ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 23-25
  • Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kan Tó Lárinrin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kan Tó Lárinrin
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Ìṣírí Fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́
  • Àwọn Ìrírí Gbígbádùnmọ́ni Látẹnu Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
  • Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead Rán Àwọn Míṣọ́nnárì Lọ sí “Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • A Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Ní Gílíádì Láti Máa Sọ̀rọ̀ “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 23-25

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kan Tó Lárinrin

“ỌLỌ́RUN bá wa ṣé, ọjọ́ òní dára gan-an ni. Oòrùn ń ràn, ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ kedere. Àwọn ewéko tutù. Àwọn ẹyẹ ń kọrin. Gbogbo ohun tó máa mú kọ́jọ́ òní pinminrin ni Ọlọ́run fún wa, kò sí nǹkan kan tó máa ba ọjọ́ òní jẹ́ fún wa. Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run tó ń jáni kulẹ̀. Ọlọ́run ìbùkún ni.”

Gbólóhùn yìí ni Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹtàdínlọ́gọ́fà [117] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. September 11, 2004 layẹyẹ ọ̀hún wáyé. Lára àwọn ohun dídùndídùn tó para pọ̀ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà ni ìmọ̀ràn tí ń gbéni ró látinú Bíbélì àtàwọn ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà àtàwọn míṣọ́nnárì tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ sọ. Ká sòótọ́, ọjọ́ tó lárinrin lọ́jọ́ náà jẹ́ fáwọn tó pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower nílùú Patterson, ìpínlẹ̀ New York, àtàwọn tó ń wo bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe ń lọ ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn àti ti Wallkill. Ẹgbẹ̀rún méje ó dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [6,974] ni gbogbo àwọn tó pésẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìṣírí Fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́

Arákùnrin John Kikot, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ ìṣírí lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Láyọ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì.” Ó ní àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì máa ń láyọ̀, ayẹyẹ ọjọ́ òní sì jẹ́rìí sí èyí. Ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà lákòókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ fún wọn láyọ̀, wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti jẹ́ káwọn mìíràn láyọ̀ bíi tiwọn. Báwo ni wọ́n á ṣe ṣe é? Nípa lílo gbogbo ara wọn nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn ni. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Báwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí ṣe ń fara wé Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀” àti ọ̀làwọ́, ẹni tó ń mú kí òtítọ́ tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́, gbogbo ìgbà làwọn fúnra wọn á máa láyọ̀.—1 Tímótì 1:11.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ wá kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni David Splane, tóun náà jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Báwo Lo Ṣe Lè Máa Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn?” Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé wíwà pa pọ̀ níṣọ̀kan dára gan-an ó sì máa ń dùn mọ́ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè gba pé ká di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:22; Sáàmù 133:1) Arákùnrin Splane sọ pé oríṣiríṣi èèyàn làwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí yóò bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn. Lára wọn láwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wọn, àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ wọn tuntun, àtàwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ń darí iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ó wá sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe tó máa mú kí àárín àwọn àtàwọn èèyàn gún régé débi tó bá ṣeé ṣe dé. Ó ní kí wọ́n kọ́ èdè táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ wọn ń sọ, kí wọ́n mọ àṣà wọn kí wọ́n sì pa á mọ́, ó tún ní kí wọ́n má ṣe lọ máa dí àwọn míṣọ́nnárì ẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ nínú ilé wọn, kí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn sáwọn tó ń múpò iwájú.—Hébérù 13:17.

Arákùnrin Lawrence Bowen tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló kàn láti sọ̀rọ̀. Ó béèrè pé: “Ṣé Ìrònú Rẹ̀ Bá Ti Ọlọ́run Mu?” Ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé àwọn tó ń fi ‘ìrísí èèyàn ṣèdájọ́’ kò gbà pé Jésù ni Mèsáyà. (Jòhánù 7:24) Nítorí pé aláìpé ni wá, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa máa ṣọ́ra ká má ṣe ‘ní ìrònú ènìyàn’ bí kò ṣe “ìrònú Ọlọ́run.” (Mátíù 16:22, 23) Kódà, àwọn tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí pàápàá gbọ́dọ̀ máa darí èrò ọkàn wọn sórí ohun tó dáa nígbà gbogbo. Béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ máa darí ọkọ̀ òkun, bẹ́ẹ̀ náà ni dídarí èrò wa sórí ohun tó dáa nísinsìnyí ṣe lè mú kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé, ọkọ̀ tẹ̀mí wa ò sì ní rì. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà gbogbo àti ríronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ń sọ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní “ìrònú Ọlọ́run.”

