Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Olóore Sí Mi
GẸ́GẸ́ BÍ JOHN ANDRONIKOS TI SỌ Ọ́
Ọdún 1956 mà ni o. Ọjọ́ kẹsàn-án tí mo ṣègbéyàwó, ni mo bára mi ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Komotiní, ní àríwá ilẹ̀ Gíríìsì. Èrò mi ni pé wọ́n máa fagi lé ẹ̀wọ̀n oṣù méjìlá tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ti rán mi látàrí pé mò ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ ìpinnu ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà—pé kí n lọ sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà—fọ́ ìrètí mi yángá, ìyẹn ló jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìjẹ́jọ́ mi ní kóòtù. Àmọ́ ṣá o, jálẹ̀ gbogbo rẹ̀, Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run olóore sí mi.
NÍGBÀ tí wọ́n bí mi ní October 1, 1931, ìlú Kaválla làwọn ìdílé mi ń gbé nígbà yẹn, ibẹ̀ ni Neapólísì ti Makedóníà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ̀ wò nígbà ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì. Ọmọ ọdún márùn-ún ni mí nígbà tí màmá mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bó ti lẹ̀ jẹ́ pé màmá mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun gbin ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù rẹ̀ sí mi lọ́kàn. Baba mi ní tiẹ̀, ẹ̀mí ohun-táa-bá-láyé-rèé ti wọ̀ ọ́ lọ́kàn jù, ìdí nìyẹn tó ṣáà fi ranrí mọ́ ẹ̀sìn àtọwọ́dọ́wọ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì. Kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì rárá, ńṣe ló máa ń ta ko màmá mi ṣáá, ọ̀pọ̀ ìgbà ló tiẹ̀ máa ń nà án.
Nípa bẹ́ẹ̀, mo dàgbà sínú ilé ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, níbi tí Baba ti máa ń lu Màmá, tó ti ń fìyà pá a lórí, àní ó tilẹ̀ pa wá tì pátápátá. Láti kékeré mi ni Màmá ti máa ń mú èmi àtàbúrò mi obìnrin lọ sípàdé Kristẹni. Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ń kún ọkàn àwọn ọ̀dọ̀ àti ẹ̀mí jẹ́-n-ṣe-tèmi fà mí kúrò nínú ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀síbẹ̀, mámà mi tí kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú òtítọ́ ṣe gudugudu méje yààyà mẹ́fà, ó máa ń sunkún ṣáá ni kó ṣáà lè ràn mí lọ́wọ́.
Nítorí àìlówó lọ́wọ́ àti ìgbésí ayé burúkú tí mò ń gbé, àìsàn dá mi wólẹ̀ gan-an débi pé ó lé lóṣù mẹ́ta tí mo fi wà lórí bẹ́ẹ̀dì. Ìgbà yẹn ní arákùnrin kan tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ẹni tó ran màmá mi lọ́wọ́ láti rí òtítọ́, wá rí ìfẹ́ àtọkànwá tí mo ní sí Ọlọ́run. Ó rí i pé òun lè ràn mí lọ́wọ́ láti padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Àwọn kan sọ fún un pé: “Ó fẹ́ ran John lọ́wọ́ àbí, o kàn ń fàkókò rẹ̀ ṣòfò ni; o jẹ́ fi sílẹ̀ sí tiẹ̀, kò lè gbọ́ mọ́.” Àmọ́, bí arákùnrin yìí ṣe ní sùúrù tó sì lo ìfaradà láti ràn mí lọ́wọ́ so èso rere. Nígbà tó di August 15, 1952, ìyẹn nígbà tí mo pé ẹni ọdún mọ́kànlélógún, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn sí Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Ẹni Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Gbéyàwó, Táa Tún Sọ Sẹ́wọ̀n
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, èmi àti Martha mọ́ra, arábìnrin yìí jẹ́ ẹni tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn gidigidi, ó si láwọn ànímọ̀ tó dára gan-an, kò sì pẹ́ táa fi gbà láti fẹ́ra wa. Lọ́jọ́ kan, ẹnu yà mí nígbà tí Martha sọ fún mi pé: “Lónìí, mo ṣètò láti wàásù láti ilé dé ilé. Ṣé wàá bá mi lọ?” Títí di ìgbà tí mò ń wí yìí, n kò tíì lọ́wọ́ nínú irú iṣẹ́ yìí, apá tó pọ̀ jù lọ nínú ìwàásù mi ni jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Nígbà yẹn, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Gíríìsì, a sì ní láti máa ṣiṣẹ́ ìwàásù wa lábẹ́lẹ̀. Àwọn táwọn ọlọ́pàá kó pọ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ ló jẹ́jọ́ ní kóòtù, tó sì wá yọrí sí fífẹ̀wọ̀n jura. Síbẹ̀, n kò lè sọ pé rárá fún àfẹ́sọ́nà mi!
