Ẹ Jẹ́ Ká Wà Lára Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́
“Àwa . . . [jẹ́ ara] àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—HÉBÉRÙ 10:39.
1. Èé ṣe táa fi lè sọ pé ìgbàgbọ́ olúkúlùkù àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà ṣeyebíye?
LỌ́JỌ́ míì tóo bá tún wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó kún fún àwọn olùjọsìn Jèhófà, gbìyànjú láti wo àwọn tó yí ọ ká. Ronú nípa ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọ́n gbà fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́. O lè rí àwọn àgbàlagbà tó ti sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, àwọn ọ̀dọ́ tún wà níbẹ̀ táwọn pẹ̀lú ń fojoojúmọ́ borí àdánwò ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, o sì tún lè rí àwọn òbí tó ti ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ tó bẹ̀rù Ọlọ́run dàgbà. Àwọn alàgbà ìjọ àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún ń bẹ níbẹ̀, tí wọ́n ń bójú tó ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, wàá rí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n ti borí onírúurú ìṣòro kí wọ́n bàa lè sin Jèhófà. Ẹ ò rí bí ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti ṣeyebíye tó!—1 Pétérù 1:7.
2. Èé ṣe tí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nínú Hébérù orí kẹwàá àti ìkọkànlá fi wúlò fún wa lónìí?
2 Táa bá rí ènìyàn aláìpé tó lóye ìjẹ́pàtàkì ìgbàgbọ́ ju àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ, wọn ò lè tó nǹkan. Àní, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ojúlówó ìgbàgbọ́ ń yọrí sí “pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé nínú ayé aláìnígbàgbọ́ táa wà yìí, wọ́n lè gbógun ti ìgbàgbọ́ yẹn, ìgbàgbọ́ náà sì lè yìnrìn. Ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà, tí wọ́n ń làkàkà láti pa ìgbàgbọ́ wọn mọ́ ká a lára gan-an ni. Báa ti ń wo àwọn apá tó wà nínú Hébérù orí kẹwàá àti ìkọkànlá, ẹ jẹ́ ká ṣàkíyèsí àwọn ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù lò láti gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. Báa ti ń bá èyí lọ, a óò rí bí àwa náà ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa àti tàwọn tó wà láyìíká wa lágbára sí i.
Ẹ Máa Fọkàn Tán Ara Yín
3. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù táa rí nínú Hébérù 10:39 ṣe fi hàn pé ó fọkàn tán àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́?
3 Ohun àkọ́kọ́ táa lè kíyè sí ni ẹ̀mí tó dáa tí Pọ́ọ̀lù ní sí àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Wàyí o, àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Ire ni Pọ́ọ̀lù ń rò nípa àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, kò ro ibi sí wọn rárá. Bákan náà, ṣàkíyèsí pé ó lo ọ̀rọ̀ náà “àwa.” Lóòótọ́, olódodo èèyàn ni Pọ́ọ̀lù. Àmọ́, kò torí bẹ́ẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu àwọn olùgbọ́ rẹ̀, bí ẹni pé òdodo tirẹ̀ pọ̀ ju tiwọn lọ. (Fi wé Oníwàásù 7:16.) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ka ara rẹ̀ mọ́ wọn. Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àtòun àtàwọn Kristẹni olóòótọ́, tí wọ́n ń kàwé tí òun kọ yóò kojú àwọn ìṣòro kàbìtì-kàbìtì, tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé wọn lórí, ó dá a lójú pé kò sí bí kinní ọ̀hún ṣe lè burú tó, àwọn ò ní fà sẹ́yìn sí ìparun, àti pé bó ṣe wù kó rí, àwọn yóò wà lára àwọn tó nígbàgbọ́.
