Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó o Gbà Pé Párádísè Ń Bọ̀?
“Mo mọ ọkùnrin kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ẹni tí a gbà . . . lọ sínú párádísè.” —2 Kọ́ríńtì 12:2-4.
1. Àwọn ìlérí Bíbélì wo ló ń múnú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn?
PÁRÁDÍSÈ. Ǹjẹ́ o rántí bó ṣe rí lára rẹ nígbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè? O lè rántí ìgbà tó o gbọ́ pé ‘ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí, àti pé aginjù yóò di ibi’ tó lẹ́wà gan-an. Ìgbà tó o gbọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn yóò jọ máa ṣeré àti pé ọmọ ewúrẹ́ òun àmọ̀tẹ́kùn yóò jọ wà pa pọ̀ ńkọ́? Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn nígbà tó o kà á pé àwọn èèyàn rẹ tó ti kú yóò jíǹde tí wọn yóò sì wà nínú Párádísè yẹn títí láé?—Aísáyà 11:6; 35:5, 6; Jòhánù 5:28, 29.
2, 3. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìrètí rẹ, tó dá lórí ohun tí Bíbélì sọ, lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? (b) Kí nìdí mìíràn tí ìrètí wa fi dájú?
2 Ìrètí tó o ní kì í ṣe èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà fún ọ láti gba àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa Párádísè yẹn gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, o ṣáà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún aṣebi tí wọ́n kàn mọ́gi yẹn gbọ́, pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) O ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tó sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” O tún gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí tó sọ pé Ọlọ́run yóò nu omijé nù kúrò lójú wa; ikú kì yóò sì sí mọ́; ìbànújẹ́, igbe ẹkún, àti ìrora á sì di nǹkan àtijọ́. Èyí túmọ̀ sí pé Párádísè ilẹ̀ ayé tún máa wà lẹ́ẹ̀kan sí i!—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:4.
3 Ìdí mìíràn tá a tún fi gbà pé Párádísè yìí máa dé ni ohun kan táwọn Kristẹni jákèjádò ayé ń gbádùn nísinsìnyí. Kí ni ohun náà? Ọlọ́run ti ṣe párádísè tẹ̀mí kan, ó sì ti mú àwọn èèyàn rẹ̀ wá sínú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà “párádísè tẹ̀mí” lè dà bí ohun tó ṣòro lóye, àmọ́ a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú párádísè bẹ́ẹ̀, ó sì wà ní tòótọ́.
Ìran Párádísè Kan
4. Ìran wo ni 2 Kọ́ríńtì 12:2-4 mẹ́nu kàn, ta ló sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló rí ìran náà?
4 Kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nípa párádísè tẹ̀mí yìí, ó ní: “Mo mọ ọkùnrin kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ẹni tí a gbà lọ lọ́nà bẹ́ẹ̀ sí ọ̀run kẹta. . . . Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ irúfẹ́ ọkùnrin kan bẹ́ẹ̀—yálà nínú ara tàbí láìsí ara, èmi kò mọ̀, Ọlọ́run mọ̀—pé a gbà á lọ sínú párádísè, ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò lè fẹnu sọ, èyí tí kò bófin mu fún ènìyàn láti sọ.” (2 Kọ́ríńtì 12:2-4) Àyọkà yẹn ló tẹ̀ lé àwọn ẹsẹ tí Pọ́ọ̀lù ti gbèjà iṣẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì ò sọ nípa ẹlòmíràn tó rí irú ìran yẹn, Pọ́ọ̀lù sì lẹni tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wa. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ pé Pọ́ọ̀lù lẹni tó rí ìran yìí. Inú “párádísè” wo ló wọ̀ nínú ìràn tí Jèhófà fi hàn án yìí?—2 Kọ́ríńtì 11:5, 23-31.
