Ìtàn Ìgbésí Ayé
“Ẹ Kò Mọ Ohun Tí Ìwàláàyè Yín Yóò Jẹ́ Lọ́la”
GẸ́GẸ́ BÍ HERBERT JENNINGS ṢE SỌ Ọ́
“Bí mo ṣe kúrò ní ìlú Tema tí àwọn ọkọ̀ òkun máa ń gúnlẹ̀ sí, tí mo ń padà bọ̀ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society tó wà ní Gánà ni mo dúró gbé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń wá ọkọ̀ ọ̀fẹ́ tó máa gbé e dé àárín ìlú. Mo lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí fún un. Mo rò pé mò ń wàásù tó gbámúṣé fún un! Àmọ́, báa ṣe dé ibi tí ọ̀dọ́kùnrin náà ń lọ, ṣe ló bẹ́ jáde nínú ọkọ̀ tó sì feré ge.”
ÌṢẸ̀LẸ̀ yìí ló jẹ́ kí n mọ̀ pé nǹkan kan tí kò bára dé ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi. Kí n tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ bí èmi, ará Kánádà, ṣe wá di ẹni tó ń gbé Gánà.
Ní àárín December ọdún 1949, ní ẹ̀yìn odi àríwá ìpínlẹ̀ Toronto, ní Kánádà la wà. A ṣẹ̀ṣẹ̀ parí gbígbẹ́ ihò tó jìn tó mítà kan láàárín ilẹ̀ dídì gbagidi kan táa ti fẹ́ fa omi jáde kí wọ́n lè rí nǹkan lò níbi iṣẹ́ ilé tuntun kan. Òtútù ń mú gan-an, ó sì ti rẹ gbogbo àwa táa ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tẹnutẹnu, a kóra jọ sídìí iná igi tí wọ́n dá síbi táa ti ń dúró de ọkọ̀ tó máa wá gbé wa, a ń yáná. Nígbà tó yá, Arnold Lorton, ọ̀kan lára àwa òṣìṣẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí sọ nǹkan kan nípa “àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun,” “òpin ayé,” àti àwọn nǹkan mìíràn tí mi ò gbọ́ rí. Bí olúkúlùkù ṣe dákẹ́ wẹ́lo nìyẹn, ara wa kó tìì bákan bákan, àwọn kan tiẹ̀ kanra mọ́ ọn pàápàá. Mo wá rò ó nínú ara mi pé, ‘Ọkùnrin yìí mà láyà o! Kò sẹ́ni tó fẹ́ gbọ́ nǹkan tó ń sọ, síbẹ̀ kò dákẹ́.’ Àmọ́ ohun tó ń sọ wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ni, mi ò sì tíì gbọ́ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rí nínú ẹ̀sìn Christadelphian tí ìdílé wa ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, àwọn àlàyé rẹ̀ sì wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.
Ni mo bá yára lọ bá Arnold kí n lè túbọ̀ gbọ́ tẹnu ẹ̀ sí i. Tí n bá ti ronú nípa ìgbà yẹn, mo máa ń rántí bí òun àti Jean aya rẹ̀ ṣe gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, tí wọ́n sì finúure hàn sí mi, èmi tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tí n kò dá nǹkan kan mọ̀. N kì í sọ fún wọn pé mò ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kì í pè mí kí n tó lọ bá wọn fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀ nínú ilé wọn. Wọ́n là mí lóye, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti rí ojútùú sí gbogbo ohun tó ń kọ èmi ọ̀dọ́ lóminú nípa àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kora lórí ìlànà àti ìwà rere. Oṣù mẹ́wàá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá níbi táa ti ń yáná lẹ́bàá ọ̀nà yẹn ni mo ṣe ìrìbọmi, tí mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní October 22, 1950, mo sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Willowdale ní North York tó ti wá di apá kan Toronto báyìí.
