‘Ẹ Lọ, Kí ẹ Sì Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’
“Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.”—MÁTÍÙ 28:18, 19.
1, 2. (a) Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nípa àṣẹ Jésù?
NÍ ỌJỌ́ kan tó bọ́ sígbà ìrúwé ní Ísírẹ́lì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kóra jọ sórí òkè ńlá kan ní Gálílì. Olúwa wọn tó jíǹde ti fẹ́ gòkè re ọ̀run, àmọ́ ó ní ohun pàtàkì kan tó fẹ́ sọ fún wọn. Jésù ní iṣẹ́ kan tó fẹ́ gbé lé wọn lọ́wọ́. Kí ni iṣẹ́ náà? Irú ọwọ́ wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi mú iṣẹ́ náà? Báwo ni iṣẹ́ yẹn ṣe kàn wá lónìí?
2 Ohun tí Jésù sọ wà nínú Mátíù 28:18-20, ó ní: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Jésù sọ̀rọ̀ nípa “gbogbo ọlá àṣẹ,” “gbogbo orílẹ̀-èdè,” “gbogbo ohun,” àti “gbogbo àwọn ọjọ́.” Àṣẹ tí Jésù pa yìí àti lílò tí ó lo gbólóhùn mẹ́rin tó wà lókè yìí mú àwọn ìbéèrè pàtàkì kan jáde, èyí tá a lè ṣàkópọ̀ sọ́nà mẹ́rìn, àwọn ni: kí nìdí? ibo ni? Kí ni? àti ìgbà wo? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè náà yẹ̀ wò ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.a
“Gbogbo Ọlá Àṣẹ Ni A Ti Fi fún Mi”
3. Kí nìdí tá a fi ní láti ṣègbọràn sí àṣẹ tó sọ pé ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?
3 Lákọ̀ọ́kọ́, kí nìdí tá a fi ní láti pa àṣẹ tó ní ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn mọ́? Jésù sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” Ọ̀rọ̀ náà “nítorí náà” tọ́ka sí ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká pa àṣẹ yìí mọ́. Ìdí ni pé Jésù tó pa àṣẹ yìí, ní “gbogbo ọlá àṣẹ.” Báwo ni ọlá àṣẹ rẹ̀ ṣe gbòòrò tó?
4. (a) Báwo ni ọlá àṣẹ tí Jésù ní ṣe gbòòrò tó? (b) Báwo ni òye tá a ní nípa ọlá àṣẹ Jésù ṣe yẹ kó nípa lórí ojú tá a fi ń wo àṣẹ tó pa pé ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?
4 Jésù ní ọlá àṣẹ lórí ìjọ rẹ̀, àtọdún 1914 ló sì ti ní ọlá àṣẹ lórí Ìjọba tuntun tí Ọlọ́run fìdí rẹ̀ múlẹ̀. (Kólósè 1:13; Ìṣípayá 11:15) Òun ni olú-áńgẹ́lì, ipò tó wà yìí sì jẹ́ kó ní àṣẹ lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tó jẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16; 1 Pétérù 3:22; Ìṣípayá 19:14-16) Bàbá rẹ̀ ti fún un láṣẹ láti sọ “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára” tó bá lòdì sí ìlànà òdodo di asán. (1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Éfésù 1:20-23) Ọlá àṣẹ tí Jésù ní kò mọ sórí àwọn tó wà láàyè nìkan o. Òun tún ni “onídàájọ́ alààyè àti òkú” ó sì ní agbára tí Ọlọ́run fún un láti jí àwọn tó ti sùn nínú ikú dìde. (Ìṣe 10:42; Jòhánù 5:26-28) Ó dájú pé àṣẹ tí Ẹni tá a fún ní ọlá àṣẹ gíga bẹ́ẹ̀ bá pa ni a ní láti kà sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an. Nítorí náà, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tinútinú la fi ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Kristi pa pé ká ‘lọ sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’
5. (a) Báwo ni Pétérù ṣe ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù? (b) Ìbùkún wo ni ìgbọràn tí Pétérù ṣe sí ìtọ́ni Jésù mú wa?
