Bí a Ṣe Ń fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
DÍDI ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn kàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lásán. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé ṣe mọ̀, bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní fún un yóò máa jinlẹ̀ sí i, bá a sì ṣe ń mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtèyí tó kórìíra, tá à ń mọ àwọn ohun tó fara mọ́ àtohun tó fẹ́ ká ṣe, ni ìfẹ́ náà yóò túbọ̀ máa lágbára sí i.
Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí í ṣe Bíbélì, nínú èyí tó ti fi ẹni tí òun jẹ́ hàn. Inú rẹ̀ la ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó ọ̀ràn ní onírúurú ipò. Bíi lẹ́tà tá a gbà látọ̀dọ̀ èèyàn wa kan ṣe máa ń múnú wa dùn, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe ń fúnni láyọ̀ bá a ṣe ń rí àwọn apá tuntun tá a ṣí payá lára ànímọ́ Jèhófà.
Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe sábà máa ń kíyè sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, a rí i pé bí ẹnì kan tiẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, ìyẹn ò ní kí onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jésù sọ fáwọn Júù abaraámóorejẹ tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; . . . ṣùgbọ́n èmi mọ̀ dunjú pé ẹ kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú yín.” (Jòhánù 5:39, 42) Àwọn kan kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un kò tó nǹkan. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn kì í ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó wé mọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn olóòótọ́ èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Kí lò mú kó rí bẹ́ẹ̀? Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ásáfù gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti ṣe. Lọ́nà wo?
Máa Fi Ìmọrírì Ṣàṣàrò
Ásáfù pinnu láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sínú ọkàn ara rẹ̀. Ó kọ ọ́ pé: “Èmi yóò fi ìdàníyàn hàn nínú ọkàn-àyà mi . . . èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sáàmù 77:6, 11, 12) Ìfẹ́ fún Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i nínú ọkàn ẹni tó bá ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀nà Jèhófà gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe.
Láfikún sí i, rírántí àwọn ìrírí dídára tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà yóò mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ sì jọ máa ń ní ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ni. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Nígbà tá a bá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ó máa ń mọyì rẹ̀ èyí sì máa ń mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Nígbà náà, tá a bá wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, tó sì tọ́ wa sọ́nà láti yanjú àwọn ìṣòro kan, èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kò fi wá sílẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún un yóò sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
Àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn méjì túbọ̀ máa ń dára sí i bí wọ́n ṣe ń finú han ara wọn. Bákan náà, nígbà tá a bá sọ ìdí tá a fi ń sin Jèhófà tọkàntọkàn fún un, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ lágbára sí i. A ò rí i pé ohun tí Jésù sọ là ń ṣe, tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Kí ni a lè ṣe láti rí i dájú pé à ń bá a nìṣó ní fífi gbogbo ọkàn-àyà wa, gbogbo ọkàn wa, gbogbo èrò-inú wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Fífi Gbogbo Ọkàn-Àyà Wa Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tó túmọ̀ sí ohun tí ẹnì kan jẹ́ ní inú lọ́hùn ún, ìyẹn àwọn ohun tó máa ń wù ú, ìṣarasíhùwà rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Nítorí náà, fífi gbogbo ọkàn-àyà wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ọ̀ràn èyíkéyìí lọ, ó túmọ̀ sí pé à ń fẹ́ láti ṣe àwọn ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí. (Sáàmù 86:11) Nípa híhu ìwà tí inú rẹ̀ dùn sí ni ó ń fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. À ń sapá láti fara wé Ọlọ́run nípa ‘fífi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú kí a sì rọ̀ mọ́ ohun rere.’—Róòmù 12:9.
Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ń nípa lórí irú ojú tá a fi ń wo gbogbo nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, a lè fẹ́ràn iṣẹ́ tá à ń ṣe gan-an tàbí kó máa gba àfiyèsí wa gan-an, àmọ́ ṣé ibẹ̀ ni ọkàn wa máa ń wà? Rárá o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ọkàn-àyà wa la fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí mú kí jíjẹ́ tá a jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run gba ipò iwájú. Síbẹ̀síbẹ̀, a fẹ́ mú inú àwọn òbí wa dùn, a sì fẹ́ mú inú ọkọ tàbí aya wa àti ọ̀gá wa níbi iṣẹ́ dùn àmọ́ ọ̀nà tí a ó gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn ni pé ká máa ṣe àwọn ohun tí yóò mú inú rẹ̀ dùn. Ó ṣe tán, òun ló yẹ kó gba ipò kìíní nínú ọkàn wa.—Mátíù 6:24; 10:37.