Ọdún 1956 ni Martha di ìyàwó mi. Ọjọ́ kẹsàn-án lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni wọ́n rán mi lẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà ní ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́run yẹn ní Komotiní. Èyí mú mi rántí ìbéèrè kan tí mo béèrè lọ́wọ́ Kristẹni arábìnrin tó jẹ́ ọ̀rẹ́ màmá mi pé: “Báwo ni mo ṣe lè fi hàn lóòótọ́ pé ojúlówó Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí? N kò tíì láǹfààní láti fi ìgbàgbọ́ mi hàn.” Nígbà tí arábìnrin yìí wá wò mí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó rán mi létí ìbéèrè yẹn, ó si wí pé: “Wàyí o, o lè jẹ́ kí Jèhófà mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó. Ẹnu iṣẹ́ tó yàn ọ́ sí lo wà yìí.”
Nígbà tí mo gbọ́ pé agbẹjọ́rò mi fẹ́ fowó gba béèlì mi, mo sọ fún un pé kó jẹ́ kí n kúkú ṣẹ̀wọ̀n náà tán. Nígbà tó di oṣù mẹ́fà gééré tí mo ti wà lẹ́wọ̀n, méjì nínú àwọn táa jọ wà lẹ́wọ̀n ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́, áà, inú mi mà dùn o! Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, mo jẹ́jọ́ ní kóòtù lọ́pọ̀ ìgbà nítorí ìhìn rere.
Yíyàn Tí A Kò Kábàámọ̀ Rẹ̀
Lọ́dún 1959, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti dá mi sílẹ̀, mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ, tàbí alábòójútó olùṣalága, wọ́n sì ní kí ń wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ibi táa ti ń dá àwọn alàgbà ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, àkókò kan náà ni mo rí iṣẹ́ gidi kan ní ilé ìwòsàn gbogbo gbòò, iṣẹ́ kan tí yóò máa mú owó tó tóó ná wọlé fún èmi àti ìdílé mi. Èwo ni kí n ṣe o? Mo ti ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta nílé ìwòsàn náà gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ onígbà díẹ̀, iṣẹ́ mi sì tẹ́ ọ̀gá àgbà ibẹ̀ lọ́rùn, ṣùgbọ́n nígbà tí ìkésíni láti wá sílé ẹ̀kọ́ yẹn dé, kò tiẹ̀ gbà kí ń gba ìsinmi tí wọn kò ti ní sanwó fún mi lẹ́nu iṣẹ́ láti lè rí àyè lọ. Lẹ́yìn tí mo ti kúnlẹ̀ àdúrà ti ìṣòro yìí, mo pinnu láti fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́, mo sì kọ iṣẹ́ tí wọ́n fún mi, mo ní mi ò ṣe.—Mátíù 6:33.