5 Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ọ́ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́nà tó gbàfiyèsí pé tí wọ́n bá gbà pé òun ní ọlá àṣẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ òun mọ́, wọ́n yóò rí ìbùkún. Ìgbà kan wà tó sọ fún Pétérù, tó jẹ́ apẹja pé: “Wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀ fún àkópọ̀ ẹja.” Ó dá Pétérù lójú pé kò sí ẹja kankan níbẹ̀, ìyẹn ló mú kó sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́ni, ní gbogbo òru ni àwa ṣe làálàá, a kò sì mú nǹkan kan.” Àmọ́ Pétérù fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Ṣùgbọ́n nítorí àṣẹ àsọjáde rẹ, ṣe ni èmi yóò rọ àwọn àwọ̀n náà sísàlẹ̀.” Lẹ́yìn tí Pétérù ṣe ohun tí Kristi ní kó ṣe, ó rí “ògìdìgbó ńlá ẹja” kó. Nítorí pé ọ̀ràn náà jọ Pétérù lójú, ó “wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jésù, ó wí pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa.’” Àmọ́ Jésù fèsì pé: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:1-10; Mátíù 4:18) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ìtàn yẹn?
6. (a) Kí ni ìtàn ẹja tí wọ́n rí kó lọ́nà ìyanu fi hàn nípa irú ìgbọràn tí Jésù fẹ́ kéèyàn ṣe? (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jésù.
6 Ẹ̀yìn ìgbà tí Pétérù, Áńdérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja kó ni Jésù gbé iṣẹ́ ‘dídi apẹja ènìyàn’ lé wọn lọ́wọ́, kì í ṣe ṣáájú kí wọ́n tó rí ọ̀pọ̀ ẹja kó. (Máàkù 1:16, 17) Ní kedere, Jésù ó retí pé kí wọ́n ṣègbọràn láìnídìí. Ó fún àwọn ọkùnrin náà ní ẹ̀rí tó dájú nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí òun. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jésù pa pé kí wọ́n ju àwọ̀n wọn sínú odò ṣe mú ìbùkún tó pabanbarì jáde, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n ‘kó àwọn èèyàn bí ẹja’ yóò ṣe mú ọ̀pọ̀ ìbùkún jáde. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún, àwọn àpọ́sítélì náà ṣe ohun tí Jésù sọ pé kí wọ́n ṣe. Ìtàn náà sọ pé: “Wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” (Lúùkù 5:11) Jésù là ń fara wé lóde òní, bá a ṣe ń gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. A ò fẹ́ káwọn èèyàn wulẹ̀ ṣe ohun tá a sọ fún wọn nìkan, àmọ́ à tún ń fún wọn ní ẹ̀rí tó dájú nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi.
Ẹ̀rí Tó Dájú àti Èrò Tó Tọ̀nà
7, 8. (a) Kí ni àwọn ìdí bíi mélòó kan tá a rí nínú Ìwé Mímọ́ tá a fi ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn? (b) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo gan-an ló ń mú kó o máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
7 Nítorí pé a mọyì ọlá àṣẹ Kristi la ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn ìdí mìíràn wo tá a fi ń ṣe iṣẹ́ yìí ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tá a lè sọ fún àwọn tá a fẹ́ sún láti ṣe iṣẹ́ rere? Gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò látẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí tòótọ́ bíi mélòó kan láti onírúurú orílẹ̀-èdè, kó o sì kíyè sí bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ ṣe ti ọ̀rọ̀ wọ́n lẹ́yìn.
8 Roy, tó ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1951 sọ pé: “Nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo ṣèlérí láti máa sìn ín títí ayé. Mo fẹ́ mú ìlérí mi ṣẹ.” (Sáàmù 50:14; Mátíù 5:37) Heather, tó ṣe ìrìbọmi ní 1962 sọ pé: “Nígbà tí mo bá ronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún mi, ó wù mí láti fi ìmọrírì mi hàn nípa fífi ìṣòtítọ́ sìn ín.” (Sáàmù 9:1, 9-11; Kólósè 3:15) Hannelore, tó ṣe ìrìbọmi ní 1954 sọ pé: “Gbogbo ìgbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí làwọn áńgẹ́lì máa ń tì wá lẹ́yìn, ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́!” (Ìṣe 10:30-33; Ìṣípayá 14:6, 7) Honor, tó ṣe ìrìbọmi ní 1969 sọ pé: “Nígbà tí àkókò ìdájọ́ Jèhófà bá dé, mi ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni lára àwọn aládùúgbò mi dẹ́bi fún Jèhófà àtàwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ nípa sísọ pé, ‘a ò rẹ́ni kìlọ̀ fún wa!’” (Ìsíkíẹ́lì 2:5; 3:17-19; Róòmù 10:16, 18) Claudio, tó ṣe ìrìbọmi ní 1974 sọ pé: “Nígbà tá a bá ń wàásù, a wà ‘ní iwájú Ọlọ́run’ àti ‘ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.’ Ẹ ò ri pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, à ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àwọn Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ.”—2 Kọ́ríńtì 2:17.b
9. (a) Kí ni ìtàn iṣẹ́ ẹja pípa tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ṣe fi hàn nípa ohun tó yẹ kó mú ká ṣe ìgbọràn sí Kristi? (b) Kí ni ohun tó yẹ kó mú ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Kristi lóde òní, kí sì nìdí?
