Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Ìwà Àgàbàgebè?
NÍNÚ ọgbà Gẹtisémánì, Júdásì Ísíkáríótù lọ bá Jésù, “ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an.” Àmì ìfẹ́ àtọkànwá ni ìfẹnukonu sábà máa ń jẹ́. (Mátíù 26:48, 49) Àmọ́ ìfẹnukonu ti Júdásì yìí, ti ojú ayé ni, kí ó lè fi Jésù han àwọn tó fòru bojú wá mú un ni. (Mátíù 26:48, 49) Alágàbàgebè ni Júdásì—ìyẹn, ẹni tí ń fi ẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun síta, aṣenibánidárò. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “alágàbàgebè” túmọ̀ sí “ẹni tí ń dáhùn,” ó tún túmọ̀ sí eléré orí ìtàgé. Nígbà tó yá ni wọ́n wá ń lo ọ̀rọ̀ náà fún ẹni tí ń díbọ́n láti tan àwọn èèyàn jẹ.
Ojú wo lo fi ń wo ìwà àgàbàgebè? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ inú máa ń bí ẹ tó o bá gbọ́ pé àwọn tó ń ṣe sìgá ń polówó rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí ìṣègùn fi hàn pé jàǹbá tí sìgá ń ṣe kò kéré? Ǹjẹ́ o máa ń fara ya nígbà tó o bá rí ìwà àgàbàgebè àwọn tó sọ pé àwọn ń tọ́jú èèyàn, àmọ́ tí wọ́n ń hùwà ìkà sí àwọn tí wọ́n ń tọ́jú? Ǹjẹ́ ó máa ń dùn ẹ́ nígbà tó o bá rí i pé ọ̀dàlẹ̀ ọ̀rẹ́ ni ọ̀rẹ́ kan tó o fọkàn tán? Ojú wo lo fi ń wo ìwà àgàbàgebè nínú ẹ̀sìn?
“Ègbé Ni fún Yín . . . Ẹ̀yin . . . Alágàbàgebè!”
Ronú lórí bí ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe rí nígbà ayé Jésù. Àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí máa ń díbọ́n pé ohun tó wà nínú Òfin Ọlọ́run gan-an làwọn fi ń kọ́ni. Àmọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ènìyàn tí ń mọ́kàn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ń rọ́ sí wọn lágbárí. Àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí sọ òfin Ọlọ́run di òfin má-ṣu-má-tọ̀, wọn ò bìkítà fún àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú tí òfin náà gùn lé. Lójú ayé, wọ́n ń ṣe bí olùfọkànsin Ọlọ́run, àmọ́ ní kọ̀rọ̀, ìwà ibi ló kún ọwọ́ wọn. Ìwà wọn ò bá ọ̀rọ̀ ẹnu wọn mu rárá. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe gbogbo nǹkan ni pé “kí àwọn ènìyàn lè rí wọn.” Wọ́n ò yàtọ̀ sí “àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun, tí wọ́n fara hàn lóde bí ẹlẹ́wà ní tòótọ́ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn àti gbogbo onírúurú ohun àìmọ́.” Nígbà tí Jésù ń fi àìṣojo tú ìwà àgàbàgebè wọn fó, léraléra ló sọ fún wọn pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!”—Mátíù 23:5, 13-31.
Ká ní o wà láyé nígbà yẹn ni, irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ nínú ẹ̀sìn kò ní ṣàì kó ẹ nírìíra gan-an, bó ṣe kó àwọn olóòótọ́ ọkàn ìgbàanì nírìíra. (Róòmù 2:21-24; 2 Pétérù 2:1-3) Àmọ́, ṣé ò bá ti jẹ́ kí ìwà àgàbàgebè àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí bí ẹ nínú débi tí wàá fi kẹ̀yìn sí gbogbo ẹ̀sìn, títí kan ẹ̀sìn tí Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń ṣe, tí wọ́n sì ń fi kọ́ni? Ǹjẹ́ ìyẹn ò ní pa ọ́ lára?
