ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 1/15 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Ìlérí Tó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìlérí Tó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan . . . Tí Ó Kùnà”
  • Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
  • Àwọn Ìlérí Tó Máa Nímùúṣẹ Nínú Párádísè
  • A Óò Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Títí Láé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Ní Ìrètí Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kí Ni Jèhófà Ń Retí Pé Ká Máa Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 1/15 ojú ìwé 4-7

Àwọn Ìlérí Tó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

MÍKÀ tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run mọ̀ pé ìlérí àwọn èèyàn kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Kódà, nígbà ayé rẹ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kì í fìgbà gbogbo gba ara wọn gbọ́. Nítorí náà, Míkà kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú alábàákẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ àfinúhàn. Ṣọ́ líla ẹnu rẹ lọ́dọ̀ obìnrin tí ń dùbúlẹ̀ ní oókan àyà rẹ.”—Míkà 7:5.

Ǹjẹ́ Míkà jẹ́ kí ipò búburú yìí mú òun ṣiyèméjì nípa gbogbo ìlérí? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀! Ó fi hàn pé gbogbo ọkàn lòun fi gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ṣe. Míkà kọ̀wé pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7.

Kí nìdí tí Míkà fi ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó mọ̀ pé Jèhófà máa ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Gbogbo ohun tí Ọlọ́run búra pé òun máa ṣe fún àwọn baba ńlá Míkà ló ṣe. (Míkà 7:20) Bí Jèhófà ṣe jẹ́ awímáyẹhùn látẹ̀yìn wá ló fi Míkà lọ́kàn balẹ̀ láti gbà pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.

“Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan . . . Tí Ó Kùnà”

Bí àpẹẹrẹ, Míkà mọ̀ pé Jèhófà ló gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Míkà 7:15) Jóṣúà tó wà níbẹ̀ nígbà tá a dá wọn nídè, gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ìlérí Ọlọ́run. Nítorí kí ni? Jóṣúà rán wọn létí pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣúà 23:14.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ dáadáa pé Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun àrà fún wọn. Ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù baba ńlá wọn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run pé irú ọmọ rẹ̀ yóò di púpọ̀ bí ìràwọ̀ àti pé àwọn ọmọ yẹn ni yóò ni ilẹ̀ Kénáánì. Jèhófà tún sọ fún Ábúráhámù pé àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò jìyà fún odindi irinwó ọdún [400], ṣùgbọ́n wọn yóò padà sí Kénáánì “ní ìran kẹrin.” Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 15:5-16; Ẹ́kísódù 3:6-8.

Nígbà ayé Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù, àwọn ará Íjíbítì gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tó yá, ńṣe làwọn ará Íjíbítì sọ wọ́n dẹrú tí wọ́n sì ń mú wọn sìn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí Ọlọ́run, ìran kẹrin sí èyí tó bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti dé Íjíbítì kò kọjá táwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù wọ̀nyí fi bọ́ kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ará Íjíbítì.a

Jálẹ̀ ogójì ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún rí ẹ̀rí síwájú sí i pé Jèhófà máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà táwọn ará Ámálékì gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láìnídìí, Ọlọ́run jà fún àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì dáàbò bò wọ́n. Gbogbo ohun tí wọ́n nílò nígbà tí wọ́n ń rìn nínú aginjù fún ogójì ọdún ló pèsè fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló tún pèsè ohun tí wọ́n nílò nígbà tó yá tí wọ́n wá fàbọ̀ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Nígbà tí Jóṣúà ń rántí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù yìí, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.”—Jóṣúà 21:45.

Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà

Gẹ́gẹ́ bíi Míkà àti Jóṣúà ti ṣe, báwo lo ṣe lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Jèhófà? Ó dára, báwo lo ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé ẹlòmíràn? Ó dájú pé wàá gbìyànjú láti lè mọ wọ́n dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí bí wọ́n ṣe máa ń sa gbogbo ipá wọn láti mú ìlérí wọn ṣẹ, wàá lè mọ bí wọ́n ti ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó. Bó o ṣe ń mọ àwọn èèyàn yẹn dáadáa sí i, wàá máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn díẹ̀díẹ̀. O lè ṣe bákan náà, tó o bá fẹ́ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run.

Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe èyí ni nípa ríronú jinlẹ̀ lórí àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá àtàwọn òfin tó ń ṣàkóso wọn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òfin wọ̀nyí, bí irú òfin tó ń ṣàkóso bí sẹ́ẹ̀lì kan ṣoṣo nínú ara ènìyàn ṣe ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí ẹgbàágbèje àwọn sẹ́ẹ̀lì tó para pọ̀ di odindi ẹnì kan. Ká sòótọ́, àwọn òfin tó ń ṣàkóso bí àwọn nǹkan ṣe ń ṣẹlẹ̀ àti agbára tó so ilé ayé ró fi hàn pé Olófin kan tó ṣeé gbára lé ló ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn òfin tó ń ṣàkóso ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó yẹ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí rẹ̀ pẹ̀lú.—Sáàmù 139:14-16; Aísáyà 40:26; Hébérù 3:4.

Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà tí òun àti Míkà jọ gbé ayé lákòókò kan náà, Jèhófà lo ìgbà tí kì í tàsé àti àgbàyanu àyípoyípo omi láti ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó. Ọdọọdún ni òjò máa ń rọ̀. Òjò yẹn á rin ilẹ̀ gbingbin, á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe láti gbin nǹkan àti láti kórè yanturu. Jèhófà sọ nípa èyí pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:10, 11.

Àwọn Ìlérí Tó Máa Nímùúṣẹ Nínú Párádísè

Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Ọlọ́run dá lè jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá, ṣùgbọ́n a nílò jù ìyẹn lọ bá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí tó jẹ́ ara “ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu [rẹ̀] jáde.” To o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlérí wọ̀nyí kí o bàa lè gbẹ́kẹ̀ lé wọn, ó gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun tó ń ṣe fún ìràn ènìyàn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí.—2 Tímótì 3:14-17.

Wòlíì Míkà gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Jèhófà. Kódà, àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ ju èyí tí Míkà ní lọ. Bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń ṣàṣàrò le é lórí, ìwọ náà á lè ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ń ṣẹ. Kì í ṣe àwọn tí Ábúráhámù bí nìkan ni ìlérí yìí kàn o, ó tún kan gbogbo ìràn ènìyàn lápapọ̀. Jèhófà ṣèlérí fún baba ńlá tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà náà jẹ́ apá pàtàkì lára “irú-ọmọ,” tàbí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù.—Gálátíà 3:16.

Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi bù kún ìràn ènìyàn onígbọràn. Kí wá ni Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò ṣe lákòókò wa? Míkà 4:1, 2 fi àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ yìí dáhùn pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’”

Gbogbo àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà Jèhófà ló ń ‘fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn sì ń fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.’ Ẹ̀mí ogun jíjà yóò pòórá. Láìpẹ́, kìkì àwọn adúróṣinṣin ni yóò kún inú ayé, kò sì ní sí ẹni tí yóò máa mú wọn wárìrì nínú ìbẹ̀rù mọ́. (Míkà 4:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù Kristi yóò ṣàkóso, Jèhófà yóò pa gbogbo àwọn aninilára run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 11:6-9; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 11:18.

Kódà gbogbo àwọn tó ti jìyà tó sì ti kú látàrí ọ̀tẹ̀ táwọn èèyàn dì sí Ọlọ́run là óò jí dìde, tí wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (Jòhánù 5:28, 29) Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tó wà nídìí ìwà láabi yóò ti pòórá, ẹbọ ìràpadà Jésù yóò wá mú gbogbo àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò. (Mátíù 20:28; Róòmù 3:23, 24; 5:12; 6:23; Ìṣípayá 20:1-3) Kí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn èèyàn onígbọràn? Ó dájú pé a óò fi ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìlera pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé jíǹkí wọn!—Sáàmù 37:10, 11; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3-5.

Àwọn ìlérí yìí mà dára o! Àmọ́, ṣe wọ́n ṣeé gbà gbọ́? Dájúdájú, o lè gbà wọ́n gbọ́. Wọn kì í ṣe ìlérí tí ènìyàn tó ní ohun rere lọ́kàn ṣe ṣùgbọ́n tí kò lágbára láti mú un ṣẹ. Ìlérí Ọlọ́run Olódùmarè ni wọ́n, ẹni tí kò le purọ́ tí kì í sì “fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀.” (2 Pétérù 3:9; Hébérù 6:13-18) O lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì látòkèdélẹ̀ nítorí ọ̀dọ̀ “Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́” ni wọ́n ti wá.—Sáàmù 31:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Insight on the Scriptures, ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 911 àti 912, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.”—Jóṣúà 23:14

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Jèhófà mú àwọn ìlérí tó ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ ní Òkun Pupa àti nígbà tí wọ́n wà láginjù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jèhófà mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Jésù Kristi tó jẹ́ Irú Ọmọ rẹ̀ yóò bù kún ìràn èèyàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́