5. Kí ni Pọ́ọ̀lù ò rí, kí sì ni irú “párádísè” yẹn?
5 Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé kì í ṣe gbalasa òfuurufú ni “ọ̀run kẹta” tí Pọ́ọ̀lù rí náà ń tọ́ka sí. Bíbélì sábà máa ń lo nọ́ńbà náà mẹ́ta láti dúró fún ìtẹnumọ́, ìró gbọnmọ-gbọnmọ, tàbí láti túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ kan ṣe lágbára tó. (Oníwàásù 4:12; Aísáyà 6:3; Mátíù 26:34, 75; Ìṣípayá 4:8) Látàrí èyí, ohun tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran yẹn jẹ́ ohun kan tá a gbé ga tàbí tó ga lọ́lá. Ó jẹ́ nǹkan tẹ̀mí.
6. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun tí Pọ́ọ̀lù rí?
6 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ṣáájú jẹ́ ká ní òye tó jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà láyé ọjọ́un kò ṣègbọràn sí i mọ́, ó pinnu pé òun á jẹ́ káwọn ará Bábílónì kọ lu Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Èyí sì yọrí sí ìparun lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa níbàámu pẹ̀lú ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àádọ́rin ọdún; ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run yóò jẹ́ káwọn Júù tó ronú pìwà dà padà sí ilẹ̀ wọn, kí wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Èyí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ láti ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa lọ síwájú. (Diutarónómì 28:15, 62-68; 2 Àwọn Ọba 21:10-15; 24:12-16; 25:1-4; Jeremáyà 29:10-14) Kí lo wá ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ náà fúnra rẹ̀? Láàárín àádọ́rin ọdún yẹn, ilẹ̀ náà di igbó kìjikìji, ó gbẹ táútáú, ó sì di ibùgbé àwọn akátá. (Jeremáyà 4:26; 10:22) Síbẹ̀, ìlérí yìí ṣì wà níbẹ̀ pé: “Ó dájú pé Jèhófà yóò tu Síónì nínú. Ó dájú pé òun yóò tu gbogbo ibi ìparundahoro rẹ̀ nínú, òun yóò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà [tàbí Párádísè, Septuagint] Jèhófà.”—Aísáyà 51:3; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
7. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àádọ́rin ọdún tí ìlú náà ti pa run?
7 Lẹ́yìn àádọ́rin ọdún nìyẹn ṣẹlẹ̀. Pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run, ipò nǹkan yí padà sí rere. Fojú inú wo èyí ná: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. Láìkùnà, yóò yọ ìtànná, ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. . . . Ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-únhán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi. Ibi gbígbé àwọn akátá, ibi ìsinmi wọn, ni koríko tútù yóò wà pẹ̀lú esùsú àti òrépèté.”—Aísáyà 35:1-7.
Ọlọ́run Mú Wọn Padà Bọ̀ Sípò Ó sì Yí Wọn Padà
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn èèyàn ni Aísáyà orí karùnlélọ́gbọ̀n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
8 Ìyípadà ńlá mà lèyí o! Ilẹ̀ tí ó dahoro wá di Párádísè. Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ṣeé fọkàn tẹ̀ fi hàn pé àwọn èèyàn pàápàá yóò yí padà, bí ìgbà tí ilẹ̀ tó dahoro tẹ́lẹ̀ bá di ilẹ̀ eléso. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tóò, “àwọn tí Jèhófà tún rà padà” ni Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ìyẹn àwọn tí yóò “fi igbe ìdùnnú” padà sí ilẹ̀ wọn, tí ọwọ́ wọn yóò si tẹ “ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀.” (Aísáyà 35:10) Kì í ṣe ilẹ̀yílẹ̀ nìyẹn ń tọ́ka sí o, bí kò ṣe àwọn èèyàn. Láfikún sí i, ibòmíràn wà tí Aísáyà tún ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn tó padà sí Síónì, ó ní: “A ó sì máa pè wọ́n ní igi ńlá òdodo, ọ̀gbìn Jèhófà . . . Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ayé ti ń mú ìrújáde rẹ̀ wá, . . . Jèhófà . . . yóò mú kí òdodo àti ìyìn rú jáde ní iwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.” Aísáyà tún sọ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó ní: “Ó dájú pé Jèhófà yóò máa ṣamọ̀nà rẹ nígbà gbogbo . . . , yóò sì fún egungun rẹ gan-an lókun; ìwọ yóò sì dà bí ọgbà tí a ń bomi rin dáadáa.” (Aísáyà 58:11; 61:3, 11; Jeremáyà 31:10-12) Nítorí náà, bí ipò tí ilẹ̀ náà wà ṣe máa sunwọ̀n sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ipò àwọn Júù tá a mú padà bọ̀ yóò ṣe yí padà.
