ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 10/15 ojú ìwé 3
  • Ṣíṣe Ìpinnu Jẹ́ Ohun Tí Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Ìpinnu Jẹ́ Ohun Tí Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Ìgbàgbọ́ —Kó O Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Máa Fi Ọgbọ́n Ṣe Ìpinnu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 10/15 ojú ìwé 3

Ṣíṣe Ìpinnu Jẹ́ Ohun Tí Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀

OLÚ ỌBA ilẹ̀ Faransé ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Napoleon Bonaparte sọ nígbà kan rí pé: “Kò sí ohun tó ṣòro tó kéèyàn mọ bá a ṣe ń ṣèpinnu, kò sì sí ohun tó ṣeyebíye tó kéèyàn lè ṣèpinnu.” Ó ṣeé ṣe kó o fara mọ́ ohun tí olú ọba yìí sọ nípa ìpinnu, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ káwọn ẹlòmíràn bá wọn ṣèpinnu. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n gbà pé àwọn ìgbà mìíràn wà tí kì í rọrùn rárá láti ṣèpinnu.

Bóyá ó rọrùn tàbí kò rọrùn, a ò le ṣe ká má ṣèpinnu. Ojoojúmọ́ là ń ṣèpinnu. Bá a bá jí láàárọ̀, ó di dandan ká pinnu aṣọ tá a fẹ́ wọ̀, ohun tá á fẹ́ jẹ láàárọ̀, àti bí à ó ṣe ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ohun mìíràn lọ́jọ́ yẹn. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìpinnu wọ̀nyí ni kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Bóyá la tiẹ̀ máa ń tún irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ rò lẹ́ẹ̀mejì. Irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tó lè dá oorun mọ́ni lójú téèyàn á wá máa rò ó bóyá wọ́n dára tàbí wọn kò dára.

Nígbà míì sì rèé, àwọn ìpinnu mìíràn gba kéèyàn ronú lórí wọn jinlẹ̀jinlẹ̀. Nínú ayé lónìí, àwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí wọ́n á máa lépa nínú ìgbésí ayé wọn. Ó yẹ kí wọ́n lè pinnu irú ẹ̀kọ́ tí wọ́n fẹ́ kọ́ nílé ìwé àti bí wọ́n ṣe fẹ́ kàwé tó. Nígbà tó bá yá, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn á pinnu bóyá wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tàbí wọ́n fẹ́ máa bá a lọ láìṣègbéyàwó. Àwọn tó bá pinnu láti ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ pinnu pé: ‘Ṣé mo ti tó ẹní tó lè ṣègbéyàwó? Irú ẹni wo ló wù mí, tàbí ní pàtàkì, irú ẹni wo ló máa wúlò fún mi?’ Ṣàṣà ni ìpinnu tó lágbára lórí ìgbésí ayé wa bíi ti yíyan ẹní tá a fẹ́ẹ́ fẹ́.

A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nínú àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì, nítorí pé àwọn ìpinnu tá a bá ṣe ló máa sọ wa di aláyọ̀. Àwọn kan lè rò pé, àwọn lè dá ṣèpinnu àti pé àwọn ò nílò ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni. Ǹjẹ́ ìyẹn mọ́gbọ́n dání? Ẹ jẹ́ ká gbé e yẹ̀ wò.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Napoleon: Láti inú ìwé The Pictorial History of the World

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́