4. Kí ló fà á tí Pọ́ọ̀lù fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀?
4 Kí ló lè mú kí Pọ́ọ̀lù ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀? Ṣé kò rí àṣìṣe àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù ni? Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe bó fún wọn nímọ̀ràn pàtó tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó tí wọ́n ní nípa tẹ̀mí. (Hébérù 3:12; 5:12-14; 6:4-6; 10:26, 27; 12:5) Síbẹ̀, ó kéré tán, Pọ́ọ̀lù ní ìdí méjì pàtàkì tó fi fọkàn tán àwọn arákùnrin rẹ̀. (1) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń fara wé Jèhófà, Pọ́ọ̀lù ń sapá láti fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ènìyàn rẹ̀ wò wọ́n. Ìyẹn kì í ṣe nípa ti àṣìṣe wọn o, àmọ́ ó ń kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní àti ṣíṣeéṣe náà pé wọ́n lè yàn láti ṣe rere lọ́jọ́ ọ̀la. (Sáàmù 130:3; Éfésù 5:1) (2) Pọ́ọ̀lù ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú agbára ẹ̀mí mímọ́. Ó mọ̀ pé kò sí ìṣòro èyíkéyìí, tàbí èèyàn aláìpé kankan, tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ pé kó má fún Kristẹni tó bá ń sapá láti fi tòótọ́tòótọ́ sìn Ín ní “agbára tó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13) Nítorí náà fífi tí Pọ́ọ̀lù fọkàn tán àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ kì í ṣe àṣìṣe, kì í ṣe tí ojú ayé, bẹ́ẹ̀ ni kì í kàn án ṣe pé ó lẹ́mìí nǹkan yóò dára láìnídìí. Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in, a sì gbé e ka Ìwé Mímọ́.
5. Báwo la ṣe lè fara wé ẹ̀mí ìfọkàntánni tí Pọ́ọ̀lù ní, kí ló sì lè yọrí sí?
5 Dájúdájú, ẹ̀mí ìfọkàntán tí Pọ́ọ̀lù ní ran àwọn ẹlòmíràn. Kò sí àní-àní pé, ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí nípa gidigidi lórí àwọn ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó jẹ́ alátakò àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù kò dáwọ́ ìfiniṣẹ̀sín àti ẹ̀mí ìdágunlá wọn tó kún fún ìrera dúró, àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ wọ̀nyí ran àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù lọ́wọ́ láti pinnu lọ́kàn wọn láti wà lára àwọn tó nígbàgbọ́. Ǹjẹ́ a lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún ara wa lónìí? Ó rọrùn púpọ̀ láti rí àṣìṣe àti àléébù rẹpẹtẹ lára àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 7:1-5) Síbẹ̀, a lè ran ara wa lọ́wọ́ dáadáa báa bá túbọ̀ ń ṣàkíyèsí ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní, táa sì mọrírì rẹ̀. Tí irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ bá wà, ó dájú gbangba pé ìgbàgbọ́ yóò gbèrú sí i.—Róòmù 1:11, 12.
Ọ̀nà Yíyẹ Táa Lè Gbà Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
6. Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti ń fa ọ̀rọ̀ yọ nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Hébérù 10:38?
6 Pọ́ọ̀lù tún gbé ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ró nípa bó ṣe lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà jíjáfáfá. Fún àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé pé: “‘Ṣùgbọ́n olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,’ àti pé, ‘bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.’” (Hébérù 10:38) Pọ́ọ̀lù ń fa ọ̀rọ̀ yọ níhìn-ín láti inú ìwé wòlíì Hábákúkù.a Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò ṣàjèjì sí àwọn tó ń ka lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, ìyẹn àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, àwọn tí wọ́n mọ àwọn ìwé alásọtẹ́lẹ̀ bí ẹni mowó. Táa bá ronú nípa góńgó rẹ̀—ìyẹn ni láti fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀ ní 61 Sànmánì Tiwa lókun—àpẹẹrẹ Hábákúkù tó yàn láti lò bá a mu wẹ́kú. Èé ṣe?
7. Ìgbà wo ni Hábákúkù kọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, báwo sì ni ipò nǹkan ti ri ní Júdà nígbà yẹn?
