ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 9/15 ojú ìwé 10-15
  • “Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Pinnu Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
  • Ó Ní Ìtara fún Ilé Jèhófà
  • Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Bùáyà ní Gálílì
  • Ó Fi Ìgboyà Jẹ́rìí ní Jùdíà àti Pèríà
  • Iṣẹ́ Ìyanu Tí Ẹnikẹ́ni Kò Lè Fojú Pa Rẹ́
  • “Wákàtí Náà Ti Dé!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kí Nìdí Tí Jésù Kò Fi Kánjú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ó ń kọ́ni ní Pèríà bó ṣe ń lọ sí Jùdíà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Iṣẹ́-àpèrán Aláàánú kan Sí Judia
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 9/15 ojú ìwé 10-15

“Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”

“Kò sí ẹnì kankan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí pé wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.”—JÒHÁNÙ 7:30.

1. Kókó méjì wo ló darí ìgbòkègbodò Jésù?

JÉSÙ KRISTI sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ó sọ fún gómìnà ará Róòmù nì, Pọ́ńtíù Pílátù, pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Jésù mọ ìdí náà gan-an tí òun yóò fi kú àti iṣẹ́ tí òun ní láti ṣe kí òun tó kú. Ó tún mọ ìwọ̀n àkókò tó ṣẹ́ kù fóun láti parí iṣẹ́ tí a rán òun. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré ni yóò fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Iṣẹ́ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ nígbà tó ṣèrìbọmi nínú Odò Jọ́dánì (ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa) lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ àádọ́rin ìṣàpẹẹrẹ táa sọ tẹ́lẹ̀, ó sì parí nígbà ikú rẹ̀ lórí òpó igi oró ní àárín ọ̀sẹ̀ yẹn (ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa). (Dáníẹ́lì 9:24-27; Mátíù 3:16, 17; 20:17-19) Nítorí náà, kókó méjì pàtó ló darí gbogbo ìgbòkègbodò Jésù lórí ilẹ̀ ayé, èyíinì ni: ète tí ó fi wá àti bí àkókò ti ṣe pàtàkì tó.

2. Báwo làwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣe ṣàpèjúwe Jésù Kristi, báwo lòun alára sì ṣe fi hàn pé òun mọ̀ nípa iṣẹ́ táa rán òun?

2 Àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣàpèjúwe Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọkùnrin, tó rìnrìn àjò jákèjádò igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ Palẹ́sìnì, tó ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára. A sọ nípa Jésù lápá ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ aláápọn rẹ̀ pé: “Wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.” Jésù alára sọ pé: “Àkókò yíyẹ mi kò tíì dé ní kíkún.” Ní apá ìparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lo gbólóhùn náà “wákàtí náà ti dé.” (Jòhánù 7:8, 30; 12:23) Wíwà tí Jésù wà lójúfò nípa wákàtí, tàbí àkókò tí yóò fi ṣe iṣẹ́ táa yàn fún un, títí kan ikú ìrúbọ tí yóò kú, kò ṣàì nípa lórí ohun tó sọ, tó sì ṣe. Lílóye èyí lè fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa irú ẹni tó jẹ́ àti ọ̀nà tó gbà ń ronú, èyí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.

Ó Pinnu Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

3, 4. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi àsè ìgbéyàwó kan tó wáyé ní Kánà? (b) Kí ló dé tí Ọmọ Ọlọ́run ò fi fara mọ́ àbá tí Màríà mú wá pé kí ó wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn wáìnì tí kò tó, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí?

3 Ọdún 29 Sànmánì Tiwa lọdún náà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù fúnra rẹ̀ yan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àkọ́kọ́ ni. Ní báyìí, gbogbo wọn ló wá sí abúlé táa ń pè ní Kánà ní àgbègbè Gálílì, láti wá ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níbẹ̀. Màríà ìyá Jésù wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Wáìnì ò tó. Láti fi hàn pé ó yẹ kí ọmọ òun wá nǹkan ṣe sí i, Màríà sọ fún un pé: “Wọn kò ní wáìnì kankan.” Àmọ́ Jésù dáhùn pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin? Wákàtí mi kò tíì dé síbẹ̀.”—Jòhánù 1:35-51; 2:1-4.