Àkókò yẹn náà ni àwọn alábòójútó àgbègbè àti alábòójútó àyíká wá bẹ ìjọ wa wò. A ní láti ṣèpàdé wa nínú ilé àdáni nítorí àtakò burúkú táwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì àti àwọn aláṣẹ ń ṣe. Lẹ́yìn tí ìpàdé kan parí, alábòójútó àgbègbè tọ̀ mí wá, ó sì béèrè bóyá mo ti ronú láti gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rí. Èrò rẹ̀ yìí gún ọkàn mi ní kẹ́ṣẹ́ nítorí ohun tí mo ti ń lálàá rẹ̀ nígbà tí mo ti ṣèrìbọmi nìyí. Mo fèsì pé: “Ó wù mí gan-an.” Àmọ́, mo ti gbaṣẹ́ mìíràn báyìí, mó ti lọ́mọbìnrin kan tí mo gbọ́dọ̀ tọ́ dàgbà. Arákùnrin náà sọ fún mi pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, òun yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lé góńgó rẹ bá.” Nípa báyìí, láìjẹ́ pé a pa ẹrù iṣẹ́ ìdílé wa tì, ó ṣeé ṣe fún èmi àti aya mi láti tún ipò wa ṣe, nígbà tó sì di December 1960, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn ní ìlà oòrùn Makedóníà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe—ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe márùn-ún tó wà ní orílẹ̀-èdè náà nígbà yẹn.
Lẹ́yìn tí mo ti ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe fún ọdún kan, ẹ̀ka ọ́fíìsì Áténì pè mí kí n wá sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Bí mo ṣe darí sílé láti ìdálẹ́kọ̀ọ́ oṣù kan tí mo lọ gbà fún iṣẹ́ yìí, tí mo ṣì ń sọ ìrírí tí mo ní níbẹ̀ fún Martha, ni ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ìwakùsà kan wá mi wálé, tó ní kí n wá bóun ṣe máníjà ilé iṣẹ́ ìwakùsà náà, ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń yọ́ kùsà mọ́, ó sì bá mi ṣàdéhùn iṣẹ́ ọdún márùn-ún tó fọkàn ẹni balẹ̀, ilé tó dáa, pẹ̀lú ọkọ̀ kan tí ń o fi máa ṣẹsẹ̀ rìn. Ó ní kí n fóun lésì láàárín ọjọ́ méjì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, láìbojú wẹ̀yìn rárá, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo ní: “Èmi nìyí, Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Gbágbáágbá ni ìyàwó mi tì mí lẹ́yìn. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú Ọlọ́run, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò, Jèhófà nínú oore rẹ̀ kò sì já wa kulẹ̀.
Sísìn Bí Nǹkan Ò Tiẹ̀ Fara Rọ
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún wa rárá, Jèhófà ṣì ń pèsè ohun táa nílò. Nígbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, tatapùpù kékeré kan báyìí ni mo ń gùn láti bẹ ìjọ wò, mo sì máa ń gùn ún lọ́ sí nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń yọnu, mo sì máa ń ṣubú lórí ẹ̀ nígbà míì. Mò ń padà bọ̀ láti ìjọ kan tí mo lọ bẹ̀ wò nígbà ọ̀gìnnìtìn kan, bí mo ti ní kí n sọdá odò kan ni tatapùpù bá dákú, omi sì mù mí de orúnkún. Ibi tí mo ti ń dọ́gbọ́n ìyẹn ni mo tún rí i pé táyà tatapùpù ti kanlẹ̀. Ẹnì kan tó ń kọjá lọ tó ní pọ́ǹpù ló ṣàánú mi, tó bá mi pọ́ ọ, bí mo ṣe lè dé abúlé kejì nìyẹn níbi tí mo ti tún táyà náà ṣe. Aago mẹ́ta ìdájí ni mo tó délé, ìgbà tí màá fi délé, mo ti fẹ́ẹ̀ gan, ó ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu.
Lọ́jọ́ kan, bí mo tún ti ń lọ láti ìjọ kan sí ìkejì, tatapùpù yọ̀ gẹ̀rẹ̀, ló ba yí lé mi lórúnkún. Ni ṣòkòtò mi bá ya, ẹ̀jẹ̀ sì rin ín gbingbin. Ẹyọ ṣòkòtò kan tí mo ni nìyí, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ṣá, ṣòkòtò arákùnrin mìíràn ni mo wọ̀, yàgbùrù-yagburu ló rí nídìí mi. Síbẹ̀, kò síṣòro tó bomi paná ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà àti àwọn arákùnrin mi ọ̀wọ́n.