9 Ìtàn nípa bí wọ́n ṣe rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja kó tún jẹ́ ká mọ ìjẹ́pàtàkì níní ohun tó yẹ kó mú ká máa ṣe ìgbọràn sí Kristi, ìyẹn ni ìfẹ́. Nígbà tí Pétérù sọ pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí,” Jésù kò kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá Pétérù lẹ́bi fún ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (Lúùkù 5:8) Kódà Jésù ò bínú sí Pétérù nítorí ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jésù fèsì lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé: “Dẹ́kun fífòyà.” Ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì kì í ṣe ohun tó yẹ kó mú kéèyàn máa ṣe ìgbọràn sí Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún Pétérù pé òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yóò wúlò gan-an nínú iṣẹ́ apẹja ènìyàn. Bákan náà lónìí, a kì í dẹ́rù ba àwọn èèyàn tàbí ká hùwà àìdáa mìíràn sí wọn, bíi ká máa dá wọn lẹ́bi tàbí ká máa kó ìtìjú bá wọn láti lè fagbára mú wọn ṣègbọràn sí Kristi. Kìkì ìgbọràn tá a ṣe tọkàntọkàn tó dá lórí ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti Kristi nìkan ló máa ń mú inú Jèhófà dùn.—Mátíù 22:37.
Ẹ “Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
10. (a) Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ló lè jẹ́ ìṣòro ńlá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nípa àṣẹ tó pa pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? (b) Ìhà wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn kọ sí àṣẹ Jésù?
10 Ìbéèrè kejì tá a lè béèrè nípa àṣẹ tí Kristi pa ni pé, ibo ni a ó ti máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yìí? Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ . . . máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ṣáájú ìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, tọwọ́tẹsẹ̀ ni wọ́n máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tó bá fẹ́ wá jọ́sìn Jèhófà ní Ísírẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 8:41-43) Àwọn tó jẹ́ Júù ló pọ̀ jù lọ lára àwọn tí Jésù fúnra rẹ̀ wàásù fún, àmọ́ ó wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ báyìí pé kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Lẹ́nu kan, ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń pẹja tàbí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tẹ́lẹ̀ kò kọjá “odò” kékeré kan—ìyẹn àwọn Júù—àmọ́ kò ní pẹ́ tí wọ́n máa fi lọ dé “òkun” gbogbo aráyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ńlá ni èyí máa jẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, síbẹ̀ wọ́n ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jésù láìjanpata. Ní ohun tó dín ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìhìn rere náà ni a ti wàásù rẹ̀ fún “gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run,” kì í kàn án ṣe fún àwọn Júù nìkan.—Kólósè 1:23.
11. Báwo ni ‘àwọn ilẹ̀ tá a ti ń pẹja’ ṣe ń gbòòrò sí i láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún?
11 Bákan náà lóde òní, a tún rí i pé ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù ń gbòòrò sí i lọ́nà tó fara jọ ti ìgbà yẹn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ‘ilẹ̀ tá a ti ń pẹja’ kò kọjá àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ìgbà yẹn lọ́hùn-ún fara wé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, tìtaratìtara ni wọ́n sì fi mú kí ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń wàásù gbòòrò sí i. (Róòmù 15:20) Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, wọ́n ti ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún orílẹ̀-èdè. Àwọn ‘ilẹ̀ tá a ti ń pẹja’ lónìí ti gbòòrò dé igba ó lé márùndínlógójì orílẹ̀-èdè.—Máàkù 13:10.
“Láti Inú Gbogbo Èdè”
12. Ìṣòro wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sekaráyà 8:23 fi hàn?