4 Èsì Jésù pé, “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin?” jẹ́ irú ìbéèrè kan táwọn èèyàn máa ń lò láyé ọjọ́un láti fi hàn pé àwọn ò fara mọ́ èrò tàbí àbá tí ẹnì kan dá. Kí ló dé tí Jésù ò fi fara mọ́ ọ̀rọ̀ Màríà? Ó ti pé ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà táa ń wí yìí o. Kò tíì ju ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn tó ṣe batisí, táa fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, tí Jòhánù Olùbatisí sì pè é ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29-34; Lúùkù 3:21-23) Láti ìgbà yẹn lọ, Aláṣẹ Gíga Jù Lọ, tó rán an níṣẹ́ nìkan ló láṣẹ lórí rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Kò sí ẹnikẹ́ni, ì báà jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé tó sún mọ́ ọn, tí Jésù lè gbà láyè láti dí iṣẹ́ tóun wálé ayé wá ṣe lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ìdáhùn tí Jésù fún Màríà fi hàn pé ó ti pinnu láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀! Ǹjẹ́ kí àwa náà pinnu bẹ́ẹ̀ láti ṣe “gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe” tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́.—Oníwàásù 12:13.

5. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù Kristi ṣe ní Kánà, ipa wo ló sì ní lórí àwọn ẹlòmíràn?

5 Màríà lóye ohun tí ọmọ rẹ̀ sọ, nítorí náà ó yáa juwọ́ sílẹ̀, ó sì sọ fún àwọn tí ń ṣèránṣẹ́ pé: “Ohun yòówù tí ó bá sọ fún yín, ẹ ṣe é.” Jésù sì yanjú ìṣòro náà. Ó ní kí àwọn tí ń ṣèránṣẹ́ pọnmi kún àwọn ìṣà náà, ó sì wá sọ omi náà di ògidì wáìnì. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Jésù lo agbára tó ní láti fi ṣe iṣẹ́ ìyanu, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára rẹ̀. Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tuntun rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára sí i.—Jòhánù 2:5-11.

Ó Ní Ìtara fún Ilé Jèhófà

6. Èé ṣe tí inú fi bí Jésù sí ohun tó rí nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ìgbésẹ̀ wo ló sì gbé?

6 Kò pẹ́ tí ìgbà ìrúwé wọlé dé wẹ́rẹ́ lọ́dún 30 Sànmánì Tiwa, Jésù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì wà lẹ́nu ìrìn àjò wọn sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí i tí Aṣáájú wọ́n ṣe ohun tí wọn ò rí i kó ṣe rí. Àwọn Júù oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò ń ta àwọn ẹran àti ẹyẹ tí a fi ń rúbọ nínú tẹ́ńpìlì gan-an. Ọ̀wọ́nlọ́wọ̀n-ọ́n sì ni wọ́n ń tà á fáwọn Júù olóòótọ́ tó wá jọ́sìn. Bí inú ṣe bí Jésù nìyẹn, tó sì gbégbèésẹ̀. Ó fi àwọn ìjàrá ṣe pàṣán, ó sì lé àwọn ọlọ́jà náà dà nù. Ó da owó ẹyọ àwọn olùpààrọ̀ owó nù, ó sì sojú tábìlì wọn dé. Ó pàṣẹ fáwọn tí ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín!” Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù rí bí ọ̀ràn yìí ṣe ká a lára tó, wọ́n rántí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run pé: “Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.” (Jòhánù 2:13-17; Sáàmù 69:9) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa fi tìtaratìtara dáàbò bo ara wa, kí a má ṣe jẹ́ kí àwọn ìtẹ̀sí ayé kó èérí bá ìjọsìn wa.

7. (a) Kí ló sún Nikodémù láti wá bẹ Mèsáyà wò? (b) Kí ni ẹ̀kọ́ táa rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà kan?

7 Nígbà tí Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù, ó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó kàmàmà, ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́. Nikodémù pàápàá, tí í ṣe mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn, èyíinì ni ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù, gba ti Jésù gan-an, ó sì wá bá a ní ọ̀gànjọ́ òru láti wá gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà ní “ilẹ̀ àwọn ará Jùdíà” fún nǹkan bí oṣù mẹ́jọ, wọ́n ń wàásù wọ́n sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, lẹ́yìn tí wọ́n fi Jòhánù Olùbatisí sẹ́wọ̀n, wọ́n fi Jùdíà sílẹ̀ lọ sí Gálílì. Bí wọ́n ti ń rìnrìn àjò la àgbègbè Samáríà kọjá, Jésù lo àǹfààní kan láti jẹ́rìí kúnnákúnná fún obìnrin ará Samáríà kan. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà láti di onígbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa wà lójúfò ní lílo àwọn àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà.—Jòhánù 2:23; 3:1-22; 4:1-42; Máàkù 1:14.

Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tó Bùáyà ní Gálílì

8. Iṣẹ́ wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ ní Gálílì?

8 Kí “wákàtí” ikú Jésù tó dé, ó ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ní Gálílì, Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tún pabanbarì ju ti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù lọ. Ó ń lọ “yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín àwọn ènìyàn.” (Mátíù 4:23) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ń gúnni ní kẹ́sẹ̀ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé,” ń dún kíkankíkan jákèjádò àgbègbè yẹn. (Mátíù 4:17) Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Olùbatisí wá fojú ara wọn rí ohun tí Jésù ń ṣe, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ, ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a ń gbé àwọn òkú dìde, a ń sọ ìhìn rere fún àwọn òtòṣì. Aláyọ̀ sì ni ẹni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”—Lúùkù 7:22, 23.

9. Èé ṣe táwọn ogunlọ́gọ̀ fi ń rọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù Kristi, kí sì ni ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú èyí?

9 ‘Ọ̀rọ̀ rere nípa Jésù bẹ̀rẹ̀ sí tàn ká gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká náà,’ ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń rọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀—láti Gálílì, Dekapólì, Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, àti láti òdì kejì Odò Jọ́dánì. (Lúùkù 4:14, 15; Mátíù 4:24, 25) Kì í ṣe torí ìwòsàn tó ń ṣe lọ́nà ìyanu nìkan ni wọ́n fi ń tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń wá nítorí àwọn ẹ̀kọ́ àgbàyanu tó fi ń kọ́ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń wúni lórí ó sì ń fúnni níṣìírí. (Mátíù 5:1–7:27) Ọ̀rọ̀ Jésù lárinrin ó sì dùn mọ́ni jọjọ. (Lúùkù 4:22) “Háà ń ṣe” àwọn ogunlọ́gọ̀ náà nítorí “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,” torí pé ó ń fi ọlá àṣẹ sọ̀rọ̀ látinú Ìwé Mímọ́. (Mátíù 7:28, 29; Lúùkù 4:32) Ta ni ọkàn rẹ̀ ò ní fà mọ́ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ kí àwa náà mú ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ dàgbà, kí ọkàn àwọn olóòótọ́ inú lè fà sí òtítọ́.

10. Èé ṣe táwọn aráàlú Násárétì fi fẹ́ pa Jésù, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi kùnà?

10 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá gbọ́rọ̀ Jésù ló ní àyà ìgbàṣe. Àní àwọn kan fẹ́ pa á ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, nígbà tó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù tí ń bẹ ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Násárétì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹnu ń ya àwọn aráàlú nítorí “àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin” tó ń tẹnu rẹ̀ jáde, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ rí iṣẹ́ ìyanu. Ṣùgbọ́n, kàkà tí Jésù ì bá fi ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀, ńṣe ló tú ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìnígbàgbọ́ wọn fó. Ni inú àwọn tó wà ní sínágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí ru ṣùù, ni wọ́n bá pa kuuru mọ́ Jésù, ni wọ́n bá ń fà á nífàkufà lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kan, kí wọ́n lè taari rẹ̀ lógèdèǹgbé láti ibẹ̀. Àmọ́, ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, ó sì rọra yọ́ lọ láàárín wọn. “Wákàtí” ikú rẹ̀ kò tíì dé.—Lúùkù 4:16-30.

11. (a) Èé ṣe táwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan fi wá ń gbọ́rọ̀ Jésù? (b) Èé ṣe tí wọ́n fẹ̀sùn kan Jésù pé ó rú òfin ọjọ́ Sábáàtì?

