Ẹ̀mí Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní?
Gbogbo wa pátá la bí ìfẹ́ pàtàkì náà mọ̀ pé, ká jẹ́ ẹni tó bẹ́gbẹ́ mu. Kò sẹ́ni tó fẹ́ ká kórìíra òun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sẹ́ni tó fẹ́ ká ta òun nù. Nípa báyìí, onírúurú ọ̀nà ni àwọn ẹgbẹ́ wa fi ń nípa lórí wa.
ẸGBẸ́ ẹni túmọ̀ sí “ẹni tó jẹ́ ojúgbà ẹni; . . . ẹni táa jọ wà nínú ẹgbẹ́ kan náà láwùjọ, pàápàá jù lọ tó bá di tọjọ́ orí, ilé ẹ̀kọ́, tàbí ipò.” Nítorí náà, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ni agbára táwọn ojúgbà wa ń lò lórí wa, kí a bàa lè fara mọ́ ìrònú wọn tàbí ìwà wọn, yálà ó tọkàn wa wá o tàbí kò tọkàn wa wá. Lọ́pọ̀ ìgbà la sábà máa ń gbà pé kò sáǹfààní kankan nínú ṣíṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. Ṣùgbọ́n, bí a óò ṣe rí i, a lè mú kó ṣe wá láǹfààní.
Agbára Tó Ń Ní Lórí Tọmọdé-Tàgbà
Kì í ṣe àwọn èwe nìkan ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ń nípa lé lórí; tọmọdé-tàgbà ni ọ̀rọ̀ yìí kàn. Ipa tó ń ní lórí wa máa ń hàn nígbà táa bá bi ara wa ní àwọn ìbéèrè bí èyí: “Àwọn mìíràn ń ṣe é, kí ló dé témi náà ò fi ní ṣe é?” “Èé ṣe tí mo fi ní láti dá yàtọ̀ nígbà gbogbo?” “Kí làwọn yòókù yóò máa rò nípa mi tàbí kí ni wọn yóò máa sọ nípa mi?” “Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti láfẹ̀ẹ́sọ́nà, tí wọ́n sì ń ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n n kò tí ì ṣèkankan. Ṣé kì í ṣe pé ó ní nǹkan tó ń ṣe mí?”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí láti bẹ́gbẹ́ mu ń nípa lórí tọmọdé-tàgbà, àkókò ọ̀dọ́langba ló máa ń lágbára jù lọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé “àwọn ọ̀dọ́langba tó pọ̀ jù lọ ni wọléwọ̀de wọn pẹ̀lú àwọn ojúgbà wọn máa ń pọ̀ lápọ̀jù—ìyẹn ni, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ wọn. Àwọn ọ̀dọ́langba wọ̀nyí máa ń fẹ́ rí ojúure àwọn ojúgbà wọn, dípò ti àwọn òbí wọn, wọ́n sì lè yí ìwà wọn padà láti lè rí ojúure yẹn.” Ó fi kún un pé, àwọn ọ̀dọ́langba “gbà pé àwọn ń dàgbà bó ṣe yẹ kó rí gan-an bí àwọn ojúgbà wọn bá tẹ́wọ́ gbà wọ́n tàbí tí wọ́n bá fẹ́ràn wọn.” Nítorí èyí wọ́n “máa ń fara wọn fún gbogbo ohun tó bá lè nípa lórí òkìkí wọn, irú bí aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, agbára àtidi aṣáájú, àti àṣeyọrí nínú ìfẹ́nisọ́nà.”
Àwọn tọkọtaya lè rí i pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe—ìyẹn ohun tó wọ́pọ̀ láwùjọ wọn, láàárín àwọn ẹgbẹ́ wọn tàbí láàárín ẹ̀yà wọn—ń nípa lórí irú ilé tí wọ́n rà tàbí tí wọ́n fẹ́ háyà, irú ọkọ̀ tí wọ́n fẹ́ rà, bóyá wọ́n fẹ́ bímọ tàbí wọn kò fẹ́ bí, àti àwọn ọ̀ràn mìíràn. Àwọn ìdílé kan tiẹ̀ máa ń tọrùn bọ gbèsè kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ ní nǹkan táwọn aládùúgbò wọn ní, wọ́n fẹ́ bẹ́gbẹ́ mu. Bẹ́ẹ̀ ni, góńgó wa, ìrònú wa, àti ìpinnu wa lọ́pọ̀ ìgbà máa ń fi agbára tí kò ṣeé tètè fura sí, tí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa ń ní lórí ẹni hàn. Bó ṣe wá lágbára tó yìí, ǹjẹ́ a lè jàǹfààní nínú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ká jẹ́ kó ràn wá lọ́wọ́ nípa ohun táa fẹ́ ṣe? Dájúdájú, a lè ṣe bẹ́ẹ̀!