9. Irú “párádísè” wo ni Pọ́ọ̀lù rí, ìgbà wo ló sì nímùúṣẹ?
9 Ìtàn yìí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìràn. Yóò kan ìjọ Kristẹni, èyí tó pè ní “pápá Ọlọ́run tí a ń ro lọ́wọ́” tó sì gbọ́dọ̀ mú èso jáde. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Ìgbà wo ni ìran yẹn máa nímùúṣẹ? Pọ́ọ̀lù pe ohun tó rí ní ‘ìṣípayá,’ ìyẹn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ̀ pé lẹ́yìn ikú òun, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni yóò di apẹ̀yìndà. (2 Kọ́ríńtì 12:1; Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:3, 7) Nígbà tí àwọn apẹ̀yìndà bá pọ̀ yamùrá, tó sì dà bíi pé wọ́n fẹ́ borí, a ò lè sọ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ dà bí ọgbà tó ń méso jáde. Síbẹ̀, àkókò ń bọ̀ tí a óò gbé ìjọsìn tòótọ́ ga lẹ́ẹ̀kan sí i. A óò mú àwọn èèyàn Ọlọ́run padà bọ̀ sípò kí ‘àwọn olódodo lè máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.’ (Mátíù 13:24-30, 36-43) Ìyẹn sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tá a fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ ní ọ̀run. Bí ọ̀pọ̀ ọdún sì ti kọjá, ó ti wá hàn kedere pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn párádísè tẹ̀mí, tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran yẹn.
10, 11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé a wà nínú párádísè tẹ̀mí bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá?
10 Ní ti tòótọ́, a mọ̀ pé aláìpé ni gbogbo wa, nítorí náà kò yà wá lẹ́nu pé àwọn ìṣòro máa ń wà láàárín wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bó ṣe rí láàárín àwọn Kristẹni nígbà ayé Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́ríńtì 1:10-13; Fílípì 4:2, 3; 2 Tẹsalóníkà 3:6-14) Àmọ́, ronú nípa párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí. Tá a bá fi wé ipò aláìsàn nípa tẹ̀mí tá a wà tẹ́lẹ̀, a ó rí i pé a ti mú wa lára dá nípa tẹ̀mí. Tún fi oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń jẹ ní àjẹyó nísinsìnyí wé bá a ṣe ń ráágó nípa tẹ̀mí nígbà kan rí. Dípò táwọn èèyàn Ọlọ́run yóò fi máa rá pálá lórí ilẹ̀ gbígbẹ táútáú nípa tẹ̀mí, Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà wọn, ó sì ń rọ̀jò ìbùkún sórí wọn. (Aísáyà 35:1, 7) Dípò kí a wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí, a ti rí ìmọ́lẹ̀ òmìnira àti ojú rere Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ tí kò gbọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì rí ti gbọ́ báyìí, wọ́n sì ti lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ wí nípa rẹ̀. (Aísáyà 35:5) Bí àpẹẹrẹ, àìmọye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ti kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì láti ẹsẹ dé ẹsẹ. Ẹ̀yìn ìyẹn la tún gbé gbogbo orí tó wà nínú ìwé Aísáyà inú Bíbélì yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan. Ǹjẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí tó tuni lára yìí kì i ṣe ẹ̀rí tó hàn kedere pé inú párádísè tẹ̀mí la wà?
