ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/15 ojú ìwé 10-13
  • Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí Gíríìkì—Ṣé Ó Ṣe Ẹ̀sìn Kristẹni Lóore?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí Gíríìkì—Ṣé Ó Ṣe Ẹ̀sìn Kristẹni Lóore?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ̀sìn Àwọn Júù Tó Di ti Gíríìkì”
  • “Àṣà Gíríìkì Táa Mú Wọnú Ẹ̀sìn Kristẹni”
  • “Ẹ̀sìn Kristẹni Táa Sọ Di ti Gíríìkì” àti “Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí ti Ẹ̀sìn Kristẹni”
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Ba Nǹkan Jẹ́
  • Òtítọ́ Pọ́ńbélé
  • Èrò Náà Wọnú Ẹ̀sìn Àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Ṣé Alágbàwí Òtítọ́ Bíbélì Ni Wọ́n?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Plato
    Jí!—2013
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/15 ojú ìwé 10-13

Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí Gíríìkì—Ṣé Ó Ṣe Ẹ̀sìn Kristẹni Lóore?

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn Kristẹni tako àwọn Gíríìkì abọ̀rìṣà àti àṣà àwọn ará Róòmù, ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí wọn ló ti gbà wọlé.”—The Encyclopedia Americana.

TÁA bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó nípa lórí ìrònú “Kristẹni”, ipò tí Augustine “Mímọ́” dì mú kò fa àríyànjiyàn rárá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica, ti sọ, “èrò inú” Augustine “ni ibi tí a ti jó ẹ̀sìn inú Májẹ̀mú Tuntun pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ Plato tó jẹ́ ti ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì; òun tún ni ọ̀nà tí a gbà tàtaré àbájáde àjópọ̀ yìí sínú àwọn ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti Roman Kátólíìkì ní sànmánì agbedeméjì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì ti ìgbà Ìmúsọjí Ọ̀làjú.”

Ká sòótọ́, ogún tí Augustine fi sílẹ̀ jẹ́ èyí tó wà pẹ́ títí. Nígbà tí Douglas T. Holden ń sọ nípa bí ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ti nípa lórí ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù tó, ó wí pé: “Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni ti wá dà pọ̀ mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ẹ̀sìn náà ti wá bí àwọn èèyàn tó jẹ́ pé táa bá dá ìrònú wọn sọ́nà mẹ́wàá, mẹ́sàn-án nínú rẹ̀ ló jẹ́ ìrònú àwọn Gíríìkì, nígbà tí apá kan tó kù jẹ́ ti Kristẹni.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà gbọ́ gidigidi pé irú ipá bẹ́ẹ̀ tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí ní fi kún ìdàgbàsókè ẹ̀sìn Kristẹni ní ìjímìjí, ó ṣàlékún ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ jẹ́ èyí táa lè tètè fi yíni lérò padà. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí lóòótọ́? Báwo ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí ẹ̀sìn Kristẹni, nígbà wo ló sì nípa lórí rẹ̀? Ká sọ̀rọ̀ síbi ọ̀rọ̀ wà, ṣé ó ṣe ẹ̀sìn Kristẹni lóore ni àbí ó bà á jẹ́?

Yóò túbọ̀ lani lóye táa bá lè tọpasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa títí di ọ̀rúndún karùn-ún ti Sànmánì Tiwa, nípasẹ̀ ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ipò mẹ́rin tó ṣàjèjì: (1)“Ẹ̀sìn Àwọn Júù Tó Di ti Gíríìkì,” (2) “Àṣà Àwọn Gíríìkì Tó Di ti Àwọn Kristẹni,” (3) “Ẹ̀sìn Kristẹni Táa Sọ Di ti Gíríìkì,” àti (4) “Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí ti Ẹ̀sìn Kristẹni.”