11 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn—ìyẹn àwọn akọ̀wé òfin, àwọn Farisí, àwọn Sadusí, àtàwọn míì—tún máa ń wà níbi tí Jésù bá ti ń wàásù. Kì í ṣe torí àtiwá gbọ́rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì rí ẹ̀kọ́ kọ́, ni ọ̀pọ̀ nínú wọ́n ṣe ń wá o, ṣùgbọ́n ohun tó ń gbé wọn wá ni láti wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀, kí wọ́n sì dẹkùn mú un. (Mátíù 12:38; 16:1; Lúùkù 5:17; 6:1, 2) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wá sí Jerúsálẹ́mù fún Ìrékọjá ti ọdún 31 Sànmánì Tiwa, ó mú ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì lára dá. Ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù bá fẹ̀sùn rírú òfin ọjọ́ Sábáàtì kan Jésù. Ó wá fèsì pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” Kíá làwọn Júù tún ti wá ẹ̀sùn míì sí i lẹ́sẹ̀, wọ́n ní ọ̀rọ̀ òdì ni kéèyàn pe ara rẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run nítorí ó sọ pé Ọlọ́run ni Bàbá òun. Wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù, ṣùgbọ́n òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, wọ́n sì gbọ̀nà Gálílì lọ. Bákan náà, bí a ti ń fi gbogbo agbára wa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, á dáa ká máa yẹra fún ohun tó lè fa ìforígbárí láàárín àwa àtàwọn alátakò.—Jòhánù 5:1-18; 6:1.

12. Báwo ni Jésù ṣe lọ káríkárí ìpínlẹ̀ Gálílì tó?

12 Láàárín nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ tó tẹ̀ lé e, àárín àgbègbè Gálílì nìkan ni Jésù ti ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìgbà tó bá fẹ́ lọ ṣe àwọn àjọyọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táwọn Júù ń ṣe lọ́dọọdún nìkan ló ń yọjú sí Jerúsálẹ́mù. Lápapọ̀, ẹ̀ẹ̀mẹta ló ti rìnrìn àjò lọ sí Gálílì láti lọ wàásù níbẹ̀: ìgbà àkọ́kọ́ ni ìgbà tóun àtàwọn ọmọlẹ́yìn mẹ́rin tuntun jọ lọ, ẹ̀ẹ̀kejì ni ìgbà tóun àtàwọn àpọ́sítélì méjìlá jọ lọ, àtèyí tí wọ́n ṣe tó rinlẹ̀ gan-an nígbà tó tún rán àwọn àpọ́sítélì tó ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ jáde. Ẹ wo ẹ̀rí bíbùáyà tí wọ́n jẹ́ sí òtítọ́ ní Gálílì!—Mátíù 4:18-25; Lúùkù 8:1-3; 9:1-6.

Ó Fi Ìgboyà Jẹ́rìí ní Jùdíà àti Pèríà

13, 14. (a) Ìgbà wo làwọn Júù ń wá ọ̀nà láti mú Jésù? (b) Èé ṣe táwọn onípò àṣẹ náà kò fi lè mú Jésù?

13 Ìgbà ìkórè ọdún 32 Sànmánì Tiwa ti dé wàyí, ṣùgbọ́n “wákàtí” Jésù kò tíì dé síbẹ̀. Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn ti sún mọ́lé. Àwọn iyèkan Jésù wá ń rọ̀ ọ́ pé: “Ré kọjá kúrò ní ìhín, kí o sì lọ sí Jùdíà.” Wọ́n fẹ́ kí Jésù lọ fi agbára tó ní láti ṣe iṣẹ́ ìyanu han gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbi àjọyọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé ewu wà níbẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó sọ fáwọn àbúrò rẹ̀ pé: “Kò tíì yá mi tí èmi yóò gòkè lọ sí àjọyọ̀ yìí, nítorí àkókò yíyẹ mi kò tíì dé ní kíkún.”—Jòhánù 7:1-8.

14 Jésù kọ́kọ́ tẹsẹ̀ dúró díẹ̀ ní Gálílì, kó tó wá gbọ̀nà Jerúsálẹ́mù, àmọ́ “kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ní bòókẹ́lẹ́.” Àwọn Júù sì ti ń wá a kiri níbi àjọyọ̀ náà lóòótọ́, wọ́n ń sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yẹn wà?” Nígbà tí àjọyọ̀ náà ti kọjá ìdajì, ni Jésù wá wọlé dé wẹ́rẹ́ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà kọ́ni níbẹ̀. Wọ́n ń wá bí ọwọ́ wọ́n ṣe máa tẹ̀ ẹ́, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ lè fi í sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n ṣekú pa á. Àmọ́ wọn ò rọ́nà gbé e gbà, nítorí pé “wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn sì wá gba Jésù gbọ́. Kódà àwọn onípò àṣẹ táwọn Farisí rán wá pé kí wọ́n lọ mú un wá, ọwọ́ òfo ni wọ́n padà, wọ́n ní: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.”—Jòhánù 7:9-14, 30-46.

