“Ẹrú” Tí ó Jẹ́ Olóòótọ́ Àti Olóye
“Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀?”—MÁTÍÙ 24:45.
1, 2. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé lónìí?
NÍ Ọ̀SÁN ọjọ́ Tuesday Nísàn 11, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì fún wa gan-an lónìí. Wọ́n bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Nínú èsì tí Jésù fún wọn, ó sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan. Ó mẹ́nu bá sáà tí rúkèrúdò ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀ àti àrùn yóò wà. “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà” ni sáà náà yóò jẹ́. Ipò ọ̀hún ṣì máa burú sí i. Áà, ohun tó ń bọ̀ yìí mà ń dáyà foni o!—Mátíù 24:3, 7, 8, 15-22; Lúùkù 21:10, 11.
2 Láti ọdún 1914 wá, ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ló ti ní ìmúṣẹ. “Ìroragógó wàhálà” tó dé bá aráyé kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa bẹ̀rù. Ó ṣe tán, Jésù ṣèlérí pé òun yóò máa fi oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ bọ́ wọn. Nísinsìnyí tí Jésù ti wà lọ́run, ètò wo ló ṣe kí àwa tá a wà lórí ilẹ̀ ayé lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé?
3. Ètò wo ní Jésù ti ṣe kí a lè máa rí ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ gbà?
3 Jésù fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn. Nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá yìí, ó béèrè pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?” Ó wá sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mátíù 24:45-47) Bẹ́ẹ̀ ni o, “ẹrú” kan yóò wà tá a ti yàn láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, “ẹrú” náà yóò jẹ́ olóòótọ́ àti olóye. Àmọ́, ṣé ẹnì kan ṣoṣo ni ẹrú tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí tàbí ẹnì kan tó wà fún sáà àkókò kan tí ẹlòmíràn á sì tún gba ipò rẹ̀ tàbí ohun mìíràn ni ó jẹ́? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ oúnjẹ tá a nílò ni ẹrú olóòótọ́ yìí ń fún wa, àǹfààní ńlá ni yóò jẹ́ fún wa láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn.
Ṣé Ẹnì Kan Ṣoṣo Ni Ẹrù Yìí àbí Ẹgbẹ́ Kan?
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kò lè jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo?
4 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yìí kò lè jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rúndún kìíní ni ẹrú yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí Jésù sì ti wí, ẹrú náà á ṣì máa bá iṣẹ́ náà lọ nígbà tí Ọ̀gá rẹ̀ dé ní ọdún 1914. Èyí á wá jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbàá dín ní ọgọ́rùn-ún [1,900] ọdún ni ẹnì kan ṣoṣo fi fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn. Kódà Mètúsélà pàápàá ò lo ọdún tó tóyẹn láyé!—Jẹ́nẹ́sísì 5:27.
5. Ṣàlàyé ìdí tí a kò fi lo ọ̀rọ̀ náà “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fún Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
5 Nígbà náà, ṣé a lè wá lo ọ̀rọ̀ náà “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fún Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Òótọ́ ni pé gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ àti olóye; àmọ́ ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù ní lọ́kàn jùyẹn lọ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Báwo la ṣe mọ̀? Nítorí ó sọ pé ‘nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé’ yóò yan ẹrú náà sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” Báwo la ṣe lè yan Kristẹni kọ̀ọ̀kan sípò lórí gbogbo nǹkan, ìyẹn lórí “gbogbo” nǹkan ìní Olúwa? Kò lè ṣeé ṣe láé!
6. Ọ̀nà wo la ní kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbà jẹ́ “ìránṣẹ́” tàbí “ẹrú” fún Ọlọ́run?
6 Ohun tó máa bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí ni pé, àwùjọ àwọn Kristẹni kan ni Jésù pè ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ǹjẹ́ irú ẹgbẹ́ tí kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo gíro bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè wà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún ṣáájú ìgbà tí Kristi wá sáyé, Jèhófà pe gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní “ẹlẹ́rìí mi” àti “ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.” (Aísáyà 43:10) Gbogbo àwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìyẹn láti ìgbà tá a pèsè Òfin Mósè títí di Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, jẹ́ ara ẹgbẹ́ ìránṣẹ́ yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kì í kópa nínú bíbójútó ètò orílẹ̀-èdè náà ní tààràtà tàbí kí wọ́n máa ṣe kòkáárí báwọn èèyàn á ṣe rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. Àwọn ọba, onídàájọ́, wòlíì, àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ni Jèhófà lò láti ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn. Síbẹ̀, Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan ní láti ṣojú fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, kí wọn sì máa sọ ìyìn rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì ní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà.—Diutarónómì 26:19; Aísáyà 43:21; Málákì 2:7; Róòmù 3:1, 2.
