ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 11/1 ojú ìwé 9-14
  • Báwo Lo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Ní Ìyánhànhàn” fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Onísáàmù Tó Nífẹ̀ẹ́ Òfin Ọlọ́run
  • Ọmọ Ọba Tí Kò Bẹ̀rù Àtidáyàtọ̀
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Gbé Jésù Ró
  • Àwọn Mìíràn Tí Wọ́n Jẹ́ Aláfarawé Kristi
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tànmọ́lẹ̀ Sí Òpópónà Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • ‘Ó Ń Bá A Nìṣó Ní Fífà Mọ́ Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bíbélì Kíkà—Ó Lérè, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 11/1 ojú ìwé 9-14

Báwo Lo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó?

“Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—SÁÀMÙ 119:97.

1. Kí ni ọ̀nà kan tí àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ń gbà fi ìfẹ́ wọn hàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin lóbìnrin ló ní ẹ̀dà Bíbélì tiwọn. Àmọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín ká ní Bíbélì àti ká nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹnì kan lè fi gbogbo ẹnu sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bá jẹ́ pé agbára káká ló fi ń kà á? Rárá o! Nǹkan ti wá yàtọ̀ ṣá, àwọn kan tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ka Bíbélì sí dan-indan-in tẹ́lẹ̀ ti wá ń fojoojúmọ́ kà á báyìí. Wọ́n ti kọ́ báa ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti pé bíi ti onísáàmù láwọn náà ṣe wá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ìdàníyàn wọn báyìí “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 119:97.

2. Báwo ni ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú lábẹ́ ipò líle koko?

2 Ẹnì kan tó kọ́ báa ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Nasho Dori. Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ni òun àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ fi ìfaradà sin Jèhófà ní Albania tó jẹ́ ìlú rẹ̀. Ìgbà tó pọ̀ jù láwọn àkókò wọ̀nyẹn ni ìjọba fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí kò sì fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ Arákùnrin Dori kò yingin. Lọ́nà wo? Ó sọ pé: “Góńgó mi ni pé kí ń ka Bíbélì fún ó kéré tán wákàtí kan lójúmọ́, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún nǹkan bí ọgọ́ta ọdún kó tó di pé ń kò ríran kàwé mọ́.” Kò tíì pẹ́ báyìí tí odindi Bíbélì ṣẹ̀ṣẹ̀ wà ní èdè Albanian, àmọ́, Arákùnrin Dori ti kọ́ èdè Gíríìkì nígbà tó wà lọ́mọdé, Bíbélì tí wọ́n fi èdè yẹn kọ ló sì ń kà. Bíbélì kíkà déédéé ló mú Arákùnrin Dori dúró tó fi lè la onírúurú àdánwò já, ó sì lè mú àwa náà dúró pẹ̀lú.

“Ẹ Ní Ìyánhànhàn” fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

3. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni ní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

3 “Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà.” (1 Pétérù 2:2) Bí ọmọ ọwọ́ kan ṣe ń yán hànhàn fún wàrà ìyá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Kristẹni tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn ń rí ìdùnnú kíkọyọyọ nínú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? Tí kì í báa ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀, má sọ̀rètí nù. Ìwọ náà lè kọ́ báa ṣe ń yán hànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

4. Kí ni sísọ Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ dàṣà ń béèrè?

4 Ọ̀nà tí o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ rèé, kọ́kọ́ kọ́ ara rẹ láti sọ Bíbélì kíkà déédéé dàṣà, tó bá ṣeé ṣe, máa kà á lójoojúmọ́. (Ìṣe 17:11) Ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti lò tó wákàtí kan lórí Bíbélì kíkà lójúmọ́ bíi ti Nasho Dori, àmọ́, o lè ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló tètè máa ń jí kí wọ́n lè ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì kan. Ǹjẹ́ ọ̀nà míì tún lè dára ju ìyẹn lọ láti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kan? Àwọn mìíràn yàn láti máa ka Bíbélì kí wọ́n tó sùn láti fi mú gbogbo ìgbòkègbodò ọjọ́ náà wá sópin. Síbẹ̀ àwọn mìíràn máa ń ka Bíbélì láwọn àkókò mìíràn tó bá wọ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì níbẹ̀ ni pé kóo máa ka Bíbélì déédéé. Lẹ́yìn náà, lo àkókò díẹ̀ láti ṣàṣàrò lórí ohun tóo kà. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn kan tó ti jàǹfààní nínú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣe àṣàrò lórí rẹ̀.