15. Èé ṣe táwọn Júù fi ṣa òkò láti sọ ọ́ lu Jésù, iṣẹ́ ìjẹ́rìí wo ló sì dáwọ́ lé lẹ́yìn náà?

15 Ìjà tí àwọn Júù alátakò ń gbé ko Jésù ṣì ń bá a nìṣó bó ti ń kọ́ni nípa Bàbá rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì nígbà àjọyọ̀ náà. Ní ọjọ́ tó gbẹ̀yìn àjọyọ̀ náà, inú bí àwọn Júù gan-an nítorí tí Jésù sọ pé òun ti wà tẹ́lẹ̀ kí òun tó di ẹ̀dá ènìyàn, nítorí náà wọ́n ṣa òkò láti sọ ọ́ lù ú. Àmọ́ ó fara pa mọ́, ó sì lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ láìṣèṣe. (Jòhánù 8:12-59) Jésù wá kúkú jáde ní Jerúsálẹ́mù, ó sì dáwọ́ lé iṣẹ́ ìjẹ́rìí tó fakíki ní Jùdíà. Ó yan àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn, lẹ́yìn tó sì ti fún wọn nítọ̀ọ́ni, ó rán wọn ní méjìméjì, kí wọ́n lọ máa ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà. Wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ sí gbogbo ibi àti ìlú ńlá tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń wéwèé láti dé.—Lúùkù 10:1-24.

16. Ewu wo ló kọjá lórí Jésù nígbà Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́, àmọ́ iṣẹ́ wo ló tún padà jára mọ́?

16 “Wákàtí” Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́lé nígbà tó fi máa di ìgbà òtútù ọdún 32 Sànmánì Tiwa. Ó wá sí Jerúsálẹ́mù fún Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́. Àwọn Júù ṣì ń wá ọ̀nà láti pa á. Ńṣe ni wọ́n pagbo yí Jésù ká nígbà tó ń rìn ní ìloro tẹ́ńpìlì. Ni wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì kàn án, bí wọ́n tún ṣe fẹ́ sọ ọ́ lókùúta pa nìyẹn o. Àmọ́ Jésù lọ mọ́ wọn lọ́wọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Kò pẹ́ tó tún bọ́ sọ́nà tó ń kọ́ni, lọ́tẹ̀ yìí láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé ní àgbègbè Pèríà, ní ìsọdá Jọ́dánì láti Jùdíà. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ pàjáwìrì kan tí wọ́n rán sí i nípa Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n mú kí ó padà sí Jùdíà.—Lúùkù 13:33; Jòhánù 10:20-42.

17. (a) Iṣẹ́ pàjáwìrì wo ni wọ́n rán sí Jésù bó ṣe ń wàásù ní Pèríà? (b) Kí ló fi hàn pé Jésù mọ ète ìgbésẹ̀ tóun gbọ́dọ̀ gbé àti àkókò tí àwọn nǹkan gbọ́dọ̀ wáyé?

17 Màtá àti Màríà, ìyẹn àwọn arábìnrin Lásárù, tí ń gbé ní Bẹ́tánì ti Jùdíà, ló rán iṣẹ́ pàjáwìrì ọ̀hún. Ońṣẹ́ náà ròyìn pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí ìwọ ní ìfẹ́ni fún ń ṣàìsàn.” Jésù fèsì pé: “Ikú kọ́ ni ìgbẹ̀yìn àìsàn yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Láti lè mú ète yìí ṣẹ, Jésù mọ̀ọ́mọ̀ dúró síbi tó wà fún ọjọ́ méjì. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tún lọ sí Jùdíà.” Kàyéfì gbáà lèyí jẹ́ fún wọn, ni wọ́n bá dáhùn pé: “Rábì, àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta, ìwọ ha sì tún ń lọ sí ibẹ̀ bí?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé ìyókù ‘wákàtí ojúmọmọ,’ ìyẹn àkókò tí Ọlọ́run yàn kálẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé, ti fẹ́ parí. Ó mọ ohun náà gan-an tó yẹ kóun ṣe àti ìdí tóun fi gbọ́dọ̀ ṣe é.—Jòhánù 11:1-10.

Iṣẹ́ Ìyanu Tí Ẹnikẹ́ni Kò Lè Fojú Pa Rẹ́

18. Nígbà tí Jésù dé sí Bẹ́tánì, báwo ni nǹkan ti rí níbẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó débẹ̀?

18 Ní Bẹ́tánì, Màtá lẹni àkọ́kọ́ tó wá pàdé Jésù, ó sì wí pé: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” Màríà náà tẹ̀ lé e tòun ti àwọn tó wá sílé ọ̀dọ̀ wọn. Gbogbo wọn ń sunkún. Jésù wá béèrè pé: “Ibo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n dáhùn pé: “Olúwa, wá wò ó.” Nígbà tí wọ́n dé ibojì ìrántí náà—tó jẹ́ hòrò tí òkúta kan wà lójú rẹ̀—Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Níwọ̀n bí Màtá kò ti mọ ohun tí Jésù fẹ́ ṣe, ńṣe ló kọ̀ tó wí pé: “Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó di ọjọ́ mẹ́rin.” Àmọ́ Jésù béèrè pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”—Jòhánù 11:17-40.

19. Èé ṣe tí Jésù fi gbàdúrà ní gbangba kí ó tó jí Lásárù dìde?

19 Bí wọ́n ti yí òkúta tó wà lójú ibojì Lásárù kúrò, Jésù gbàdúrà sókè ketekete kí gbogbo àwọn èèyàn lè mọ̀ pé agbára Ọlọ́run lòun fẹ́ fi ṣe ohun tóun fẹ́ ṣe. Ó wá kígbe ní ohùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!” Lásárù sì jáde wá pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì, tí aṣọ kan sì bò ó lójú. Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.”—Jòhánù 11:41-44.

20. Kí làwọn tó rí Jésù nígbà tó jí Lásárù dìde ṣe?

20 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wá tu Màtá àti Màríà nínú ló gba Jésù gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí. Àmọ́, ṣe ni àwọn míì gbọ̀nà ọ̀dọ̀ àwọn Farisí lọ, láti lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Kí wá ni wọ́n ṣe o? Ojú ẹsẹ̀ ni àwọn àtàwọn olórí àlùfáà pèpàdé gbogbo Sànhẹ́dírìn ní pàjáwìrì. Pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo, wọ́n fi ìdààmú ọkàn sọ pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” Ṣùgbọ́n Káyáfà Àlùfáà Àgbà wí fún wọn pé: “Ẹ kò . . . ronú pé ó jẹ́ fún àǹfààní yín pé kí ọkùnrin kan kú nítorí àwọn ènìyàn, kí gbogbo orílẹ̀-èdè má sì pa run.” Nítorí náà, látọjọ́ yẹn ni wọ́n ti gbìmọ̀ pọ̀ pé pípa ni àwọn máa pa Jésù.—Jòhánù 11:45-53.

21. Iṣẹ́ ìyanu àjíǹde Lásárù jẹ́ àkókò ìyípadà wo?

21 Bó ṣe jẹ́ nìyẹn o, tó fi di pé nítorí àìtètèdé sí Bẹ́tánì, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹnikẹ́ni kò lè fojú pa rẹ́. Nípasẹ̀ agbára tí Ọlọ́run fún Jésù, ó jí ọkùnrin kan tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin dìde. Kódà ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ọlọ́lá kò lè sẹ́ iṣẹ́ ìyanu náà, ṣebí ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún Oníṣẹ́ Ìyanu náà! Iṣẹ́ ìyanu náà wá tipa báyìí dúró gẹ́gẹ́ bí ohun tó mú àkókò ìyípadà ńlá bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù—ìyẹn ìyípadà láti ìgbà tí “wákàtí rẹ̀ kò tíì dé” sí ìgbà tí “wákàtí náà ti dé.”

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀ nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún òun?

• Kí ló dé tí Jésù kò fi fara mọ́ àbá tí ìyá rẹ̀ mú wá nípa wáìnì?

• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa ọwọ́ tí Jésù sábà fi ń mú àwọn alátakò?

• Èé ṣe tí Jésù kò fi tètè gbéra nígbà tó gbọ́ nípa àìsàn Lásárù?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jésù fi gbogbo okun rẹ̀ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́