ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/1 ojú ìwé 20-23
  • Ǹjẹ́ O Tẹjú Mọ́ Èrè Náà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Tẹjú Mọ́ Èrè Náà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Èrè Náà Sọ́kàn
  • Bí A Ṣe Lè Mú Kí Ojú Tẹ̀mí Wa Ríran Sí I
  • Ẹ Jẹ́ Ká Pọkàn Pọ̀ Bíi Jóṣúà
  • Ní Ìrètí Nínú Jèhófà Kó o Sì Jẹ́ Onígboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Jẹ́ Kí Ìrètí Tó O Ní Dá Ẹ Lójú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Wò Kọjá Ohun Tí O rí!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jèhófà Máa Ń Sẹ̀san fún Àwọn Tó Ń Fi Taratara Wá A
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/1 ojú ìwé 20-23

Ǹjẹ́ O Tẹjú Mọ́ Èrè Náà?

DÍẸ̀DÍẸ̀ ni àìsàn náà máa ń bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, kì í jẹ́ kéèyàn ríran kedere. Bá a bá wá fi í sílẹ̀ láìtọ́jú, àìsàn náà lè ràn dé àárín ojú. Níkẹyìn, ó lè fọ́ èèyàn lójú pátápátá. Kí lórúkọ àìsàn ọ̀hún? Àìsàn Glaucoma ni, òun ni àìsàn tó burú jù lọ nínú àwọn àìsàn tó ń sọ èèyàn dafọ́jú.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ojúyòójú wa lè fọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ojú tó ṣeyebíye, ìyẹn ojú tẹ̀mí wa ṣe lè fọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sọ́kàn.

Fífi Èrè Náà Sọ́kàn

Lára ‘àwọn ohun tí a kò lè fi ojúyòójú wa rí’ ni èrè ìyè àìnípẹ̀kun tó jẹ́ ológo, èyí tí Jèhófà máa fún àwọn tó dúró ṣinṣin tì í. (2 Kọ́ríńtì 4:18) Lóòótọ́, olórí ohun tó ń mú káwọn Kristẹni máa sin Ọlọ́run ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mátíù53 22:37) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ ká máa wo èrè tó wà fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ó fẹ́ ká mọ̀ pé Baba ọlọ́làwọ́ lòun àti pé òun ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Nítorí náà, gbogbo àwọn tó jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n mọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ló mọyì àwọn ìbùkún tó ṣèlérí, wọ́n sì ń fojú sọ́nà láti rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí wọ̀nyẹn.—Róòmù 8:19, 24, 25.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa ń ka ìwé ìròyìn yìí àti ìwé ìròyìn Jí! tó jẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń gbádùn àwọn àwòrán tó ń fi hàn bí Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ yóò ṣe rí. Lóòótọ́, a ò mọ bí Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ yóò ṣe rí gan-an, ńṣe ni àwọn àwòrán wọ̀nyẹn wulẹ̀ ń ṣàpèjúwe ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀, irú bí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 11:6-9. Síbẹ̀, obìnrin Kristẹni kan sọ pé: “Nígbà tí mo bá rí àwòrán Párádísè tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, mo máa ń wò ó fínnífínní, bí ìgbà tẹ́nì kan ń wo ìwé tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ibì kan. Mo máa ń wò ó bíi pé mo ti wà níbẹ̀ ni, nítorí pé ibẹ̀ ni mò fẹ́ wà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run.”

Bí “ìpè sí òkè” tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà ṣe rí lára rẹ gan-an nìyẹn. Kò ka ara rẹ̀ sí ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ èrè náà, nítorí pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. Ṣùgbọ́n, ó ń bá a lọ láti máa ‘nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.’ (Fílípì 3:13, 14) Bákan náà, Jésù fara da ikú lórí òpó igi oró “nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.”—Hébérù 12:2.

Ǹjẹ́ o ti ṣiyèméjì rí nípa bóyá wàá wọnú ayé tuntun? Dájúdájú, ohun tó dáa ni pé ká máà dá ara wa lójú jù, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ká tó lè gba èrè ìyè, a ní láti jẹ́ olóòótọ́ títí dópin. (Mátíù 24:13) Àmọ́ ṣá o, bá a bá ń ṣa gbogbo ipá wa láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, ó yẹ kó dá wa lójú pé a óò gba èrè náà. Rántí pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Bá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, yóò ràn wá lọ́wọ́ kí ọwọ́ wa lè tẹ ohun tí à ń lépa. Àní, kò bá ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan mu pé kó máa wá ẹ̀sùn sẹ́sẹ̀ àwọn tó ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó fẹ́, kí wọ́n má bàa tóótun láti gba èrè náà.—Sáàmù 103:8-11; 130:3, 4; Ìsíkíẹ́lì 18:32.