Nínú jàǹbá mìíràn, mo fara pa yánnayànna, mo kán lápá, àwọn eyín mi iwájú sì kán. Ìgbà yẹn làbúrò mi obìnrin tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà wá kí mi, àmọ́, òun kìí ṣe Ẹlẹ́rìí o. Àfi bí ẹni pé gbogbo ìṣòro mi ti tán nígbà tó ra ọkọ̀ fún mi! Nígbà tí àwọn ará tó wà ní Áténì gbọ́ nípa ìjàǹbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí mi, wọ́n kọ lẹ́tà tó fún mi níṣìírí sí mi, lára àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n sì kọ ni àwọn ọ̀rọ̀ Róòmù 8:28, èyí tọ sọ lápá kan pé: “Ọlọ́run ń mú kí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.” Léraléra ni ọ̀rọ̀ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ wọ̀nyí ti rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ nínú ìgbésí ayé mi!
Ìyàlẹ́nu Ńlá
Lọ́dún 1963, mò ń bá aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan ṣiṣẹ́ lábúlé kan tí àwọn èèyàn kì í ti í fẹ́ gbọ́. Àwa méjèèjì pinnu pé ká ṣiṣẹ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí ẹnì kan wàásù lápá kan, kí ẹnì kejì sì wàásù lápá kejì. Nínú ilé kan, ǹjẹ́ kí n kan ilẹ̀kùn, lobìnrin kan bá sáré fà mí wọlé, kíá ó ti pa ilẹ̀kùn dé, ó ti yí kọ́kọ́rọ́ sí i. Ẹ mà gbani o, èyí ò yé mi o, ni mo bá ṣáà ń wò duu. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, ó tún ti sáré lọ pe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe yẹn wọlé wá. Ìgbà yẹn lóbìnrin yìí wá sọ fún wa pé: “Ẹ má gbin o! Ẹ má tiẹ̀ kúrò lójú kan tẹ́ẹ wà!” Nígbà tó ṣe, la bá ń gbáriwo níta. Àwọn èèyàn ti ń wá wa. Nígbà tí gbogbo ariwo náà rọlẹ̀, lobìnrin náà bá wí fún wa pé: “Torí kí wọ́n má bàá ṣe yín léṣe ni mo ṣe pè yín wọlé. Ẹ wò ó, èmi ò kóyán yín kéré o, nítorí mo mọ̀ pé Kristẹni tòótọ́ ni yín.” La bá fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, la bá túká, ṣùgbọ́n, a fún un láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ká tó máa lọ.
Ọdún mẹ́rìnlá lẹ́yìn náà, nígbà tí mo lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan ní ilẹ̀ Gíríìsì, lobìnrin kan bá tọ̀ mí wá, ló wí pé: “Bọ̀ọ̀dá, ǹjẹ́ ẹ tún mọ̀ mí? Èmi lobìnrin tí ò jẹ́ káwọn aṣòdì rí yín mú nígbà tẹ́ẹ fi wá wàásù lábúlé wa.” Obìnrin náà ti fìlú ẹ̀ sílẹ̀, ó ti kó wá sí Jámánì, ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, gbogbo ìdílé ẹ̀ ló wà nínú òtítọ́.
Lóòótọ́, ni gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti bù kún wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ “lẹ́tà ìdámọ̀ràn.” (2 Kọ́ríńtì 3:1) Ọ̀pọ̀ àwọn táa ti láǹfààní láti ràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì ló ti di alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti aṣáájú ọ̀nà. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó, bí mo ṣe ń wo àwọn àyíká tí mo ti sìn láwọn ọdún 1960, tó jẹ́ pé akéde wọn kò tó nǹkan nígbà yẹn, àmọ́ tí àwọn olùjọsìn Jèhófà tó wà níbẹ̀ ti wá tó ẹgbàárùn-ún [10,000] báyìí! Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, ẹni tó ń lò wá ní ọ̀nà rẹ̀, la fi gbogbo ìyìn fún.