“Ẹ̀sìn Àwọn Júù Tó Di ti Gíríìkì”

Ká sòótọ́, èyí àkọ́kọ́ yìí, “Ẹ̀sìn Àwọn Júù Tó Di ti Gíríìkì,” takora rẹ̀. Ẹ̀sìn àwọn Hébérù ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, èyí tó jẹ́ pé, Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà fúnra rẹ̀, ló dá a sílẹ̀, ni a kò pète pé kí a fi àwọn àbá èrò orí ẹ̀sìn èké bà jẹ́. (Diutarónómì 12:32; Òwe 30:5, 6) Àmọ́ ṣá o, láti àárọ̀ ọjọ́ ni ìwà ìbàjẹ́ àwọn ẹ̀sìn èké àti ìrònú wọn tó yí ìjọsìn mímọ́ ká ti fẹ́ kéèràn ràn án—lára àwọn ohun tó fẹ́ kéèràn ràn án ni ìwà àti ìrònú àwọn ará Íjíbítì, ti àwọn ọmọ Kénáánì, àti tàwọn ará Bábílónì. Ó bani nínú jẹ́ pé, Ísírẹ́lì jẹ́ kí a ba ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀ jẹ́ gidigidi.—Àwọn Onídàájọ́ 2:11-13.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nígbà tí Palẹ́sìnì ìgbàanì di apá kan Ilẹ̀ Ọba Gíríìkì, lábẹ́ ìṣàkóso Alẹkisáńdà Ńlá, ní ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, ìwà ìbàjẹ́ yìí ti wá gogò, ó sì wá fi ogún kan tí yóò wà pẹ́ títí, tí yóò sì túbọ̀ máa nípa lórí ẹni sílẹ̀ fáwọn ìran tí ń bọ̀. Alẹkisáńdà kó àwọn Júù sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Àjọṣe tó wà láàárín àwọn Júù àti ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́gun wọn yìí nípa tó jinlẹ̀ lórí ìrònú àwọn Júù nípa ẹ̀sìn. Ìrònú àwọn Gíríìkì di èyí tó wọnú ẹ̀kọ́ àwọn Júù. Òkìkí tilẹ̀ kàn pé Àlùfáà Àgbà, Jason, dá ilé ẹ̀kọ́ àwọn Gíríìkì kan sílẹ̀ ni Jerúsálẹ́mù lọ́dún 175 ṣááju Sànmánì Tiwa láti lè gbé ẹ̀kọ́ Homer lárugẹ.

Óhun tí a rí ni pé, ará Samáríà kan, tó kọ̀wé ní apá kejì ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, gbìyànjú láti gbé ìtàn Bíbélì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn táa ti sọ di tàwọn Gíríìkì. Ìwé àwọn Júù, tí kì í ṣe apá kan Ìwé Mímọ́, irú bí Judith àti Tobit, ní tòótọ́ tọ́ka sí àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè, tó jẹ́ ti àwọn Gíríìkì. A rí ọ̀pọ̀ àwọn Júù onímọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n gbìyànjú láti mú ìrònú àwọn Gíríìkì bá ẹ̀sìn àwọn Júù àti Bíbélì dọ́gba.

Ẹni táa bu ọlá yìí fún gan-an ni Philo, Júù kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Ó lo ẹ̀kọ́ Plato (ti ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa), ti Pythagoras, àti ti Sítọ́íkì láìgbàṣẹ. Ojú ìwòye Plato sì wá nípa lórí àwọn Júù gidigidi. Nígbà tí òǹṣèwé tó jẹ́ Júù náà, Max Dimont, ń ṣàkópọ̀ bí ìrònú Gíríìkì yìí ṣe yọ́ wọnú àṣà àwọn Júù, ó sọ pé: “Nítorí tí ìrònú Plato, ọgbọ́n Aristotle, àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Euclidia, ti kún orí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, tí wọ́n jẹ́ Júù, ni ojú tí wọ́n fi ń wo Torah ṣe yí padà pátápátá. . . . Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi ìrònú Gíríìkì kún ìṣípayá táa fún àwọn Júù.”

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ará Róòmù gba Ilẹ̀ Ọba Gíríìkì, bí wọ́n ṣe gba Jerúsálẹ́mù nìyẹn. Èyí ló ṣí àyè sílẹ̀ fún àwọn ìyípadà pàtàkì mìíràn. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa, ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àwọn afìrònúṣeṣẹ́-ṣe tí wọ́n sakun láti mú kí èrò Plato gbèrú, kí ó sì di ọ̀kan ṣoṣo, ti wá bọ́ sí ipò kan pàtó, èyí táa mọ̀ lápapọ̀ sí Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato. Àbá èrò orí yìí wá di èyí tó nípa jíjinlẹ̀ lórí ẹ̀sìn Kristẹni apẹ̀yìndà.

