ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/1 ojú ìwé 20-23
  • Ṣé Ìṣòro Tó Dé Bá Ọ Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìṣòro Tó Dé Bá Ọ Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Dojú Kọ Ìṣòro Líle Koko
  • Yàgò fún Ìkórìíra àti Ìbínú Kíkorò
  • Lo Ipò Ìṣòro Rẹ Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ
  • Dúró De Jèhófà
  • Jèhófà Yóó Mẹ́sẹ̀ Rẹ Dúró
  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/1 ojú ìwé 20-23

Ṣé Ìṣòro Tó Dé Bá Ọ Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?

ÀWỌN ipò tó ń kóni sí wàhálà àti ìṣòro pọ̀ bí nǹkan míì láwọn “àkókò lílekoko” yìí. (2 Tímótì 3:1) Àwọn ìṣòro kan lè wà fúngbà díẹ̀ tí wọ́n á sì kọjá lọ nígbà tó bá yá. Àwọn mìíràn máa ń wà fún ọ̀pọ̀ oṣù kódà fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ ló máa ń ronú bíi ti onísáàmù náà Dáfídì, tó ké gbàjarè sí Jèhófà pé: “Wàhálà ọkàn-àyà mi ti di púpọ̀; mú mi jáde kúrò nínú másùnmáwo tí ó bá mi.”—Sáàmù 25:17.

Ṣé àwọn ìṣòro tó ju agbára rẹ lọ ló ń bá ọ fínra? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè rí ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìgbésí ayé àwọn méjì tó jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà tí wọ́n kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí, àwọn ni Jósẹ́fù àti Dáfídì. Nípa ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú ìṣòro, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó wúlò gan-an tí yóò ràn wá lọ́wọ́ lóde òní láti kojú àwọn ìṣòro tó fara jọ tiwọn.

Wọ́n Dojú Kọ Ìṣòro Líle Koko

Nígbà tí Jósẹ́fù pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ní ìṣòro kan tó le koko láàárín ìdílé tiẹ̀ fúnra rẹ̀. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin rí i pé Jékọ́bù, baba àwọn “nífẹ̀ẹ́ [Jósẹ́fù] ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ.” Nígbà tó yá, “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀, wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:4) A lè fojú inú wo hílàhílò àti másùnmáwo tí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí á ti kó Jósẹ́fù sí. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìkórìíra táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ní sí i wá pọ̀ gan-an débi pé wọ́n tà á sí oko ẹrú.—Jẹ́nẹ́sísì 37:26-33.

Nígbà tí Jósẹ́fù jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì, ó sá fún ìṣekúṣe tí ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ fi ń lọ̀ ọ́. Inú bí obìnrin náà gan-an pé Jósẹ́fù ò gbà láti bá òun ṣe ìṣekúṣe, nítorí náà ó fi ẹ̀sùn èké kàn án pé ó fẹ́ fipa bá òun ṣe. Wọ́n sì fi í “sí ilé ẹ̀wọ̀n,” níbi tí ‘wọ́n ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́, tí ọkàn rẹ̀ sì wá sínú àwọn irin.’ (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-20; Sáàmù 105:17, 18) Àdánwò ńlá mà lèyí o! Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá ni Jósẹ́fù fi jẹ́ ẹrú tàbí ẹlẹ́wọ̀n nítorí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn ẹlòmíràn hù sí i, títí kan àwọn tó wà nínú ìdílé tiẹ̀ fúnra rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 37:2; 41:46.

Dáfídì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì náà dojú kọ àdánwò nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ọdún bíi mélòó kan ló fi ń gbé ìgbésí ayé ìsáǹsá, tí Sọ́ọ̀lù Ọba ń dọdẹ rẹ̀ kiri bí ẹran. Gbogbo ìgbà ni ẹ̀mí Dáfídì máa ń wà nínú ewu. Ìgbà kan wà tó lọ sí ọ̀dọ̀ Áhímélékì àlùfáà pé kó fún òun ní oúnjẹ. (1 Sámúẹ́lì 21:1-7) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Áhímélékì ṣèrànwọ́ fún Dáfídì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa Áhímélékì àti gbogbo àlùfáà àtàwọn ìdílé wọn pẹ̀lú. (1 Sámúẹ́lì 22:12-19) Ǹjẹ́ a lè fojú inú wo bí inú Dáfídì á ṣe bà jẹ́ tó nítorí àjálù tó tipasẹ̀ rẹ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí kò ṣe tààrà?