“Lórí Àga Ìnàyìn ti Àmódi”
Nínú àwọn ọdún táa lò nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, Martha mà ràn mí lọ́wọ́ gidi o, ojú rẹ̀ ò kọ́rẹ́ lọ́wọ́ rí. Àmọ́, nígbà tó di October 1976, nǹkan yí padà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòjòjò, òjòjò ọ̀hún sì pọ̀, kódà wọ́n ní láti ṣe iṣẹ abẹ kan tó nira fún un. Lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó di ẹni tí ò lè gbápá gbẹ́sẹ̀ àfi kó jókòó sórí àga onítáyà. Báwo la ṣe wá fẹ́ gbọ́ gbogbo bùkátà yìí, ká sì fàyà rán ipò ìbànújẹ́ tó wà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí táa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a gbádùn ìfẹ́ àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ rẹ̀. Nígbà tí mo bá lọ sìn ní Makedóníà, Martha a wà nílé arákùnrin kan ní Áténì, fún ìtọ́jú ara rẹ̀. Kò lè ṣe kó má tẹ̀ mí láago látibẹ̀, yóò máa bá mi sọ̀rọ̀ ìṣírí, yóò ní: “Ara mi le ò. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, ẹ má wẹ̀yìn o, nígbà tí mo bá lè gbápá gbẹ́sẹ̀ dáadáa, èmi náà a lè lo àga onítáyà mi láti tẹ̀ lé yín.” Lóòótọ́, ohun tó ṣe nìyẹn. Ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìwúrí ni àwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n láti Bẹ́tẹ́lì kọ sí wa. Gbogbo ìgbà ni Martha máa ń rán ara rẹ̀ létí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 41:3, tó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.”
Nítorí àìsàn tó le yìí, lọ́dún 1986, ìpinnu náà dé wí pé, yóò dára tí mo bá lè sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Kaválla, a wá ń gbé nítòsí ìdílé ọmọbìnrin wa. Ọdún tó kọjá ni Martha mi ọ̀wọ́n kú, àmọ́ ó ṣe olóòótọ́ títí dópin. Kó tó di pé ó kú, tí àwọn ará bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo lara yín?” ohun tó sábà máa ń jẹ́ èsì rẹ̀ ni pé: “Níwọ̀n ìgbà tí n kò ti jìnnà sí Jèhófà, koko lara mi le!” Táa bá ń múra ìpàdé tàbí táa bá pè wá lọ́nà tó fani mọ́ra gan-an láti wá sìn ní àgbègbè tí ìkórè ti pọ̀, ohun tí Martha sábà máa ń sọ ni pé: John, jẹ́ a lọ sìn níbi tí àìní ti pọ̀.” Kò sọ ẹ̀mì ìtara tó ní nù rárá.
Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, àìsàn ńlá kan dá èmi náà wó. Ní March 1994, àyẹ̀wò ara tí mo ṣe fi hàn pé ọkàn-àyà mi ò ṣiṣẹ́ dáadáa, àìsàn náà sì lè pa mí, ló bá di dandan pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún mi. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo rọ́wọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára mi jálẹ̀ gbogbo àkókò làásìgbò yìí. Títí láé, n kò lè gbàgbé àdúrà tí alábòójútó àyíká kan gbà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi, nígbà tí mo jáde níbi yàrá ìtọ́jú àwọn tí wọ́n ti dé bèbè ikú, bákan náà sì ni n kò lè gbàgbé ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tí mo darí nínú yàrá tí mo wà nílé ìwòsàn náà pẹ̀lú àwọn aláìsàn mẹ́rin tí wọ́n fi ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́.
Jèhófà Ti Jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ Wa
Ọjọ́ ọ̀hún rèé bí àná yìí, ara wa sì ti ń dara àgbà, ṣùgbọ́n ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ ìsìn ń sọ ẹ̀mí wa dọ̀tun. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Ọdún kọkàndínlógójì nìyí tí mo sọ pé, “Èmi nìyí! Rán mi.” Ìgbésí ayé tó nítumọ̀, tó láyọ̀, tó sì kún fún èrè ló jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà mìíràn mo máa ń rò pé “ẹni tí a ǹ ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí,” àmọ́ mo tún lè fi ìdanílójú sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ìrànwọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” (Sáàmù 40:17) Ká sòótọ́, Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run olóore sí mi.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Martha ní 1956
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èbúté tó wà ní Kaválla
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Martha ní 1997