Mímọ̀ tá a mọ èrò ti Jèhófà ní nípa àwọn èèyàn rẹ̀ ń mú ká ní ìrètí, ìyẹn ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì bí ìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 13:13) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìrètí” nínú Bíbélì ní èrò fífi ìháragàgà “retí ohun kan tó dára.” Ìrètí yẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin, kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:11, 12) Ṣàkíyèsí pé bí a bá ń bá a lọ láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, a lè ní ìdánilójú pé a óò rí ohun tá à ń retí gbà. Ìrètí yìí “kì í . . . ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀,” kò dà bí ìgbà téèyàn bá ń retí àwọn nǹkan ti ayé yìí. (Róòmù 5:5) Nígbà náà, báwo la ṣe lè mú kí ìrètí wa máa wà lọ́kàn wa digbí, kó sì lágbára sí i?

Bí A Ṣe Lè Mú Kí Ojú Tẹ̀mí Wa Ríran Sí I

Ojúyòójú wa kò lè máa wo nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Bákan náà ni ojú tẹ̀mí wa. Tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tó wà nínú ètò àwọn nǹkan yìí ló máa ń gbà wá lọ́kàn, ó dájú pé yóò gbé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé tuntun kúrò lọ́kàn wa. Láìpẹ́, àwòrán ayé tuntun tó ti di bàìbàì lọ́kàn wa kò wá ní wù wá mọ́, bí yóò ṣe pòórá nìyẹn. Ẹ ò ri pé àjálù ńlá nìyẹn yóò jẹ́! (Lúùkù 21:34) Nítorí náà, ẹ ò ri pé ó ṣe pàtàkì fún wa gan-an láti jẹ́ kí ‘ojú wa mú ọ̀nà kan,’ ìyẹn ni pé ká tẹjú mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti èrè ìyè àìnípẹ̀kun!—Mátíù 6:22.

Kì í sábà rọrùn láti jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan. Àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ ń gbà àfiyèsí wa, ìpínyà ọkàn àti ìdẹwò lè wáyé pàápàá. Nínú irú àwọn ipò báwọ̀nyí, báwo la ṣe lè pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba Ọlọ́run àti ìlérí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣe láìpa àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì mìíràn tì? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò.

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́. Kíka Bíbélì déédéé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Lóòótọ́ o, a lè ti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, bí a ṣe gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ nípa tara kí a lè máa wà láàyè nìṣó. A kò ní ṣíwọ́ oúnjẹ nítorí pé a ti jẹun láìmọye ìgbà sẹ́yìn. Nítorí náà, bó ti wù ká mọ Bíbélì tó, ó sì yẹ ká máa bá a lọ láti jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ látinú rẹ̀, ìyẹn á mú kí ìrètí wa wà lọ́kàn wa digbí, yóò sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wa túbọ̀ lágbára.—Sáàmù 1:1-3.

Máa fi ìmọrírì ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tí àṣàrò fi ṣe pàtàkì? Ohun méjì ló fà á. Àkọ́kọ́, àṣàrò yóò jẹ́ ká lè lóye ohun tí a kà, yóò sì jẹ́ ká mọrírì rẹ̀ jinlẹ̀. Ìkejì, àṣàrò kò ní jẹ́ ká gbàgbé Jèhófà, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àti ìrètí tó gbé síwájú wa. Bí àpẹẹrẹ: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bá Mósè kúrò ní Íjíbítì fi ojú wọn kòrókòró rí bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu. Wọ́n tún rí ààbò onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ bó ṣe ń darí wọn síbi tí ogún wọ́n wà. Síbẹ̀, kò pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé aginjù ní ojú ọ̀nà Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí kùn, èyí tó fi hàn pé wọn ò nígbàgbọ́ rárá. (Sáàmù 78:11-17) Kí ni ìṣòro wọn gan-an?

Àwọn èèyàn náà yí àfiyèsí wọn kúrò lórí ìrètí àgbàyanu tí Jèhófà gbé síwájú wọn, wọ́n wá gbájú mọ́ ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àtàwọn nǹkan tara. Láìka gbogbo iṣẹ́ àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fojú ara wọn rí sí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló di aláìnígbàgbọ́ tó ń ráhùn. Sáàmù 106:13 sọ pé: “Kíákíá ni wọ́n gbàgbé àwọn iṣẹ́ [Jèhófà].” Irú àìkaǹkansí burúkú bẹ́ẹ̀ yẹn ni kò jẹ́ kí ìran yẹn wọ Ilẹ̀ Ìlérí.

