Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni ìbatisí nítorí àwọn òkú?
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa àjíǹde ti ọ̀run, ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó gba àfiyèsí gan-an. Nínú Bibeli Mimọ, a kà pé: “Njẹ ki ni awọn ti a batisi nitori òkú yoo ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn òkú kò jinde rara? Nitori ki ni a ha ṣe n batisi wọn nitori òkú?” Bíbélì ÌRÒHÌN AYỌ̀ sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Nitori ki ni awọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ń jí àwọn òkú dìde, ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn?”—1Kọ́ríńtì 15:29.
Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí ni pé kí a máa batisí àwọn èèyàn tó wà láàyè nítorí àwọn tó kú láìṣe batisí? Ó jọ bẹ́ẹ̀ lójú ohun tí àwọn ìtumọ̀ yìí àtàwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ. Àmọ́ tá a bá wò ó fínnífínní, Ìwé Mímọ́ àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fi hàn pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé a batisí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí a rì wọ́n bọmi sí ọ̀nà ìgbésí ayé tí yóò yọrí sí ikú tó dà bíi ti Kristi ní ti pé wọ́n á kú nítorí pípá ìwà títọ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, a óò jí wọn dìde sí ìyè tẹ̀mí bíi ti Kristi.
Ìwé Mímọ́ ti àlàyé yìí lẹ́yìn dáadáa. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ara Róòmù, ó sọ́ pé: “Tàbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo wa tí a ti batisí sínú Kristi Jésù ni a batisí sínú ikú rẹ̀?” (Róòmù 6:3) Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ̀ sí àwọn ará Fílípì, ó sọ níbẹ̀ pé òun ní “àjọpín nínú àwọn ìjìyà [Kristi], ní jíjọ̀wọ́ ara [òun] fún ikú tí ó dà bí tirẹ̀, láti rí i bí ọwọ́ [òun] lọ́nàkọnà bá lè tẹ àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú òkú.” (Fílípì 3:10, 11) Pọ́ọ̀lù ń fi hàn pé ìgbésí ayé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró jẹ́ ti pípa ìwà títọ́ mọ́ lábẹ́ àdánwò, tí wọn ń dojú kọ ikú lójoojúmọ́, tí wọ́n á sì wá kú níkẹyìn nítorí pípa ìwà títọ́ mọ́, tí àjíǹde sí ọ̀run yóò sì tẹ̀ lé e.
Ohun tó gba àfiyèsí ni pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a mẹ́nu bà wọ̀nyí àti àwọn mìíràn tó sọ̀rọ̀ nípa ikú àtàwọn tá a ti batisí kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti kú bí kò ṣe nípa àwọn èèyàn tó wà láàyè tí a ti batisí. Pọ́ọ̀lù tún sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “A sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìbatisí rẹ̀, àti pé nípa ìbátan pẹ̀lú rẹ̀, a tún gbé yín dìde pa pọ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ẹni tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú.”—Kólósè 2:12.
Ọ̀rọ̀ atọ́ka èdè Gíríìkì náà hy·perʹ, tí a túmọ̀ sí “nítorí” nínú oríṣiríṣi ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì ní 1 Kọ́ríńtì 15:29, lè tún túmọ̀ sí “fún ète.” Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yòókù, Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun túmọ̀ ẹsẹ 1Kọ 15:29 ìwé yìí lọ́nà tó tọ́ pé: “Kí ni àwọn tí a ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú yóò ṣe? Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá, èé ṣe tí a fi ń batisí wọn pẹ̀lú fún ète jíjẹ́ bẹ́ẹ̀?”