Lílo Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Lọ́nà Tó Gbámúṣé
Àwọn dókítà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa ètò ìlera dunjú mọyì jíjẹ́ kí àwọn èèyàn tó lẹ́mìí rere àti àwọn tó lè nípa rere lórí ẹni wà nítòsí àwọn tí ń gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ wọn. Irú ipò bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ara irú aláìsàn bẹ́ẹ̀ tètè yá. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n gé lápá tàbí lẹ́sẹ̀ tètè máa ń dára yá, tí wọ́n á sì ṣara gírí, bí wọ́n bá rí àpẹẹrẹ rere àti ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn mìíràn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí. Ó wá ṣe kedere pé, ríri ara ẹni bọ inú ipò tó gbámúṣé, irú bí wíwà láàárín àwọn tó lẹ́mìí nǹkan yóò dára, tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere láwùjọ, jẹ́ ọ̀nà kan láti lo ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lọ́nà tó gbámúṣé.
Ìlànà yìí tún rí bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, ìdí ni pé, kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè jẹ́ èyí tó nípa rere lórí ẹni ló mú kí Jèhófà pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ láti máa pàdé pọ̀ déédéé. Ọlọ́run rọ̀ wá láti “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24, 25) Irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye púpọ̀ nítorí ti ọ̀pọ̀ ohun tí ń nípa lórí ẹni nínú ayé lónìí, tó lè múni rẹ̀wẹ̀sì, tó sì lè pani lára. Nítorí àwọn nǹkan tí ń nípa lórí ẹni wọ̀nyí, àwọn Kristẹni ní láti “tiraka tokuntokun” láti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 13:24) Nípa báyìí, a nílò ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, a sì mọrírì rẹ̀. Ní àfikún sí i, àwọn kan lè ní láti fara da ‘àwọn ègún nínú ẹran ara’ bóyá àìsàn tàbí àbùkù ara. (2 Kọ́ríńtì 12:7) Àwọn mìíràn lè máa ṣaápọn láti borí ìwà búburú tàbí ìsoríkọ́, tàbí kó jẹ́ pé ó ṣòro fún wọn láti gbọ́ bùkátà ìgbésí ayé. Nítorí náà, ó jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa láti wà láyìíká àwọn ènìyàn tó sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ń gbádùn sísìn ín. Irú àwọn ẹlẹgbẹ́ wa bẹ́ẹ̀ yóò gbé wa ró, wọn yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ‘fi tòótọ́tòótọ́ fara dà á títí dé òpin.’—Mátíù 24:13.
Báa bá yan ẹgbẹ́ rere, a óò lè ṣàkóso ipa tí wọ́n lè ní lórí wa. Ní àfikún sí i, oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ àti ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ tí à ń rí gbà nínú àwọn ìpàdé Kristẹni ń fi kún ìṣírí tí àwọn ẹgbẹ́ wa ń fún wa.
Àmọ́ ṣá o, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti wà ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Ọkọ tàbí aya àwọn ẹlòmíràn lè má ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn mìíràn lè ní àwọn ọmọ tí wọn yóò múra fún, ohun ìrìnnà sì lè jẹ́ ìṣòro àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ronú nípa rẹ̀ ná: Bí o kò bá jẹ́ kí àwọn ìṣòro wọ̀nyí dá ọ dúró, nígbà náà, àpẹẹrẹ tìrẹ lè fún àwọn mìíràn níṣìírí, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ń dojú kọ irú ipò kan náà. Lédè mìíràn, kì í ṣe àpẹẹrẹ rere nìkan ni ìwọ àti àwọn mìíràn tí wọ́n dà bíi tìrẹ ń fi lélẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ tún ń ní ipa tó dára lórí àwọn ẹlòmíràn—ẹ sì ń ṣe ìyẹn láìjẹ́ pé ẹ fagbára mú wọn.
