítọ̀hún. Ní ti èyí pàápàá, ohun tó dáa jù lọ ni pé kéèyàn sinmi agbaja, kó gbà pẹ̀lú ìpinnu tí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ṣe. Àwọn ló lè fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀ràn náà láìgbè sọ́tùn-ún sósì, wọ́n sì lè mọ òkodoro ọ̀ràn náà jù wá lọ. Àìmọye ìgbà ló máa ń jẹ́ pé ikun imú tọ̀tún máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí tòsì káwọn arákùnrin wọ̀nyí tó lè dórí ìpinnu bẹ́ẹ̀; iṣẹ́ ńlá mà ló jẹ́ láti ‘máa ṣe ìdájọ́ fún Jèhófà.’ (2 Kíróníkà 19:6) Gbogbo ipá wọn ni wọ́n máa ń sà láti lè ṣojú àánú, nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Àmọ́, dandan tún ni pé kí wọ́n mú kí ìjọ wà ní mímọ́, Bíbélì sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹlẹ́ṣẹ̀ alára máa ń gbà pẹ̀lú ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ó lè jẹ́ ìbáwí yẹn gan-an ló máa pe orí rẹ̀ wálé. Bí àwa, táa fẹ́ràn rẹ̀, bá jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba nígbà tí irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ bá délẹ̀, a lè máa tipa bẹ́ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ìbáwí náà.—Hébérù 12:11.
“Máa fún Wọn ní Ìkàsí Tí Ó Ju Àrà Ọ̀tọ̀ Lọ”
14, 15. (a) Gẹ́gẹ́ bí 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13 ti wí, èé ṣe tó fi yẹ kí a ka àwọn alàgbà sí? (b) Èé ṣe táa fi lè sọ pé àwọn alàgbà ‘ń ṣiṣẹ́ kára láàárín wa’?
14 A tún lè fi hàn pé a mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” nípa kíkà wọ́n sí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí ìjọ Tẹsalóníkà, ó gba àwọn mẹ́ńbà ìjọ náà níyànjú pé: “Ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń ṣí yín létí; kí ẹ sì máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.” (1 Tẹsalóníkà 5:12, 13) “Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára”—àpèjúwe yẹn kò ha bá àwọn alàgbà olùfọkànsìn mu, àwọn tí ń yọ̀ǹda ara wọn fún wa tọkàntara? Tiẹ̀ ronú ná, fún ìṣẹ́jú kan, nípa ẹrù bàǹtà-banta tí àwọn arákùnrin ọ̀wọ́n wọ̀nyí ń gbé.
15 Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ló jẹ́ onídìílé, tí wọ́n ní láti máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. (1 Tímótì 5:8) Bí alàgbà bá sì lọ́mọ, àwọn ọmọ náà yóò máa gba àkókò rẹ̀, wọn yóò sì máa fẹ́ àbójútó rẹ̀. Ó lè di dandan fún un láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ iléèwé, kó sì tún ṣètò àkókò fún eré ìdárayá tó gbámúṣé níbi tí wọn á ti lè lo okun ọ̀dọ́ wọn. (Oníwàásù 3:1, 4) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó ń bójú tó àwọn kòṣeémánìí ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí, nípa dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé, bíbá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti mímú wọn dání lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. (Diutarónómì 6:4-7; Éfésù 6:4) Ká má sì gbàgbé o, pé ní àfikún sáwọn ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ń ṣe, àwọn alàgbà tún ní àwọn ojúṣe mìn-ín-ìn: mímúrasílẹ̀ fún àwọn apá ìpàdé, ṣíṣe àwọn àbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, bíbójútó ire tẹ̀mí ìjọ àti bíbójútó ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, nígbà tó bá délẹ̀. Àwọn kan tilẹ̀ tún ń gbé àfikún ẹrù iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àwọn ìpàdé àyíká, àpéjọpọ̀ àgbègbè, kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àti Àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn arákùnrin wọ̀nyí “ń ṣiṣẹ́ kára lóòótọ́”!
16. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà táa lè gbà fi hàn pé a ka àwọn alàgbà sí.
16 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kà wọ́n sí? Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23; 25:11) Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ìmọrírì àti ìṣírí látọkànwá lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a kò fojú tín-ín-rín iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe. Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò yẹ ká máa retí pé kí wọ́n ṣe ju ohun tí agbára wọn lè gbé. Ṣùgbọ́n ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ tìtorí èyí lọ́tìkọ̀ láti tọ̀ wọ́n lọ fún ìrànlọ́wọ́. Ìgbà mí-ìn lè wà tí ‘ọkàn-àyà wa ń jẹ ìrora mímúná,’ táa sì nílò ìṣírí, ìtọ́sọ́nà, tàbí ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́ látẹnu àwọn tí ó “tóótun láti kọ́ni” ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 55:4; 1 Tímótì 3:2) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún yẹ ká rántí pé alàgbà kan kò lè máa fi gbogbo àkókò ẹ̀ gbọ́ tiwa, torí pé kò lè dágunlá sí àwọn ìṣòro ìdílé tirẹ̀ tàbí àwọn ìṣòro tàwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Táa bá ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì,” táa sì fi ìmọ̀lára yẹn hàn fún àwọn arákùnrin wọ̀nyí tí ń ṣiṣẹ́ kára, a ò ní máa béèrè ohun tí agbára wọn ò ní lè gbé lọ́wọ́ wọn. (1 Pétérù 3:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi ìmọrírì hàn fún àkókò tàbí àfiyèsí yòówù tí agbára wọn bá yọ̀ǹda fún wọn láti fún wa.—Fílípì 4:5.