Onísáàmù Tó Nífẹ̀ẹ́ Òfin Ọlọ́run

5, 6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ orúkọ rẹ̀, kí la lè mọ̀ nípa ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà nípa kíka ohun tó kọ àti ṣíṣàṣàrò lé e lórí?

5 Ó dájú pé ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ta ló tiẹ̀ kọ sáàmù yẹn? Bíbélì kò sọ ẹni tó kọ ọ́ fún wa. Àmọ́, láti inú àyíká ọ̀rọ̀ náà, a mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa rẹ̀, a sì wá mọ̀ pé nǹkan ò rọrùn fún onítọ̀hún. Àwọn kan lára àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tó yẹ kí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ni kò ka ìfẹ́ tó ní fún àwọn ìlànà Bíbélì sí. Síbẹ̀síbẹ̀, onísáàmù náà kò jẹ́ kí ìṣarasíhùwà wọn dí òun lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́. (Sáàmù 119:23) Bí o bá ń bá ẹnì kan tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Bíbélì gbé tàbí tí ẹ bá jọ ń ṣiṣẹ́, o lè rí i bí ipò onísáàmù náà ṣe bá tìrẹ mu.

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onísáàmù náà jẹ́ ẹni tí ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ kò jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ rárá. Ó sọ gbangba gbàǹgbà pé aláìpé lòun. (Sáàmù 119:5, 6, 67) Àmọ́, kò jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ darí òun. Ó béèrè pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” Ó sì fèsì pé: “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.” (Sáàmù 119:9) Lẹ́yìn náà, nígbà tí onísáàmù náà ń sọ nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ agbára tó lè súnni hùwà rere tó, ó fi kún un pé: “Inú ọkàn-àyà mi ni mo fi àsọjáde rẹ ṣúra sí, kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.” (Sáàmù 119:11) Agbára tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún dídẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run yìí mà pọ̀ o!

7. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ gan-an ló yẹ kí Bíbélì kíkà jẹ lọ́kàn jù?

7 Ì bá dára tí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni bá lè gbé ọ̀rọ̀ onísáàmù náà yẹ̀ wò. Ohun tí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ń dojú kọ lónìí kọjá sísọ. Ohun tí Èṣù ń fẹ́ gan-an ni pé kó lè ba àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí tí ń jọ́sìn Jèhófà jẹ́. Ohun tí Sátánì ń lépa ni pé kó lè tan àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni jẹ, kí wọ́n lè ṣubú sínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ẹran ara, kí wọ́n sì rú àwọn Òfin Ọlọ́run. Èrò inú Èṣù ni àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ sinimá àti tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń gbé yọ. Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tí a ń wò nínú irú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ àwọn èèyàn tó jojú ní gbèsè, tó sì fani mọ́ra; gbogbo ìṣekúṣe wọn la máa ń gbé yọ bí ohun tó dára. Kí ni wọ́n fi ń kọ́ni? Òun ni pe, ‘kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn tí kò gbéra wọn níyàwó máa ní ìbálòpọ̀, tí wọ́n bá ṣáà ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn.’ Ó bani nínú jẹ́ pé ọdọọdún ni irú ìrònú bẹ́ẹ̀ ń fa ìṣubú fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Kristẹni. Ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn kan ti rì. Lóòótọ́, wàhálà náà pọ̀! Àmọ́, ṣé wàhálà náà wá le débi pé kò lè ṣeé ṣe fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ láti borí rẹ̀ ni? Rárá o! Jèhófà ti pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ láti ṣẹ́pá èrò burúkú. Wọ́n lè dènà ohun ìjà èyíkéyìí tí Èṣù bá hùmọ̀ nípa ‘ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa fi àsọjáde Ọlọ́run ṣúra sínú ọkàn-àyà wọn.’ Báwo ni àkókò tí o fi ń ka Bíbélì déédéé tí o sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀ ṣe pọ̀ tó?

8. Báwo ni àwọn àpẹẹrẹ táa tò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìpínrọ̀ yìí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì tóo ní fún Òfin Mósè dàgbà?

