Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
NÍGBÀ tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí wọ́n ṣe ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ó kọ ọ́ pé: “Lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti gba èyíinì tí èmi pẹ̀lú fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú ìṣù búrẹ́dì ní òru tí a ó fi í léni lọ́wọ́, àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú, ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ti ife náà pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: ‘Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.”—1 Kọ́ríńtì 11:23-26.
Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà lọ́lẹ̀ “ní òru” ọjọ́ tí Júdásì Ísíkáríótù yóò ‘fi Jésù lé’ àwọn aṣáájú ìsìn Júù lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tó fínná mọ́ àwọn ará Róòmù pé kí wọ́n kan Kristi mọ́gi. Alẹ́ ọjọ́ Thursday March 31, ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni wọ́n jẹ oúnjẹ yìí. Jésù kú sórí òpó igi oró ní ọ̀sán Friday, April 1. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bí àwọn Júù ṣe máa ń ka ọjọ́ lórí kàlẹ́ńdà wọn ni pé ọjọ́ kan á bẹ̀rẹ̀ láti alẹ́ ọjọ́ kìíní sí alẹ́ ọjọ́ kejì, ó túmọ̀ sí pé ọjọ́ kan náà tí ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa wáyé ni Jésù Kristi kú, ìyẹn Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Tiwa.
Àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì náà ní láti “máa ṣe èyí” ní ìrántí Jésù. (1 Kọ́ríńtì 11:24) A tún máa ń pe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣe Ìrántí Ikú Jésù?
Òye ohun tí ikú Jésù dúró fún á jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Jésù mú ipò iwájú nínú dídúró ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ títí dójú ikú. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú Sátánì ní òpùrọ́ nítorí ẹ̀sùn tó fi ń kanni pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú wa sin Ọlọ́run. (Jóòbù 2:1-5; Òwe 27:11) Nípasẹ̀ ikú tí Jésù kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, ó tún “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Nígbà tí Ádámù ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ó pàdánù ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé àtàwọn nǹkan tí ì bá gbádùn. Àmọ́ “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [ìran ènìyàn] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Lóòótọ́, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.
Nípa bẹ́ẹ̀, ikú Jésù Kristi wé mọ́ ìfẹ́ méjì tó ga jù lọ tá a tíì fi hàn rí, ìyẹn ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí aráyé nípa fífi Ọmọ rẹ̀ fúnni àti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù fi hàn sí aráyé nípa yíyọ̀ǹda tinútinú láti fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀. Ṣíṣe Ìrántí Ikú Jésù ń gbé ìfẹ́ méjì tó ga jù lọ yìí lárugẹ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwa ni wọ́n fi ìfẹ́ yìí hàn sí, ǹjẹ́ kò yẹ ká fi ìmọrírì wà hàn? Ọ̀nà kan tá a sì lè gbà fi hàn pé a mọrírì rẹ̀ ni pé ká wá sí ibi tá a ti máa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà.
Ìjẹ́pàtàkì Búrẹ́dì àti Wáìnì Náà
Nígbà tí Jésù ń fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, ìṣù búrẹ́dì àti ife wáìnì ni ó lò gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ. Jésù mú ìṣù búrẹ́dì, àti pé “lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú, ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín.’” (1 Kọ́ríńtì 11: 24) Wọ́n ní láti bu búrẹ́dì náà kí ó lè ṣeé pín fún àwọn tó máa jẹ ẹ́ nítorí pé ìṣù búrẹ́dì tó ṣe é bú ni, ìyẹ̀fun àti omi ni wọ́n fi ṣe é láìlo ìwúkàrà kankan. Nínú Ìwé Mímọ́, ìwúkàrà dúrò fún ẹ̀ṣẹ̀. (Mátíù 16:11, 12; 1 Kọ́ríńtì 5:6, 7) Jésù kì í sì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé ni ohun tó dára jù lọ láti fi ṣe ẹbọ ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. (1 Jòhánù 2:1, 2) Ó mà bá a mu gan-an o pé búrẹ́dì aláìwú la fi ṣàpẹẹrẹ ara Kristi aláìlẹ́ṣẹ̀!