Àní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí òun fúnra rẹ̀ dojú kọ ọ̀pọ̀ ìnira àti ìṣòro, fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti fara wé àpẹẹrẹ rere tòun àti ti àwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú. Ó wí pé: “Ẹ di aláfarawé mi ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ará, kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí ó bá àpẹẹrẹ tí ẹ rí nínú wa mu.” (Fílípì 3:17; 4:9) Àwọn Kristẹni ìjímìjí ní Tẹsalóníkà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Ẹ sì di aláfarawé wa àti ti Olúwa, níwọ̀n bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ wá di àpẹẹrẹ fún gbogbo onígbàgbọ́ ní Makedóníà àti ní Ákáyà.” (1 Tẹsalóníkà 1:6, 7) Lọ́nà kan náà, ìwà àti àpẹẹrẹ rere wa lè nípa lórí àwọn tí à ń bá kẹ́gbẹ́.
Yẹra fún Jíjẹ́ Kí A Nípa Búburú Lórí Rẹ
Báa bá fẹ́ yẹra fún jíjẹ́ kí àwọn ojúgbà wa nípa búburú lórí wa, a gbọ́dọ̀ dènà ipa tí ‘àwọn tí ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara’ lè ní lórí wa. (Róòmù 8:4, 5; 1 Jòhánù 2:15-17) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jíjẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe mú wa ṣe ohun búburú yóò mú wa kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì mú kí a ṣá ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀ tì. Òwe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Ǹjẹ́ o lè rántí ẹnì kan tó rí láburú nítorí pé ó jẹ́ kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe nípa búburú lórí òun? Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan ti kó wọnú ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, ìṣekúṣe, tàbí jíjoògùnyó àti mímu àmupara nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí àwọn ẹgbẹ́ wọn ń ṣe.
Kódà láàárín ìjọ Kristẹni pàápàá, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè nípa búburú lórí wa, bó bá jẹ́ àwọn tó tútù nípa tẹ̀mí ni ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa. (1 Kọ́ríńtì 15:33; 2 Tẹsalóníkà 3:14) Lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ jíròrò nǹkan tẹ̀mí; wọ́n tiẹ̀ lè máa fi àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sírú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́. Bó bá jẹ́ irú àwọn ẹni wọ̀nyí ni ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè mú kí a dà bíi tiwọn, ká sì tó mọ̀, a lè rí i pé ìrònú wa àti ìwà wa ti jọ tiwọn gẹ́lẹ́. A tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà òdì nípa àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ ojúlówó, tí wọ́n ń gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—1 Tímótì 4:15.
Ẹ wo bó ti bọ́gbọ́n mu tó láti máa dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ohun tẹ̀mí! Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.” Ó “kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, . . . kì í ṣe àgàbàgebè.” (Jákọ́bù 3:17) Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn tí ohun tẹ̀mí jẹ lọ́kàn kì í sọ̀rọ̀ lórí nǹkan mìíràn àyàfi nǹkan tẹ̀mí. Rárá o, ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀! Ìwọ náà ronú lórí onírúurú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ fífani mọ́ra tí à ń gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower bí ìwé ìròyìn Jí! Àwọn kókó ọ̀rọ̀ gbígbámúṣé táa lè jíròrò pọ̀ lọ jàra, táa bá sì nífẹ̀ẹ́ nínú kókó ẹ̀kọ́ tó gbòòrò bẹ́ẹ̀, a ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè àti iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà.
Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tó mọ nípa bọ́ọ̀lù tẹníìsì dáadáa ti lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n gbà bó bá ń bá ẹlòmíràn tóun náà ò kẹ̀rẹ̀ nínú ayò náà gbá tẹníìsì, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa ṣe ń mú ọpọlọ wa jí pépé sí i, tí wọ́n ń mú ìmọ̀lára wa sunwọ̀n sí i, tí wọ́n sì ń mú ipò tẹ̀mí wa dára sí i. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ burúkú lè tì wá lọ sínú ìwà àgàbàgebè nípa rírọ̀ wá láti gbé ìgbésí ayé méjì. Ó mà dára láti gbádùn ìgbésí ayé ẹlẹ́rìí-ọkàn tó mọ́, tó sì buyì kúnni o!
Àwọn Kan Tí Wọ́n Ti Jàǹfààní
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló rí i pé kíkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àti àwọn ohun tó ń béèrè fún ní ti ìwà rere àti tẹ̀mí kò fi bẹ́ẹ̀ nira. Ṣùgbọ́n, ohun tó lè nira ni fífi àwọn nǹkan wọ̀nyí sílò. Bí àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti fi hàn, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, èyí tó jẹ́ ohun tó dára lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà.