7 Ó hàn gbangba pé ó lé díẹ̀ ní ogún ọdún ṣáájú ìgbà táa pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Hábákúkù kọ ìwé rẹ̀ yìí. Nínú ìran rẹ̀, wòlíì náà rí àwọn ará Kálídíà (tàbí, àwọn ará Bábílónì), “orílẹ̀-èdè tí ó korò, tí ó sì ní inú fùfù,” bó ṣe bo Júdà mọ́lẹ̀ lójijì, tó fọ́ Jerúsálẹ́mù túútúú, tó sì tún ń lọ káàkiri láti gbé àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè mì káló. (Hábákúkù 1:5-11) Ṣùgbọ́n láti ọjọ́ Aísáyà, ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sígbà tí a kọ ìwé yìí, la ti sọ pé irú gudugbẹ̀ báyìí yóò já. Nígbà ayé Hábákúkù, lẹ́yìn tí Jòsáyà Ọba rere kú tí Jèhóíákímù gorí oyè, ìwà ibi tún wá bú rẹ́kẹ́ ní Jùdíà. Jèhóíákímù ṣenúnibíni sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà, kódà ó pa lára wọn. (2 Kíróníkà 36:5; Jeremáyà 22:17; 26:20-24) Abájọ tí wòlíì Hábákúkù tí làásìgbò bá fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ké pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?”—Hábákúkù 1:2.
8. Báwo ni àpẹẹrẹ Hábákúkù ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní?
8 Hábákúkù ò mọ bí ìparun Jerúsálẹ́mù ti sún mọ́lé tó. Bákan náà ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò mọ ìgbà tí ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù yóò dópin. Lónìí, àwa pẹ̀lú ò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí ìdájọ́ Jèhófà yóò dé sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Mátíù 24:36) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kíyè sí ìdáhùn alápá méjì tí Jèhófà fún Hábákúkù. Èkíní, ó mú un dá wòlíì náà lójú pé òpin yóò dé nígbà tí àkókò bá tó. Ọlọ́run wí pé: “Kì yóò pẹ́,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú èèyàn, ó lè jọ pé ọ̀ràn náà ń falẹ̀. (Hábákúkù 2:3) Èkejì, Jèhófà rán Hábákúkù létí pé: “Ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.” (Hábákúkù 2:4) Ẹ ò ri pé òdodo ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé lèyí! Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká máa gbé ìgbésí ayé tó fi ìgbàgbọ́ hàn, kì í ṣe ká máa ṣírò ìgbà tí òpin yóò dé.
9. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà onígbọràn ṣe ń wà láàyè nìṣó nípasẹ̀ ìṣòtítọ́ wọn (a) lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa? (d) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
9 Nígbà tí ogun kó Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jeremáyà, akọ̀wé rẹ̀ Bárúkù, Ebedi-mélékì, àti àwọn adúróṣinṣin ọmọ Rékábù rí i pé òótọ́ ní ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Hábákúkù. Wọ́n ń “wà láàyè nìṣó” ní ti pé, wọ́n yọ nínú ìparun burúkú tó dé bá Jerúsálẹ́mù. Èé ṣe? Jèhófà ló san èrè ìṣòtítọ́ wọn fún wọn. (Jeremáyà 35:1-19; 39:15-18; 43:4-7; 45:1-5) Bákan náà, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó jẹ́ Hébérù ò fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣeré rárá, nítorí pé nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù dó ti Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì tún kógun wọn lọ láìsẹ́ni tó mọ ohun tí wọ́n rí, àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ṣì fi ẹ̀mí ìgbàgbọ́ ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Jésù pé kí wọ́n tètè yáa bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀. (Lúùkù 21:20, 21) Ìṣòtítọ́ wọn ló mú kí wọ́n máa wà láàyè nìṣó. Bákan náà, àwa náà yóò máa wà láàyè nìṣó bí òpin náà bá bá wa gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Ẹ ò ri pé ìdí pàtàkì lèyí jẹ́ táa fi ní láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun nísinsìnyí!
Mímú Àwọn Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wá Sójútáyé
10. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ìgbàgbọ́ Mósè, báwo la sì ṣe lè fara wé Mósè nípa èyí?