8 Ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà náà polongo pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (Sáàmù 119:97) Òfin wo? Ó ń tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà, títí kan Òfin Mósè. Táwọn kan bá kọ́kọ́ gbọ́ ọ, wọ́n lè ka àkójọ Òfin náà sí ohun tí kò bóde mu, kó sì máa yà wọ́n lẹ́nu bí ẹnì kan ṣe lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, báa ṣe ń ṣàṣàrò lórí onírúurú apá tí Òfin Mósè pín sí, bí onísáàmú náà ti ṣe, a lè wá mọrírì ọgbọ́n tó wà nínú Òfin yẹn. Yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ apá tó jẹ mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Òfin náà ní, ó tún ní ètò fún ìtọ́jú ìlera àti oúnjẹ jíjẹ nínú, èyí tó lè ṣàlékún ìmọ́tótó àti ìlera ara. (Léfítíkù 7:23, 24, 26; 11:2-8) Òfin náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níṣìírí láti jẹ́ aláìlábòsí nídìí òwò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú láti ṣàánú fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọ́n tó jẹ́ aláìní. (Ẹ́kísódù 22:26, 27; 23:6; Léfítíkù 19:35, 36; Diutarónómì 24:17-21) Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́. (Diutarónómì 16:19; 19:15) Bí ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà ṣe túbọ̀ ń nírìírí sí i, kò sí iyèméjì pé ó ti ní láti rí bí nǹkan ṣe wá ń dára fún àwọn tí wọ́n fi Òfin Ọlọ́run sílò, èyí sì wá mú kí ìfẹ́ tó ní fún un túbọ̀ lágbára sí i. Bákan náà lónìí, bí fífi tí àwọn Kristẹni ń fi ìlànà Bíbélì sílò ṣe ń mú kí wọn kẹ́sẹ járí, èyí ń jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìmọrírì tí wọ́n ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i.

Ọmọ Ọba Tí Kò Bẹ̀rù Àtidáyàtọ̀

9. Irú ẹ̀mí wo ni Hesekáyà Ọba ní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

9 Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù Kọkàndínlọ́gọ́fà bá ohun tí a mọ̀ nípa Hesekáyà nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ mu wẹ́kú. Àwọn kan tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé Hesekáyà ló kọ sáàmù náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ò dájú, a ṣáà mọ̀ pé Hesekáyà ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀nà tó gbà lo ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 119:97. Bíbélì sọ nípa Hesekáyà pé: “Ó sì ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà. Kò yà kúrò nínú títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.”—2 Àwọn Ọba 18:6.

10. Irú ìṣírí wo ni àpẹẹrẹ Hesekáyà jẹ́ fún àwọn Kristẹni tí kì í ṣe àwọn òbí tó ka òfin Ọlọ́run sí ló tọ́ wọn dàgbà?

10 Lójú gbogbo ẹ̀rí táa rí, wọn ò tọ́ Hesekáyà dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti ka òfin Ọlọ́run sí. Aláìgbàgbọ́ àti abọ̀rìṣà paraku ni baba rẹ̀, Áhásì Ọba, àní, ó kéré tán, ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀—arákùnrin Hesekáyà fúnra rẹ̀—rúbọ sí ọlọ́run èké nípa sísun ún láàyè! (2 Àwọn Ọba 16:3) Pẹ̀lú àpẹẹrẹ burúkú yìí, Hesekáyà “mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́” kò jẹ́ kí ìbọ̀rìṣà nípa lórí òun, èyí ṣeé ṣe fún un nítorí pé ó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.—2 Kíróníkà 29:2.

