ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/15 ojú ìwé 4-7
  • Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Wà Láàyè Títí Láé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Wà Láàyè Títí Láé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ayé Máa Súni Téèyàn Bá Wà Láàyè Títí Láé?
  • Ṣé Ẹ̀mí Èèyàn Tì Kò Gùn Ló Mú Kí Ìwàláàyè Jọni Lójú?
  • Àwọn Èèyàn Rẹ Ń Kọ́?
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Jẹ́ Ohun Aláyọ̀ Tá À Ń Retí
  • Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tó Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/15 ojú ìwé 4-7

Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Wà Láàyè Títí Láé?

MÀMÁ àgbàlagbà kan ní orílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Ẹ̀rù ikú ò bà mí. Ṣùgbọ́n, ó máa ń dùn mí gan-an pé máa fi àwọn òdòdó yìí sílẹ̀ lọ́jọ́ kan.” Obìnrin oníwàásù kan tó wá kí màmá àgbàlagbà yìí mọ̀ pé ọgbà rírẹwà tí màmá náà ní ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó sọ pé ẹ̀rù ikú ò bá àwọn ni àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá máa ń wù, wọn ò sì ní fẹ́ kú.

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn wà láàyè títí láé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé kò ṣeé ṣe. Àwọn kan tiẹ̀ lè sọ pé àwọn ò fẹ́ wà láàyè títí láé. Kí ló lè mú kéèyàn ní irú èrò yẹn?

Ǹjẹ́ Ayé Máa Súni Téèyàn Bá Wà Láàyè Títí Láé?

Àwọn kan rò pé ayé á súni téèyàn bá wà láàyè títí láé. Wọ́n lè máa tọ́ka sáwọn tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ pé wọn ò níṣẹ́ míì ju pé kí wọ́n máa wo tẹlifíṣọ̀n. Tí ìwọ náà bá nírú èrò yẹn, ronú lórí ohun tí Robert Jastrow, onímọ̀ nípa sánmà, sọ nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ìbùkún tàbí ègún ló máa jẹ́ téèyàn bá wà láàyè títí láé. Nígbà tí Jastrow fèsí, ó sọ pé: “Ìbùkún ló máa jẹ́ fáwọn tó fẹ́ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọn ò sì yéé kẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe lọkàn wọn máa balẹ̀ bí wọ́n ṣe mọ̀ pé títí ayé làwọn yóò máa kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, ègún ni ìyè àìnípẹ̀kun máa jẹ́ fáwọn tí wọ́n rò pé àwọn ti mọ gbogbo nǹkan tán, tí wọ́n sì ti tilẹ̀kùn ọkàn wọn pa. Wọn ò ní mọ́ ohun tí wọ́n máa fàkókò wọn ṣe.”

Irú ẹ̀mí tó o ní ló máa fi hàn bóyá ayé máa sú ọ tàbí kò ní sú ọ tó o bá wà láàyè títí láé. Tó o bá jẹ́ ẹnì kan ‘tó fẹ́ máa mọ nǹkan tí ò sì yéé kẹ́kọ̀ọ́,’ ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè gbéṣe nídìí iṣẹ́ ọnà, orin kíkọ, iṣẹ́ ilé kíkọ́, iṣẹ́ ọ̀gbìn tàbí àwọn nǹkan míì tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ kó o láǹfààní láti túbọ̀ mọ oríṣiríṣi nǹkan ṣe, àgàgà àwọn nǹkan tó o nífẹ̀ẹ́ sí.