10 Pọ́ọ̀lù gbé ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn ró nípa lílo àwọn àpẹẹrẹ lọ́nà tó gbéṣẹ́. Bóo ti ń ka Hébérù orí kọkànlá, ṣàkíyèsí bó ṣe mú àpẹẹrẹ àwọn ẹni ìtàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn wá sójútáyé. Fún àpẹẹrẹ, ó wí pé, Mósè “ń báa lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Nǹkan tó ń sọ ni pé, Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí Mósè débi pé ó wá dà bíi pé ó ń rí Ọlọ́run àìrí. Ṣé a lè sọ bẹ́ẹ̀ nípa wa? Ó rọrùn láti máa sọ̀rọ̀ nípa níní ìbátan pẹ̀lú Jèhófà, ṣùgbọ́n kí ìbátan náà lè dán mọ́rán, kó sì lágbára ń béèrè iṣẹ́. Iṣẹ́ yẹn ló sì yẹ ká ṣe! Ǹjẹ́ Jèhófà jẹ́ ẹni gidi sí wa tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé a máa ń ronú nípa rẹ̀ nígbà táa bá fẹ́ ṣe ìpinnu, títí kan àwọn ìpinnu mìíràn tó dà bíi pé wọn ò tó nǹkan? Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àtakò tó burú jù lọ.
11, 12. (a) Lábẹ́ àwọn ipò wo ló ṣeé ṣe ká ti dán ìgbàgbọ́ Énọ́kù wò? (b) Kí ni èrè to fúnni ní ìṣírí tí Énọ́kù rí gbà?
11 Àpẹẹrẹ mìíràn tóo tún lè gbé yẹ̀ wò ni ti Énọ́kù. Àtakò tó dojú kọ ṣòro fún wa láti lóye. Énọ́kù ní láti jíṣẹ́ ìdájọ́ amúbíiná tí yóò dé sórí àwọn ènìyàn búburú tó wà nígbà yẹn. (Júúdà 14, 15) Ká sòótọ́, inúnibíni tó dé bá ọkùnrin olóòótọ́ yìí gbóná débi gẹ́ẹ́, àní ó tiẹ̀ burú tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà ‘fi ṣí i nípò,’ ó mú un kúrò láàárín àwọn alààyè, ó mú kó sùn nínú ikú, kó tó di pé ọwọ́ àwọn ọ̀tá yóò tẹ̀ ẹ́. Nítorí náà, Énọ́kù kò rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó fẹnu ara rẹ̀ sọ. Ṣùgbọ́n, ó gba ẹ̀bùn tó jẹ́ pé ó sàn ju kó rí ìmúṣẹ náà lọ.—Hébérù 11:5; Jẹ́nẹ́sísì 5:22-24.
12 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, [Énọ́kù] ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” (Hébérù 11:5) Kí lèyí túmọ̀ sí? Kó tó di pé ó sùn nínú ikú, ó ṣeé ṣe kí Énọ́kù ti rí àwọn ìran kan, bóyá ó ti rí Párádísè ilẹ̀ ayé nínú ìran, níbi tí yóò padà wá jí dìde sí lọ́jọ́ ọjọ́ kan láìpẹ́. Èyí ó wù kó jẹ́, Jèhófà jẹ́ kí Énọ́kù mọ̀ pé inú Òun dùn gan-an sí ẹ̀mí ìṣòtítọ́ tó ní. Énọ́kù mú kí inú Jèhófà dùn. (Fi wé Òwe 27:11.) Ríronú nípa ìgbésí ayé Énọ́kù wúni lórí gidigidi, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé wàá fẹ́ gbé irú ìgbésí ayé ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? Nígbà náà, ronú jinlẹ̀ lórí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀; gbà pé àwọn ènìyàn tó ti wà láàyè rí ni wọ́n. Pinnu láti máa fi ìgbàgbọ́ lo ìgbésí ayé rẹ, láti ọjọ́ dé ọjọ́. Tún rántí pé, àwọn tó ní ìgbàgbọ́ kì í sin Jèhófà pẹ̀lú ìrètí pé ọjọ́ báyìí tàbí àkókò báyìí ni Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ti pinnu láti sin Jèhófà títí ayé! Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ nínú ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí àti èyí tí ń bọ̀.
Bí Ìgbàgbọ́ Wa Ṣe Lè Lágbára Sí I
13, 14. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Hébérù 10:24, 25 lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ìpàdé wa di àkókò ayọ̀? (b) Kí ni ète pàtàkì tí àwọn ìpàdé Kristẹni wà fún?
