Wọ́n Máyàle
KÌÍ sábà rọrùn láti máyàle kí a lè wàásù. Lóòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà kan, àmọ́ “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì” ni òun fi ṣe é. (1 Tẹsalóníkà 2:2) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ ká ‘jìjàkadì’ nítorí àtiwàásù? Kò sí ìdánilójú kankan pé ohun bàbàrà kan yóò ṣẹlẹ̀ báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ inú àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa ń dùn nígbà gbogbo pé àwọn máyàle. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Tara, ọmọbìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ ń sọ fún wọn nínú kíláàsì pé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n kó àwọn Júù sí ní láti lẹ Ìràwọ̀ Dáfídì tó ní àwọ̀ ìyeyè mọ́ ẹ̀wù wọn, káwọn èèyàn lè dá wọn mọ̀. Ẹ̀rù àtisọ̀rọ̀ ń ba Tara. Ó rántí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò dijú, mò ń fọkàn gbàdúrà lọ.” Lẹ́yìn náà, ó nawọ́ sókè, ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà wà nínú àwọn àgọ́ yẹn, àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò wà lára ẹ̀wù tiwọn pẹ̀lú. Inú tíṣà náà dùn, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọbìnrin yìí. Ohun tí Tara sọ yìí ló jẹ́ kí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún un láti tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún tíṣà wọn, débi pé ó ní láti fi fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, han gbogbo kíláàsì wọn.
Ní Guinea, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọmọbìnrin kan tí kò tíì ṣèrìbọmi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irène fẹ́ tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Míṣọ́nnárì tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọ̀ ọ́ pé kó gbìyànjú fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nílé ìwé. Àmọ́ Irène ń lọ́ tìkọ̀ nítorí pé àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kì í fẹ́ gbọ́. Ṣùgbọ́n, nítorí pé ìṣírí tí míṣọ́nnárì yẹn fún un wọ̀ ọ́ lọ́kàn, Irène pinnu láti kọ́kọ́ kàn sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó dà bí ẹni pé òun ló máa ń ta kò ó jù lọ. Ó ya Irène lẹ́nu pé, ọmọbìnrin náà fara balẹ̀, ó sì gba ìwé ìròyìn náà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn bíi tirẹ̀ tún ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Táa bá ṣírò iye ìwé ìròyìn tí Irene fi síta ní oṣù márùn-ún tó ṣáájú papọ̀, kò tó èyí tó fi síta ní oṣù yẹn nìkan ṣoṣo.
Ní Trinidad, alàgbà kan ń lọ́ra láti bá ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ kí ó bàa lè mọyì ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! Síbẹ̀síbẹ̀, ó máyàle. Ó wí pé: “Bí mo ṣe ń wọnú ọgbà ilé ìwé náà lọ ni mo gbàdúrà. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí ọ̀gá àgbà náà fọ̀yàyà tẹ́wọ́ gbà mí.” Obìnrin yìí gba ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ lórí “Ìrètí Tó Wà fún Àwọn Ọ̀dọ́ Òde Òní?” ó tilẹ̀ gbà láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Lẹ́nu ìgbà náà síhìn-ín, ó ti gba ogójì ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó.
Gẹ́gẹ́ bí èwe, ìwàásù máa ń nira fún Vaughn nígbà gbogbo. “Ńṣe ni gbogbo ara mi a máa gbọ̀n, ti màá máa làágùn ní àtẹ́lẹwọ́, tí màá sì máa yára sọ̀rọ̀—n kò ní lè rọra sọ̀rọ̀.” Síbẹ̀, ó di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àmọ́, kò tíì rọrùn fún un síbẹ̀ láti fìgboyà sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn tó ti wáṣẹ́-wáṣẹ́, tí kò rí, ó fẹ́ jẹ́rìí fún ẹnì kan nínú ọkọ̀ rélùwéè, “kó ṣáà lè rí i pé òun ṣe ohun kan tó ní láárí lọ́jọ́ burúkú yẹn.” Àmọ́ ẹ̀mí rẹ̀ ò gbé e láti bá àwọn ọkùnrin oníṣòwò tí ìmúra wọn fi hàn pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n, tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ rélùwéè abẹ́lẹ̀ náà, sọ̀rọ̀. Níkẹyìn, ó máyàle láti bá baba àgbàlagbà kan tó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ni wọ́n bá sọ̀rọ̀. Oníṣòwò náà dáhùn pé: “Bóo ṣe kéré tó yìí, àwọn ìbéèrè tó dáa mà wà nínú ọpọlọ rẹ o, ṣé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ni ẹ́ ni?” Vaughn fèsì pé: “Rárá o, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi.” Ọkùnrin náà rẹ́rìn-ín músẹ́, ó ní: “Mo sọ bẹ́ẹ̀ náà, ó ṣẹ̀ẹ̀ wá yé mi ni wàyí.”
Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí—àti àìmọye àwọn mìíràn—ni inú wọn ń dùn bí wọ́n ti ń máyàle láti wàásù. Ṣé wàá ṣe bíi tiwọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Tara
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Vaughn