Wọ́n Gbaṣẹ́ Lọ́wọ́ “Ìránṣẹ́” Kan
7. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò tóótun mọ́ gẹ́gẹ́ bí “ìránṣẹ́” Ọlọ́run?
7 Níwọ̀n bí Ísírẹ́lì ti jẹ́ “ìránṣẹ́” Ọlọ́run fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ṣé òun tún ni ẹrú náà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Rárá o, nítorí pé nígbà tó ṣe Ísírẹ́lì ìgbàanì kò jẹ́ olóòótọ́ àti olóye mọ́. Pọ́ọ̀lù ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà nígbà tó fa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún orílẹ̀ èdè náà yọ, ó ní: “Orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 2:24) Ìwà ọ̀tẹ̀ tí Ísírẹ́lì ti ń hù látọjọ́ pípẹ́ dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ Jésù sílẹ̀, ìgbà yẹn gan-an ni Jèhófà wá kọ̀ wọ́n sílẹ̀.—Mátíù 21:42, 43.
8. Ìgbà wo la yan “ìránṣẹ́” tó gbapò Ísírẹ́lì, kí sì ni àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lákòókò náà?
8 Ìwà àìṣòótọ́ tí orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ “ìránṣẹ́” náà hù, kò túmọ̀ sí pé àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ jọ́sìn kò ní rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà mọ́ láé. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ìyẹn àádọ́ta ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde Jésù, a tú ẹ̀mí mímọ́ sórí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà nínú yàrà òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Bí a ṣe bí orílẹ̀-èdè tuntun kan nìyẹn. Ìròyìn nípa ìbí orílẹ̀-èdè náà sì tàn kálẹ̀ nígbà tí àwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà sọ “ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” fún àwọn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:11) Nípa bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè tuntun yẹn tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, di “ìránṣẹ́” tí yóò máa polongo ògo Jèhófà fáwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì máa pèsè oúnjẹ ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (1 Pétérù 2:9) Nígbà tó yá, wọ́n wá ń pè orílẹ̀-èdè náà ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” orúkọ náà sì bá mu wẹ́kú.—Gálátíà 6:16.
9. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (b) Àwọn wo ni “àwọn ará ilé”?
9 Olúkúlùkù àwọn tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” jẹ́ Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó ti ṣe ìrìbọmi, tí a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, tó sì ní ìrètí ti ọ̀run. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tọ́ka sí gbogbo àwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò èyíkéyìí, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di ìsinsìnyí. Wọ́n jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ́nà kan náà tí olúkúlùkù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà láàyè láàárín ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa sí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa gbà jẹ́ ara ẹgbẹ́ ìránṣẹ́ tó wà ṣáájú ìgbà Kristẹni. Àmọ́, àwọn wo wá ni “àwọn ara ilé,” tí wọ́n ń gba oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ látọ̀dọ̀ ẹrú náà? Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, gbogbo àwọn Kristẹni ló ń retí àtilọ sọ́run. Èyí fi hàn pé, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló tún jẹ́ àwọn ará ilé náà, ìyẹn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan. Gbogbo wọn pátá, títí kan àwọn tí wọ́n wà ní ipò àbójútó nínú ìjọ nílò oúnjẹ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ ẹrú náà.—1 Kọ́ríńtì 12:12, 19-27; Hébérù 5:11-13; 2 Pétérù 3:15, 16.
“Ó fún Olúkúlùkù Ní Iṣẹ́ Rẹ̀”
10, 11. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú náà ló ni irú iṣẹ́ kan náà?
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà, wọ́n ní iṣẹ́ tá a yàn fún wọn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn tún ní ojúṣe ti ara rẹ̀ láti bójú tó. Ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Máàkù 13:34 mú kí èyí ṣe kedere. Ó sọ pé: “Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó ń rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ọlá àṣẹ fún àwọn ẹrú rẹ̀, tí ó fún olúkúlùkù ní iṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì pàṣẹ fún olùṣọ́nà láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Olúkúlùkù àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú náà ti gba iṣẹ́ kan, ìyẹn iṣẹ́ sísọ àwọn nǹkan ìní tí Kristi ní lórí ilẹ̀ ayé di púpọ̀. Olúkúlùkù wọn ń ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ibi tí agbára wọn mọ àti bí àǹfààní tí wọ́n ní ṣe mọ.—Mátíù 25:14, 15.
11 Síwájú sí i, àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pétérù 4:10) Nítorí náà, ojúṣe àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn ni láti fi àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn ṣe ìránṣẹ́ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Síwájú sí i, àwọn ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ fi hàn pé kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló máa ní agbára àti òye, ẹrù iṣẹ́ tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan náà. Àmọ́ ṣá o, olúkúlùkù àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú náà lè ṣèrànwọ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn láti mú kí orílẹ̀-èdè tẹ̀mí náà túbọ̀ gbòòrò sí i. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é?
12. Ọ̀nà wo ni àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin ṣe ń mú kí ẹgbẹ́ ẹrú náà gbèrú sí i?
12 Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Aísáyà 43:10-12; Mátíù 24:14) Kété ṣáájú kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó pàṣẹ fún gbogbo àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kùnrin lóbìnrin pé kí wọ́n máa kọ́ni. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:19, 20.
13. Àǹfààní wo ní gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ní?
13 Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àwọn kan di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n ní láti kọ́ wọn láti pa gbogbo ohun tí Kristi pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn tó gbẹ̀kọ́ lára wọn tóótun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ là ń pèsè fáwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́kùnrin lóbìnrin ló ń kópa nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 2:17, 18) Iṣẹ́ yìí sì ní láti máa bá a lọ látìgbà tí ẹrú náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ títí di òpin ètò àwọn nǹkan yìí.
14. Àwọn wo la fi àǹfààní kíkọ́ni nínú ìjọ mọ sọ́dọ̀ rẹ̀, báwo ni ọ̀rọ̀ náà sì ṣe rí lára àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró?
14 Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tó jẹ́ ẹni àmì òróró di ara ẹrú yìí, láìka ẹni tó kọ́kọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí, wọ́n gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ àwọn ara ìjọ tó dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí àgbà ọkùnrin. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:6-9) Èyí fún àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò wọ̀nyí láǹfààní láti mú kí orílẹ̀-èdè náà gbèrú sí i lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró kò bínú pé àwọn Kristẹni ọkùnrin nìkan ni wọ́n yàn láti máa kọ́ni nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 14:34, 35) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni inú wọn ń dùn pé àwọn ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ tí àwọn ọkùnrin inú ìjọ ń ṣe, wọ́n sì mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí àwọn obìnrin ní, títí kan mímú ìhìn aláyọ̀ tọ àwọn èèyàn lọ. Bákan náà lónìí, àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ń fi irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn, yálà àwọn alàgbà tá a yàn sípò jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró.
15. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì tí àwọn èèyàn ń gbà rí oúnjẹ tẹ̀mí ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn wo ló sì ń mú ipò iwájú nínú ìpèsè náà?
15 Pàtàkì oúnjẹ tẹ̀mí tí àwọn èèyàn ń rí gbà ní ọ̀rúndún kìíní wá tààràtà látinú àwọn ìwé tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mìíràn tó ń mú ipò iwájú kọ. Àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ yìí—ní pàtàkì àwọn tó wà lára àwọn ìwé onímìísí mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì—ni a pín fún àwọn ìjọ, ó sì dájú pé ìwọ̀nyí ni àwọn alàgbà ìjọ wọ̀nyẹn ń lò láti kọ́ni. Àwọn tí ń ṣojú fún ẹrú olóòótọ́ náà ń tipa báyìí pín oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ fún àwọn Kristẹni olóòótọ́. Ẹgbẹ́ ẹrú tó wà ní ọ̀rúndún kìíní fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
Ipò Tí “Ẹrú” Náà Wà Ní Ọ̀rúndún Mọ́kàndínlógún Lẹ́yìn Ìgbà Náà
16, 17. Ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà gbà fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láti àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá títí di ọdún 1914?
16 Lónìí ńkọ́? Nígbà tí wíwàníhìn-ín Jésù bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, ǹjẹ́ ó rí ẹgbẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ pèsè oúnjẹ ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Ó dájú pé ó rí i. Èèyàn lè dá ẹgbẹ́ yìí mọ̀ ní kedere nípa àwọn èso rere tó ń mú jáde. (Mátíù 7:20) Àwọn ohun tó sì ti ṣẹlẹ̀ látìgbà náà wá fi hàn pé lóòótọ́ wọ́n ń mú èso rere jáde.
17 Nígbà tí Jésù dé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn tó jẹ́ ará ilé ni ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ sísọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn níbi gbogbo. Àwọn òṣìṣẹ́ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún, àmọ́ ẹrú náà dá àwọn ọgbọ́n kan láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀. (Mátíù 9:38) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣètò láti gbé ìwàásù tó dá lórí ọ̀rọ̀ Bíbélì jáde nínú ìwé ìròyìn tí ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì. Lọ́nà yìí, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ ẹgbẹẹgbàárùn-ún èèyàn tó ń ka àwọn ìwé ìròyìn yìí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ oníwákàtí mẹ́jọ tó jẹ́ àwòrán ara ògiri àti sinimá. Iṣẹ́ tí ọ̀nà ìgbàkọ́ni tuntun yẹn ṣe kò kéré, ó jẹ́ kí àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà Ìṣẹ̀dá sí òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí àpapọ̀ wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ní ibi mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé. Ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún gbà tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀ ni ìwé títẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1914, nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] irú ẹ̀dà ìwé ìròyìn tó o mú lọ́wọ́ yìí ní wọ́n tẹ̀ jáde.
18. Ìgbà wo ní Jésù yan ẹrú náà sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀, kí sì nìdí tó fi yàn án?
18 Nígbà tí Ọ̀gá náà dé, ó ri pé tọkàntọkàn ni ẹrú rẹ̀ olóòótọ́ fi ń fún àwọn ará ilé ní oúnjẹ, àti pé gbogbo ọkàn ló fi ń wàásù ìhìn rere náà. Wàyí o, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni ẹrú yìí ń bọ̀ wá bójú tó. Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mátíù 24:47) Jésù ṣe èyí ní ọdún 1919, ìyẹn lẹ́yìn tí ẹrú náà ti la sáà ìdánwò kọjá. Àmọ́, kí nìdí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi ní ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i? Ìdí ni pé àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà ti pọ̀ sí i. A gbé Jésù gorí ìtẹ́ ní ọdún 1914.
19. Ṣàlàyé ọ̀nà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” gbà ń rí àbójútó nípa tẹ̀mí.
19 Kí ni àwọn nǹkan ìní tí Ọ̀gá tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ládé yìí yan ẹrú olóòótọ́ ṣe olórí wọn? Ìyẹn ni gbogbo àwọn nǹkan tẹ̀mí tó jẹ́ ti Ọ̀gá náà lórí ilẹ̀ ayé. Bí àpẹẹrẹ, ogún ọdún lẹ́yìn tí Kristi gorí ìtẹ́ ní ọdún 1914 ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” wá sójú táyé. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àwọn wọ̀nyí kò sí lára àwọn ẹni àmì òróró ti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” àmọ́ wọ́n jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí wọ́n ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà wọ́n sì fẹ́ láti máa sìn ín bí àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń ṣe. Lẹ́nu kan, wọ́n ń sọ fáwọn “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sekaráyà 8:23) Oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ kan náà tí àwọn ará ilé tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń jẹ làwọn Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà ń jẹ, àtìgbà yẹn wá ni ẹgbẹ́ méjèèjì sì ti jọ ń jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí yìí. Ìbùkún gbáà ni èyí jẹ́ fáwọn tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá”!
20. Ipa wo ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ń kó nínú mímú kí àwọn nǹkan ìní Olúwa pọ̀ sí i?
20 Tayọ̀tayọ̀ ni àwọn tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” fi dara pọ̀ mọ ẹgbẹ́ ẹrú tó jẹ́ ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. Bí wọ́n ṣe ǹ wàásù, àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà lórí ilẹ̀ ayé ń pọ̀ sí i, èyí sì ń fi kún ẹrù iṣẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Nítorí pé iye àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ń pọ̀ sí i, ó wá pọn dandan pé ká fi kún àwọn ilé ìtẹ̀wé kí gbogbo àwọn tó ń fẹ́ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bàa lè rí wọn gbà. A dá ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. A rán àwọn míṣọ́nnárì jáde lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún tí iye àwọn ẹni àmì òróró jẹ́ ní ọdún 1914, ó ti wá lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó fi ń ìyìn fún Ọlọ́run lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sì jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn nǹkan ìní Ọba náà ti wá pọ ní ìlọ́po-ìlọ́po látìgbà tó ti gorí ìtẹ́ ní ọdún 1914!
21. Àwọn àkàwé méjì wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tó kàn?
21 Gbogbo èyí fi hàn pé ẹrú náà jẹ́ “olóòótọ́ àti olóye.” Kété lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ó ṣe àkàwé méjì tó gbé àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn yọ: àkàwé nípa àwọn wúńdíá olóye àti òmùgọ̀ àti àkàwé nípa tálẹ́ńtì. (Mátíù 25:1-30) Èyí mà mú inú wa dùn gan-an o! Àmọ́, kí ni àwọn àkàwé yìí túmọ̀ sí fún wa lónìí? A óò dáhùn ìbéèrè yìí ní àpilẹ̀kọ tó kàn.
Kí Ni Èrò Rẹ?
• Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”?
• Àwọn wo ni “àwọn ará ilé”?
• Ìgbà wo ni a yan ẹrú olóòótọ́ sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní Olúwa, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà yẹn ni?
• Àwọn wo ló ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn nǹkan ìní Olúwa pọ̀ sí i láti àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sí àkókò tá wà yìí, ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ṣe é?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹgbẹ́ ẹrú ti ọ̀rúndún kìíní fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