11 Tún ronú nípa ìyípadà tó ti wáyé nínú ìwà àbínibí bí àwọn olóòótọ́ èèyàn tó wá láti onírúurú ibi tó yàtọ̀ síra ṣe ń sapá láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fi ṣèwà hù. Láìsí àní-àní, wọ́n ti sapá gidigidi láti pa àwọn ìwà ẹhànnà wọn àtijọ́ tì pátápátá. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti pa àwọn ìwà búburú kan tì, kó o sì ti rí i pé àbájáde rẹ̀ dára gan-an, bí ọ̀ràn àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí ṣe rí náà nìyẹn. (Kólósè 3:8-14) Nítorí náà, bó o ṣe ń wá sí ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àárín àwọn èèyàn tí kì í fa wàhálà rárá tí wọ́n sì dún ún bá da nǹkan pọ̀ lo wà. Síbẹ̀, wọn ò tíì di ẹni pípé o, àmọ́ ó dájú pé wọ́n ti kúrò lẹ́ni tá a lè pè ní kìnnìún tàbí ẹranko ẹhànnà tí ń pẹran jẹ. (Aísáyà 35:9) Kí ni ìpéjọpọ̀ tẹ̀mí tó lárinrin yìí fi hàn? Dájúdájú, ipò tẹ̀mí kan là ń gbádùn yẹn, ìyẹn gan-an la sì ń pè ni párádísè tẹ̀mí. Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn nísinsìnyí jẹ́ àpẹẹrẹ Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí a óò gbádùn lọ́jọ́ iwájú tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.
12, 13. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa wà nínú párádísè tẹ̀mí títí lọ?
12 Àmọ́, ohun kan wà tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá. Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ sì máa pa gbogbo àṣẹ tí mo ń pa fún ọ lónìí mọ́, kí ẹ bàa lè di alágbára, kí ẹ sì lè wọlé ní tòótọ́, kí ẹ sì gba ilẹ̀” náà. (Diutarónómì 11:8) A tún mẹ́nu kan ilẹ̀ kan náà yìí nínú Léfítíkù 20:22, 24 tó sọ pé: “Kí ẹ máa pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn, kí ilẹ̀ tí èmi yóò mú yín wá sí láti máa gbé má bàa pọ̀ yín jáde. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wí fún yín pé: ‘Ẹ̀yin, ní tiyín, yóò gba ilẹ̀ wọn, àti èmi, ní tèmi, yóò fi í fún yín láti gbà á, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, tí ọwọ́ wọn bá máa tẹ Ilẹ̀ Ìlérí náà, wọ́n ní láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Tìtorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ló ṣe fàyè gba àwọn ará Bábílónì láti ṣẹ́gun wọn, tí wọ́n sì kó wọn kúrò ní ibùgbé wọn.
13 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè máa múnú wa dùn nínú párádísè tẹ̀mí tá a wà yìí. Àyíká ibẹ̀ dùn ún wò, ó sì tuni lára. A wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí wọ́n ti pa ìwà ẹhànnà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀ tì. Wọ́n ń sapá láti jẹ́ onínúure àti ẹni tó wúlò fáwọn ẹlòmíràn. Síbẹ̀, a ní láti ṣe ju pé ká kàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn wọ̀nyí láti lè wà nínú párádísè tẹ̀mí yìí títí lọ. Ó tún gba pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, ká sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Míkà 6:8) Lóòótọ́, àwa fúnra wa la wá sínú párádísè tẹ̀mí yìí, àmọ́ a lè sú lọ kúrò níbẹ̀ tàbí kí wọ́n yọ wá kúrò níbẹ̀ tá ò bá sapá láti pa àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run mọ́.
14. Kí ni ohun kan tí yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa wà nínú párádísè tẹ̀mí nìṣó?
14 Ohun pàtàkì kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa bá a lọ láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa fi okun kún okun wa. Kíyè sí èdè ìṣàpẹẹrẹ tó wà nínú Sáàmù 1:1-3, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì, tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń tẹ̀ jáde tún ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa nínú párádísè tẹ̀mí náà.—Mátíù 24:45-47.
Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ọ Lójú Pé Párádísè Ń Bọ̀
15. Kí nìdí tí Mósè ò fi lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ kí ló rí?
15 Tún wo ohun mìíràn tó jẹ́ àpẹẹrẹ bí Párádísè náà yóò ṣe rí. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rìn káàkiri láginjù fún ogójì ọdún gbáko, Mósè kó àwọn èèyàn náà lọ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, ní ìhà ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Nítorí àṣìṣe kan tí Mósè ṣe, Jèhófà pinnu pé Mósè ò ní kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá odò Jọ́dánì. (Númérì 20:7-12; 27:12, 13) Mósè bẹ Ọlọ́run pé: “Jẹ́ kí ń ré kọjá, jọ̀wọ́, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára tí ó wà ní òdì-kejì Jọ́dánì.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè ò lè wọ ilẹ̀ náà, ó mọ̀ pé “ilẹ̀ dáradára” ni nígbà tó gorí Òkè Písígà, tó wá rí gbogbo àwọn agbègbè ilẹ̀ náà. Báwo lo ṣe rò pé ilẹ̀ ọ̀hún ṣe rí?—Diutarónómì 3:25-27.
16, 17. (a) Báwo ni Ilẹ̀ Ìlérí ìgbàanì ṣe yàtọ̀ sí bí ilẹ̀ náà ṣe rí lóde òní? (b) Kí nìdí tá a fi lè gbà gbọ́ pé bíi Párádísè ni Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí láyé ìgbà kan?
16 Tó o bá ń fojú bí agbègbè yẹn ṣe wá dà báyìí wò ó, o lè rò pé ilẹ̀ oníyanrìn tó gbẹ táútáú kan ni tàbí aṣálẹ̀ olókùúta kan, o sì tún lè rò pé ilẹ̀ olóoru gbígbóná kan ni. Ṣùgbọ́n ìdí wà tó fi hàn pé ilẹ̀ yẹn ò rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì. Nínú ìwé ìròyìn náà, Scientific American, Ọ̀mọ̀wé Walter C. Lowdermilk, tó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ erùpẹ̀ àti omi, ṣàlàyé pé, àwọn ilẹ̀ tó wà ní àgbègbè yẹn làwọn èèyàn ti “bà jẹ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.” Ọ̀mọ̀wé yìí tún kọ ọ́ pé: “Ilẹ̀ tó tutù yọ̀yọ̀ tẹ́lẹ̀ tó wá ‘daṣálẹ̀’ báyìí ò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ adáríhurun ni.” Kódà, ìwádìí rẹ̀ fi hàn pé “ilẹ̀ yìí ti fìgbà kan rí jẹ́ ilẹ̀ eléwéko tútù yọ̀yọ̀ bíi Párádísè.” Nítorí náà, àṣìlò àwọn ọmọ èèyàn ló sọ “ilẹ̀ eléwéko tútù yọ̀yọ̀ bíi Párádísè náà” dìdàkudà.a
17 Tó o bá ronú lórí ohun tó o ti kà nínú Bíbélì, ó lè rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Párádísè ni ilẹ̀ náà. Rántí ohun tí Jèhófà tipasẹ̀ Mósè mú dá àwọn èèyàn náà lójú, ó ní: “Ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń sọdá sí láti gbà jẹ́ ilẹ̀ àwọn òkè ńlá àti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì. Láti inú òjò ojú ọ̀run ni ó ti ń mu omi; ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń bójú tó.”—Diutarónómì 11:8-12.
18. Báwo ni ìwé Aísáyà 35:2 ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn mọ bí Ilẹ̀ Ìlérí náà ṣe máa rí?
18 Ilẹ̀ ọlọ́ràá ni Ilẹ̀ Ìlérí, nǹkan ọ̀gbìn sì máa ń ṣe dáadáa níbẹ̀ débi pé wíwulẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ibi kan níbẹ̀ máa ń mú ohun tó dà bíi Párádísè wá síni lọ́kàn. Ìyẹn hàn kedere nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà orí karùnlélọ́gbọ̀n, èyí tó ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà dé láti Bábílónì. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Láìkùnà, yóò yọ ìtànná, ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Ògo Lẹ́bánónì pàápàá ni a ó fi fún un, ọlá ńlá Kámẹ́lì àti ti Ṣárónì. Àwọn kan yóò wà tí yóò rí ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run wa.” (Aísáyà 35:2) Bí ẹsẹ yẹn ṣe tọ́ka sí Lẹ́bánónì, Kámẹ́lì, àti Ṣárónì ti ní láti gbé àwòrán kan tó dára tó sì lẹ́wà wá sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn.