11. Bí Hesekáyà ṣe ń wo bí nǹkan ṣe ń lọ, báwo ni ọ̀ràn ṣe wá rí fún baba rẹ̀ aláìgbàgbọ́?

11 Bí Hesekáyà ṣe ń dàgbà, ó fi ojú ara rẹ̀ rí i bí baba rẹ̀ abọ̀rìṣà ṣe ń ṣe ètò Ìlú. Àwọn ọ̀tá ló yí Júdà ká. Résínì, ọba Síríà wà níbẹ̀, ẹni tó dara pọ̀ mọ́ Pékà Ọba Ísírẹ́lì láti sàga ti Jerúsálẹ́mù. (2 Àwọn Ọba 16:5, 6) Àwọn ará Édómù àti àwọn Filísínì náà wà níbẹ̀, àwọn tí wọ́n kógun wọ Júdà, tí wọ́n tilẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ìlú ńláńlá bíi mélòó kan ní Júdà pàápàá. (2 Kíróníkà 28:16-19) Báwo ni Áhásì ṣe kojú ìṣòro wọ̀nyí? Kàkà tí ì bá fi bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun Síríà, ọba Ásíríà ni Áhásì lọ bẹ̀ lọ́wẹ̀, tó ń fún un ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wúrà àti fàdákà, títí kan èyí tó wà nínú ìṣúra tẹ́ńpìlì pàápàá. Àmọ́, èyí kò mú àlàáfíà pípẹ́ títí wá fún Júdà.—2 Àwọn Ọba 16:6, 8.

12. Kí ni Hesekáyà ní láti ṣe kí ó má bàa ṣe irú àṣìṣe tí baba rẹ̀ ṣe?

12 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Áhásì kú, Hesekáyà sì di ọba lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. (2 Kíróníkà 29:1) Lóòótọ́ táa bá ní ká wò ó, ọmọdé ni, àmọ́, ìyẹn kò dí i lọ́wọ́ láti jẹ́ ọba tó kẹ́sẹ járí. Dípò tí ì bá fi fara wé baba rẹ̀ aláìṣòdodo, ọ̀pá ìdiwọ̀n Òfin Jèhófà ló dì mú. Èyí ní àkànṣe àṣẹ kan táa pa fún àwọn ọba nínú pé: “Nígbà tí [ọba] bá mú ìjókòó rẹ̀ lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ láti inú èyí tí ó wà ní àbójútó àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì. Kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí . . . mọ́.” (Diutarónómì 17:18, 19) Nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, Hesekáyà yóò kọ́ bí a ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà, yóò sì yẹra fún ṣíṣe irú àṣìṣe tí baba rẹ̀ tí kò ka òfin Ọlọ́run sí ṣe.

13. Báwo ló ṣe lè dá Kristẹni kan lójú pé nípa tẹ̀mí, gbogbo ohun tó bá ń ṣe ni yóò kẹ́sẹ járí?

13 Yàtọ̀ sí pé a rọ àwọn ọba Ísírẹ́lì láti máa ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà, a tún fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bẹ̀rù Ọlọ́run níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Sáàmù kìíní ṣàpèjúwe ènìyàn tí ó ní ayọ̀ tòótọ́ bí ẹni tí ‘inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, tó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.’ (Sáàmù 1:1, 2) Onísáàmù sọ nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:3) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì sọ nípa ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ó jẹ́ aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:8) Gbogbo wa la fẹ́ ní ayọ̀, ká sì kẹ́sẹ járí. Kíka Bíbélì déédéé lọ́nà tó nítumọ̀ lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Gbé Jésù Ró

14. Báwo ni Jésù ṣe fi ìfẹ́ hàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

14 Ní àkókò kan, àwọn òbí Jésù rí i tó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́ nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ wo bí àwọn ògbógi nínú Òfin Ọlọ́run wọ̀nyí ṣe “ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀”! (Lúùkù 2:46, 47) Ìgbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá nìyẹn o. Bí ọjọ́ orí rẹ̀ tilẹ̀ kéré, ó hàn gbangba pé ó nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jésù lo Ìwé Mímọ́ láti bá Èṣù wí, ní sísọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:3-10) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí Jésù fi lo Ìwé Mímọ́ láti wàásù fún àwọn tó ń gbé Násárétì tó jẹ́ ìlú rẹ̀.—Lúùkù 4:16-21.

15. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn?

15 Léraléra ni Jésù máa ń ṣàyọlò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ṣe “háà sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Abájọ tó jẹ́ pé—ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ti wá! Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, ẹni yìí jẹ́ olóòótọ́, kò sì sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀.”—Jòhánù 7:16, 18.

