Àwọn Síkítíánì—Àwọn Abàmì Ẹ̀dá Ayé Ọjọ́un
ERUKU ń sọ lálá, bí agbo agẹṣinjagun àwọn ẹ̀yà kan tí ń ṣí kiri ti ń gẹṣin bọ̀ kútúpà-kútúpà. Àpò tí wọ́n so mọ́ ẹ̀yìn ẹṣin wọn kún fún ẹrù tí wọ́n rí kó lójú ogun. Àwọn abàmì ẹ̀dá wọ̀nyí ni ògúnnágbòǹgbò tí ń dátọ́ lẹ́nu ìgbín ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà tí ó tẹ́jú lọ salalu láti nǹkan bí ọdún 700 sí 300 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn náà, wọ́n pòórá—àmọ́ wọ́n ṣe orúkọ fúnra wọn nínú ìtàn kí wọ́n tó pòórá. A mẹ́nu kàn wọ́n nínú Bíbélì pàápàá. Ìyẹn ni àwọn Síkítíánì.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn alákòókiri àti agbo ẹṣin wọn fi ń rìn kiri pápá tó nasẹ̀ láti àwọn Òkè Ńlá Carpathian ní ìhà ìlà oòrùn Yúróòpù títí dé ibi tá a wá mọ̀ sí gúúsù ìlà oòrùn Rọ́ṣíà báyìí. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, ìgbésẹ̀ ológun tí Hsüan, Olú Ọba China gbé mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣí lọ sí ìwọ̀ oòrùn. Bí àwọn Síkítíánì ṣe ṣí lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn ni wọ́n gbógun ti àwọn Cimmerian, tí ń ṣàkóso àgbègbè Caucasus àti àgbègbè tó wà ní ìhà àríwá Òkun Dúdú, tí wọ́n sì lé wọn dà nù.
Nítorí àtidi ọlọ́rọ̀, àwọn Síkítíánì kó gbogbo ẹrù Nínéfè, tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà lọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Ásíríà láti bá Mídíà, Babilóníà, àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jagun. Ogun tí wọ́n ń jà ọ̀hún nasẹ̀ dé ìhà àríwá Íjíbítì pàápàá. Bí ìlú ńlá Bẹti-ṣánì tó wà ní ìhà àríwá ìlà oòrùn ṣe wá di èyí tí wọ́n ń pè ní Scythopolis nígbà tó yá lè jẹ́ àmì pé àwọn Síkítíánì gba ìlú náà fún sáà kan.—1 Sámúẹ́lì 31:11, 12.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn Síkítíánì wá tẹ̀dó sí àwọn ibi tá a wá mọ̀ sí Romania, Moldova, Ukraine, àti gúúsù Rọ́ṣíà lóde òní. Ibẹ̀ ni wọ́n ti wá dọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ níbi tí wọ́n ti ń ṣe alágbàtà láàárín àwọn Gíríìkì àtàwọn tó ń ṣọ̀gbìn ọkà ní Ukraine àti gúúsù Rọ́ṣíà òde òní. Àwọn Síkítíánì ń fi ọkà, oyin, irun ẹran àti màlúù ṣe pàṣípààrọ̀ wáìnì, aṣọ, ohun ìjà àtàwọn iṣẹ́ ọnà lọ́wọ́ àwọn Gíríìkì. Bí wọ́n ṣe kó ọrọ̀ rẹpẹtẹ jọ nìyẹn.
Ewèlè Ni Wọ́n Lórí Ẹṣin
Bí ràkúnmí ṣe wúlò tó fáwọn ará aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹṣin wúlò fún àwọn jagunjagun ilẹ̀ títẹ́jú wọ̀nyí. Ọ̀gá làwọn Síkítíánì nínú ẹṣin gígùn, wọ́n sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ lo gàárì àti ìdásẹ̀lé ara ẹṣin. Wọ́n ń jẹ ẹran ẹṣin, wọ́n sì ń mu wàrà ẹṣin. Àní, wọ́n ń lo ẹṣin fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun. Nígbà tí jagunjagun Síkítíánì bá kú, wọ́n á pa ẹṣin rẹ̀, wọ́n á sì sin ín lọ́nà tó gbayì—pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.
Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn nì, Herodotus, ṣe sọ ọ́, àwọn Síkítíánì ní àwọn àṣà òǹrorò. Lára irú àṣà bẹ́ẹ̀ ni fífi agbárí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́gun ṣe ife. Tí wọ́n bá ti lè mú àwọn ọ̀tá wọn báyìí, wọ́n á fi idà onírin, àáké ogun, ọ̀kọ̀, àtàwọn ọfà onírin, ẹlẹ́nu ṣóńṣó fa ẹran ara wọn ya.