Jésù tún dúpẹ́ nítorí ife wáìnì pupa tí kò lábùlà náà, ó sì wí pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi.” (1 Kọ́ríńtì 11:25) Wáìnì pupa tó wà nínú ife náà dúró fún ẹ̀jẹ̀ Jésù. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ewúrẹ́ tó wà fún ìrúbọ ṣe mú kí májẹ̀mú Òfin tó wà láàárín Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀jẹ̀ Jésù tá a tú jáde nínú ikú ṣe mú kí májẹ̀mú tuntun náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Àwọn Wo Ló Yẹ Kó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Náà?
Láti lè mọ àwọn tó yẹ kó jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí, a ní láti lóye ohun tí májẹ̀mú tuntun náà jẹ́, ká sì mọ àwọn tó wà nínú májẹ̀mú náà. Bíbélì sọ pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun . . . èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi. . . . Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.’”—Jeremáyà 31:31-34.
Májẹ̀mú tuntun náà mú kó ṣeé ṣe láti ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Àwùjọ èèyàn kan tipa májẹ̀mú yìí di èèyàn Ọlọ́run, òun náà sì di Ọlọ́run wọn. A kọ òfin Jèhófà sínú wọn, nínú ọ̀kan wọn, kódà àwọn tí kò sí lára àwọn Júù tó ń dádọ̀dọ́ pàápàá lè wọnú májẹ̀mú àjọṣe tuntun náà pẹ̀lú Ọlọ́run. (Róòmù 2:29) Lúùkù tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì kọ̀wé nípa ète Ọlọ́run láti ‘yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.’ (Ìṣe 15:14) Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú 1 Pétérù 2:10, wọn “kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí [wọ́n] jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.” Nínú Ìwé Mímọ́, a pè wọ́n ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Gálátíà 6:16; 2 Kọ́ríńtì 1:21) Nígbà náà, májẹ̀mú tuntun yìí jẹ́ májẹ̀mú láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì tẹ̀mí.
Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kẹ́yìn, òun náà bá wọn dá májẹ̀mú kan tó yàtọ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:29) Èyí ni májẹ̀mú Ìjọba náà. Iye àwọn èèyàn aláìpé tá a bá dá májẹ̀mú Ìjọba yìí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Lẹ́yìn tá a bá sì ti jí wọn dìde sí ọ̀run, wọn yóò máa bá Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá Jèhófà Ọlọ́run wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ló tún bá Jésù Kristi wà nínú májẹ̀mú Ìjọba. Àwọn nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Báwo làwọn tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí ṣe máa mọ̀ pé àwọn ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n á sì mọ̀ pé àwọn jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí [mímọ́] tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa [ọkàn wa lọ́hùn ún] pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.”—Róòmù 8:16, 17.
Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tàbí ipa ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti fòróró yàn àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. Èyí mú kó dá wọn lójú pé àwọn jẹ́ ajogún Ìjọba náà. Ó mú kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìrètí ti ọ̀run. Wọ́n gbà pé gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyè ti ọ̀run ló kan àwọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n ṣe tán láti yááfì gbogbo nǹkan tó jẹ́ ti ayé, títí kan ìwàláàyè ti orí ilẹ̀ ayé àti gbogbo àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí yàn mọ̀ pé ìgbésí ayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò lárinrin gan-an, síbẹ̀ èyí kọ́ ni wọ́n fọkàn sí. (Lúùkù 23:43) Kì í ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn tí kò tọ̀nà ló mú kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bá wọn lò, wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run tí kì í yí padà, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí.
Ká sọ pé kò dá ẹnì kan lójú hán-ún pé òun wà nínú májẹ̀mú tuntun náà àti ti májẹ̀mú Ìjọba náà. Ká ní ẹ̀mí Ọlọ́run kò tún bá ẹ̀mí onítọ̀hún jẹ́rìí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ńkọ́? Nígbà náà, kò ní tọ̀nà kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí. Àní, inú Ọlọ́run kò ní dùn rárá tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó gba ìpè ti ọ̀run láti jẹ́ ọba àti àlùfáà nígbà tó sì jẹ́ pé onítọ̀hún kò gba irú ìpè bẹ́ẹ̀.—Róòmù 9:16; Ìṣípayá 22:5.