Títẹ̀ Síwájú Pẹ̀lú Àwọn Olùjọ́sìn Ẹlẹgbẹ́ Ẹni
Nǹkan ò wá fara rọ mọ́ rárá nínú ilé nígbà tí baba mi rí i pé mo ti pinnu pé n kò ní kúrò nínú ẹ̀sìn tuntun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí. Àìpẹ́ sí àkókò yẹn ni Dádì kàgbákò jàǹbá ọkọ̀ tí awakọ̀ tó mutí yó fà, nítorí bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń kanra ní gbogbo ìgbà. Nǹkan ò wá rọrùn rárá fún Mọ́mì, àwọn àbúrò mi ọkùnrin méjì, àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì. Wàhálà tó dìde lórí òtítọ́ Bíbélì túbọ̀ ń peléke sí i. Mo wá rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kí n fi ilé sílẹ̀ kí àlàáfíà lè wà, kí n sì lè fìdí ara mi múlẹ̀ ní “ọ̀nà òtítọ́.”—2 Pétérù 2:2.
Nígbà tó di òpin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1951, mo kó lọ sí ìpínlẹ̀ ìjọ kékeré kan ní ìlú Coleman ní ìpínlẹ̀ Alberta. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì tí orúkọ wọ́n ń jẹ́ Ross Hunt àti Keith Robbins wà níbẹ̀, tí ọwọ́ wọ́n dí nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún tí a mọ̀ sí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Wọ́n ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni bákan náà. Èmi náà sì wọ ẹgbẹ́ àwọn òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní March 1, 1952.
Inú mi máa ń dùn gan-an nígbàkigbà tí mo bá rántí ìṣírí tí wọ́n fún mi. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà fún mi láti kọ́ nígbà yẹn, ibi ti mo sì ti máa fi ohun tí mò kọ́ hàn ni mo dé yìí. Nígbà tó yá, lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí ọdún kan nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ní Ìjọ Lethbridge ní Alberta, mo rí ìkésíni kan tí n kò retí rárá gbà pé kí n wá sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí n óò máa bẹ̀ wò ni àwọn tó wà káàkiri etíkun ìlà oòrùn Kánádà láti Moncton, New Brunswick, sí Gaspé, Quebec.
Nítorí pé mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún lọ, tí mo sì jẹ́ ẹni tuntun nínú òtítọ́, ó ṣe mi bí ẹni pé mi ò tóótun rárá, àgàgà nígbà tí mo wo ara mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó dàgbà dénú tí mo máa bẹ̀ wò. Mo sa gbogbo ipá mi láwọn oṣù bíi mélòó kan tó tẹ̀ lé e. Nǹkan ìyàlẹ́nu mìíràn tún wá ṣẹlẹ̀.
Wọ́n Pè Mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Wọ́n Sì Rán Mi Lọ sí Gold Coast
Ní September 1955, wọ́n pè mi láti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn bí ọgọ́rùn-ún mìíràn tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ láti wà ní kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní Gúúsù Lansing, New York. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ tí mo máa fi oṣù márùn-ún ṣe náà bọ́ sákòókò, nítorí ohun tí mo nílò gẹ́lẹ́ nìyẹn. Àwọn tó jáfáfá táa jọ wà ní kíláàsì kan náà ló túbọ̀ fún ìtara ti mo ní lókun. Láàárín àkókò yìí, ohun mìíràn tún ṣẹlẹ̀ tó mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i títí di òní olónìí.
Arábìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aileen Stubbs wà lára àwa tí a ń múra àtilọ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ohun tí mo rí lára Aileen ni pé ó jẹ́ adúróṣinṣin, ó ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ó mẹ̀tọ́mọ̀wà, ó sì jẹ́ ọlọ́yàyà. Mo mọ̀ pé mo dáyà fò ó nígbà tí mo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ ohun tí mo ní lọ́kàn fún un. Àmọ́, kó sọ pé òun kò ṣe o! Àwa méjèèjì gbà pé kí Aileen gba ẹnu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ lọ ní Costa Rica, èmi náà yóò kọrí sí Gold Coast (tó ń jẹ́ Gánà báyìí), ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní May 1956, mo bá ara mi ní ọ́fíìsì Arákùnrin Nathan Knorr tó wà ní àjà kẹwàá iléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York. Òun ni ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn. Wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹ̀ka láti bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Gold Coast, Togoland (tó ń jẹ́ Tógò báyìí) Ivory Coast (tó ń jẹ́ Côte d’Ivoire báyìí), Upper Volta (tó ń jẹ́ Burkina Faso báyìí), àti The Gambia.
Mo ń rántí ọ̀rọ̀ Arákùnrin Knorr bíi pé àná ló sọ ọ́. Ó ní “Má wulẹ̀ sọ pé gbàrà tóo bá débẹ̀ lo máa gbaṣẹ́. Máà kánjú; kí o kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arákùnrin tó nírìírí níbẹ̀. Nígbà tóo bá wá rí i pé o ti ṣe tán, kóo bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹ̀ka. . . . Lẹ́tà tí a fi yàn ọ́ síṣẹ́ náà rèé. Ọjọ́ keje lẹ́yìn tóo bá débẹ̀ ni kóo gbaṣẹ́.”
Mo ronú pé, ‘ọjọ́ méje péré. Ó ṣe wáá sọ pé kí n “máà kánjú”?’ Tìyanutìyanu ni mo fi kúrò níbi ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò yẹn.
Ọjọ́ ń sáré tete. Láìpẹ́, mo bá ara mi nídùúró nínú ọkọ̀ òkun kan tí wọ́n fi ń kẹ́rù, tó fẹ́ gba ojú omi East River kọjá ọ́fíìsì Society tó wà ní ìlú Brooklyn, bí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún lójú òkun lọ sí Gold Coast ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Èmi àti Aileen máa ń kọ lẹ́tà síra wa ṣáá ni. A tún pàdé ní 1958, a sì ṣe ìgbéyàwó ní August 23 ọdún yẹn. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ni irú ẹnì àtàtà bẹ́ẹ̀ ṣaya.
Fún ọdún mọ́kàndínlógún gbáko ni mo fi mọyì àǹfààní tí mo ní láti sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ mi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tí wọ́n jẹ́ ará Áfíríkà táa jọ wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Society. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì náà pọ̀ sí i, láti ẹni mélòó kan péré sí ẹni márùndínlọ́gbọ̀n lákòókò yẹn. Àwọn àkókò yẹn ò rọgbọ, a ò lè gbàgbé àkókò yẹn, a sì ṣàṣeyọrí gan-an. Àmọ́ o, mi ò ní tàn yín jẹ. Ìpèníjà ńlá ni ọ̀ràn ti ooru tó ń mú gan-an níbẹ̀ jẹ́ fún mi. Ó dà bí ẹni pé gbogbo ìgbà ní mo máa ń làágùn yọ̀bọ̀, tí gbogbo ara mi a rẹ gbindin, ìgbà mìíràn sì wà, tó máa ń múnú bí mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ìdùnnú ńlá ló jẹ́ láti sìn, bí iye wa ní Gánà ṣe ń pọ̀ sí i láti iye àwa tí a kàn fi díẹ̀ lé ní ẹgbàáta [6,000] akéde Ìjọba ní 1956 sí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀rún [21,000] ní ọdún 1975. Ohun tó tún múnú wa dùn gan-an ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ Ìjẹ́rìí níbẹ̀ báyìí.
“Ọjọ́ Ọ̀la” Kan Tí A Kò Retí
Ní nǹkan bí ọdún 1970, mo bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ ọ́n lára pé àìsàn kan ń ṣe mi, ó sì ṣòro gan-an láti mọ irú àìsàn tó jẹ́. Gbogbo ara mi ni wọ́n yẹ̀ wò kínníkínní nílé ìwòsàn, ohun ti wọ́n sì sọ fún mi níkẹyìn ni pé mi ò “láìsàn kankan lára.” Kí ló dé tí ń kò gbádùn, tó máa ń rẹ̀ mí, tí ara mi kì í sì í balẹ̀? Ohun méjì ló jẹ́ kí n rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, wọ́n sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi. Àní, ṣe ló rí bí ìwé tí Jákọ́bù kọ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.”—Jákọ́bù 4:14.
Ohun àkọ́kọ́ ti mo fura sí ni ìrírí tí mo ní pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin tí mo wàásù fún nígbà tí mo fi ọkọ̀ gbé e wá sí àárín ìlú. Mi ò mọ̀ rárá pé ṣe ni mo kàn ń sọ̀rọ̀ gbuurugbu láìdánudúró, tí mo ń yára sọ̀rọ̀ gan-an, tọ́rọ̀ ọ̀hún sì ń le kankan sí i báa ṣe ń lọ. Nígbà táa dé ibi tí ọ̀dọ́kùnrin náà ń lọ, ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tó bẹ́ jáde nínú ọkọ̀ tó sì feré gé e. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Gánà ni kì í ṣe oníjàgídíjàgan ènìyàn, tó jẹ́ pé ara wọ́n balẹ̀, tí wọn kì í sì í tètè bínú. Àwọn ará ìlú náà kì í ṣe bí ó ṣe ṣe yẹn rárá. Mo jókòó síbẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ronú. Mo mọ̀ pé mo níṣòro kan. Ohun tí ìṣòro ọ̀hún jẹ́ gan-an ni mi ò mọ̀. Àmọ́, ó dá mi lójú pé mo níṣòro kan.
Èkejì, lẹ́yìn ìjíròrò kan tó múni ronú jinlẹ̀, Aileen dábàá pé: “Tóò, bí ìṣòro yìí kì í bá ṣe ti ara, a jẹ́ pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ọpọlọ nìyẹn.” Nítorí ìdí èyí, mo wá kọ gbogbo bó ṣe ń ṣe mi sílẹ̀, mo sì kọrí sọ́dọ̀ oníṣègùn ọpọlọ. Nígbà tí mo ka gbogbo ohun tí mo kọ sílẹ̀ fún un, èsì tó fún mi ni pé: “Ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ lèyí. Àrùn ọpọlọ tí ìsoríkọ́ máa ń fà ló ń ṣe ẹ.”
Jìnnìjìnnì mú mi! Ńṣe ni ìṣòro náà túbọ̀ ń burú sí i bí mo ṣe ń tiraka láti máa bá a yí fún ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà. Mo ṣáà ń wá ìwòsàn kiri. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo bí mo ṣe ń làkàkà já sí!
Ohun táa pinnu láti ìbẹ̀rẹ̀ ni pé a óò fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wa, iṣẹ́ sì pọ̀ fún wa láti ṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo fìtara gbàdúrà àtọkànwá pé: “Jèhófà, bí o bá fẹ́, èmi ‘yóò wà láàyè, máa sì ṣe èyí.’” (Jákọ́bù 4:15) Àmọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, a gba ọ̀ràn náà bó ṣe rí, a ṣètò láti fi Gánà àti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ táa ní sílẹ̀, a sì padà sí Kánádà ní June 1975.
Jèhófà Fi Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Kẹ́ Wa
Kò pẹ́ tí mo fi wá mọ̀ pé bí n kò tilẹ̀ sí níbẹ̀ iṣẹ́ yóò máa bá a lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro tèmi kì í sì í ṣe èyí tí kò ṣe ẹnì kan rí. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Pétérù 5:9 wá sí mi lọ́kàn pé: “[Mọ̀] pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.” Nígbà tí mo lóye èyí, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí fojú inú wo bi Jèhófà ṣe ti àwa méjèèjì lẹ́yìn gidigidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyípadà yìí kò dùn mọ́ wa nínú. Ó mà dára o, bí ‘ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ará’ ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní àìmọye ọ̀nà!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò là kò ṣagbe ni wá, síbẹ̀ Jèhófà kò fi wá sílẹ̀. Ó fi àwọn ọ̀rẹ́ wa ní Gánà kẹ́ wa nípa ti ara àti láwọn ọ̀nà mìíràn. Pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn tó ga, a gbéra kúrò lọ́dọ̀ àwọn táa ti jọ di ọmọ ìyá, a sì lọ kojú “ọjọ́ ọ̀la” tí a kò retí yìí.
Lenora, ẹ̀gbọ́n Aileen, àti Alvin Friesen ọkọ rẹ̀ gbà wá sílé, wọ́n sì fi ìwà ọ̀làwọ́ bójú tó àwọn àìní wa fún oṣù bíi mélòó kan. Oníṣègùn ọpọlọ kan tó lókìkí fọwọ́ sọ̀yà pé: “Láàárín oṣù mẹ́fà, ara rẹ yóò yá.” Bóyá ó sọ ìyẹn láti fi mí lọ́kàn balẹ̀ ni, àmọ́ àwítẹ́lẹ̀ rẹ̀ yẹn kò nímùúṣẹ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà pàápàá. Títí di oní olónìí ni mo ń kojú ohun tí wọ́n kàn pé ní àìsàn ìṣesí tí kò bára dé yìí. Ó dájú pé orúkọ àpọ́nlé tí wọ́n kàn pè é nìyẹn, àmọ́ ohun táwọn tí àìsàn ọ̀hún ń ṣe mọ̀ dájú ni pé, fífi orúkọ àpọ́nlé pè é kò mú kí àwọn àmì àrùn náà tuni lára lọ́nà èyíkéyìí.
Ní àkókò yẹn, Arákùnrin Knorr ti wà lẹ́nu àìsàn tó wá pa á ní June ọdún 1977. Síbẹ̀, ó wá àyè àti okun láti kọ àwọn lẹ́tà ìṣírí sí mi, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìmọ̀ràn. Mo ṣì ń fi ojú ribiribi wo àwọn lẹ́tà wọ̀nyẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe láti mú àwọn ìmọ̀lára òdì tó máa ń yọjú ṣáá kúrò.
Ní ìparí ọdún 1975, a fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa tó níye lórí sílẹ̀, a sì gbájú mọ́ bí ara mi ṣe máa yá. Ìmọ́lẹ̀ ojúmọmọ lásán máa ń mú ojú dùn mí. Ohùn tó bá ṣàdédé dún máa ń dà bí ìró ìbọn létí mi. Rírí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ máa ń kó jìnnìjìnnì bá mi. Ìṣòro ńlá ni lílọ́ sí àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀, mi ò ṣiyèméjì rárá nípa bí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tẹ̀mí ṣe níye lórí tó. Kí n lè borí ìṣòro náà, mó sábà máa ń wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn tí gbogbo èèyàn bá ti jókòó tán, màá sì kúrò níbẹ̀ kó tó di pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí lọ sókè lọ sódò lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ.
Kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba tún jẹ́ ìṣòro lílé koko mìíràn. Nígbà mìíràn, nígbà tí mo bá tiẹ̀ dé ilé kan pàápàá, ẹ̀rù àtitẹ aago ẹnu ilẹ̀kùn máa ń bà mí. Àmọ́ ṣá o, mi ò ní juwọ́ sílẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túmọ̀ sí ìgbàlà fún wa àti fún ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. (1 Tímótì 4:16) Tó bá wá ṣe díẹ̀, máa gbìyànjú àtikápá ìmọ̀lára mi, máa lọ sílé tó tẹ̀ lé ìyẹn, máa sì tún gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i. Nípa bíbá a nìṣó láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti ní ìlera tó dára nípa tẹ̀mí, ìyẹn sì túbọ̀ fún mi lágbára láti máa fara dà á.
Nítorí jíjẹ́ tí àìsàn ìṣesí tí kò bára de jẹ́ àrùn bára kú, mo ti wá mọ̀ pé àrùn yìí kò lè fi mi sílẹ̀ mọ́ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ní ọdún 1981, àwọn àpilẹ̀kọ kan tó tayọ lọ́lá fara hàn nínú Jí!a Ipasẹ̀ wọn ni mo fi wáá mọ̀ bí àìsàn yìí ṣe jẹ́ gan-an, tí mo sì kọ́ àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ dára jù lọ láti fara dà á.
Kíkọ́ Bí A Ṣe Ń Fara Dà Á
Gbogbo èyí kò ṣẹ̀yìn bí ìyàwó mi ṣe ń fara ṣe àti bó ṣe tún àwọn ètò ṣe. Bí o bá jẹ́ ẹnì kan tó ń tọ́jú ẹni tó wà nírú ipò kan náà, ó ṣeé ṣe kí o mọyì àwọn ohun tó kíyè sí:
“Ìṣarasíhùwà ẹnì tó ní àrùn ìṣesí tí kò bára dé máa ń ṣàdédé yí padà. Láàárín wákàtí díẹ̀, aláìsàn náà lè yí padà kúrò ní ẹni tó lọ́yàyà, tó ń fúnni níṣìírí, tó tún ní àwọn ìwéwèé àti èrò tó dára lọ́kàn pàápàá kó di ẹni tí nǹkan sú, tó lérò òdì, tàbí kó tiẹ̀ máa bínú pàápàá. Tí a kò bá mọ̀ pé àìsàn ni, ó lè múnú bíni, ó sì lè kó ṣìbáṣìbo báni pàápàá. Ó ṣe kedere pé, àwọn ohun tí a wéwèé gbọ́dọ̀ yí padà lójú ẹsẹ̀, kéèyàn si bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti ìmí ẹ̀dùn tó wá látinú ìjákulẹ̀.”