Àwọn Ibojì Tí Wọ́n Ṣe Lọ́ṣọ̀ọ́ Ayérayé
Àwọn Síkítíánì ń ṣe iṣẹ́ òkùnkùn, wọ́n gba àwọn ẹ̀mí àìrí gbọ́, wọ́n sì jọ́sìn iná àti ìyá abo-ọlọ́run. (Diutarónómì 18:10-12) Wọ́n gbà pé inú ibojì ni àwọn òkú ń gbé. Wọ́n máa ń fi àwọn ẹrú àtàwọn ẹranko rúbọ kí àwọn ọ̀gá tó ti kú lè máa lò wọ́n. Wọ́n gbà pé àwọn ìṣúra àtàwọn ẹrú wọ̀nyẹn máa ń tẹ̀ lé ìjòyè náà dé “ayé tó tẹ̀ lé èyí.” Nínú ibojì ìjòyè kan, wọ́n rí òkú àwọn ìránṣẹ́kùnrin márùn-ún tí wọ́n na ẹsẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn, tí wọ́n ṣe tán láti dìde kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ ni wọ́n máa ń rú nígbà tí wọ́n bá ń sìnkú àwọn alákòóso, tó bá sì di àkókò ọ̀fọ̀, àwọn Síkítíánì máa ń ta ẹ̀jẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n á sì fá irun orí ara wọn. Herodotus kọ̀wé pé: “Wọ́n máa ń gé díẹ̀ lára etí ara wọn, wọ́n á fá irun orí wọn, wọ́n á kọ apá ara wọn lábẹ yí po, wọ́n a fi nǹkan gé iwájú orí àti imú ara wọn, wọ́n a sì fi ọfà gún ọwọ́ òsì ara wọn.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní sànmánì yẹn kan náà ni pé: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ nítorí ọkàn tí ó ti di olóògbé.”—Léfítíkù 19:28.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kurgan (ojú oórì) ni àwọn Síkítíánì fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ọ̀ṣọ́ táwọn èèyàn rí nínú àwọn kurgan náà fi bí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn Síkítíánì ṣe rí hàn. Peter Ńlá, tó jẹ́ Olú Ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí kó irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jọ ní 1715, a sì lè rí àwọn nǹkan dídán yinrin wọ̀nyí ní àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ní Rọ́ṣíà àti Ukraine. Àwọn ẹṣin, idì, àwòdì, ológbò, àmọ̀tẹ́kùn, ìgalà, àgbọ̀nrín, àwọn àdàmọ̀dì ẹyẹ àtàwọn àdàmọ̀dì kìnnìún (ìyẹn àwọn ẹranko inú ìtàn àròsọ tí wọ́n ní ara ẹranko kan yálà èyí tó níyẹ̀ẹ́ tàbí èyí tí kò níyẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ní orí ẹranko mìíràn) wà lára “ère àwọn ẹranko” yìí.
Àwọn Síkítíánì àti Bíbélì
Ibì kan ṣoṣo péré ni Bíbélì ti dárúkọ àwọn Síkítíánì. A kà á nínú Kólósè 3:11 pé: “Kò . . . sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì, ẹrú, òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.” Nígbà tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún “Síkítíánì” kò tọ́ka sí orílẹ̀-èdè kan pàtó, àmọ́ ó tọ́ka sí àwọn tó burú jù lọ nínú àwọn èèyàn tí kò lajú. Àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe ni pé lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, kódà irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàápàá lè gbé àkópọ̀ ìwà bí Ọlọ́run wọ̀.—Kólósè 3:9, 10.
Àwọn awalẹ̀pìtàn kan gbà gbọ́ pé orúkọ náà Áṣíkénásì tá a rí nínú Jeremáyà 51:27 jẹ́ èyí tó bá orúkọ náà Ashguzai ti àwọn ará Ásíríà mu wẹ́kú, ìyẹn ọ̀rọ̀ tó tọ́ka sí àwọn Síkítíánì. Àwọn wàláà tá a gbẹ́ nǹkan sí lára sọ̀rọ̀ nípa àdéhùn tó wà láàárín àwọn èèyàn yìí àtàwọn Mannai nígbà tí wọ́n dìtẹ̀ sí Ásíríà ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa. Kété ṣáájú àkókò tí Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀ ni àwọn Síkítíánì gba ilẹ̀ Júdà kọjá lọ sí Íjíbítì, tí wọ́n sì tún gbabẹ̀ bọ̀ láìbá ẹnikẹ́ni jà. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ tó gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà nípa ogun tí ń bọ̀ wá ja Júdà láti ìhà àríwá ti lè kọminú pé bóyá ni àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fi jẹ́ òtítọ́.—Jeremáyà 1:13-15.