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe É Léraléra Tó?
Ṣé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí ojoojúmọ́ ló yẹ ká máa ṣe ìrántí ikú Jésù? Kristi fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, wọ́n sì pa á láìṣẹ̀ láìrò ní Ọjọ́ Àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré lọ́dọọdún, ìyẹn ní Nísàn 14 ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá láti rántí ọjọ́ tí Ísírẹ́lì kúrò ní ìgbèkùn àwọn ara Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 12:6, 14; Léfítíkù 23:5) Nítorí náà, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dọọdún ló yẹ ká máa ṣe ìrántí ikú “Kristi ìrékọjá wa,” kì í ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí lójoojúmọ́. (1 Kọ́ríńtì 5:7) Tí àwọn Kristẹni bá sì ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe é nígbà tó fi í lọ́lẹ̀ làwọn náà ń tẹ̀ lé.
Nígbà náà, kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé”? (1 Kọ́ríńtì 11:26) Nínú ẹsẹ yìí, Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “gbogbo ìgbà tí.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó ń sọ pé gbogbo ìgbà tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà, wọ́n á máa polongo ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù.
Ńṣe làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò máa ṣe ìrántí ikú Kristi “títí yóò fi dé.” Ṣíṣe Ìrántí yìí yóò máa bá a nìṣó títí Jésù yóò fi dé láti kó àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ sọ́run nípasẹ̀ àjíǹde sí ìyè ti ẹ̀mí nígbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:14-17) Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Kristi sọ fáwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ adúróṣinṣin pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”—Jòhánù 14:3.
Ǹjẹ́ Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Náà Tiẹ̀ Kàn Ọ́?
Ǹjẹ́ ó pọn dandan pé ká jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí ká tó lè jàǹfààní látinú ìràpadà Jésù ká sì ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé? Rárá o. Kò síbì kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé àwọn èèyàn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Ísákì, Rèbékà, Jósẹ́fù, Mósè àti Dáfídì á jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà lẹ́yìn tá a bá jí wọn dìde sorí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, àwọn àti gbogbo àwọn tó fẹ́ láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi, wọ́n sì ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ti Jèhófà pèsè. (Jòhánù 3:36; 14:1) Kí ìwọ náà bàa lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, o ní láti ní irú ìgbàgbọ́ yẹn. Wíwá tó o bá wá sí ayẹyẹ ìrántí ikú Kristi tá à ń ṣe lọ́dọọdún yóò rán ọ létí ìràpadà ńlá yìí, yóò sì mú kí ìmọrírì tó o ní fún un túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
Àpọ́sítélì Jòhánù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ẹbọ ìràpadà Jésù nígbà tó sọ pé: “Mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín [ẹ̀yìn ẹni àmì òróró ẹlẹ́gbẹ́ mi] kí ẹ má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Àwọn ẹni àmì òróró lè sọ pé ẹbọ ìràpadà Jésù jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn. Àmọ́ ó tún jẹ́ ẹbọ ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe fáwọn tó jẹ́ onígbọràn!
Ṣé wàá wà níbi ayẹyẹ ìrántí ikú Jésù ní April 4, 2004? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ṣayẹyẹ yìí káàkiri ayé ní àwọn ibi ìpàdé wa. Tó o bá wá, wàá jàǹfààní látinú àsọyé pàtàkì kan tá a gbé karí Bíbélì. Wàá tún mọ bí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ṣe fún wa ṣe pọ̀ tó. Á sì tún ṣe ọ́ làǹfààní nípa tẹ̀mí láti pé jọ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run àti Kristi àti fún ẹbọ ìràpadà Jésù. Àṣeyẹ náà sì tún lè mú kí fífẹ́ tó o fẹ́ láti jàǹfààní látinú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, tó ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, túbọ̀ lágbára sí i. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́. Wá sí àṣeyẹ aláyọ̀ tó ń bu ọlá fún Jèhófà, Baba wa ọ̀run, tó sì ń mú inú rẹ̀ dùn yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ikú Jésù wé mọ́ ìfẹ́ méjì tó ga jù lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì náà jẹ́ ohun tó dára láti ṣàpẹẹrẹ ara Jésù tí kò lẹ́ṣẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n tú jáde