Àǹfààní tá a máa ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn títí láé kí àwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ wa máa jẹ́ kí ìyè àìnípẹ̀kun lárinrin. Ọlọ́run ti dá ìfẹ́ mọ́ wa, ìdí nìyẹn tínú wa fi máa ń dùn nígbà tá a bá mọ̀ pé àwọn èèyàn fẹ́ràn wa. Tí àwa àtàwọn ẹlòmíràn bá ń fi ìfẹ́ gbé, èyí máa ń fini lọ́kàn balẹ̀, ìbàlẹ̀ ọkàn ọ̀hún sì máa ń wà pẹ́. Kì í ṣe pé ìyè àìnípẹ̀kun máa jẹ́ ká láǹfààní láti bá àwọn èèyàn dọ́rẹ̀ẹ́ nìkan ni, àmọ́ á tún mú ká di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run pàápàá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 8:3) Àǹfààní yẹn mà pọ̀ gan-an o, ká mọ Ọba Aláṣẹ àgbáyé kí òun náà sì mọ̀ wá! Kì í tún ṣe ìyẹn nìkan, títí ayé ni a óò láǹfààní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́. Kí ló máa mú kí ìyè àìnípẹ̀kun súni nínú ìyẹn?

Ṣé Ẹ̀mí Èèyàn Tì Kò Gùn Ló Mú Kí Ìwàláàyè Jọni Lójú?

Àwọn kan rò pé àkókò kúkúrú téèyàn ń lò láyé ló ń mú káyé dùn ún gbé. Wọ́n lè máa fi ẹ̀mí èèyàn wé wúrà nítorí pé wúrà ò wọ́pọ̀. Wọ́n ní wúrà ò ní jọ èèyàn lójú mọ́ tó bá jẹ́ ibi gbogbo la ti lè rí i. Síbẹ̀, ìyẹn ò bú ẹwà wúrà kù. Bí ọ̀rọ̀ ẹ̀mí èèyàn ṣe rí gan-an nìyẹn.

A lè fi wíwà tá a máa wà láàyè títí láé wé afẹ́fẹ́ tó wà níbi gbogbo. Tí ọkọ̀ kan tó ń rìn lábẹ́ omi bá bà jẹ́, tí kò sì lè kúrò lábẹ́ omi wá sókè, àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà á mọyì afẹ́fẹ́ gan-an. Lẹ́yìn tá a bá sì fa ọkọ̀ náà sókè tí àwọn tó wà nínú rẹ̀ jáde síta, ǹjẹ́ ẹ rò pé afẹ́fẹ́ tó wà káàkiri lórí ilẹ̀ ò wá ní jọ wọ́n lójú mọ́? Rárá o, á jọ wọ́n lójú mọ̀nà!

Bíi ti àwọn tó ń rìnrìn àjò lábẹ́ omi yẹn, wọ́n lè yọ àwa náà nínú ewu, kí á lè láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Ọlọ́run yóò tipa ẹbọ ìràpadà Jésù mú àìpé àti ikú kúrò, yóò sì fún àwọn èèyàn onígbọràn ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ ò rí pé ó yẹ ká dúpẹ́, ká sì tún ọpẹ́ dá fún irú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí!

Àwọn Èèyàn Rẹ Ń Kọ́?

Àwọn kan lè máa sọ pé: ‘Àwọn èèyàn mi ńkọ́? Ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ò ní jámọ́ nǹkan kan lójú mi tí mo bá wà ńbẹ̀ táwọn èèyàn mi ò sí ńbẹ̀.’ Ó ṣeé ṣe kó o ti ní ìmọ̀ Bíbélì kó o sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àǹfààní téèyàn ní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16; 17:3) Kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ káwọn ara ilé rẹ, àwọn míì tó jẹ́ èèyàn rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Wàá sì fẹ́ káwọn náà jẹ̀gbádùn àwọn nǹkan tó ò ń retí láti gbádùn nínu ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:13.

Àmọ́, tí kò bá wu àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn èèyàn rẹ pé kí wọ́n wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Má tìtorí ìyẹn sọ pé o ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Máa gba ìmọ̀ pípéye inú Ìwé Mímọ́ nìṣó, kó o sì máa fi àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ nínú rẹ̀ ṣèwà hù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí, aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?” (1 Kọ́ríńtì 7:16) Èèyàn máa ń yí padà. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tí kò fara mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni nígbà kan rí yí padà, ó tiẹ̀ di alàgbà nínú ìjọ Kristẹni. Ọkùnrin náà sọ pé: “Inú mi dùn pé àwọn ará ilé mi dúró gbọn-in, wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí mo fi ṣe inúnibíni sí wọn.”