19, 20. (a) Ṣàpèjúwe bí Ṣárónì ìgbàanì ṣe rí. (b) Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà túbọ̀ fún ìrètí wa nípa Párádísè lókun?
19 Ronú nípa Ṣárónì, pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun kan tó wà láàárín àwọn òkè Samáríà àti Òkun Ńlá tàbí Mẹditaréníà. (Wo fọ́tò tó wà lójú ìwé 10.) A mọ ilẹ̀ yẹn sí ilẹ̀ eléwéko tútù yọ̀yọ̀ tó máa ń méso jáde gan-an. Bó ṣe jẹ́ ilẹ̀ tó lómi dáadáa tó sì lọ́ràá yẹn mú kó dáa gan-an fún àwọn ẹran ọ̀sìn láti jẹko níbẹ̀, àmọ́ ó tún ní àwọn igbó tó kún fún igi óákù ní ìhà àríwá rẹ̀. (1 Kíróníkà 27:29; Orin Sólómọ́nì 2:1; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Aísáyà 65:10) Abájọ tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 35:2 fi sọ nípa ìmúbọ̀sípò, tó tún sọ nípa ilẹ̀ kan tó ń yọ ìtànná pẹ̀lú ọlá ńlá, tó sì dà bíi Párádísè. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún ń sọ nípa párádísè tẹ̀mí kan tó tuni lára, èyí tó bá ohun tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran lẹ́yìn ìgbà yẹn mu. Ni paríparì rẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn ń fún ìrètí wa lókun pé Párádísè yóò wà fún ìran ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé.
20 Bá a ṣe ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí báyìí, a lè túbọ̀ mọyì rẹ̀, a sì lè mú kí ìrètí tá a ní pé Párádísè ilẹ̀ ayé yóò dé túbọ̀ lágbára sí i. Báwo la ó ṣe ṣe èyí? Nípa jíjẹ́ kí òye ohun tá à ń kà nínú Bíbélì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Àwọn ibi tí Bíbélì júwe àtàwọn ibi tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sábà máa ń jẹ́ àwọn àgbègbè pàtó kan. Ṣé ó wù ọ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa ibi táwọn àgbègbè wọ̀nyí wà àti bí wọ́n ṣe jìnnà sí àwọn àgbègbè mìíràn tó? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a ó jíròrò ọ̀nà tó o lè gbà ṣe èyí tí yóò sì ṣe ọ́ láǹfààní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Denis Baly, sọ nínú ìwé The Geography of the Bible pé: “Bí àwọn igbó ibẹ̀ ṣe rí á ti yí padà gan-an láti àwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì.” Kí lohun tó fà á? “Àwọn èèyàn máa ń lo igi fún iná dídá àti ilé kíkọ́, nítorí náà . . . wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn igi tó wà níbẹ̀ tó fi di pé òjò àti oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí ba ilẹ̀ náà jẹ́. Bí wọ́n ṣe pa igbó ibẹ̀ run yìí ni olórí ohun tó ba agbègbè ilẹ̀ náà jẹ́.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• “Párádísè” wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran?
• Ìmúṣẹ wo ni Aísáyà orí karùnlélọ́gbọ̀n kọ́kọ́ ní, báwo ló sì ṣe kan ohun tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran?
• Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọyì párádísè tẹ̀mí tá a wà nínú rẹ̀ tí a ó sì mú kí ìrètí wa nípa Párádísè ilẹ̀ ayé túbọ̀ lágbára sí i?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì jẹ́ àgbègbè kan ní Ilẹ̀ Ìlérí, ó sì ń méso jáde
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Mósè rí i pé “ilẹ̀ dáradára” ni