12 Kì í ṣe bí ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù ṣe tóbi tó nìkan ló máa mú kó ṣòro láti máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, àmọ́ onírúurú èdè táwọn èèyàn ń sọ tún jẹ́ kó ṣòro pẹ̀lú. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Nínú ìmúṣẹ gbígbòòrò ti àsọtẹ́lẹ̀ yìí, “ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù” dúró fún ìyókù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, nígbà tí “ọkùnrin mẹ́wàá” dúró fún “ogunlọ́gọ̀ ńlá.”c (Ìṣípayá 7:9, 10; Gálátíà 6:16) Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi yóò wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti pé gẹ́gẹ́ bí Sekaráyà ṣe sọ ọ́, wọn yóò máa sọ onírúurú èdè. Ǹjẹ́ ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní fi apá yẹn hàn nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? Bẹ́ẹ̀ ni.
13. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun wo ló ti wáyé nípa èdè láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní? (b) Kí ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ti ṣe nípa báwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè ṣe túbọ̀ ń fẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí? (Fi àlàyé tó wà nínú àpótí “Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà fún Àwọn Afọ́jú” kún un.)
13 Tá a bá pín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà jákèjádò ayé ní ọdún 1950 sí ọ̀nà márùn-ún, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èdè àbínibí tí ìpín mẹ́ta lára wọn ń sọ. Nígbà tó fi máa di ọdún 1980, iye yẹn ti dín sí ìpín méjì nínú ìpín márùn-ún, àti pé lóde òní, ìpín kan péré nínú ìpín márùn-ún ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí èdè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ èdè àbínibí wọn. Kí ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà ti ṣe nípa onírúurú èdè tó wà báyìí? Ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n pèsè àwọn oúnjẹ tẹ̀mí ní àwọn èdè púpọ̀ sí i. (Mátíù 24:45) Bí àpẹẹrẹ, àádọ́rùn-ún èdè ni wọ́n fi ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa jáde ní ọdún 1950, àmọ́ iye yẹn ti lọ sókè sí nǹkan bí irínwó èdè lóde òní. Ǹjẹ́ ipá tí wọ́n túbọ̀ ń sà nítorí àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè ti mú èso jáde? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ní ìpíndọ́gba, ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn ‘látinú gbogbo èdè’ ló ń di ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! (Ìṣípayá 7:9) Iye náà sì túbọ̀ ń lọ sókè sí i ni. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹja ni “àwọn àwọ̀n” náà ń kó jáde!—Lúùkù 5:6; Jòhánù 21:6.
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Lérè —Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Rẹ̀?
14. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ní ìpínlẹ̀ wa lọ́wọ́? (Fi àlàyé tó wà nínú àpótí “Lílo Èdè Àwọn Adití Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn” kún un.)
14 Dídé táwọn aṣíwọ̀lú ń dé sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti mú kó ṣeé ṣe láti sọ àwọn èèyàn ‘gbogbo ahọ́n’ di ọmọ ẹ̀yìn láìkúrò ní ìlú ẹni. (Ìṣípayá 14:6) Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa tí wọ́n ń gbé ní ìpínlẹ̀ wa? (1 Tímótì 2:4) A lè lo ohun èlò tí ó tọ́ tó sì yẹ fún iṣẹ́ ìpẹja náà. Fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a kọ ní èdè wọn. Tó bá ṣeé ṣe, ṣètò pé kí Ẹlẹ́rìí kan tó gbọ́ èdè wọn máa lọ sọ́dọ̀ wọn. (Ìṣe 22:2) Ṣíṣe àwọn ètò wọ̀nyí ti wá rọrùn báyìí, nítorí pé ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti kọ́ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn àjèjì láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ìròyìn fi hàn pé ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀nà yìí máa ń mérè wá.
15, 16. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ń mérè wá? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè gbé yẹ̀ wò nípa sísìn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè?