Ẹ̀mí rẹ àti tàwọn èèyàn rẹ ṣeyebíye gan lójú Ọlọ́run. Àní, “Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ wà láàyè títí láé. Ìfẹ́ tó ní sí wa ju èyí táwọn èèyàn aláìpé ní sí wa lọ. (Aísáyà 49:15) Nítorí náà, o ò ṣe múra sí bí wàá ṣe ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè ran àwọn èèyàn rẹ lọ́wọ́ kí àwọn náà lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí wọn ò bá tiẹ̀ tíì ní irú ìrètí tó o ní láti wà láàyè títí láé báyìí, wọ́n lè yí ìwà wọn padà tí wọ́n bá rí i pé ò ń fi ìmọ̀ pípéye tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù.

Àmọ́, àwọn èèyàn rẹ tó ti kú ńkọ́? Bíbélì sọ pé ohun ìyanu kan máa ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú, ohun ìyanu náà sì ni pé wọ́n máa jíǹde, wọn á sì máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Jésù Kristi ṣèlérí pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Kódà àwọn tí ò mọ Ọlọ́run kí wọ́n tó kú pàápàá yóò jíǹde, nítorí Bíbélì sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Inú wa á má dùn gan o láti rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà àjíǹde!

Ìyè Àìnípẹ̀kun Jẹ́ Ohun Aláyọ̀ Tá À Ń Retí

Tí inú rẹ bá lè máa dùn kó o sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú ayé tá a wà yìí láìka àwọn ìṣòro tó kúnnú rẹ̀ sí, ó dájú pé wàá gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí ọkàn lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún obìnrin kan nípa àwọn ìbùkún téèyàn máa gbádùn nígbà téèyàn bá ní ìyè àìnípẹ̀kun, obìnrin náà sọ pé: “Mi ò fẹ́ wà láàyè títí láé. Àádọ́rin ọdún sí ọgọ́rin ọdún téèyàn ń lò láyé yìí ti tó mi.” Kristẹni alàgbà kan tó wà níkàlẹ̀ lọ́jọ́ náà béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé: “Ǹjẹ́ o tíì fìgbà kan rí ronú nípa bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ rẹ tó o bá kú?” Bí omi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú obìnrin náà nìyẹn nígbà tó ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn tí ikú òun máa kó bá àwọn ọmọ òun. Obìnrin náà sọ pé: “Mó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà nísinsìnyí ni pé tara mi nìkan ni mò ń rò, mo sì wá rí i pé ìyè àìnípẹ̀kun kì í ṣe kéèyàn kàn wà láàyè àmọ́ ó kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”

Àwọn kan lè máa rò pé àwọn kú o àwọn wà láàyè o, kò sẹ́ni tó kàn. Àmọ́, ó kan Ẹni tó fún wa ní ìyè, tó sọ pé: “Bí mo ti ń bẹ láàyè, . . . èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Tí Ọlọ́run bá lè ka ẹ̀mí àwọn èèyàn búburú sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ yẹn, ó dájú pé kò ní fọ̀rọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá àti rárá.

Ó dá Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì lójú hán-ún pé Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ṣeré. Nígbà kan, Dáfídì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ó ṣeé ṣé kí Dáfídì mọ̀ pé àwọn òbí òun fẹ́ràn òun. Àmọ́ bí àwọn òbí rẹ̀, ìyẹn àwọn tó sún mọ́ ọn jù lọ láyé yìí bá tiẹ̀ pa á tì, ó mọ̀ pé Ọlọ́run ò ní pa òun tì. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé ló mú kó sọ pé òun máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, tó sì mú kó fún wọn láǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ títí láé. (Jákọ́bù 2:23) Ǹjẹ́ kò yẹ ká dúpẹ́ ká sì tẹ́wọ́ gba àgbàyanu ẹ̀bùn wọ̀nyí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àtàwọn ọmọnìkejì wa kò ní jẹ́ kí wíwà láàyè títí láé sú wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́