“Àṣà Gíríìkì Táa Mú Wọnú Ẹ̀sìn Kristẹni”

Ní ọ̀rúndún márùn-ún ti sànmánì tiwa yìí, àwọn ọ̀mọ̀ràn kan fẹ́ ká rí ìbátan tó wà láàárín ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì àti òtítọ́ Bíbélì tí a ti ṣí payá. Ìwé náà, A History of Christianity sọ pé: “Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀dá àti àgbáálá ayé fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú ká to bí Jésù ni àwọn Gíríìkì ti ń jà fitafita láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí ohun tí wọ́n ń ṣe ò yé wọn, tí wọ́n ń gbìyànjú láti fi òye ẹ̀kọ́ àwọn ará Áténì tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ ẹni tí Jésù í ṣe, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fòye àwọn abọ̀rìṣà lásán-làsàn tó wà lọ́pọlọ wọn gbé ẹ̀sìn Kristẹni kalẹ̀.”

Plotinus (205 sí 270 Sànmánì Tiwa), aṣáájú nínú irú àwọn ọ̀mọ̀ràn bẹ́ẹ̀, gbé ètò kan kalẹ̀ tó jẹ́ pé àbá èrò orí Plato gan-an ló gbé e kà. Plotinus ló dá èròǹgbà pé ọkàn yàtọ̀ sí ara sílẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n E. W. Hopkins sọ nípa Plotinus pé: “Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn rẹ̀ . . . kò fi bẹ́ẹ̀ nípa lórí àwọn tó ṣagbátẹrù ojú ìwòye ẹ̀sìn Kristẹni.”

“Ẹ̀sìn Kristẹni Táa Sọ Di ti Gíríìkì” àti “Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí ti Ẹ̀sìn Kristẹni”

Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, àwọn “Kristẹni” afìrònúṣeṣẹ́-ṣe wọ̀nyí sapá gidigidi láti lè bá àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n ní làákàyè sọ̀rọ̀. Láìka ìkìlọ̀ ṣíṣe kedere tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sí, èyí tó ti sọ pé kí wọ́n ṣọ́ra fún “àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́” àti “ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀’” irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ fi àṣà àwọn Gíríìkì tó wà lágbègbè wọn há àwọn ẹ̀kọ́ wọn. (1 Tímótì 6:20) Àpẹẹrẹ Philo dà bí èyí tó fi hàn pé ó lè ṣeé ṣe láti mú Bíbélì bá èrò Plato dọ́gba.—Fi wé 2 Pétérù 1:16.

Àmọ́ ṣá o, òtítọ́ Bíbélì gan-an ló fara gbá jù nínú ọ̀ràn yìí. Àwọn olùkọ́ “tí í ṣe Kristẹni” gbìyànjú láti fi hàn pé ẹ̀sìn Kristẹni wà ní ìbámu pẹ̀lú ojú ìwòye Gíríìkì òun Róòmù lórí ire ẹ̀dá ènìyàn. Clement ti Alẹkisáńdíríà àti Origen (ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa) sọ Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato di ìpìlẹ̀ ohun táa wá mọ̀ sí “Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí ti Ẹ̀sìn Kristẹni” lónìí. Ambrose (ọdún 339 sí 397 Sànmánì Tiwa), bíṣọ́ọ̀bù Milan, ti “tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Gíríìkì tó bóde mu jù lọ, ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni àti abọ̀rìṣà—pàápàá jù lọ àwọn ìwé . . . tó dá lórí ìbọ̀rìṣà Agbátẹrù Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato, Plotinus.” Ó gbìyànjú láti jẹ́ kí àwọn ará Róòmù tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé mọ̀ nípa apá ẹ̀sìn Kristẹni tó ní í ṣe pẹ̀lú àṣà àwọn Gíríìkì. Àpẹẹrẹ yìí náà ni Augustine tẹ̀ lé.

Ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, Díónísíù Onídàájọ́ ní ilé ẹjọ́ Áréópágù (tí wọ́n tún ń pè ní ayédèrú Díónísíù), tó ṣée ṣe kó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé, ará Síríà, gbìyànjú láti pa Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn “Kristẹni.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan ti sọ, “lọ́nà tó ṣe pàtó, àwọn ìwé rẹ̀ gbé Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato kalẹ̀ nínú alagbalúgbú ẹ̀kọ́ Kristẹni tó wà ní sànmánì agbedeméjì àti ipò tẹ̀mí tó wà nígbà náà . . . èyí tó ti mú kí onírúurú apá ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni àti ọ̀nà ìjọsìn rẹ̀ jẹ yọ, títí di àkókò tí a wà yìí.” Ẹ ò ri pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ò ka ìkìlọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sí rárá, nígbà tó wí pé kí wọ́n ṣọ́ra fún “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn”!—Kólósè 2:8.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Ba Nǹkan Jẹ́

A ti ṣàkíyèsí pé “àwọn Kristẹni tó tẹ́wọ́ gba Ẹ̀kọ́ Plato fọwọ́ pàtàkì mú ríríran, wọ́n sì ka ìmọ̀ ọgbọ́n orí Plato sí ohun dídára jù lọ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lè ní òye Ìwé Mímọ́ àti láti gbèjà àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti àṣà ṣọ́ọ̀ṣì.”

Plato alára ti gbà pé àìleèkú ọkàn ń bẹ. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ èké tó lókìkí jù lọ tó yọ́ wọnú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn “Kristẹni” ni àìleèkú ọkàn. Títẹ́wọ́gba ẹ̀kọ́ yìí nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ mú kí ẹ̀sìn Kristẹni fa àwọn ènìyàn mọ́ra kò tọ̀nà rárá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò fi ẹ̀kọ́ Plato nípa ọkàn kọ́ni nígbà tó ń wàásù ní Áténì tó jẹ́ àárín gbùngbùn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wàásù nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni nípa àjíǹde, kódà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn Gíríìkì tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ṣòro fún láti tẹ́wọ́ gba ohun tí ó ń sọ.—Ìṣe 17:22-32.

Lọ́nà tó tako ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé ọkàn kì í ṣe ohun tí ènìyàn ní ṣùgbọ́n ohun tí ó jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Nígbà ikú, ọkàn kò sí láàyè mọ́. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Oníwàásù 9:5 sọ fún wa pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn.” A kò fi ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn kọ́ni nínú Bíbélì.

Ẹ̀kọ́ ìtànjẹ mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú Jésù kí ó tó wá sórí ilẹ̀ ayé ni èrò náà pé, ó bá Baba rẹ̀ dọ́gba. Ìwé náà The Church of the First Three Centuries ṣàlàyé pé: “Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan . . . pilẹ̀ láti orísun kan tó jìnnà pátápátá sí ẹ̀sìn àwọn Júù àti Ìwé Mímọ́ àwọn Kristẹni.” Kí ni orísun yẹn? Ẹ̀kọ́ náà “gbèrú, a sì mú un wọnú ẹ̀sìn Kristẹni, nípasẹ̀ àwọn Agbátẹrù Ẹ̀kọ́ Plato.”

Ní tòótọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ tí àwọn Baba Ṣọ́ọ̀ṣì túbọ̀ ń nípa lórí Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato, bẹ́ẹ̀ ni ọmọlẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato tó gbalẹ̀ kan ní ọ̀rúndún kẹta dà bí ẹní mú kí ohun tí kò bára mu dí èyí táa mú bára mu—ìyẹn ni mímú kí Ọlọ́run mẹ́ta dà bí Ọlọ́run kan ṣoṣo. Nípasẹ̀ èrò orí, wọ́n sọ pé ẹni mẹ́ta ṣì lè jẹ́ Ọlọ́run kan ṣoṣo, tí wọ́n a ṣì jẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ síbẹ̀!