Ní tèmi, ìgbà tí ara mi bá yá kọjá ààlà lẹ̀rù máa ń bà mí. Nítorí mo mọ̀ pé ohun tó máa tẹ̀ lé “ara tó yá gágá” ni kéèyàn kàn máa “wo sii.” Nínú ọ̀ràn tèmi, “wíwò sii” tẹ́ mi lọ́rùn ju kí “ara mi yá gágá” nítorí mo mọ̀ pé wíwò sii máa ń ká mi lọ́wọ́ kò fún àwọn ọjọ́ bíi mélòó kan, mi ò sì ní ṣe ohunkóhun tí kò yẹ lákòókò yẹn. Aileen ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó máa ń kìlọ̀ fún mi pé kí n má máa jẹ́ kí ara mi gbóná kọjá ààlà, ó máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń fún mi níṣìírí nígbà tí ìṣesí mi kò bá bójú mu rárá.
Ewu ńlá wà nínú kéèyàn máa dá tara ẹ̀ ṣe kó máà dá sí àwọn ẹlòmíràn ní àkókò tí àìsàn náà bá kì í mọ́lẹ̀. Ẹnì kan lè pa gbogbo èèyàn tì pátápátá lákòókò tó bá sorí kọ́ tàbí kó máà mọ bí ó ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn àti ìṣesí wọn lákòókò tí ara rẹ̀ kò balẹ̀. Látijọ́, ó ṣòro fún mi láti gbà pé mo ni ìṣòro ọpọlọ àti ti ìmọ̀lára. Mo ní láti gbógun ti ríronú pé nǹkan kan, bí ìwéwèé kan tó forí ṣánpọ́n tàbí ẹlòmíràn, ló fa ìṣòro tí mo ní. Léraléra ni mo máa ń rán ara mi létí pé, ‘Ohunkóhun kò yí padà láyìíká mi. Inú ni ìṣòro mi wà kì í ṣe ìta.’ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìrònú mi ti yí padà.
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àwa méjèèjì ti kọ́ bí a ṣe ń bá ara wa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, tí a kì í sì í fi ohunkóhun pa mọ́ fún ara wa àtàwọn ẹlòmíràn nípa ipò ti mo wà. A gbìyànjú láti ní ẹ̀mí pé nǹkan-yóò-dára, a kò sì gba àrùn náà láyè láti jẹ gàba lé ìgbésí ayé wa lórí.
“Ọjọ́ Ọ̀la” Tó Dára Jù
Nípasẹ̀ àdúrà táa ń fìtara gbà àti ọ̀pọ̀ ìlàkàkà, a ti jàǹfààní láti inú ìbùkún Jèhófà àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀. Àwa méjèèjì ti darúgbó báyìí. Mo ń gba ìtọ́jú déédéé, mo sì ń lo egbòogi tó mọ níwọ̀n ní gbogbo ìgbà, ara mi sì le dé ààyè kan. A mọyì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí táa ní. Mo ṣì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. A máa ń gbìyànjú láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìgbàgbọ́.
Òótọ́ ni ohun tí Jákọ́bù 4:14 sọ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.” Ìyẹn yóò wà bẹ́ẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ètò àwọn nǹkan yìí bá ṣì wà. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀rọ̀ inú Jákọ́bù 1:12 náà tún jẹ́ òtítọ́ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè, èyí tí [Jèhófà] ṣèlérí fún àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ǹjẹ́ kí gbogbo wa dúró gbọn-in lónìí, kí a lè rí àwọn ìbùkún tí Jèhófà yóò fún wa lọ́la.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Iwọ Lè Kojú Igbesi Aye,” nínú ẹ̀dà Jí! ti January 8, 1983; “Bí O Ṣe Lè Gbógun Ti Ìsoríkọ́,” nínú ẹ̀dà ti September 8, 1981, (Gẹ̀ẹ́sì); àti “Kíkojú Ìsoríkọ́ Lílékenkà,” nínú ẹ̀dà ti October 22, 1981, (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mo dá nìkan wà nínú ṣọ́ọ̀bù tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ ọnà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Aileen, aya mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
A wà ní Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” táa ṣe ní Tema, Gánà, ní ọdún 1963