Ronú nípa ọ̀pọ̀ ọdún tí Jósẹ́fù àti Dáfídì fi fara da ìpọ́njú àti ìfìyàjẹni. Àwa náà lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an nípa ṣíṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí wọ́n gbà borí ipò líle koko tí wọ́n bá ara wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn ọkùnrin wọ̀nyí fi yẹ lẹ́ni tá a ń fara wé.

Yàgò fún Ìkórìíra àti Ìbínú Kíkorò

Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ni pé, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyí ò bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀tá, wọ́n ò sì jẹ́ kí ìkórìíra gbà wọ́n lọ́kàn. Nígbà tí Jósẹ́fù wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kò sóhun tó ní kó má ronú òdì nípa bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe dà á, bóyá kó máa wá ronú bí òun á ṣe gbẹ̀san tóun bá tún lè rí wọn. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jósẹ́fù kò fàyè gba irú ìrònú búburú bẹ́ẹ̀? Wo ohun tó ṣe nígbà tó láǹfààní láti gbẹ̀san lára àwọn arákùnrin rẹ̀ tó wá sí Íjíbítì láti wá ra ọkà. Ìtàn náà sọ pé: “[Jósẹ́fù] kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. . . . Lẹ́yìn ìyẹn, Jósẹ́fù pàṣẹ, [àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀] sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọkà kún ìkóhunsí [àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀]. Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí a dá owó àwọn ọkùnrin náà padà sínú àpò ìdọ̀họ olúkúlùkù wọn, kí wọ́n sì fún wọn ní ìpèsè oúnjẹ fún ìrìn àjò.” Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jósẹ́fù ń rán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ láti lọ mú baba wọn wá sí Íjíbítì, ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ fún wọn ni pé: “Ẹ má ṣe dá ara yín lágara lójú ọ̀nà.” Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, Jósẹ́fù fi ẹ̀rí hàn kedere pé òun kò jẹ́ kí ìbínú kíkorò àti ìkórìíra nípa lórí ìgbésí ayé òun.—Jẹ́nẹ́sísì 42:24, 25; 45:24.

Bákan náà ni Dáfídì kò bá Sọ́ọ̀lù Ọba ṣọ̀tá. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Dáfídì láǹfààní àtipa Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, nígbà táwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé kí Dáfídì pa á, ó sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, láti ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n ṣe ohun yìí sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà, nípa nína ọwọ́ mi lòdì sí i, nítorí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni.” Dáfídì fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ó sọ fún àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò mú ìyọnu àgbálù bá a; tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò dé tí yóò sì ní láti kú, tàbí yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìjà ogun, a ó sì gbá a lọ dájúdájú.” Kódà nígbà tó yá, Dáfídì kọ orin arò láti ṣọ̀fọ̀ ikú Sọ́ọ̀lù àti ti Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù. Dáfídì náà ṣe bíi ti Jósẹ́fù, kò jẹ́ kí ẹ̀mí ìkórìíra gba òun lọ́kàn.—1 Sámúẹ́lì 24:3-6; 26:7-13; 2 Sámúẹ́lì 1:17-27.

Ǹjẹ́ a máa ń ní ẹ̀mí ìkórìíra àti ìbínú kíkorò nígbà tí ìwà àìdáa táwọn kan hù sí wa bá bà wá nínú jẹ́? Èyí lè ṣẹlẹ̀. Tá a bá ń jẹ́ kí nǹkan dùn wá ju bó ṣe yẹ lọ, àbájáde rẹ̀ lè fa ìpalára fún wa ju ohun tí ìwà àìdáa áà fúnra rẹ̀ fà lọ. (Éfésù 4:26, 27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máà rí ohunkóhun ṣe sí ohun táwọn ẹlòmíràn ń ṣe sí wa, síbẹ̀ a lè lo ìkóra ẹni níjàánu. Ó máa ń rọrùn láti yàgò fún ìbínú àti ìkórìíra tá a bá ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà yóò bójú tó ọ̀ràn nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀.—Róòmù 12:17-19.