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ronú pé àwọn Síkítíánì ni ìwé Jeremáyà 50:42 ń tọ́ka sí, nígbà tó sọ pé: “Ọrun àti ẹ̀ṣín ni wọ́n mú dání. Wọ́n níkà, wọn kì yóò sì fi àánú hàn. Ìró wọn dà bíi ti òkun tí í ṣe aláriwo líle, ẹṣin ni wọn yóò gùn; tí a tò ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo fún ogun lòdì sí ọ, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.” Àmọ́, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà tó ṣẹ́gun Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa ni ẹsẹ yẹn ń tọ́ka sí.
Àwọn kan dá a lábàá pé “ilẹ̀ Mágọ́gù” tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì orí kejìdínlógójì àti ìkọkàndínlógójì ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀yà Síkítíánì. Àmọ́ ṣá o, èdè ìṣàpẹẹrẹ ni “ilẹ̀ Mágọ́gù” jẹ́. Ó hàn gbangba pé sàkáání ilẹ̀ ayé, níbi tá a há Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ogun tí wọ́n jà ní ọ̀run ló ń tọ́ka sí.—Ìṣípayá 12:7-17.
Àwọn Síkítíánì kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí Náhúmù sọ nípa bí a ó ṣe ṣẹ́gun Nínéfè. (Náhúmù 1:1, 14) Àwọn ará Kálídíà, àwọn Síkítíánì, àtàwọn Mídíà ṣẹ́gun Nínéfè ní ọdún 632 ṣááju Sànmánì Tiwa, èyí sì fa ìṣubú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà.
Wọ́n Rá Bí Isó
Àwọn Síkítíánì ti pòórá, àmọ́ kí nìdí? Òléwájú awalẹ̀pìtàn ará Ukraine kan sọ pé: “Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, a ò wulẹ̀ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ni.” Àwọn kan gbà gbọ́ pé, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí kíkó ọrọ̀ jọ, wọ́n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ alákòókiri tuntun kan tó wá láti Éṣíà ní ọ̀rúndún kìíní àti èkejì ṣááju Sànmánì Tiwa—ìyẹn àwọn Sarmatian.
Àwọn mìíràn gbà pé gbọ́nmi-si omi-ò-to tó wáyé láàárín ẹ̀yà àwọn Síkítíánì ló fà á ti wọ́n fi dàwátì. Síbẹ̀, àwọn mìíràn sọ pé a ṣì lè rí ìyókù àwọn Síkítíánì láàárín àwọn Ossetian tó wà ní Caucasus. Bó ti wù kó rí, àwọn abàmì ẹ̀dá wọ̀nyí fi ohun kan sílẹ̀ nínú ìtàn ìran ènìyàn—ìyẹn ni ohun tó sọ orúkọ náà Síkítíánì di èyí tá a fi ń ṣàpèjúwe ìwà òǹrorò.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
◻ Ìlú Ńlá Òde Òní
• Ìlú Ńlá Ìgbàanì
Danube
SÍKÍTÍÀ
• Kiev ← OJÚ Ọ̀NÀ ÌṢÍKIRI
Dnieper
Dniester
Òkun Dúdú
OSSETIA
Àwọn Òkè Ńlá Caucasus
Òkun Caspian
ÁSÍRÍÀ ← OJÚ Ọ̀NÀ ÌGBÓGUN
◻ Nínéfè
Tígírísì
MÍDÍÀ ← OJÚ Ọ̀NÀ ÌGBÓGUN
MESOPOTÁMÍÀ
BABILÓNÍÀ ← OJÚ Ọ̀NÀ ÌGBÓGUN
◻ Bábílónì
Yúfírétì
ILẸ̀ ỌBA PÁṢÍÀ
◻ Súsà
Ìyawọlẹ̀ Omi Páṣíà
PALẸ́SÌNÌ
• Beth-shan (Scythopolis)
ÍJÍBÍTÌ ← OJÚ Ọ̀NÀ ÌGBÓGUN
Náílì
Òkun Mẹditaréníà
GÍRÍÌSÌ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Jagunjagun ni àwọn Síkítíánì
[Credit Line]
The State Hermitage Museum, St. Petersburg
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Síkítíánì fi ọjà wọn ṣe pàṣípààrọ̀ iṣẹ́ ọ̀nà àwọn Gíríìkì, èyí sì sọ wọ́n dolówó rẹpẹtẹ
[Credit Line]
Lọ́lá àṣẹ Ukraine Historic Treasures Museum, Kiev