16. Báwo ni Jésù ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn tó?

16 Láìdà bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà, kò sí “àìṣòdodo kankan” nínú Jésù. Òun jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tó “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú.” (Fílípì 2:8; Hébérù 7:26) Síbẹ̀, bí Jésù ṣe jẹ́ ẹni pípé tó yẹn, ó kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run. Èyí gan-an ni olórí ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà tí Pétérù lo idà láti gba Ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ mú un, Jésù bá àpọ́sítélì náà wí, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí? Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?” (Mátíù 26:53, 54) Dájúdájú, ìmúṣẹ Ìwé Mímọ́ ṣe pàtàkì sí Jésù ju pé kí ó bọ́ lọ́wọ́ ikú oró, tó lè bu ẹ̀tẹ́ luni. Ẹ wo irú ìfẹ́ títayọ tó ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

Àwọn Mìíràn Tí Wọ́n Jẹ́ Aláfarawé Kristi

17. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?

17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Gẹ́gẹ́ bíi ti Ọ̀gá rẹ̀, Pọ́ọ̀lù mú ìfẹ́ fún Ìwé Mímọ́ dàgbà. Ó jẹ́wọ́ pé: “Ní ti ẹni tí mo jẹ́ ní inú, mo nífẹ̀ẹ́ Òfin Ọlọ́run gan-an.” (Róòmù 7:22, The Jerusalem Bible) Léraléra ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàyọlò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 13:32-41; 17:2, 3; 28:23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fún Tímótì, tó jẹ́ òjíṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, olùfẹ́ ọ̀wọ́n nítọ̀ọ́ni ìkẹyìn, ó tẹnu mọ́ ipa pàtàkì tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kó nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ gbogbo “ènìyàn Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:15-17.

18. Sọ àpẹẹrẹ ẹnì kan tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóde oní?

18 Ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní làwọn náà ti fara wé ìfẹ́ tí Jésù ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ọ̀dọ́mọkùnrin kan rí Bíbélì kan gbà látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ṣàpèjúwe ipa tí ẹ̀bùn tó níye lórí gan-an yìí ní lórí òun pé: “Mo pinnu pé ojoojúmọ́ ayé ni n ó máa ka apá kan nínú Bíbélì náà.” Frederick Franz ni ọ̀dọ́mọkùnrin yẹn, ìfẹ́ tó sì ní fún Bíbélì sún un láti gbádùn ìgbésí ayé gígùn, tó sì kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìgbà gbogbo là ń rántí rẹ̀ nítorí ẹ̀bùn tó ní láti lè ka orí èyíkéyìí nínú Bíbélì, láìṣí Bíbélì.

19. Báwo làwọn kan ṣe ṣètò Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run?

19 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú kíka Bíbélì déédéé. Ọ̀pọ̀ orí Bíbélì ni wọ́n máa ń kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń múra ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé Kristẹni wọn sílẹ̀, ìyẹn ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Tí wọ́n bá tún dé ìpàdé, ẹnì kan yóò jíròrò àwọn kókó tó wà nínú apá Bíbélì tí a yàn fún wọn láti kà. Ó rọrùn fún àwọn Ẹlẹ́rìí kan láti pín apá tí a yàn fún kíkà ní ọ̀sẹ̀ kan sí ọ̀nà kéékèèké méje kí wọ́n sì máa ka apá kọ̀ọ̀kan lójúmọ́. Bí wọ́n ṣe ń kà á, ni wọ́n ń ronú jinlẹ̀ lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tó bá ṣeé ṣe, wọ́n máa ń lo àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì láti ṣèwádìí síwájú sí i.

20. Kí ló pọndandan láti ṣe ká lè wá àkókò fún kíka Bíbélì déédéé?

20 O lè ní láti ‘ra àkókò padà’ lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò mìíràn kí o lè máa ka Bíbélì déédéé. (Éfésù 5:16) Bó ti wù kó rí, àǹfààní tó wà níbẹ̀ yóò pọ̀ ju èyí tó wà nínú ohunkóhun tóo lè fi rúbọ. Bóo ṣe ń mú àṣà Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí o ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i. Láìpẹ́, yóò sún ọ láti sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:97) Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò mú àǹfààní ńlá wá nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú, bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣe fi hàn.

Ǹjẹ́ O Rántí?

◻ Báwo ni ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà ṣe fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

◻ Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àwọn àpẹẹrẹ Jésù àti ti Pọ́ọ̀lù?

◻ Báwo làwa fúnra wa ṣe lè mú kí ìfẹ́ táa ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ ní láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ṣé ìwọ náà ń kà á?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Kódà nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, ó ní ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́