13 Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ní àwọn ọ̀nà mélòó kan tó ṣeé mú lò, èyí tí wọ́n lè gbà fún ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Ẹ jẹ́ á gbé méjì péré yẹ̀ wò níbẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wa la mọ ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó wà nínú Hébérù 10:24, 25 dáadáa, èyí tó rọ̀ wá láti máa péjọ déédéé ní àwọn ìpàdé Kristẹni wa. Àmọ́, ẹ jẹ́ á rántí pé, àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ níhìn-ín kò túmọ̀ sí pé ká kàn wá sírú ìpàdé bẹ́ẹ̀, ká kàn jókòó lásán, ká máa wòye. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ibì kan tó lè fún wa ní àǹfààní láti mọ ara wa dáadáa, láti sún ara wa láti túbọ̀ mú sísin Ọlọ́run ní ọ̀kúnkúndùn, àti láti fún ara wa níṣìírí. Ète táa fi wà níbẹ̀ ni láti fúnni, kì í ṣe láti gbà nìkan. Ìyẹn ń jẹ́ kí àwọn ìpàdé wa jẹ́ ibi aláyọ̀.—Ìṣe 20:35.
14 Àmọ́ ṣá o, olórí ète táa fi ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni ni láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run. A ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa dídara pọ̀ mọ́ àwọn ará nínú àdúrà àti orin kíkọ, nípa fífetísílẹ̀ dáadáa, àti nípa rírú ẹbọ “èso ètè”—ìyẹn ni sísọ̀rọ̀ ìyìn sí Jèhófà nípa ìbéèrè táa dáhùn àti nípa àwọn apá táa lọ́wọ́ sí nínú ìpàdé. (Hébérù 13:15) Báa bá fi àwọn góńgó yẹn sọ́kàn, táa si ṣiṣẹ́ lé wọn lórí ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan, ó dájú pé, gbogbo ìgbà la ó máa gbé ìgbàgbọ́ wa ró.
15. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù láti di iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn mú gírígírí, èé sì ti ṣe tí irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ fi bá wa mu lónìí?
15 Ọ̀nà mìíràn táa lè gbà gbé ìgbàgbọ́ wa ró ni nípa iṣẹ́ ìwàásù. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn, nítorí olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí.” (Hébérù 10:23) Nígbà tó bá jọ pé àwọn kan fẹ́ ṣubú, o lè rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá nǹkan dì mú. Ó dájú pé Sátánì gbógun ti àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, ó fẹ́ kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n lè jáwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń gbógun ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí. Tírú pákáǹleke bẹ́ẹ̀ bá dé, kí ni ṣíṣe? Ronú nípa ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe.
16, 17. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe rí ìgboyà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́? (b) Kí la lè ṣe báa bá rí i pé apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa ń fò wá láyà?
16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi (gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀) ní ìlú Fílípì, [a] ti máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” (1 Tẹsalóníkà 2:2) Báwo ni ‘wọ́n ṣe ṣàfojúdi sí’ Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní Fílípì? Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí líláálí ẹni, dídójú tini, tàbí kíkanni lábùkù tó pọ̀. Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Fílípì ní kí àwọn èèyàn nà wọ́n, wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ inú àbà. (Ìṣe 16:16-24) Ipa wo ni ìrírí burúkú yẹn ní lórí Pọ́ọ̀lù? Ǹjẹ́ àwọn tó wà ní ìlú kejì tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ bẹ̀ wò nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn ni Tẹsalóníkà, rí i kó máa gbọ̀n jìnnìjìnnì? Rárá o, ńṣe ló “máyàle.” Ó borí ìbẹ̀rù, ó sì ń wàásù lọ láìṣojo.
17 Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti rí ìgboyà rẹ̀? Ṣé láti inú ara rẹ̀ ni? Rárá o, ó wí pé, òun máyàle “nípasẹ̀ Ọlọ́run wa.” Ìwé ìṣèwádìí kan tí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ń lò sọ pé a lè túmọ̀ gbólóhùn náà báyìí, “Ọlọ́run yọ ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn wa.” Nítorí náà, bó bá jẹ́ pé ẹ̀rù n bà ọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, tàbí tó jẹ́ pé apá kan nínú rẹ̀ ló ń fò ọ́ láyà, kí ló dé tóò bẹ Jèhófà kó ṣe ohun tó ṣe fún Pọ́ọ̀lù fún ọ? Bẹ̀ ẹ́ pé kó dákun, kó yọ ìbẹ̀rù náà kúrò lọ́kàn rẹ. Ní kó jọ̀ọ́, kó fún ọ lágbára àtimáyàle nínú iṣẹ́ náà. Ní àfikún sí i, gbé àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ṣètò láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ògbóṣáṣá nínú apá ìjẹ́rìí tó jẹ́ ìṣòro rẹ. Ó lè jẹ́ àgbègbè iṣẹ́ ajé, ìjẹ́rìí òpópónà, ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà, tàbí jíjẹ́rìí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ kọ́kọ́ fẹ́ wàásù ní ilé àkọ́kọ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ wo bó ṣe ń ṣe é, kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìyẹn, máyàle láti gbìyànjú rẹ̀ wò.