Lo Ipò Ìṣòro Rẹ Lọ́nà Tó Dára Jù Lọ

Ẹ̀kọ́ kejì tá a lè kọ́ ni pé ká máà jẹ́ kí ìṣòro tá a ní sọ wá dẹni tí kò ní mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. A lè jẹ́ kí ohun tí a ò lágbára láti ṣe gbà wá lọ́kàn débi pé a ò tiẹ̀ ní rántí ohun tá a lè ṣe. Á túmọ̀ sí pé a ti jẹ́ kí ìṣòro tá a ní darí ìgbésí ayé wa nìyẹn. Èyí ì bá ti ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yàn láti lo ipò tó bá ara rẹ̀ lọ́nà tó dára jù lọ. Nígbà tí Jósẹ́fù jẹ́ ẹrú, ó “ń rí ojú rere ṣáá ní ojú [ọ̀gá rẹ̀], ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣèránṣẹ́ fún un, tí ó fi jẹ́ pé ó yàn án ṣe olórí ilé rẹ̀.” Ohun kan náà ni Jósẹ́fù ṣe nígbà tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Nítorí ìbùkún Jèhófà àti jíjẹ́ tí Jósẹ́fù jẹ́ aláápọn, “ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n náà fi gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀wọ̀n lé Jósẹ́fù lọ́wọ́; gbogbo ohun tí wọ́n bá sì ń ṣe níbẹ̀, òun ni ń mú kí ó di ṣíṣe.”—Jẹ́nẹ́sísì 39:4, 21-23.

Gbogbo ọdún tí Dáfídì fi gbé ìgbésí ayé ìsáǹsá ni òun náà lò ipò tó bá ara rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára jù lọ. Nígbà tó ń gbé ní aginjù Páránì, òun àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dáàbò bo agbo ẹran Nábálì kúrò lọ́wọ́ àwọn agbo ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí. Ọ̀kan nínú àwọn darandaran Nábálì sọ pé: “Ògiri ni wọ́n jẹ́ yí wa ká ní òru àti ní ọ̀sán.” (1 Sámúẹ́lì 25:16) Nígbà tó yá, lákòókò tí Dáfídì ń gbé ní Síkílágì, ó gbógun ti àwọn ìlú tó jẹ́ ti àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì ní apá gúúsù, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn ààlà ìpínlẹ̀ Júdà.—1 Sámúẹ́lì 27:8; 1 Kíróníkà 12:20-22.

Ǹjẹ́ kò yẹ ká túbọ̀ sapá gidigidi láti lò ipò ìṣòro tá a bá ara wa lọ́nà tó dára jù lọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ a lè kẹ́sẹ járí. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. . . . Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.” Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe wá ń fi irú ojú yìí wo ìgbésí ayé? Nítorí pé ó ń gbára lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà ni. Ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:11-13.

Dúró De Jèhófà

Ẹ̀kọ́ kẹta ni pé dípò tá a ó fi lò àwọn ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mú láti yanjú ìṣòro wa, ńṣe ló yẹ ká dúró de Jèhófà. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:4) A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfaradà “ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré” nípa fífarada àdánwò wa dé òpin láìlo àwọn ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti fòpin sí i lójú ẹsẹ̀. Ìgbà náà ni ìgbàgbọ́ wa yóò di èyí tá a dán wò tá a sì yọ́ mọ́, tí agbára tí ìgbàgbọ́ náà ní láti mẹ́sẹ̀ wa dúró yóò sì hàn kedere. Irú ìfaradà yìí ni Jósẹ́fù àti Dáfídì ní. Wọn ò gbìyànjú láti wá ojútùú tó lè mú kí Jèhófà bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti fara mọ́ ipò tí wọ́n bá ara wọn. Wọ́n dúró de Jèhófà, àwọn ìbùkún tí wọ́n rí gbà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sì pọ̀ jọjọ! Jèhófà lo àwọn méjèèjì láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè àti láti ṣe aṣáájú wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 41:39-41; 45:5; 2 Sámúẹ́lì 5:4, 5.

Àwa náà lè dojú kọ àwọn ipò tó lè sùn wá dórí wíwá ojútùú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí pé o ò tíì rí ọkọ tàbí aya tí ọkàn rẹ fẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, yẹra fún ìdẹwò èyíkéyìí tó lè mú kó o ṣàìgbọràn sí àṣẹ Jèhófà tó sọ pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Ǹjẹ́ o ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ? Dípò tó o fi máa tẹ̀ lé ẹ̀mí ayé tó ń gba àwọn èèyàn níyànjú láti pínyà tàbí kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀, á dára kí ẹ̀yìn méjèèjì sapá láti yanjú ìṣòro náà. (Málákì 2:16; Éfésù 5:21-33) Ǹjẹ́ o ní ìṣòro àtigbọ́ bùkátà ìdílé rẹ nítorí ìṣòro ìṣúnná owó? Dídúró de Jèhófà kan kéèyàn yẹra fún ṣíṣe àwọn nǹkan tí kò bójú mu tàbí èyí tí kò bá òfin mu nítorí àtiní owó. (Sáàmù 37:25; Hébérù 13:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó yẹ kí gbogbo wa sapá gidigidi láti lo ipò ìṣòro wa lọ́nà tó dára jù lọ ká sì sa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tí Jèhófà yóò fi bù kún wa. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu láti dúró de Jèhófà láti yanjú ìṣòro náà pátápátá.—Míkà 7:7.

Jèhófà Yóó Mẹ́sẹ̀ Rẹ Dúró

Ṣíṣe àṣàrò lórí ọ̀nà táwọn èèyàn bíi Jósẹ́fù àti Dáfídì tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Bíbélì gbà kẹ́sẹ járí nínú kíkojú àdánwò àti àwọn ìṣòro líle koko tí wọ́n ní lè ní ipa tó dára lórí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ìwé bíi mélòó kan péré la kọ ìtàn wọn sí nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi kojú àdánwò tó bá wọn. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni irú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ṣe fara da ipò tí wọ́n bá ara wọn? Báwo ni wọn ṣe ṣe é tí wọ́n fi máa ń láyọ̀ ṣáá? Àwọn ànímọ́ wo ni wọ́n sapá láti ní?’

A tún lè jàǹfààní látinú ṣíṣàyẹ̀wò ìfaradà àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní. (1 Pétérù 5:9) Ọdọọdún ni ọ̀pọ̀ ìtàn ìgbésí ayé máa ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ǹjẹ́ o máa ń ka nípa àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyí, tó o sì máa ń ṣe àṣàrò lórí wọn? Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tún wà nínú ìjọ wa tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ fara da àwọn ipò tí kò bára dé. Ǹjẹ́ o máa ń bá wọn rìn déédéé kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn láwọn ìpàdé ìjọ?—Hébérù 10:24, 25.

Nígbà tó o bá níṣòro, mọ̀ dájú pé Jèhófà bìkítà nípa rẹ, yóò sì mú ẹsẹ̀ rẹ dúró. (1 Pétérù 5:6-10) Sa gbogbo ipá rẹ láti má ṣe jẹ́ kí ìṣòro tó o ní darí ìgbésí ayé rẹ. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn bíi Jósẹ́fù, Dáfídì, àtàwọn mìíràn nípa yíyẹra fún ìkórìíra, nípa lílo ipò ìṣòro tó o bá bá ara rẹ lọ́nà tó dára jù lọ, àti nípa dídúró de Jèhófà láti yanjú ìṣòro ọ̀hún pátápátá. Sún mọ́ ọn nípasẹ̀ àdúrà àtàwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ náà á rí i pé ìdùnnú àti ayọ̀ yóò jẹ́ tìrẹ, kódà láwọn àkókò tí nǹkan le koko pàápàá.—Sáàmù 34:8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Jósẹ́fù sapá láti lo ipò ìṣòro tó bá ara rẹ̀ lọ́nà tó dára jù lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Dáfídì dúró de Jèhófà láti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́