17, 18. Àwọn ìrúbọ wo ni ọ̀pọ̀ àwọn aya tí ọkọ wọ́n jẹ́ alàgbà ń ṣe, báwo sì la ṣe lè fi hàn pé a kò fojú tín-ín-rín àwọn arábìnrin olóòótọ́ wọ̀nyí?
17 Tóò, ìyàwó àwọn alàgbà ńkọ́ o? Ṣé kò yẹ ká ro tàwọn náà ni? Ó ṣe tán, wọ́n ń fi ọkọ wọn sílẹ̀ kí ìjọ lè rí wọn lò. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ nǹkan rúbọ. Nígbà mìíràn, ó lè di dandan káwọn alàgbà lo ọ̀pọ̀ wákàtí lálẹ́ fún bíbójútó ọ̀ràn ìjọ, bí kò bá sì jẹ́ torí èyí ni, ṣe ni wọn ì bá máa lo àkókò yẹn pẹ̀lú ìdílé wọn. Nínú ọ̀pọ̀ ìjọ, àwọn obìnrin Kristẹni olóòótọ́ múra tán láti ṣe irú ìrúbọ bẹ́ẹ̀, kí ọkọ wọn bàa lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 12:15.
18 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kò fojú tín-ín-rín àwọn Kristẹni arábìnrin olóòótọ́ wọ̀nyí? Dájúdájú a lè fi èyí hàn nípa ṣíṣàì máa béèrè ju bó ṣe yẹ lọ lọ́wọ́ ọkọ wọn. Ṣùgbọ́n, ó dáa ká máa rántí agbára àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí táa lè sọ jáde lẹ́nu wẹ́rẹ́. Òwe 16:24 sọ pé: “Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.” Dákun fetí sí ìrírí yìí. Lẹ́yìn ìpàdé Kristẹni lọ́jọ́ kan, tọkọtaya kan tọ alàgbà kan lọ, wọ́n sì ní àwọn fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ọmọkùnrin àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́langba. Nígbà tí alàgbà náà ń bá tọkọtaya yìí sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìyàwó rẹ̀ mú sùúrù, ó dúró dè é. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọn, ìyá ọmọ náà lọ bá ìyàwó alàgbà, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àkókò tí ọkọ yín fi ran ìdílé mi lọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ ìṣírí yẹn, tó jáde wẹ́rẹ́, tó sì tuni lára, wú ìyàwó alàgbà náà lórí.
19. (a) Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn alàgbà ń fi ìṣòtítọ́ mú àwọn ète wo ṣẹ? (b) Kí ló yẹ kí gbogbo wa pinnu láti máa ṣe?
19 Ìpèsè àwọn alàgbà láti máa tọ́jú àwọn àgùntàn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “ẹ̀bùn rere” tí Jèhófà fún wa. (1 Jákọ́bù 1:17) Ó tì o, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í ṣe ẹni pípé; gẹ́gẹ́ bí gbogbo wa, àwọn náà ń ṣàṣìṣe. (1 Ọba 8:46) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn alàgbà tí ń bẹ nínú àwọn ìjọ kárí ayé ń fi ìṣòtítọ́ mú àwọn ète tí Jèhófà ní lọ́kàn fún wọn ṣẹ—èyíinì ni, láti máa tọ́ agbo sọ́nà, láti máa gbé e ró, láti mú kí ó wà níṣọ̀kan, àti láti dáàbò bò ó. Ǹjẹ́ kí alàgbà kọ̀ọ̀kan pinnu láti máa bá a nìṣó ní fífi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn àgùntàn Jèhófà, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ẹ̀bùn, tàbí ìbùkún lòun jẹ́ fún àwọn arákùnrin òun. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa sì pinnu láti máa fi ìmọrírì hàn fún “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” nípa jíjẹ́ onígbọràn àti ẹni tí ń tẹrí ba fún wọn, àti nípa kíkà wọ́n sí nítorí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè àwọn èèyàn tó jẹ́ pé, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: ‘Ojúṣe wa ni láti ràn yín lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sin Ọlọ́run nìṣó’!
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tó fi bá a mu láti fi ìjọ wé ara?
◻ Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó?
◻ Èé ṣe tó fi yẹ ká má kàn jẹ́ onígbọràn nìkan, ṣùgbọ́n ká tún jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba pẹ̀lú, fún àwọn tí ń mú ipò iwájú?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a ka àwọn alàgbà sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa gbóríyìn fáwọn èèyàn fún àwọn ìsapá àtọkànwá tí wọ́n bá ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ onítara táwọn alàgbà ń fi lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n lè ran àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn àti àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sìn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwa mọrírì àwọn alàgbà wa tí ń ṣiṣẹ́ kára!