Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Màríà Yan “Ìpín Rere”
NÍGBÀ tí Jésù wà láyé, òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rábì ká àwọn obìnrin Júù lọ́wọ́ kò. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Òfin. Ní gidi, èrò kan tí wọ́n ṣàyọlò rẹ̀ nínú Mishnah sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fún ọmọ rẹ̀ obìnrin ní ìmọ̀ Òfin, ó dà bí ẹni ń kọ́ ọ ní ìṣekúṣe.”—Sotah 3:4.
Ìyọrísí èyí ni pé, ọ̀pọ̀ obìnrin tó wà ní Jùdíà ní ọ̀rúndún kìíní ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀kọ́ ìwé. Ìwé atúmọ̀ èdè The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Kò sí ẹ̀rí pé wọ́n gba àwọn obìnrin láyè láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn olùkọ́ ńlá kankan ṣáájú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nípa gbígbà wọ́n láyè láti máa bá irú olùkọ́ bẹ́ẹ̀ rìnrìn àjò, tàbí kí wọ́n kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé.” Àwọn olórí ẹ̀sìn kan tiẹ̀ túbọ̀ sọ àwọn obìnrin di yẹpẹrẹ débi pé wọ́n gbé òfin kan kalẹ̀ tó sọ pé ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ bá obìnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba!
Jésù fi hàn pé irú àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu bẹ́ẹ̀ kò ní láárí rárá. Bó ṣe ń kọ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ náà ló ń kọ́ obìnrin, tọkùnrin tobìnrin ló sì wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Ní àkókò kan, Màtá àti Màríà gba Jésù lálejò sílé wọn. (Lúùkù 10:38) Arábìnrin Lásárù ni àwọn obìnrin méjèèjì wọ̀nyí, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà sì jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà pẹ̀lú. (Jòhánù 11:5) Ó ṣeé ṣe kí ìdílé yìí ti jẹ́ ìdílé tó gbajúmọ̀ gan-an tí a bá wo iye ènìyàn tó wá ń tu Màtá àti Màríà nínú nígbà tí Lásárù kú. Bó ti wù kó rí, kì í ṣe àwọn nìkan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé wọn nígbà tí Jésù dé wọn lálejò jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n fún, ó tún jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwa náà pẹ̀lú.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lẹ́bàá Ẹsẹ̀ Jésù
Láìsí àní-àní, Màtá àti Màríà ń hára gàgà láti se àsè ńlá fún Jésù, ó sì jọ pé wọ́n lówó tí wọn óò fi se àsè yìí. (Fi wé Jòhánù 12:1-3.) Àmọ́, bí àlejò wọ́n ṣe ń dé ni Màríà “jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Lúùkù 10:39) Kò mà sí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn kankan tó lè dí Jésù lọ́wọ́ kó máà kọ́ obìnrin tó ń fi tọkàntọkàn hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ yìí o! A lè fojú inú wo Màríà tó jókòó síwájú Jésù, tó fi ara rẹ̀ sípò ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ tó ń gbọ́ ohun tí Ọ̀gá rẹ̀ ń kọ́ ọ.—Fi wé Diutarónómì 33:3; Ìṣe 22:3.
Láìdàbí Màríà, Màtá ní tirẹ̀ “ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe.” Kó ṣáà lè pèsè oúnjẹ rẹpẹtẹ, lọwọ́ rẹ̀ ṣe dí fún àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí kò jẹ́ kó ráyè ṣe nǹkan mìíràn. Kò pẹ́ tínú fi bẹ̀rẹ̀ sí í bí Màtá, pé òun nìkan ní wọ́n fi sílẹ̀ láti bójú tó gbogbo iṣẹ́ nígbà tó sì jẹ́ pé ẹ̀bá ẹsẹ̀ Jésù ní arábìnrin rẹ̀ lọ jókòó sí! Bí Màtá ṣe já lu ọ̀rọ̀ tí Jésù ń bá Màríà sọ nìyẹn, bóyá kò tiẹ̀ mọ ìgbà tó sọ pé: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un, nígbà náà, kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.”—Lúùkù 10:40.
Lóòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú ohun tí Màtá béèrè. Ó ṣe tán, iṣẹ́ àṣekára ló jẹ́ láti pèsè oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, kò sì yẹ kí gbogbo rẹ̀ já lé ẹnì kan ṣoṣo léjìká. Síbẹ̀, Jésù rí àǹfààní láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kan tó wúlò nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn. Ó ni: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 10:41, 42.
Jésù kò sọ pé Màtá ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ ọ́n sí obìnrin tó jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run.a Kò sì sí àní-àní pé ohun tó sún un láti pe Jésù wá sílé rẹ̀ gan-an nìyẹn. Àmọ́, nínú ìbáwí onípẹ̀lẹ́tù tí Jésù fi tọ́ ọ sọ́nà yẹn, ó ń fi hàn pé bí Màtá ṣe ń ṣàníyàn lórí oúnjẹ ń mú kó pàdánù àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tó ní láti gba ìtọ́ni ojúkoojú látọ̀dọ̀ Ọmọ Ọlọ́run.
Lóòótọ́, ó ní láti jẹ́ pé àṣà ìgbà yẹn ni pé bí obìnrin kan bá ṣe dáńgájíá tó nínú ṣíṣe iṣẹ́ ilé ló ń fi bó ṣe ní láárí tó hàn. Ṣùgbọ́n Jésù fi hàn pé bíi ti ọkùnrin náà ni obìnrin ṣe lè jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Ọmọ Ọlọ́run kí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyè náà! (Jòhánù 4:7-15; Ìṣe 5:14) Nítorí ìdí yìí, ì bá ti sàn jù fún Màtá láti pèsè oríṣi oúnjẹ díẹ̀—tàbí ọ̀kan ṣoṣo pàápàá—tó bá jẹ́ pé ìyẹn ló máa fún un láǹfààní láti jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Ọ̀gá náà kó sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀.—Fi wé Mátíù 6:25.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Lónìí, àtọkùnrin àtobìnrin ló wà lára àwọn tó ń tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jésù láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ìfẹ́ ti sún àwọn kan—tó rí bíi Màtá—láti sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè bójú tó àìní àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Ó máa ń wù wọ́n láti ṣe nǹkan fúnni, wọ́n sì máa ń yára gbégbèésẹ̀, Jèhófà sì ti ṣèlérí láti san èrè fún òpò tí wọ́n ń fìfẹ́ ṣe. (Hébérù 6:10; 13:16) Àwọn mìíràn wà tó ṣeé ṣe kí wọ́n dà bíi Màríà. Ara wọ́n balẹ̀, wọ́n sì lè pọkàn pọ̀ sórí nǹkan tẹ̀mí. Ìháragàgà tí wọ́n ní láti ṣàṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.—Éfésù 3:17-19.
Oríṣi ènìyàn méjì táa sọ yìí ló ń kópa pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́, ní òpin gbogbo rẹ̀, gbogbo wa la ní láti ‘yan ìpín rere’ nípa fífi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò kìíní. Bí a bá ń wádìí dájú nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, a óò rí ojú rere Jèhófà, a óò sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà pẹ̀lú.—Fílípì 1:9-11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Pé Màtá jẹ́ obìnrin tẹ̀mí tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára ni a rí ẹ̀rí rẹ̀ kedere nínú ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Jésù lẹ́yìn ikú Lásárù, arákùnrin rẹ̀. Ní àkókò yìí, Màtá gan-an ló ká lára jù láti lọ pàdé Ọ̀gá rẹ̀.—Jòhánù 11:19-29.