Nítorí èyí, bí o bá ń ka Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ kó o wáyè láti ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àti ìlera rẹ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń ka Sáàmù 106, tí a sàyọkà apá kan rẹ̀ lókè, ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ Jèhófà. Wo bí àánú àti sùúrù rẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pọ̀ tó. Wo bó ṣe ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Kíyè sí bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí i léraléra. Fojú inú wo bí yóò ṣe ká Jèhófà lára tó nígbà táwọn èèyàn aláìmoore tó tún jẹ́ aláìgbatẹnirò yẹn ń tẹ́ńbẹ́lú àánú rẹ̀ tí wọ́n sì tún ń tán an ní sùúrù. Síwájú sí i, nípa ríronú lórí ẹsẹ 30 àti 31 tó sọ bí Fíníhásì ṣe dúró gbọin-in, tó sì fi ìgboyà dúró ti òdodo, ìyẹn á mú kó dá wa lójú pé Jèhófà kò gbàgbé àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ àti pé ó ń san wọ́n lẹ́san lọ́pọ̀ yanturu.

Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé rẹ. Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, à ń rí i fúnra wa pé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà gbéṣẹ́. Òwe 3:5, 6 sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Ẹ wo bí ìgbésí ayé oníṣekúṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé ṣe fa ìdààmú, ìnira àtàwọn ìyọnu mìíràn bá wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àní títí ayé wọn ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi máa ń jìyà ìgbádùn tí wọ́n jẹ fúngbà díẹ̀. Ní òdìkejì, àwọn tó ń rìn ní ‘ojú ọ̀nà híhá’ ń rí ìtọ́wò ètò tuntun, èyí sì jẹ́ ìṣírí fún wọn láti máa rin ọ̀nà ìyè nìṣó.—Mátíù 7:13, 14; Sáàmù 34:8.

Ó lè má rọrùn láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Nígbà mìíràn, tá a bá wà nínú ipò tí kò rọgbọ, ó lè jẹ́ pé ojútùú kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu lò máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní ìṣòro ìṣúnná owó, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká fi ire Ìjọba náà sí ipò kejì. Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí ní ìdánilójú pé ìgbẹ̀yìn “yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” (Oníwàásù 8:12) Nígbà mìíràn, Kristẹni kan lè ní láti ṣe àfikún iṣẹ́, ṣùgbọ́n kí irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ rí i pé òun ò dà bí Ísọ̀, ẹni tó fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn nǹkan tẹ̀mí, tó gbé wọn sọnù bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan.—Jẹ́nẹ́sísì 25:34; Hébérù 12:16.

Kedere ni Jésù ṣàlàyé ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. A gbọ́dọ̀ ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi baba, nípa rírí i dájú pé a ní gbogbo ohun tá a nílò nípa tara. Kò fẹ́ ká fi àníyàn nípa àwọn ohun tó sọ pé òun fúnra òun yóò bójú tó dẹrù pa ara wa. A lè fi irú àníyàn tí kò tọ́ bẹ́ẹ̀ wé àìsàn glaucoma [asọnidafọ́jú] nípa tẹ̀mí, èyí tó jẹ́ pé tí a kò bá tọ́jú rẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ohun tara nìkan la ó máa rí, yóò sì fọ́jú tẹ̀mí wa níkẹyìn. Bí a kò bá sì kúrò nínú ipò yẹn, ọjọ́ Jèhófà yóò dé sórí wa “gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” Ẹ ò ri pé àjálù gbáà nìyẹn!—Lúùkù 21:34-36.

Ẹ Jẹ́ Ká Pọkàn Pọ̀ Bíi Jóṣúà

Ẹ jẹ́ kí ìrètí wa nípa Ìjọba ológo náà máa wà lọ́kàn wa digbí, ká sì máa fi àwọn ojúṣe yòókù sí àyè tó yẹ kí wọ́n wà. Bí a bá ń bá a lọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tí à ń ṣàṣàrò déédéé tí a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ìrètí tá a ní yóò lè dá wa lójú gẹ́gẹ́ bó ṣe dá Jóṣúà lójú. Lẹ́yìn tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, ó ní: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.”—Jóṣúà 23:14.

Ǹjẹ́ kí ìrètí Ìjọba náà máa fún ọ lókun, kó sì máa fún ọ láyọ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe ń hàn nínú èrò rẹ, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ, ìpinnu rẹ àti nínú ìgbòkègbodò rẹ.—Òwe 15:15; Róòmù 12:12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ǹjẹ́ o ti ṣiyèméjì rí pé bóyá wàá wọnú ayé tuntun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ṣíṣàṣàrò ṣe pàtàkì tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pọkàn pọ̀ sórí ire Ìjọba Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́