Ṣùgbọ́n, òtítọ́ Bíbélì fi hàn kedere pé, Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run Olódùmarè, Jésù Kristi jẹ́ Ọmọ rẹ̀ tó dá, tí ó sì kéré sí I, ẹ̀mí mímọ́ sì jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Rẹ̀. (Diutarónómì 6:4; Aísáyà 45:5; Ìṣe 2:4; Kólósè 1:15; Ìṣípayá 3:14) Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bọlá fún Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo, ó sì da àwọn èèyàn lọ́kàn rú, ó kẹ̀yìn wọn sí Ọlọ́run tí wọn kò lè lóye.

Ohun mìíràn tí Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato nípa lé lórí nínú ìrònú àwọn Kristẹni ni ìrètí ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún táa gbé ka Ìwé Mímọ́. (Ìṣípayá 20: 4-6) A mọ Origen mọ bíbẹnu àtẹ́ lu àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún. Èé ṣe tó fi tako ẹ̀kọ́ nípa ìṣàkóso Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún, ẹ̀kọ́ tó jẹ́ pé ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia dáhùn pé: “Lójú ìwòye Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato tí ó gbé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kà . . . , [Origen] kò lè fara mọ́ àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún.”

Òtítọ́ Pọ́ńbélé

Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a mẹ́nu kàn lókè yìí tó nípa kankan lórí òtítọ́. Òtítọ́ yìí sì ni gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni látòkè délẹ̀ gẹ́gẹ́ báa ti rí i nínú Bíbélì. (2 Kọ́ríńtì 4:2; Títù 1:1, 14; 2 Jòhánù 1-4) Bíbélì nìkan ni orísun òtítọ́ yìí, kò tún sì ìwé mìíràn bẹ́ẹ̀.—Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16.

Ṣùgbọ́n, ọ̀tá Jèhófà, ọ̀tá òtítọ́, elénìní aráyé, tó tún jẹ́ ọ̀tá ìyè àìnípẹ̀kun—Sátánì Èṣù, “apànìyàn” àti “baba irọ́”—ti ló onírúurú ọ̀nà àrékérekè láti bu omi la òtítọ́. (Jòhánù 8:44; fi wé 2 Kọ́ríńtì 11:3.) Lára àwọn irin iṣẹ́ lílágbára tó ti lò ni ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà, onímọ̀ ọgbọ́n orí ti Gíríìkì—èyí tó fi ìrònú rẹ̀ gan-an hàn—ó sapá gidigidi láti rí i pé òun ṣàyípadà ohun tó wà nínú àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni àti ìpìlẹ̀ rẹ̀.

Dída ẹ̀kọ́ Kristẹni pọ̀ mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, táa lè fi wé dída lúúrú pọ̀ mọ́ ṣàpà, ti jẹ́ ọgbọ́n kan láti bomi la òtítọ́ Bíbélì, láti lè dín agbára rẹ̀ kù, kó má bàa lè fa àwọn ọlọ́kàntútù mọ́ra, àwọn olóòótọ́ ọkàn, àti àwọn tí ń wá òtítọ́ kiri, tí wọ́n sì ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (1 Kọ́ríńtì 3:1, 2, 19, 20) Ó tún fẹ́ láti sọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí kò ní kọ́núukọ́họ di aláìmọ́, nípa jíjẹ́ kó jọ pé kò sí ìyàtọ̀ kan tó ṣe kedere láàárín òtítọ́ àti èké.

Lónìí, lábẹ́ ìdarí Orí ìjọ, Jésù Kristi, a ti mú ẹ̀kọ́ Kristẹni tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Bákan náà, àwọn tí ń fi tòótọ́tòótọ́ wá òtítọ́ kiri lè tètè dá ìjọ Kristẹni tòótọ́ mọ̀ nípa àwọn èso rẹ̀. (Mátíù 7:16, 20) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe tán, wọ́n sì ń hára gàgà láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti rí ògidì omi òtítọ́ tí kò lábùlà, àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ogún ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí, èyí tí Jèhófà, Baba wa, gbé lé wa lọ́wọ́.—Jòhánù 4:14; 1 Tímótì 6:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Augustine

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀rọ̀ tó wà lédè Gíríìkì: Láti inú ìwé Ancient Greek Writers: Plato’s Phaedo, 1957, Ioannis N. Zacharopoulos, Áténì; Plato: Musei Capitolini, Roma

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́