Ẹnì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún pẹ̀lú aya rẹ̀ sọ pé àpẹẹrẹ àwọn ẹgbẹ́ òun nípa lórí góńgó òun nínú ìgbésí ayé. Bó ti ń dàgbà, ó ní láti wọ̀jà pẹ̀lú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè súnni hùwà tí kò dáa. Ṣùgbọ́n àwọn tó fún un níṣìírí láti máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nínú wíwá sí ìpàdé àwọn Kristẹni ló yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Fífaramọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀nyí ràn án lọ́wọ́ láti máa dàgbà nípa tẹ̀mí.
Ẹlòmíràn tí òun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn témi àti aya mi ṣègbéyàwó, a ṣí lọ sí ìjọ kan níbi tí tọkọtaya kan tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àpẹẹrẹ wọn ràn wá lọ́wọ́ láti wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn náà, àwa pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ lórí mímú kí ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà dàgbà nínú ìjọ náà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ dara pọ̀ mọ́ wa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.”
Bíbá àwọn tí wọ́n ní góńgó ti ìṣàkóso Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ lè mú kí ṣíṣègbọràn sí Jèhófà rọrùn. Èyí tún jẹ́ àǹfààní mìíràn ti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lọ́nà tó dáa, lè mú wá. Ọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tí òun náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́, tó sì wá di alábòójútó arìnrìn àjò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ń sìn ní ọkàn nínú ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society nísinsìnyí. Ó kọ̀wé pé: “Díẹ̀ lára àwọn ohun tí mo fẹ́ràn láti máa rántí jù lọ tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọdé ni bí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe máa ń ṣèbẹ̀wò sí ilé wa. Ìgbà gbogbo la máa ń se oúnjẹ àlejò mọ́ èyí táa bá máa sè. Alábòójútó àyíká kan fún mi ní àpò òde ẹ̀rí nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Títí dòní gẹ̀gẹ̀ẹ̀gẹ̀ ni mò ń gbé àpò náà.”
Nígbà tó ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà ní ọ̀dọ́langba, Ẹlẹ́rìí náà fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tó wà nínú ìjọ ló fẹ́ kópa nínú ìgbòkègbodò ìjọ, tí àpẹẹrẹ wọn sì fún àwọn mìíràn níṣìírí láti fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.” Àwọn ojúgbà ọ̀dọ́mọkùnrin yìí, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rere, ràn án lọ́wọ́, bí èèhù, ó dàgbà di ọkùnrin Kristẹni, táa lè fi wé igi ràbàtà, tó dúró sán-ún. Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ máa ń pe àwọn tí wọ́n lè nípa rere, tó lè gbé àwọn ọmọ yín ró, wá sínú ilé yín?—Málákì 3:16.
Àmọ́ ṣá o, gbogbo wa kò lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún bíi tàwọn táa ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn tán yìí. Ṣùgbọ́n gbogbo wa ló lè kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, àti èrò inú wa.’ (Mátíù 22:37) Irú àwọn ẹgbẹ́ tí a ń bá rìn ń kó ipa pàtàkì nínú bí ìfẹ́ yẹn yóò ṣe dàgbà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ń nípa lórí ìrètí wa fún ìyè àìnípẹ̀kun.
Onísáàmù fún wa ní oògùn ajẹ́bíidán fún kíkẹ́sẹjárí nínú ìgbésí ayé, oògùn ọ̀hún rèé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì. Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:1-3.
Ìdánilójú àgbàyanu lèyí mà jẹ́ o! Báa tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, tí a sì ń ṣàṣìṣe, a óò kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé wa báa bá jẹ́ kí Jèhófà ṣamọ̀nà wa, báa bá sì lo àǹfààní àwọn ẹgbẹ́ tó lè nípa rere lórí wa ti Ọlọ́run ti fúnra rẹ̀ kó jọ—“ẹgbẹ́ àwọn ara [wa] nínú ayé.”—1 Pétérù 5:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn ẹgbẹ́ tó lè nípa rere lórí ẹni wà nínú ìjọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ẹ̀yin òbí, ẹ fún àwọn ọmọ yín níṣìírí láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tó lè gbé wọn ró