18. Àwọn ìbùkún wo la lè rí gbà báa bá máyàle nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
18 Bóo bá máyàle, wá máa wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Bóo bá ń bá a lọ, tí o kò rẹ̀wẹ̀sì, o lè ní ìrírí tó fani mọ́ra nínú ṣíṣàjọpín òtítọ́, ìyẹn ni àwọn ìrírí tí ì bá má ṣeé ṣe fún ọ láti ní. (Wo ojú ìwé 25.) Ọkàn rẹ yóò balẹ̀ pé o ti mú inú Jèhófà dùn nípa ṣíṣe ohun tó ṣòro fún ọ. Wàá wá rí ìbùkún àti ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tóo lè lò láti borí ìbẹ̀rù rẹ. Ìgbàgbọ́ rẹ yóò lágbára sí i. Lóòótọ́, o kò lè mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn lágbára sí i láìjẹ́ pé ìwọ náà sọ ìgbàgbọ́ tìrẹ di alágbára.—Júúdà 20, 21.
19. Èrè ńlá wo ló wà nípamọ́ fún “àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́”?
19 Jọ̀wọ́ máa bá a nìṣó láti máa fún ìgbàgbọ́ rẹ àti ti àwọn tó wà láyìíká rẹ lókun. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbé ara rẹ àti àwọn ẹlòmíràn ró nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó jáfáfá, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó wà nínú Bíbélì, kí o sì mú wọn wá sí ojútáyé, nípa mímúra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé Kristẹni àti lílọ́wọ́ nínú wọn, àti nípa dídi àǹfààní ṣíṣeyebíye ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ táa ní mú gírígírí. Bóo ti ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ní ìdánilójú pé ní tòótọ́, o jẹ́ ọ̀kan lára “àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́.” Sì rántí pé èrè ńlá ń bẹ fún irú àwọn wọ̀nyí. Àwọn ni “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”b Jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ máa dàgbà sí i, kí Jèhófà Ọlọ́run lè pa ọ́ mọ́ títí ayérayé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú ìtumọ̀ Septuagint ti Hábákúkù 2:4, èyí tó ní gbólóhùn náà nínú pé “bó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ni inú dídùn sí i.” Gbólóhùn yìí kò fara hàn rárá nínú ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Hébérù èyíkéyìí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí. Àwọn kan sọ pé àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti èdè Hébérù kan tí kò sí mọ́ ni wọ́n gbé ìtumọ̀ Septuagint yẹn kà. Bó ti wù kó rí, ẹ̀mí mímọ́ ló mí sí Pọ́ọ̀lù tó fi fi gbólóhùn yìí kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín. Nítorí náà, Ọlọ́run ló fún un láṣẹ láti sọ bẹ́ẹ̀.
b Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọdún 2000 yóò jẹ́: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn . . . ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́.”—Hébérù 10:39.
Ṣé O Lè Dáhùn?
◻ Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú èyí?
◻ Èé ṣe tí bí Pọ́ọ̀lù ṣe fa ọ̀rọ̀ wòlíì Hábákúkù yọ ṣe bá a mu wẹ́kú?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Pọ́ọ̀lù mú wá sí ojútáyé?
◻ Àwọn ọ̀nà tó ṣeé mú lò wo ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn pé ó lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lẹ́yìn tí wọ́n tí kàn án lábùkù púpọ̀ ní Fílípì, Pọ́ọ̀lù máyàle láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ o lè máyàle láti fi onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí dánra wò?