Ìwà àgàbàgebè táwọn ẹlẹ́sìn ń hù lè jẹ́ ká kórìíra ẹ̀sìn pátápátá. Àmọ́ ṣá o, irú ìwà yìí kò ní jẹ́ ká rí inú funfun àwọn olùjọsìn tòótọ́. Tá a bá sọ pé a ò fẹ́ rí ìwà àgàbàgebè, ìyẹn lè máà jẹ́ ká ríran rí àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi gba ọgbọ́n àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì láti mọ ọwọ́ tó yẹ ká fi mú ìwà àgàbàgebè.
“Ẹ La Ojú Yín Sílẹ̀”
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ ká mọ bá a ṣe ń dá alágàbàgebè mọ̀. Èyí kì í sábàá rọrùn. Iná ti jó dórí kókó kí ìdílé kan tóó mọ èyí. Ìyá wọ́n ti dákú lọ gbári. Ìdílé náà wá lọ gba lọ́yà kan tó tún jẹ́ oníwàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò wọn, pé kó bá àwọn pe ilé ìwòsàn tó ṣe iṣẹ́ àjàǹbàkù tó fa wàhálà yìí lẹ́jọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìwòsàn náà san owó ìtanràn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ dọ́là, kàkà kí ìṣòro ìdílé yìí dín kù, ńṣe ló túbọ̀ ń peléke sí i. Ńṣe ni ìyá náà ráre kú, wọn ò sì rówó sìnkú ẹ̀. Kí nìdí? Àpò lọ́yà ọ̀hún ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú owó náà lọ. Ìwé ìròyìn kan tó dá lórí ọ̀ràn òfin sọ nípa lọ́yà yìí, pé: “Bó bá ṣe pé ohun tó hù níwà yìí ló ń wàásù fáwọn èèyàn ni . . . , á jẹ́ pé ìwàásù rẹ̀ ò lè kọjáa: ẹ dijú, ẹ jẹ́ ká lu jìbìtì.” Báwo la ṣe lè yẹra fún bíbọ́ sí akóló irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀?
“Ẹ la ojú yín sílẹ̀,” ni ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn èèyàn tó ń rí ìwà àgàbàgebè ẹ̀sìn nígbà ayé rẹ̀. (Mátíù 16:6; Lúùkù 12:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí. Àwọn èèyàn lè máa fọ́ táá pé ọmọlúwàbí làwọn, kí wọ́n máa fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn kì í ṣe gbájú-ẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra o, nítorí pé awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bonú kò jẹ́ ká rí ikùn aṣebi. Bí a bá gbọ́ pé ayédèrú owó ń bẹ lóde, ǹjẹ́ a ò ní yẹ owó ọwọ́ wa wò fínnífínní?
Àwọn alágàbàgebè ò ṣàìsí nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́ pàápàá. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Júúdà, kìlọ̀ nípa wọn, pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àpáta tí ó fara sin lábẹ́ omi nínú àwọn àsè ìfẹ́ yín nígbà tí wọ́n ń jẹ àsè pẹ̀lú yín, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń bọ́ ara wọn láìsí ìbẹ̀rù; àwọsánmà aláìlómi tí ẹ̀fúùfù ń gbá síhìn-ín sọ́hùn-ún; àwọn igi ní apá ìgbẹ̀yìn ìgbà ìkórè, ṣùgbọ́n tí kò ní èso.”—Júúdà 12.
A ó ‘la ojú wa sílẹ̀,’ kí a má bàa tàn wá jẹ nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni tó jẹ́ afojú-fẹ́ni-má-fọkàn-fẹ́ni, tó jẹ́ pé ti ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, tó sì ń tan àwọn èrò tó lòdì sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀. Bí àpáta págunpàgun, tó forí pa mọ́ sábẹ́ omi pípa rọ́rọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn tí kò bá fura. (1 Tímótì 1:19) Alágàbàgebè náà lè máa lẹ́nu pé òun á mú ìtura wá nípa tẹ̀mí, àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó lè má yàtọ̀ sí “àwọsánmà aláìlómi”—tí kò lè rọ̀jò. Gẹ́gẹ́ bí igi aláìléso, ẹlẹ́tàn kì í so èso kankan tó jẹ́ ti Kristẹni tòótọ́. (Mátíù 7:15-20; Gálátíà 5:19-21) Àní sẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún irú àwọn ẹlẹ́tàn bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ìyẹn ò wáá ní ká máa fura sí gbogbo èèyàn o.