15 Gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò láti orílẹ̀-èdè Netherlands, níbi tí wọ́n ti ń fi èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí yọ̀ǹda ara wọn láti lọ ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn láàárín àwọn aṣíwọ̀lú tí wọ́n ń sọ èdè àwọn ará Poland. Àbájáde ìsapá tí wọ́n ṣe yìí dára gan-an débi pé ọkọ wá rí i pé ó yẹ kí òun dín àkókò tí òun fi ń lọ síbi iṣẹ́ kù kó lè ní ọjọ́ kan sí i nínú ọ̀sẹ̀ tí yóò máa fi bá àwọn tó fìfẹ́ hàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tí tọkọtaya yìí fi ń darí ogún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n sọ pe: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mú wa láyọ̀ gan-an ni.” Inú àwọn tó ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń dùn gan-an nígbà táwọn tó ń gbọ́ òtítọ́ Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ wọn bá fi ìmọrírì hàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń fi èdè àwọn ara Vietnam ṣe ìpàdé kan, bàbá àgbàlagbà kan dìde, ó ní kí wọ́n fún òun láyè láti sọ̀rọ̀. Pẹ̀lú omijé ayọ̀ lójú rẹ̀, ó sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún ipá tí ẹ̀ ń sà láti kọ́ èdè mi tó ṣòroó gbọ́. Mo dúpẹ́ gan-an pé mo lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ìyanu látinú Bíbélì ní ọjọ́ ogbó mi.”
16 Abájọ tí àwọn tó ń sìn láwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè fi gbà pé àwọn ń rí ìbùkún yanturu gbà. Tọkọtaya kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a ṣe ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè jẹ́ ọ̀kan lára apá ìjẹ́rìí tá a gbádùn jù lọ láàárín ogójì ọdún tá a ti fi ṣe iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run.” Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn àyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀ kó o bàa lè kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń mọ́kàn yọ̀ yìí? Tó o bá ṣì ń lọ sílé ìwé, ǹjẹ́ o lè kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè kan láti múra sílẹ̀ fún irú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìgbésí ayé rẹ lérè, kó sì kún fún ọ̀pọ̀ ìbùkún. (Òwe 10:22) O ò ṣe bá àwọn òbí rẹ sọ ọ́?
Yíyí Ọwọ́ Padà
17. Báwo la ṣe lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ tí ìjọ wa tí ń ṣiṣẹ́?
17 Láìsí àní-àní, bí ipò nǹkan ṣe máa ń rí nígbà míì kì í jẹ́ kí púpọ̀ nínú wa lè ju “àwọ̀n” wa sí odò ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Àmọ́, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ju bá a ṣe ń ṣe nísinsìnyí lọ ní ìpínlẹ̀ ìjọ wa. Lọ́nà wo? Kì í ṣe nípa yíyí ohun tá à ń bá àwọn èèyàn sọ padà bí kò ṣe nípa yíyí ọ̀nà tá a gbà ń sọ ọ́ padà. Ọ̀pọ̀ àgbègbè ni àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ilé tó láàbò gan-an ti ń pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ ni kì í sí nílé nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Nítorí náà, a lè ní láti ju “àwọ̀n” wa sódò làwọn àkókò tó yàtọ̀ síra àti ní àwọn ibi tó yàtọ̀ síra. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù là ń fara wé yẹn. Ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nínú onírúurú ipò tí wọ́n wà.— Mátíù 9:9; Lúùkù 19:1-10; Jòhánù 4:6-15.
18. Báwo ni jíjẹ́rìí ní onírúurú ipò ṣe jẹ́ ohun tó gbéṣẹ́ gan-an? (Fi àlàyé tó wà nínú àpótí “Sísọ Àwọn Tó Wà Lẹ́nu Iṣẹ́ Ajé Di Ọmọ Ẹ̀yìn” kún un.)
18 Ní àwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, jíjẹ́rìí níbikíbi tá a bá ti lè rí àwọn èèyàn jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ ń pe àfiyèsí sórí jíjẹ́rìí ní onírúurú ibi báyìí. Ní àfikún sí jíjẹ́rìí láti ilé dé ilé, àwọn akéde ti wá ń jẹ́rìí ní pápákọ̀ òfuurufú, àwọn ọ́fíìsì, ilé ìtajà, àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, ibùdókọ̀, lójú pópó, ní àwọn ọgbà ohun alààyè, láwọn etíkun, àti láwọn ibòmíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ní Hawaii ló jẹ́ pé irú ibi bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti kọ́kọ́ bá wọn pàdé. Yíyí ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ padà yóò mú ká lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ dójú àmì, ìyẹn iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—1 Kọ́ríńtì 9:22, 23.
