ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 1/15 ojú ìwé 14-19
  • “Àwọn Ohun Fífani-lọ́kàn-mọ́ra” Ń kún Ilé Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àwọn Ohun Fífani-lọ́kàn-mọ́ra” Ń kún Ilé Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ṣe Nímùúṣẹ ní Ọ̀rúndún Kìíní
  • “Àwọn Ohun Fífani-Lọ́kàn-Mọ́ra” Lóde Òní
  • “Ẹ Má Fòyà”
  • Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Yin Jèhófà Lógo!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Tẹ́ḿpìlì Ńlá Jèhófà Nípa Tẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • ‘Ilé Àdúrà fún Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Èmi Wà Pẹ̀lú Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 1/15 ojú ìwé 14-19

“Àwọn Ohun Fífani-lọ́kàn-mọ́ra” Ń kún Ilé Jèhófà

“Èmi [Jèhófà] yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.”—HÁGÁÌ 2:7.

1. Nígbà pàjáwìrì, èé ṣe tó fi jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa ló máa ń kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn?

KÍ NI àwọn ohun tó fani mọ́ra, tó kún inú ilé rẹ? Ṣóo láwọn àga tó jojú ní gbèsè, kọ̀ǹpútà ìgbàlódé, àbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun wà nínú ọgbà rẹ? Kódà ká lóo ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ o kò ní gbà pé ohun tó ṣeyebíye jù lọ nínú ilé rẹ ni ènìyàn—ìyẹn ni àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ? Ká sọ pé, èéfín tó kó sí ẹ nímú ló jí ẹ lóru ọjọ́ kan. Lo bá rí i pé ilé rẹ ti gbiná, ìṣẹ́jú díẹ̀ lo sì ní láti sá jáde! Kí ló máa kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé àwọn àga rẹ ni? Àbí kọ̀ǹpútà? Àbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ? Ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún ẹ ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Dájúdájú àwọn ni, nítorí pé èèyàn boni lára jaṣọ lọ.

2. Báwo ni ìṣẹ̀dá Jèhófà ti pọ̀ tó, apá wo nínú rẹ̀ sì ni Jésù nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ?

2 Wàyí o, wá ronú nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. Jèhófà ni “Ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.” (Ìṣe 4:24) Ọmọ rẹ̀, “àgbà òṣìṣẹ́,” ni Jèhófà lò láti ṣe ohun gbogbo mìíràn. (Òwe 8:30, 31; Jòhánù 1:3: Kólósè 1:15-17) Dájúdájú, Jèhófà àti Jésù mọyì gbogbo ìṣẹ̀dá. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 1:31.) Àmọ́, nínú gbogbo ìṣẹ̀dá, èwo lo rò pé ó jọ wọ́n lójú jù lọ—ṣé àwọn nǹkan ni àbí àwọn ènìyàn? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n, ó wí pé: “Àwọn ohun tí mo sì ní ìtẹ̀sí sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ti William F. Beck ṣe sọ ọ́, “inú” Jésù “máa ń dùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.”

3. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà tipasẹ̀ Hágáì sọ?

3 Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọyì àwọn ènìyàn gan-an. Ẹ̀rí kan nípa èyí hàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó tipasẹ̀ wòlíì Hágáì sọ lọ́dún 520 ṣááju Sànmánì Tiwa. Jèhófà kéde pé: “Èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí. . . . Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti àtijọ́.”—Hágáì 2: 7, 9.

4, 5. (a) Èé ṣe tí kò fi ni bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé gbólóhùn náà “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” ń tọ́ka sí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì? (b) Báwo ni wàá ṣe ṣàlàyé “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra,” èé sì ti ṣe?

4 Kí ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí yóò kún ilé Jèhófà, tí yóò sì mú ògo rẹ̀ tí kò láfiwé wá? Ṣé àwọn àga olówó iyebíye ni àbí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì? Ṣé wúrà, fàdákà, àti àwọn òkúta iyebíye ni? Ìwọ̀nyí kò jọ ohun tó bọ́gbọ́n mu rárá. Rántí pé, tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀, tí wọ́n yà sí mímọ́ ní nǹkan bí ọ̀rúndún márùn-ún sẹ́yìn, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó dọ́là ló parí ẹ̀!a Dájúdájú, Jèhófà ò retí pé kí tẹ́ńpìlì tí àwọn Júù wọ̀nyí kọ́ wá dára ní ti ohun ọ̀ṣọ́ ju tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì lọ, nítorí pé wọn ò tó nǹkan, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sí ìlú wọn ni!