“Ẹ Dẹ́kun Dídánilẹ́jọ́”
Ẹ wo bó ti rọrùn tó kí ẹ̀dá aláìpé jẹ́ arítẹni-mọ̀ọ́-wí afàpáàdì-bo-tiẹ̀-mọ́lẹ̀! Bá ò bá ṣọ́ra, ìtẹ̀sí yìí lè sọ wá di alágàbàgebè. Jésù sọ pé: “Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.” Á dára ká kọbi ara sí ìmọ̀ràn rẹ̀, pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́ . . . Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?”—Mátíù 7:1-5.
Nígbà míì táwọn èèyàn bá ṣe nǹkan tó fara jọ ìwà àgàbàgebè, kò ní dáa ká wá tìtorí ìyẹn tètè máa pè wọ́n ní alágàbàgebè. Fún àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù “fà sẹ́yìn, ó sì ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀” kúrò lọ́dọ̀ àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ nílùú Áńtíókù, torí pé ó ń wá ojú rere àwọn àlejò tí í ṣe Júù, tó wá láti Jerúsálẹ́mù. ‘A fa Bánábà pàápàá lọ pẹ̀lú Pétérù nínú ìdíbọ́n yìí.’ Pétérù ṣe eléyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kan náà yìí la lò láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn Kèfèrí kí wọ́n lè di ara ìjọ Kristẹni. (Gálátíà 2:11-14; Ìṣe 10:24-28, 34, 35) Ó dájú pé àṣìṣe tí Bánábà àti Pétérù ṣe yìí kò wá sọ wọ́n di irú èèyàn kan náà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí tàbí Júdásì Ísíkáríótù.
“Kí Ìfẹ́ Yín Wà Láìsí Àgàbàgebè”
Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Nígbà tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, má lọ gba oníkàkàkí táá máa fun kàkàkí níwájú rẹ—bíi tàwọn eléré wọ̀nyẹn nínú sínágọ́gù àti lójú pópó, tí wọ́n ń mú káwọn èèyàn máa kan sáárá sí wọn.” (Mátíù 6:2, Phillips) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.” (Róòmù 12:9) Ó gba Tímótì ọ̀dọ́ níyànjú pé kí ó ní “ìfẹ́ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́ . . . àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.” (1 Tímótì 1:5) Bí ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ wa bá jẹ́ ojúlówó—tí kò ní ìmọtara ẹni nìkan àti ẹ̀tàn—àwọn èèyàn á gbẹ́kẹ̀ lé wa. A óò jẹ́ orísun okun àti ìṣírí ńláǹlà fáwọn tó yí wa ká. (Fílípì 2:4; 1 Jòhánù 3:17, 18; 4:20, 21) Lékè gbogbo rẹ̀, a óò rí ojú rere Jèhófà.
Àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìwà àgàbàgebè á hun àwọn alágàbàgebè. Bó pẹ́ bó yá, àṣírí ìwà àgàbàgebè kò ní ṣàì tú sí gbangba. Jésù Kristi sọ pé: “Kò sí nǹkan kan tí a bò mọ́lẹ̀ tí kì yóò di títú síta, kò sì sí àṣírí tí kì yóò di mímọ̀.” (Mátíù 10:26; Lúùkù 12:2) Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kéde pé: “Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.”—Oníwàásù 12:14.
Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, èé ṣe tí a ó fi jẹ́ kí ìwà àgàbàgebè àwọn ẹlòmíì jẹ́ ká pàdánù ojúlówó ìfẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́? A lè jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra láìjẹ́ pé a ń fura sí gbogbo èèyàn. Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi láti rí i dájú pé ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ wa kò ní ìwà àgàbàgebè nínú.—Jákọ́bù 3:17; 1 Pétérù 1:22.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ṣé ò bá ti jẹ́ kí ìwà àgàbàgebè àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí mú ọ kẹ̀yìn sí Jésù Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?