ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/15 ojú ìwé 4-7
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Àwọn Òbí Ni Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ
  • Máa Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Déédéé
  • Ìbáwí Tó Dá Lórí Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì Gan-An
  • Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé Ṣe Pàtàkì
  • Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere
  • O Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Títọ́ Ọmọ
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/15 ojú ìwé 4-7

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?

ÒDÒDÓ orchid lẹ́wà púpọ̀, àmọ́ ó ṣòroó tọ́jú. Tó o bá fẹ́ gbin òdòdó náà kó o sì kẹ́sẹ járí, o ní láti bójú tó ìgbóná-òun-ìtutù àyíká ibi tó wà, kó o wo bí ìmọ́lẹ̀ ṣe ń dé ibẹ̀ tó, àti bí ìkòkò òdòdó náà ṣe fẹ̀ tó. Ilẹ̀ àti ajílẹ̀ tí kò bá dára lè nípa lórí òdòdó yìí, àrùn àti kòkòrò sì tètè máa ń bà á jẹ́. Nítorí náà, èèyàn kì í sábà kẹ́sẹ járí nígbà àkọ́kọ́ tó bá gbin òdòdó orchid.

Títọ́ àwọn ọmọ le gan-an ju ìyẹn lọ, ó díjú púpọ̀, ó si tún gba kéèyàn fara balẹ̀ wo bí nǹkan ṣe ń lọ. Nítorí náà, kì í ṣe ohun àjèjì rárá láti rí àwọn òbí tó máa ń rò pé àwọn ò tọ́ ọmọ àwọn dójú àmì. Ọ̀pọ̀ ló rí i pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́, bí ẹni tó ń gbin òdòdó orchid ṣe nílò ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹni tó jẹ́ ògbógi nínú iṣẹ́ náà. Ó dájú pé gbogbo òbí ló ń fẹ́ ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ. Ibo ni wọ́n ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìlànà ọmọ títọ́, síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá mí sí àwọn tó kọ ọ́ láti kọ àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an nípa ọ̀ràn ọmọ títọ́ sínú rẹ̀. Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé kéèyàn sapá láti ní àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra kan, èyí táwọn kan sábà máa ń gbójú fò. (Éfésù 4:22–24) Látàrí èyí, ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ apá kan tó ṣe pàtàkì lára ẹ̀kọ́ tó tọ́ tí ó sì yẹ. Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ti ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó fi í sílò, láìka àkókò tí wọ́n gbé ayé tàbí ibi tí wọ́n ti wá sí. Nítorí náà, títẹ̀lé ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí nínú títọ́ àwọn ọmọ rẹ.

Àpẹẹrẹ Àwọn Òbí Ni Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ

“Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí?”—Róòmù 2:21, 22.

Alága fún Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ètò Ẹ̀kọ́ ni ìlú Seoul sọ pé: “Àpẹẹrẹ téèyàn fi lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ni ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ fún àwọn ọmọ.” Bí àwọn òbí kò bá fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn, kí wọ́n sì fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni pàtó kan, kíá ni àwọn ọmọ náà máa kà wọ́n sí alágàbàgebè. Ọ̀rọ̀ àwọn òbí kò wá ní tà létí wọn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn òbí bá fẹ́ kọ́ ọmọ wọn pé àbòsí kò dára, àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlábòsí. Nígbà táwọn òbí kan kò bá fẹ́ dá ẹni tó ń pè wọ́n lórí tẹlifóònù lóhùn, ó ti di àṣà wọn láti máa sọ fún ọmọ wọn pé kó sọ fún onítọ̀hún pé, “Ẹ má bínú o, dádì mi (tàbí mọ́mì mi) ò sí nílé.” Ara ọmọ tí wọ́n bá fún nírú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ á lọ́ tìkọ̀, gbogbo nǹkan á sì pòrúurùu mọ́ ọn lójú. Nígbà tó bá yá, òun náà lè bẹ̀rẹ̀ sí parọ́ nígbà tó bá ṣe ohun tí kò dáa, láìsí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń dà á láàmù. Nítorí náà, táwọn òbí bá fẹ́ kí ọmọ wọn jẹ́ olóòótọ́, àwọn náà gbọ́dọ̀ máa sòótọ́, kí ìṣe wọn sì máa bá ọ̀rọ̀ ẹnu wọn mu.

Ṣé o fẹ́ kọ́ ọmọ rẹ kí ọ̀rọ̀ tó dára lè máa ti ẹnu rẹ̀ jáde? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Kíá ni ọmọ rẹ yóò fara wé ọ. Sung-sik, tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́rin, sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi ti pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé máa ti ẹnu wa jáde. A máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wa, tá a bá tiẹ̀ ń bínú pàápàá, a kì í jágbe mọ́ra wa. Àpẹẹrẹ rere gbéṣẹ́ gan-an ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ. Inú wa dùn pé àwọn ọmọ wa jẹ́ ọmọlúwàbí, wọ́n sì máa ń fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.” Bíbélì sọ nínú Gálátíà 6:7 pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Àwọn òbí tó fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn máa hu ìwà tó dára nígbà gbogbo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi hàn pé àwọn fúnra wọn ń gbé níbàámu pẹ̀lú irú ìlànà bẹ́ẹ̀.

Máa Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Déédéé

“Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn [àwọn àṣẹ Ọlọ́run] sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:7.

Ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń fẹ́ láti máa ṣe àṣekún iṣẹ́. Ó máa ń nípa lórí àwọn ọmọ gan-an tó bá jẹ́ pé ọkọ àti ìyàwó ló ń lọ sí ibi iṣẹ́. Àkókò tí ọ̀pọ̀ òbí ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ń dín kù. Nígbà táwọn òbí bá sì wà nílé, wọ́n ní láti ṣe iṣẹ́ ilé àtàwọn iṣẹ́ mìíràn, ìyẹn sì lè jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n. Báwo lo ṣe lè máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé ní irú ipò bẹ́ẹ̀? Àǹfààní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lè yọ, tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ bá jọ ń ṣe iṣẹ́ ilé pa pọ̀. Ńṣe ni olórí ìdílé kan tiẹ̀ gbé tẹlifíṣọ̀n kúrò nílé pátápátá, kó lè túbọ̀ rí àkókò láti máa bá àwọn ọmọ rẹ̀ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Ó sọ pé: “Ó kọ́kọ́ sú àwọn ọmọ níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ nígbà tí mò bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn ṣe àwọn eré àdììtú tá à ń wá ìdáhùn sí, tá a tún jọ ń jíròrò àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé aládùn tá a ti kà, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àìsí tẹlifíṣọ̀n nílé wá mọ́ wọn lára.”

Ó ṣe pàtàkì pé kó mọ́ àwọn ọmọ lára láti máa bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ láti kékeré. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà táwọn ọmọ náà bá bàlágà, tí wọ́n wá ń kojú àwọn ìṣòro, wọn ò ní ka àwọn òbí wọn sí ọ̀rẹ́ táwọn lè fọ̀rọ̀ lọ̀ mọ́ nígbà yẹn. Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde? Òwe 20:5 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.” Àwọn òbí lè mú káwọn ọmọ wọn sọ èrò inú wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn jáde nípa lílo àwọn ìbéèrè tí ń fi èrò ẹni hàn, bíi “Kí lèrò rẹ?”

Kí lo máa ṣe tí ọmọ rẹ bá ṣe àṣìṣe ńlá kan? Ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó o gba tiẹ̀ rò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Má ṣe bínú sódì nígbà tó o bá ń fetí sí ohun tí ọmọ rẹ ń sọ. Ohun tí bàbá kan sọ nípa ọ̀nà tó ń gbà bójú tó irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rèé, ó ní: “Nígbà táwọn ọmọ mi bá ṣe àṣìṣe, mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe bínú sódì. Màá jókòó, màá sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Màá wá gbìyànjú láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Nígbà tí mo bá rí i pé inú fẹ́ bí mi sódì, máa dúró fúngbà díẹ̀ máa sì fi ara mi lọ́kàn balẹ̀.” Tó o bá fara balẹ̀, tó o fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n fara mọ́ ìbáwí tó o bá fún wọn.

Ìbáwí Tó Dá Lórí Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì Gan-An

“Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

Tó o bá fẹ́ ṣe àṣeyọrí, ọ̀nà tó o gbà ń fìfẹ́ báni wí ṣe pàtàkì púpọ̀. Ọ̀nà wo ni àwọn òbí lè gbà ‘sún àwọn ọmọ wọn bínú’? Bí ìbáwí tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ ò bá tó tàbí tí ìbáwí náà bá le koko jù bó ṣe yẹ lọ, àwọn ọmọ yóò ya ìyàkuyà. Ìfẹ́ ló yẹ ká máa fi bá wọn wí ní gbogbo ìgbà. (Òwe 13:24) Tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ fèrò wérò, wọ́n á mọ̀ pé ìfẹ́ tó o ní sí àwọn ló jẹ́ kó o bá àwọn wí.—Òwe 22:15; 29:19.

Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó yẹ káwọn ọmọ jìyà nígbà tí wọ́n bá hùwà tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ náà bá ṣe ohun tí kò dára sí ẹlòmíràn, o lè sọ pé ó gbọ́dọ̀ lọ bẹ onítọ̀hún. Tó bá ṣàìgbọràn sí àwọn òfin kan tí ìdílé gbé kalẹ̀, o le fi àwọn àǹfààní kan dù ú kó lè mọ ìjẹ́pàtàkì pípa òfin mọ́.

Ó dára láti bá ọmọ wí lákòókò tó yẹ. Oníwàásù 8:11 sọ pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.” Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọmọ ló máa ń fẹ́ wò bóyá àwọn lè ṣe ohun tí kò dára láṣegbé láìjìyà kankan. Nítorí náà, tó o bá ti lè kìlọ̀ pé o máa fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe ohun pàtó kan tí kò dáa, rí i dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé Ṣe Pàtàkì

“Ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà . . . ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ùn kiri.”—Oníwàásù 3:1, 4.

Àkókò fàájì àti eré ìnàjú tó gbámúṣé tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn ọmọ kí wọ́n lè dàgbà dáadáa kí ọpọlọ wọn sì pé. Nígbà táwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn bá jọ ń ṣeré ìnàjú pa pọ̀, ìdè ìdílé á túbọ̀ lágbára sí i, ọkàn àwọn ọmọ á sì túbọ̀ balẹ̀. Irú eré ìnàjú wo ni ìdílé lè jọ ṣe pọ̀? Tó o bá fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀, o lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó lárinrin tẹ́ ẹ lè ṣe. Àwọn eré ìdárayá wà tẹ́ ẹ lè ṣe, bíi kẹ̀kẹ́ gígùn, àti eré bọ́ọ̀lù, irú bíi bọ́ọ̀lù tẹníìsì, àti bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá. Sì fojú inú wo bí ìdílé ṣe máa láyọ̀ tó nígbà tí wọ́n bá jùmọ̀ ń fi àwọn ohun èlò orin kọrin. Rírin ìrìn àjò lọ sí àwọn ibi tí kò jìnnà láti lọ wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá jẹ́ ohun téèyàn á máa rántí tí inú rẹ̀ yóò sì máa dùn.

Àwọn òbí lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ní èrò tó tọ̀nà nípa eré ìnàjú. Kristẹni ọkùnrin kan tó lọ́mọ mẹ́ta sọ pé: “Mo máa ń bá àwọn ọmọ mi ṣeré ìnàjú nígbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn eré orí kọ̀ǹpútà, mo máa ń bi wọ́n bí wọn ṣe ń ṣe eré náà. Nígbà tí wọ́n bá ṣàlàyé rẹ̀ tìtaratìtara, mo máa ń lo àǹfààní yẹn láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ewu tó wà nínú eré ìnàjú tí kò yẹ. Mo ti rí i pé gbogbo eré ìnàjú tí kò bójú mu ni wọ́n ti yàgò fún.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọmọ tínú wọn máa ń dùn sí eré ìnàjú tí ìdílé ń ṣe pa pọ̀ kì í sábà kúndùn wíwo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, sinimá, àwọn eré orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń fi ìwà ipá, ìṣekúṣe, àti lílo oògùn olóró hàn.