Fífi Gbogbo Ọkàn Wa Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” tọ́ka sí gbogbo ara wa látòkèdélẹ̀ àti ìwàláàyè wa. Nítorí náà, fífi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà túmọ̀ sí pé a ní láti máa fi ìgbésí ayé wa yìn ín, ká sì fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Òótọ́ ni pé a lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan mìíràn ní ìgbésí ayé, irú bíi ká kọ́ṣẹ́, ká ṣòwò tàbí ká ní ìdílé tẹni. Bákan náà, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan bó ṣe fẹ́, tí a sì ń fi àwọn nǹkan yòókù sí àyè tó yẹ wọ́n, nípa bẹ́ẹ̀ à ń “wá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Ohun tí ìjọsìn tá à ń fi gbogbo ọkàn ṣe tún túmọ̀ sí ni pé a ní láti jẹ́ onítara. À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífi ìtara wàásù ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, nípa jíjẹ́ kí ìdáhùn wa nípàdé jẹ́ èyí tí ń gbéni rò tàbí nípa ríran àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́. Nínú ohun gbogbo, ká máa bá a nìṣó ní “ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn.”—Éfésù 6:6.
Jésù fi bí a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn hàn nípa sísẹ́ ara rẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run ló fi ṣáájú, ó wà fi àwọn nǹkan tí ara rẹ̀ sí ipò kejì. Jésù sọ pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24, 25) Ohun tí sísẹ́ ara ẹni túmọ̀ sí ni pé ká ya ara wa sí mímọ́. Èyí fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run débi pé a jọ̀wọ́ ara wa fún un pátápátá, bí ìgbà tí ọmọ Ísírẹ́lì kan lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì ṣe máa fẹ́ràn ọ̀gá rẹ̀ débi pé á fi ara rẹ̀ ṣe ẹrú fún un títí gbére. (Diutarónómì 15:16, 17) Yíya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Fífi Gbogbo Èrò-Inú Wa Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Fífi gbogbo èrò-inú wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà túmọ̀ sí pé à ń ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe láti lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà, àwọn ète rẹ̀ àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ká ṣe. (Jòhánù 17:3; Ìṣe 17:11) À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífi gbogbo agbára àti òye wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí àwọn náà lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti nípa mímú ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i. Àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé, “ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò.” (1 Pétérù 1:13) Bákan náà, à ń sapá láti fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ní pàtàkì àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ó yẹ ká máa kíyè sí ipò wọn, ká mọ ìgbà tó yẹ ká yìn wọ́n tàbí ìgbà tí wọ́n nílò ìtùnú.
À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa nípa títẹríba fún un látọkànwá. Ká máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wo àwọn nǹkan, ká máa ṣàkíyèsí rẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu, ká sì ní ìgbọ́kànlé pé ọ̀nà rẹ̀ ló dára jù lọ. (Òwe 3:5, 6; Aísáyà 55:9; Fílípì 2:3-7) Àmọ́, báwo la ṣe lè lo okun wa bá a ṣe ń bá a nìṣó láti fi ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run hàn?
Fífi Gbogbo Okun Wa Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ Kristẹni ni wọ́n ń fi okun wọn yin Jèhófà. (Òwe 20:29; Oníwàásù 12:1) Ọ̀nà kan tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni gbà ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo okun wọn jẹ́ nípa kíkópa nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ọlọ́mọ ló ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí nígbà táwọn ọmọ wọn bá wà nílé ìwé. Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tí àwọn alàgbà olóòótọ́ ń ṣe láfikún sí bíbójú tó ìdílé wọn fi hàn pé gbogbo okun wọn ni wọ́n fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 12:15) Jèhófà máa ń fún àwọn tó ní ìrètí nínú rẹ̀ ní agbára kí wọ́n bàa lè fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i hàn nípa fífi gbogbo okun wọn yìn ín.—Aísáyà 40:29; Hébérù 6:11, 12.
Ìfẹ́ á túbọ̀ pọ̀ sí i tá a bá fi í hàn lọ́nà tí ó tọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wáyè láti máa ṣàṣàrò. Ká máa rántí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa àti ìdí tó fi jẹ́ pé òun ló yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa sìn. Nítorí pé aláìpé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá, kò sí bá a ṣe lè lẹ́tọ̀ọ́ sí “àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,” àmọ́ a lè fi hàn pé tọkàn tara la fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó!—1 Kọ́ríńtì 2:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
À ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tá à ń ṣe