19. Àwọn apá wo nínú àṣẹ tí Jésù pa fún wa ni a ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa kí nìdí àti ibo ni a ó ti ṣe iṣẹ́ náà nìkan, àmọ́ ó tún kan kí ni a ó wàásù rẹ̀ àti títí di ìgbà wo la gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn apá méjì yìí lára àṣẹ tí Jésù pa fún wa ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ó gbé ìbéèrè méjì àkọ́kọ́ yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí. A ó sì gbé ìbéèrè méjì tó kù yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
b Àwọn ìdí mìíràn tá a fi ń wàásù wà nínú Òwe 10:5; Ámósì 3:8; Mátíù 24:42; Máàkù 12:17; Róòmù 1:14, 15.
c Fún àlàyé púpọ̀ sí i lórí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 2001, ojú ìwé 12, àti ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ojú ìwé 408. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tá a fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí sì ni ohun tó ń mú wa ṣe é?
• Ibo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ti tẹ̀ síwájú dé nínú mímú àṣẹ tí Jésù pa fún wọn ṣẹ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn?
• Báwo la ṣe lè máa yíwọ́ padà nínú ‘ọ̀nà tá a ń gbà pẹja,’ kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà fún Àwọn Afọ́jú
Kristẹni alàgbà ni Albert, ó sì tún jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ó ń gbé ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Afọ́jú ni. Lílo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ṣe fún àwọn afọ́jú mú kó lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́, títí kan bíbójútó àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Báwo ló ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tá a yàn fún un nínú ìjọ?
James tó jẹ́ alábòójútó olùṣalága sọ pé: “A ò tíì ní alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tó dáńgájíá bíi ti Albert nínú ìjọ wa rí.” Albert jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáta [5,000] afọ́jú tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó jẹ́ pé yípo ọdún ni wọ́n máa ń gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì tá a sì kọ fún àwọn afọ́jú ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spanish. Ká sòótọ́, láti ọdún 1912 sí àkókò tá a wa yìí, ẹrú olóòótọ́ náà ti ṣe onírúurú ìwé tó lé ni ọgọ́rùn-ún fún àwọn afọ́jú. Nípa lílo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti òde òní, àwọn ibi ìtẹ̀wé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá ń ṣe ọ̀kẹ́ àìmọye abala ìwé àwọn afọ́jú jáde lọ́dọọdún báyìí ní èdè tó lé ní mẹ́wàá, wọ́n sì ń kó wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní àádọ́rin. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tó lè jàǹfààní látinú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì tá a ṣe fún àwọn afọ́jú?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Lílo Èdè Àwọn Adití Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí jákèjádò ayé, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ onítara ló ti kọ́ èdè àwọn adití kí wọ́n lè ran àwọn adití lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Nítorí ìdí èyí, adití mẹ́tàlélọ́gọ́ta ló ṣe ìrìbọmi ní Brazil nìkan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àti pé nísinsìnyí, àwọn adití márùndínlógójì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún níbẹ̀. Jákèjádò ayé, ó ti lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200] ìjọ àti àwọn àwùjọ tó jẹ́ ti èdè àwọn adití. Àyíká kan ṣoṣo tó wà fún kìkì èdè adití ní Rọ́ṣíà ni àyíká tó tóbi jù lọ láyé, nítorí pé jákèjádò ilẹ̀ Rọ́ṣíà ló nasẹ̀ dé!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Sísọ Àwọn Tó Wà Lẹ́nu Iṣẹ́ Ajé Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan ń wàásù fún àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ajé ní àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ní Hawaii, ó bá ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ọkọ̀ èrò kan pàdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ọkùnrin náà dí gan-an, síbẹ̀ ó gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ibi iṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo àárọ̀ Wednesday ló máa ń sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe pe òun lórí tẹlifóònù, á sì pọkàn pọ̀ sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹlẹ́rìí mìíràn ní Hawaii máa ń kọ́ ẹni kan tó ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń tún bàtà ṣe lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Orí káńtà tó wà nínú ṣọ́ọ̀bù náà gan-an ni wọ́n ti máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tí oníbàárà kan bá dé, Ẹlẹ́rìí náà á rọra dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Nígbà tí oníbàárà náà bá lọ, wọ́n á tún máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.
Ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà láti bá ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn àti oníṣọ́ọ̀bù yìí pàdé nítorí pé wọ́n lo ìdánúṣe láti ju “àwọn” wọn sí onírúurú ibi. Ǹjẹ́ o mọ ibì kan ní ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ tó o ti lè rí àwọn tí kì í sábà gbélé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ǹjẹ́ o lè sìn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè?