ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 8-9
  • “Ọ̀pọ̀ Jaburata Ọlà Àwọn Òkun”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọ̀pọ̀ Jaburata Ọlà Àwọn Òkun”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Òkun
    Jí!—2023
  • Iṣẹ́ Àrà Inú Ìṣẹ̀dá Ń Gbé Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 8-9

Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà

“Ọ̀pọ̀ Jaburata Ọlà Àwọn Òkun”

TÓ BÁ dọwọ́ ìrọ̀lẹ́, afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́ gba ojú òkun máa ń bi omi òkun, ìgbì òkun á sì máa rọra bì lu iyanrìn tó wà ní bèbè okun. Ìró ìgbì tó ń bì lu òkun yìí máa ń tu ọ̀pọ̀ èrò tí wọ́n ń rọ́ lọ gbafẹ́ létíkun lára.a

Àwọn etíkun títẹ́jú salalu tí wọ́n gùn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ló wà káàkiri àgbáyé. Òkìtì iyanrìn tó pààlà sáàárín ilẹ̀ àti òkun yìí ló fòté lé ibi tí omi lè ru gùdù dé. Bí Ẹlẹ́dàá ṣe ṣẹ̀dá nǹkan ẹ̀ nìyẹn. Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀, ó kéde pé òun ti “fi iyanrìn pa ààlà òkun.” Ó fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ìgbì rẹ̀ ń bi ara wọn síwá-sẹ́yìn, síbẹ̀, wọn kò lè borí; bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n di aláriwo líle, síbẹ̀, wọn kò lè ré e kọjá.”—Jeremáyà 5:22; Jóòbù 38:8; Sáàmù 33:7.

Omi ló pọ̀ jù ní pílánẹ́ẹ̀tì ayé wa yìí, kò sì sí pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn tó tún lómi nínú tó o lára àwọn pílánẹ́ẹ̀tì yòó kù tí wọ́n jọ ń yí oòrùn po. Ohun tó fẹ̀ tó ìdá méje nínú mẹ́wàá lára òbíríkítí ayé ni omi gbà. Nígbà tí Jèhófà ń ṣẹ̀dá ayé fáwọn ọmọ ènìyàn, ó pàṣẹ pé: “Kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́ jọpọ̀ sí ibì kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì fara hàn. Ó sì wá rí bẹ́ẹ” gẹ́lẹ́. Àkọsílẹ̀ náà tẹ̀ síwájú pé: “Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ ní Ilẹ̀ Ayé, ṣùgbọ́n ìwọ́jọpọ̀ omi ni ó pè ní Òkun. Síwájú sí i, Ọlọ́run rí i pé ó dára.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:9, 10) Iṣẹ́ kí ni alagbalúgbú omi òkun tí Ọlọ́run dá ń ṣe fún ayé?

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà kíkàmàmà ni alagbalúgbú omi tó wà nínú òkun fi wúlò fún àwọn ohun alààyè láti mú kí wọ́n máa wà láàyè nìṣó. Àpẹẹrẹ kan ni pé omi lè tọ́jú ooru pa mọ́. Nípa báyìí, ńṣe ni òkun dà bí àgbá ńlá kan tá à ń tọ́jú ooru pa mọ́ sí nínú, ooru yìí ló ń bá wa dín òtútù kù, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo omi páta ni ì bá dì nígbà òtútù.

Ọ̀nà mìíràn tún wà tí omi gbà ń so ẹ̀mí ohun alààyè ró. Omi ló máa ń mú káwọn nǹkan yòrò jù lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú oníruúrú kẹ́míkà ló ń jẹ́ káwọn ohun àlààyè máa wà, omi ṣe pàtàkì. Ìdí ni pé inú rẹ̀ ni àwọn ohun tín-tìn-tín tó ń jáde látinú kẹ́míkà ti ń yòrò kí àwọn ohun tó wúlò nínú wọn tó lè pò pọ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó para pọ̀ di kẹ́míkà tó wà lára àwọn ohun alààyè ló jẹ́ olómi. Ìwé náà The Sea sọ pé: “Onírúurú ohun alààyè ló nílò omi, inú òkun sì ni gbogbo omi ọ̀hún ti ń wá, kódà àwọn ewéko àtàwọn ẹrànko tó wà lórí ilẹ̀ nílò omi látinú òkun.”

Àwọn òkun tó wà láyé tún ń ṣiṣẹ́ ribiribi láti bá wa sọ afẹ́fẹ́ tó wà láyìíká ayé di mímọ́. Àwọn ohun tín-tìn-tín abẹ̀mí tó wà nínú òkun máa ń fa afẹ́fẹ́ carbon dioxide sínú, wọ́n sì máa ń tú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn jáde. Olùṣèwádìí kan sọ pé “ìdá méje nínú mẹ́wàá afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó máa ń kún èyí tó ti wà láyé tẹ́lẹ̀ lọ́dọọdún máa ń wá látara àwọn ohun tín-tìn-tín abẹ̀mí tó wà nínú òkun.”

A tún lè rí àwọn oògùn tá a fi lè tọ́jú àrùn nínú òkun. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá làwọn èèyàn ti ń rí àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣe oògùn lára ẹja. Ọjọ́ ti pẹ́ tọmọ aráyé ti ń lo epo ara ẹja tí wọ́n ń pè ní Cod-liver oil. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn èròjà kan tí wọ́n rí lára ẹja àtàwọn ẹ̀dá inú omi mìíràn wo ikọ́ òsúkè wọ́n sì tún fi ń kojú àwọn kòkòrò fáírọ́ọ̀sì àti àrùn jẹjẹrẹ.

Àwọn èèyàn ti gbìyànjú láti ṣírò bí àǹfààní tí òkun lè ṣe fún èèyàn lórí ọrọ̀ ajé ṣe pọ̀ tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣẹ́ni tó lè sọ ní pàtó pé bó ṣe pọ̀ tó rèé, síbẹ̀ àwọn olùṣèwádìí ti fojú bù ú pé tá a bá dá àǹfààní tá a lè rí látinú ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn sí mẹ́ta, á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì tá a máa rí látinú àwọn òkun. Èyí fi hàn pé ó nídìí tí Ẹlẹ́dàá fi dá òkun, ìdí ọ̀hún sì ni pé kó lè jẹ́ ibùgbé fáwọn ohun alààyè kó sì máa gbé ẹ̀mí wọn ró. Àbí ẹ ò rí i pé ohun tí Bíbélì sọ nípa “ọ̀pọ̀ jaburata ọlà àwọn òkun” bá ète tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ dá òkun mu!—Diutarónómì 33:19.

Ògo ló yẹ fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá, Oníṣẹ́ Ọnà àti Ẹlẹ́dàá àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí. Orí Nehemáyà wú débi tó fi sọ pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Jèhófà; ìwọ alára ṣe ọ̀run, . . . àwọn òkun àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn; ìwọ sì ń pa gbogbo wọn mọ́ láàyè.”— Nehemáyà 9:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù September àti October nínú 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Omi, Ẹ̀fúùfù àti Ìgbì Òkun

Omi àti ẹ̀fúùfù ló ń di ìgbì lílágbára tí ariwo rẹ̀ máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ dini létí, èyí tó máa ń rọ́ lu àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè bí irú àwọn èyí tó wà ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tá à ń wò níbí yìí. Ìgbà gbogbo la máa ń gbúròó ìgbì lórí òkun, ó máa ń jọni lójú, ó sì máa ń fi bí agbára ìgbì ṣe tó hàn. Tìyanutìyanu la máa ń rántí ọlá ńlá agbára Ẹlẹ́dàá nígbà tá a bá rí wọn. Jèhófà ni ẹni tó “ń rìn lórí ìgbì gíga òkun.” “Ó ti ru òkun sókè nípa agbára rẹ̀, ó sì ti fọ́ afipárọ́luni sí wẹ́wẹ́ nípa òye rẹ̀.” (Jóòbù 9:8; 26:12) Lóòótọ́, “lékè àwọn ìró alagbalúgbú omi, ọlọ́lá ńlá ìgbì òkun tí ń fọ́n ká di ìfóófòó, ọlọ́lá ńlá ni Jèhófà ní ibi gíga.”—Sáàmù 93:4.

Ó Ń Fi Iyanrìn Ṣe Iṣẹ́ Àrà

Láwọn ìgbà míì, iyanrìn etíkun ni ẹ̀fúùfù sábà máa ń fi dárà tó sì máa ń fi gbẹ́ ohun ọnà bí òkè oníyìnyín tó wà létí okun ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, níhà gúúsù Áfíríkà tá à ń wò níbí. Ẹ̀fúùfù lẹ̀lẹ̀ ni olórí ohun tó ń fi iyanrìn ṣiṣẹ́ ọnà. Àwọn òkè oníyìnyín kan lè rí bí àwọn òkìtì ọ̀gán, àwọn míì máa ń ga tó òpó iná méjìdínlógójì lóòró. Pípọ̀ tí iyanrìn etí òkun pọ̀ yẹn jẹ́ ká lóye ohun tí gbólóhùn náà, “àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun,” tó wà nínú Bíbélì túmọ̀ sí. A máa ń lò ó láti ṣàpèjúwe nǹkan tí kò ṣeé kà tàbí tó ṣòro láti wọ̀n. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Ńṣe la ń kún fún ẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ nígbà tá a bá wo ara wa níwájú Ẹlẹ́dàá tó fi iṣẹ́ àrà iyanrìn ṣe odi kí ìjì òkun máa bàa lè kọjá ibi tó yẹ kó dé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí nígbà tí oòrùn bá wọ̀ ní ẹkùn Bight of Biafra lórílẹ̀-èdè Cameroon

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́