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere

“Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

Bàbá kan tó jẹ́ Kristẹni, tó sì kẹ́sẹ járí ní títọ́ àwọn ọmọ mẹ́rin dàgbà, sọ pé: “Irú ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní ṣe pàtàkì gan-an. Ọ̀rẹ́ burúkú kan lè ba gbogbo iṣẹ́ téèyàn ti ṣe jẹ́.” Ohun tí bàbá yìí máa ń ṣe láti ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ọ̀rẹ́ tó dára ni pé ó máa ń fọgbọ́n bi wọ́n láwọn ìbéèrè bíi: Ta ni ọ̀rẹ́-minú rẹ? Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn rẹ̀? Kí lo rí lára rẹ̀ tó wù ọ́ láti fara wé? Òbí mìíràn ṣètò pé kí àwọn ọmọ òun máa mú àwọn tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ wá sílé. Ìyẹn á jẹ́ kó lè mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ kó sì fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà tó yẹ.

Ó tún ṣe pàtàkì láti kọ́ àwọn ọmọ pé bí wọ́n ṣe lè yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ni wọ́n tún lè yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú. Bum-sun, tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta sọ pé: “Mo jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ̀ pé kì í ṣe kìkì ojúgbà ẹni nìkan léèyàn ń bá ṣọ̀rẹ́, bó ṣe rí i ní ti Dáfídì òun Jónátánì inú Bíbélì. Ńṣe ni mo dìídì máa ń pe àwọn Kristẹni tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra láti bá àwọn ọmọ mi kẹ́gbẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ mi máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í ṣe ẹgbẹ́ wọn ṣọ̀rẹ́.” Bíbá àwọn àgbà tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ dọ́rẹ̀ẹ́ ti jẹ́ kí àwọn ọmọ rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́.

O Lè Ṣàṣeyọrí Nínú Títọ́ Ọmọ

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, àṣeyọrí tí ọ̀pọ̀ òbí tó gbìyànjú láti gbin àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìsẹ́ra ẹni, àti ìṣòtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ wọn máa ń ní kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó bó ṣe yẹ. Kí nìdí tó fi ṣòro tó bẹ́ẹ̀? Ìyá kan tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nígbà ìwádìí náà sọ pé: ‘Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé kìkì ọ̀nà tá a lè gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wa ni pé ká ti ilẹ̀kùn mọ́ wọn sínú ilé ká má sì jẹ́ kí wọ́n jáde lọ sínú ayé.’ Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àyíká táwọn ọmọ ti ń dàgbà nísinsìnyí burú gan-an ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Pẹ̀lú bí ipò nǹkan ṣe rí yìí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti kẹ́sẹ járí nínú títọ́ àwọn ọmọ?

Tó o bá fẹ́ gbin òdòdó orchid àmọ́ tó ò ń ronú ṣáá pé ó lè gbẹ dà nù, ìyẹn lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ kí o má fẹ́ gbìn ín. Bí ẹnì kan tó jẹ́ ògbógi nínú títọ́jú òdòdó orchid bá wá sọ àwọn ohun tó o lè ṣe fún ọ tó si fọwọ́ sọ̀yà pé, “Wàá kẹ́sẹ járí tó o bá lè ṣe ohun tí òun sọ fún ọ,” o ò rí i pé ìyẹn á fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Jèhófà, Aláṣẹ Gíga Jù Lọ lórí ìṣesí ẹ̀dá, fúnni ní ìmọ̀ràn lórí ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà tọ́ àwọn ọmọ dàgbà. Ó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Tó o bá tọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó bá ìtọ́ni inú Bíbélì mu, wàá rí i pé àwọn ọmọ rẹ yóò dàgbà di ẹni tó ní láárí, tó ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, tó sì ní ìwà rere. Ìgbà yẹn làwọn èèyàn yóò fẹ́ràn wọn, àmọ́ lékè gbogbo rẹ̀, Jèhófà, Baba wa ọ̀run pàápàá yóò fẹ́ràn wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́