5 Tí ọ̀rọ̀ bá wá rí báyìí, kí ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí yóò kún ilé Jèhófà? Ó ṣe kedere pé, èèyàn ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́. Ó ṣe tán, kì í ṣe fàdákà àti wúrà ló ń mú inú Jèhófà dùn, bí kò ṣe, àwọn èèyàn tí ìfẹ́ ń sún láti sìn ín. (Òwe 27:11; 1 Kọ́ríńtì 10:26) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà mọyì tọkùnrin, tobìnrin, àtàwọn ọmọdé tí wọ́n ń sìn ín lọ́nà tó fẹ́. (Jòhánù 4:23, 24) Àwọn wọ̀nyí ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” náà, wọ́n sì ṣeyebíye fún Jèhófà ju gbogbo ohun mèremère tí wọ́n fi ṣe tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì lọ́ṣọ̀ọ́ lọ.

6. Ète wo ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nígbàanì ṣiṣẹ́ fún?

6 Pẹ̀lú àtakò lọ́tùn-ún lósì, wọ́n parí tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Títí di ìgbà táa fi Jésù rúbọ, tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ṣì ni ojúkò fún ìjọsìn mímọ́ gaara fún ọ̀pọ̀ “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra,” ìyẹn ni àwọn Júù àbínibí àti àwọn Kèfèrí aláwọ̀ṣe. Ṣùgbọ́n tẹ́ńpìlì náà ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó tóbi ju ìyẹn lọ, gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i.

Bó Ṣe Nímùúṣẹ ní Ọ̀rúndún Kìíní

7. (a) Kí ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbàanì ń ṣàpẹẹrẹ? (b) Ṣàlàyé àwọn ohun tí àlùfáà àgbà máa ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù.

7 Tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ń ṣàpẹẹrẹ ìṣètò fún ìjọsìn kan tó tóbi ju ti ìṣáájú lọ. Ìyẹn ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, èyí tí Jèhófà gbé kalẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, tí Jésù jẹ́ Àlùfáà Àgbà níbẹ̀. (Hébérù 5:4-10; 9:11, 12) Ṣàgbéyẹ̀wò ìjọra tó wà láàárín iṣẹ́ àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì àti ti Jésù. Lọ́dọọdún, tó bá ti di Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà yóò lọ sí ibi pẹpẹ tó wà nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ ni yóò ti fi akọ màlúù kan ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà. Lẹ́yìn èyí, yóò gbé ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà wọnú tẹ́ńpìlì, yóò gba ẹnu ọ̀nà àbáwọlé táa fi pín àgbàlá náà àti Ibi Mímọ́ kọjá, lẹ́yìn èyí ni yóò gba inú aṣọ ìkélé táa fi pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ kọjá. Gbàrà tí àlùfáà àgbà bá ti wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni yóò bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n iwájú àpótí ẹ̀rí. Ẹ̀yìn èyí ni yóò ṣe gbogbo ààtò tó ti ṣe tẹ́lẹ̀, tí yóò wá fi ewúrẹ́ kan ṣètùtù fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, àwọn tí kì í ṣe ìdílé àlùfáà. (Léfítíkù 16:5-15) Báwo ni gbogbo ààtò yìí ṣe bá tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí mu?

8. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà di ẹni tí a fi rúbọ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 29 Sànmánì Tiwa? (b) Ìbátan tímọ́tímọ́ wo ni Jésù gbádùn pẹ̀lú Jèhófà jálẹ̀ gbogbo àkókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

8 Ọ̀nà tó gbà bá a mu ni pé, a fi Jésù rúbọ lórí pẹpẹ ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà tó ṣe batisí, tí a sì fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yàn án lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa. (Lúùkù 3:21, 22) Lóòótọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ, èyí tí Jésù gbé fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. (Hébérù 10:5-10) Ní àkókò yẹn, Jésù gbádùn ipò kan pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn ni dídi ẹni tí a fi ẹ̀mí bí. Ipò aláìlẹ́gbẹ́ tí Jésù ní pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run yìí kò lè yé àwọn ẹ̀dá ènìyàn yòókù lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ńṣe ló dà bíi pé a fi nǹkan kan bò wọ́n lójú, bí aṣọ tó bo Ibi Mímọ́, tí kìí jẹ́ kí àwọn tó wà nínú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn rí ohun tó ń lọ nínú lọ́hùn-ún.—Ẹ́kísódù 40:28.

9. Èé ṣe tí Jésù ò fi lè wọ òkè ọ̀run lọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, báwo la sì ṣe yanjú ìyẹn?

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti di Ọmọ Ọlọ́run, tí a fi ẹ̀mí yàn, ọwọ́ rẹ̀ ò tíì lè tẹ ìyè ní òkè ọ̀run. Èé ṣe? Nítorí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:44, 50) Níwọ̀n bí ara ènìyàn tí Jésù ní ti jẹ́ ìdènà fún un, ní rẹ́gí, ó ṣàpẹẹrẹ aṣọ ìkélé táa fi pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run láyé ìgbàanì. (Hébérù 10:20) Ṣùgbọ́n ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, ẹ̀mí Ọlọ́run jí i dìde. (1 Pétérù 3:18) Ìgbà yìí ló tó lè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí—ìyẹn ni ọ̀run gan-an. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí tí Kristi kò wọlé sí ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe [dájúdájú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ló ń tọ́ka sí], tí ó jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́, bí kò ṣe sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.”—Hébérù 9:24.

10. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó padà sí ọ̀run?

10 Nígbà tí Jésù dé òkè ọ̀run, ó ‘wọ́n ẹ̀jẹ̀’ ìrúbọ rẹ̀ nípa gbígbé ìtóye ẹbọ ìràpadà ti ẹ̀jẹ̀ ìwàláàyè rẹ̀ lọ síwájú Jèhófà. Síbẹ̀, ohun tí Jésù ṣe tún ju ìyẹn lọ. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ó kú, ó ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.” (Jòhánù 14:2, 3) Nítorí náà, wíwọ̀ tí Jésù wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tàbí òkè ọ̀run ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn mìíràn. (Hébérù 6:19, 20) Àwọn wọ̀nyí, tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni yóò jẹ́ àlùfáà ọmọ abẹ́ nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:4; 14:1; 20:6) Gan-an gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ṣe kọ́kọ́ gbé ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù táa ta sílẹ̀ ṣe kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́ wọ̀nyí.b

“Àwọn Ohun Fífani-Lọ́kàn-Mọ́ra” Lóde Òní

11. Nítorí ta ni àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ṣe ń fi ewúrẹ́ rúbọ, kí lèyí sì ṣàpẹẹrẹ?

11 Ó jọ pé ọdún 1935 ni kíkó àwọn ẹni àmì òróró jọ ní gbogbo gbòò parí.c Àmọ́ Jèhófà ò tíì parí fífi ògo kún ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” ṣì máa wọlé sínú rẹ̀. Rántí pé ẹran méjì ni àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì fi ṣèrúbọ—ó fi akọ màlúù kan rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà, lẹ́yìn náà ó tún fi ewúrẹ́ kan rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀yà tí kìí ṣe ìdílé àlùfáà. Níwọ̀n bí àwọn àlùfáà ti dúró fún àwọn ẹni àmì òróró, àwọn tí yóò wà pẹ̀lú Jésù ní Ìjọba ti ọ̀run, àwọn wo ni àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe ìdílé àlùfáà dúró fún? A rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nínú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 10:16 pé: “Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí; àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, wọn yóò sì fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” Látàrí èyí, ẹ̀jẹ̀ Jésù táa ta sílẹ̀ ṣàǹfààní fún ẹgbẹ́ méjì—ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ ni àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run, èkejì ni àwọn tó ń fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ó hàn gbangba pé, ẹgbẹ́ kejì yìí la ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì.—Míkà 4:1, 2; 1 Jòhánù 2:1, 2.

12. Báwo ni ọ̀pọ̀ “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” ṣe ń wá sínú ilé Ọlọ́run lónìí?

12 “Àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” wọ̀nyí ṣì ń kún ilé Jèhófà títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ wa ni Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, àti ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, wọ́n ti wá yọ̀ǹda pé kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run táa ti gbé kalẹ̀ máa gbèrú lọ títí di àkókò yìí láwọn àgbègbè tí iṣẹ́ náà kò tíì dé. Bí àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra ṣe ń wá sínú tẹ́ńpìlì tí Ọlọ́run ṣètò, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn pẹ̀lú ń sapá láti túbọ̀ wá ọmọ ẹ̀yìn sí i, kí wọ́n lè ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù. (Mátíù 28:19, 20) Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn pàdé, lọ́mọdé lágbà, tí wọ́n lè di “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra,” tí yóò ṣe ilé Jèhófà lógo. Jọ̀wọ́ gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò nípa bí èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀.

13. Báwo ni ọmọdébìnrin kan ní Bolivia ṣe fi ìtara sọ̀rọ̀ Ìjọba náà?

13 Ní Bolivia, ọmọdébìnrin ọlọ́dún márùn-ún tí àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tọ́ dàgbà bẹ olùkọ́ rẹ̀ pé kó fún òun láyè ọ̀sẹ̀ kan, nítorí pé àwọn fẹ́ ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Èé ṣe? Ó fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ jálẹ̀ gbogbo ọ̀sẹ̀ àkànṣe ìgbòkègbodò yẹn. Èyí ya àwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu, ṣùgbọ́n inú wọn dùn pé ó ní irú ẹ̀mí tó dáa bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, ọmọdébìnrin náà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún nínú ilé, díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí sì máa ń wá sí ìpàdé Kristẹni déédéé. Ó tiẹ̀ ti mú olùkọ́ rẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tó bá yá, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí yóò fi ògo kún ilé Jèhófà.

14. Ní Korea, báwo ni a ṣe san èrè fún ẹ̀mí ìfaradà tí arábìnrin kan ní fún ẹnì kan tó jọ pé kò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà?

14 Níbi tí Kristẹni obìnrin kan ti ń dúró de ọkọ̀ ní ibùdókọ̀ rélùwéè, ní Korea, ó tọ akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ, ẹni tó ń gbọ́ orin látinú okùn rédíò tó kì bọtí. Obìnrin náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o lẹ́sìn tìrẹ?” Akẹ́kọ̀ọ́ náà fèsì padà pé: “N kìí fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìsìn kankan rárá.” Arábìnrin náà kò tìtorí èyí panu mọ́. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹnì kan lè fẹ́ láti yan ẹ̀sìn kan. Ṣùgbọ́n bí kò bá ní òye kankan nípa ẹ̀sìn, ó lè yan èyí tí kò tọ́.” Ojú akẹ́kọ̀ọ́ náà yí padà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sílẹ̀ sí arábìnrin wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn. Arábìnrin wa fìwé náà Is There a Creator Who Cares About You? lọ̀ ọ́, ó sì sọ fún un pé ìwé náà yóò ràn án lọ́wọ́ gidigidi nígbà tí ó bá tó àkókò fún un láti yan ẹ̀sìn kan. Ojú ẹsẹ̀ ló gba ìwé náà. Lọ́sẹ̀ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní báyìí, ó ti ń wá sí gbogbo ìpàdé.

15. Báwo ni ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní Japan ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo la sì ṣe san èrè fún ìsapá rẹ̀?

15 Ní Japan, Megumi ọmọ ọdún méjìlá ka ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ sí ibi tó dára fún iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni. Ó tiẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Ọgbọ́n wo ni Megumi dá sí i? Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ó máa ń ka Bíbélì nígbà oúnjẹ ọ̀sán tàbí kó máa múra ìpàdé sílẹ̀, ìgbà gbogbo làwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ máa ń bi í léèrè pé, èwo lèyí tóò ń ṣe yìí. Àwọn kan máa ń béèrè lọ́wọ́ Megumi ìdí tí kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tí wọ́n ń ṣe nílé ẹ̀kọ́. Gbogbo ìbéèrè yẹn ni Megumi ń dáhùn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ tó ń jẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń ru ìfẹ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sókè. Ìgbà náà ni yóò wá fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n. Megumi ń darí ogún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí—méjìdínlógún nínú wọn ló jẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ̀.

16. Báwo ni ó ti ṣeé ṣe fún arákùnrin kan ní Cameroon láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn kan láàárín àwùjọ àwọn afiniṣẹ̀sín?

16 Ní Cameroon, àwọn ọkùnrin mẹ́jọ kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé kan pe arákùnrin kan tó ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ ẹnì kan tó ń kọjá lọ. Wọ́n fẹ́ fi arákùnrin náà tayín ni o, ni wọ́n bá bi í léèrè pé, kí ló dé tí kò fi gba Mẹ́talọ́kan, ọ̀run àpáàdì, tàbí àìleèkú ọkàn gbọ́. Nípa lílo Bíbélì, arákùnrin wa dáhùn ìbéèrè wọn. Látàrí èyí, mẹ́ta lára àwọn ọkùnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára wọn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Daniel, bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé, ó tiẹ̀ pa gbogbo ohun ìní rẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò run. (Ìṣípayá 21:8) Kò sì tó ọdún kan lẹ́yìn náà tó ṣèrìbọmi.

17. Báwo ni àwọn ará kan ní ilẹ̀ El Salvador ṣe lo ọgbọ́n láti wàásù fún ọkùnrin kan tí kì í fẹ́ gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tẹ́lẹ̀?

17 Ní ilẹ̀ El Salvador, tí ọkùnrin kan bá ti kófìrí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítòsí, á ti yáa so ajá rẹ̀ tó rorò bí nǹkan míì mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé. Ọkùnrin yìí á ní sùúrù títí tí àwọn Ẹlẹ́rìí á fi kọjá, á wá mú ajá náà wọlé. Àwọn ará ò láǹfààní láti bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀ rárá. Lọ́jọ́ kan, wọ́n pinnu láti lo ọgbọ́n mìíràn. Torí wọ́n mọ̀ pé táwọn bá ń sọ̀rọ̀ níta ọkùnrin náà á máa gbọ́, ni wọ́n bá kúkú pinnu láti wàásù fún ajá rẹ̀. Wọ́n wá sílé náà, wọ́n kí ajá kú ìkàlẹ̀, wọ́n sì sọ fún un báwọn ti láyọ̀ tó láti ní àǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí párádísè yóò wà lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí kò ní sí ẹnì kan tí yóò máa bínú—àní, nígbà tí àwọn ẹranko pàápàá yóò máa gbé ní àlàáfíà. Lẹ́yìn èyí, ni wọ́n bá juwọ́ sí ajá náà pé ó dàbọ̀, ni wọ́n bá bá tiwọn lọ. Kí ni wọ́n máa rí, ni ọkùnrin yẹn bá jáde síta, ló bá tọrọ àforíjì pé kí wọ́n máà bínú pé òun ò fún àwọn Ẹlẹ́rìí láǹfààní láti bá òun sọ̀rọ̀ láti àwọn ọjọ́ yìí wá. Ó gba ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sì bẹ̀rẹ̀. Ọkùnrin yìí ti di arákùnrin wa báyìí—ó ti di ọ̀kan lára “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra”!

“Ẹ Má Fòyà”

18. Ìpèníjà wo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni dojú kọ, àmọ́ ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn olùjọsìn rẹ̀?

18 Ṣé ò ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá lo ní lóòótọ́. Ká sòótọ́, nípasẹ̀ iṣẹ́ yìí ni Jèhófà fi ń fa “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” wá sínú ilé rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Òótọ́ ni pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o lè rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí gbogbo nǹkan tojú sú ọ. Nígbà mìíràn, àwọn kan—pàápàá àwọn kan lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà—ń bá èrò pé àwọn ò ní láárí wọ̀yá ìjà. Àmọ́, lọ ṣọkàn gírí o! Gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló dára lójú Jèhófà, gbogbo wọn ló sì fẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà.—2 Pétérù 3:9.

19. Ìṣírí wo ni Jèhófà tipasẹ̀ Hágáì fún wa, báwo sì ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe lè di orísun okun fún wa?

19 Nígbà tí nǹkan bá sú wa, bóyá nítorí àtakò tàbí àwọn ipò mìíràn tí kò bára dé, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá àwọn Júù tó padà sí ìlú wọn sọ lè fún wa lókun. Nínú Hágáì 2:4-6, a kà pé “‘Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, jẹ́ alágbára, ìwọ Serubábélì,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘sì jẹ́ alágbára, ìwọ Jóṣúà ọmọkùnrin Jèhósádákì, àlùfáà àgbà. Kí ẹ sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí mo wà pẹ̀lú yín,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. ‘Ẹ rántí ohun tí mo bá yín dá ní májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde wá láti Íjíbítì, nígbà tí ẹ̀mí mi sì dúró sáàárín yín. Ẹ má fòyà.’ Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i—láìpẹ́—èmi yóò sì mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì.’” Ṣàkíyèsí pé Jèhófà kò wulẹ̀ sọ pé ká mọ́kàn le, àmọ́, ó pèsè ohun tí yóò fún wa lókun. Lọ́nà wo? Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ afinilọ́kànbalẹ̀ náà pé: “Mo wà pẹ̀lú yín.” Ẹ wò bó ti fún ìgbàgbọ́ wa lókun tó láti mọ̀ pé ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà wà pẹ̀lú wa!—Róòmù 8:31.

20. Ọ̀nà wo ni ògo tí kò láfiwé gbà ń kún ilé Jèhófà nísinsìnyí?

20 Lọ́nà tó hàn gbangba, Jèhófà ti fi hàn pé òun wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn òun. Lóòótọ́, bó ti sọ látẹnu wòlíì Hágáì gẹ́lẹ́ ló rí: “Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti àtijọ́ . . . Èmi yóò sì fúnni ní àlàáfíà ní ibí yìí.” (Hágáì 2:9) Òdodo ọ̀rọ̀ ni, ògo tó ga jù lọ lónìí ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí. Họ́wù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń rọ́ wá sínú ìjọsìn tòótọ́ lọ́dọọdún. A ti bọ́ àwọn wọ̀nyí yó nípa tẹ̀mí, kódà nínú ayé oníhílàhílo yìí, wọ́n ń gbádùn àlàáfíà tó jẹ́ pé inú ayé tuntun ti Ọlọ́run nìkan la ti lè rí i.—Aísáyà 9:6, 7; Lúùkù 12:42.

21. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

21 Mímì tí Jèhófà yóò mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì ní Amágẹ́dọ́nì kù díẹ̀ báyìí. (Ìṣípayá 16:14, 16) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká lo àkókò tó ṣẹ́ kù láti gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là. Ǹjẹ́ kí a mọ́kàn le, kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ ìpinnu wa láti máa bá a lọ ní jíjọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì ńlá Jèhófà nípa tẹ̀mí, kí a sì túbọ̀ máa fi “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” kún inú rẹ̀, títí di ìgbà tí Jèhófà yóò sọ pé iṣẹ́ náà ti parí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iye owó tí wọ́n fi ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì bílíọ̀nù owó dọ́là, táa bá gbé e lé ìṣirò ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù tí wọn ò lò fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà ni wọ́n kó sínú ìṣúra tẹ́ńpìlì.—1 Àwọn Ọba 7:51.

b Jésù yàtọ̀ sí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì, ní ti pé kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan tó máa ṣètùtù fún. Àmọ́ ṣá o, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn àlùfáà alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, nítorí pé lára aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ la ti rà wọ́n.—Ìṣípayá 5:9, 10.

c Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 1998, ojú ìwé 17 sí 22.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ju nǹkan ti ara lọ?

• Ẹgbẹ́ méjì wo ni ẹ̀jẹ̀ Jésù táa ta sílẹ̀ ṣàǹfààní fún?

• Àwọn wo ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tí yóò fi ògo kún ilé Jèhófà?

• Ẹ̀rí wo la ní tó fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì ń nímùúṣẹ lónìí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ǹjẹ́ o mọ ìjẹ́pàtàkì ohun tí tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà láyé ọjọ́un dúró fún?

Aṣọ ìkélé

Ibi Mímọ́

Pẹpẹ

Ibi Mímọ́ Jù Lọ

Gọ̀bì

Àgbàlá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àlùfáà àgbà máa ń fi akọ màlúù rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà, lẹ́yìn náà yóò wá fi ewúrẹ́ kan rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kì í ṣe ẹ̀yà àlùfáà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí à ń ṣe yíká ayé ń fa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn wọnú ilé Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́