Arákùnrin Wallace Liverance, tóun náà jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sọ̀rọ̀ kẹ́yìn lára àwọn tó sọ̀rọ̀ ìṣírí náà. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó gbé ka Aísáyà 55:1 ni, “Kí Ni Wàá Rà?” Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n “ra” ìtura, ayọ̀, àtohun tó ń gbé ẹ̀mí ró, èyí tí à ń rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ, ó fi ohun tí Ọlọ́run sọ yìí wé omi, wáìnì, àti wàrà. Báwo lèèyàn ṣe lè rà á “láìsí owó àti láìsí ìdíyelé?” Arákùnrin Liverance sọ pé nípa fífiyèsí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ni àti nípa fífi àwọn èrò àti ọ̀nà Ọlọ́run rọ́pò àwọn èrò àti ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Aísáyà 55:2, 3, 6, 7) Báwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, wọ́n á lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn nílẹ̀ òkèèrè nìṣó. Èrò tó sábà máa ń wá sọ́kàn ẹ̀dá aláìpé ni pé, èèyàn ò lè láyọ̀ tí ò bá ní tibí ní tọ̀hún. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ má gbà wọ́n gbọ́ o. Ẹ má ṣe ní irú èrò yẹn rárá. Ẹ rí i pé ẹ ní àkókò tẹ́ ẹ yà sọ́tọ̀ fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ gidi nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ ní ìtura, okun àti ayọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín.”

Àwọn Ìrírí Gbígbádùnmọ́ni Látẹnu Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù. Nínú ìjíròrò tí Mark Noumair, tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì darí rẹ̀, díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàṣefihàn ìrírí wọn, èyí tó gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Èmi Kò Tijú Ìhìn Rere” jáde gan-an. (Róòmù 1:16) Àwọn tó pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà gbádùn ọ̀rọ̀ táwọn òjíṣẹ́ tí kò kẹ̀rẹ̀ yìí sọ nípa bí wọ́n ṣe wàásù láti ilé dé ilé, ní òpópó ọ̀nà, àti láwọn ilé ìtajà. Àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tó gbọ́ èdè mìíràn fínnúfíndọ̀ wá àwọn tó ń sọ àwọn èdè náà rí ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn, wọ́n sì wàásù fún wọn. Àwọn mìíràn lo àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde lọ́nà tó dára gan-an nígbà tí wọ́n ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, wọ́n tún fi àwọn ìwé náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. Wọn ò “tijú” rárá láti wàásù ìhìn rere náà.

Arákùnrin William Nonkes tó ń sìn ní Ẹka Iṣẹ́ Ìsìn, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn míṣọ́nnárì tó ti ń sìn tipẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè bíi Burkina Faso, Latvia àti Rọ́ṣíà. Wọ́n fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà làwọn ìmọ̀ràn tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Jèhófà Ń Fi Tìfẹ́tìfẹ́ San Èrè Fáwọn Olóòótọ́.” Ọ̀kan lára àwọn arákunrin tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti rantí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọmọ ogun Gídíónì. Ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan ló ní ohun tí wọ́n yàn fún un láti ṣe, èyí sì wà lára ohun tó mú kí àkitiyan Gídíónì yọrí sí rere. (Onídàájọ́ 7:19-21) Bọ̀rọ̀ àwọn míṣọ́nnárì náà ṣe rí nìyẹn, Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn tí kò bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wọn.

“Ẹ Di Ohun Gbogbo fún Ènìyàn Gbogbo” ni kókó tí Samuel Roberson tó jẹ́ olùkọ́ ní ibùdó ìdánílẹ́kọ̀ọ́ ti Patterson tẹnu mọ́ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó darí rẹ̀. Ó fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́rin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Senegal, Guam, Liberia àti Madagascar. Gbogbo àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn láwọn orílẹ̀-èdè tá a mẹ́nu kan wọ̀nyí jẹ́ Àádọ́sàn-án [170]. Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀rọ̀ táwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ nípa bí wọ́n ṣe ń ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì lọ́wọ́ kí ara wọn lè mọlé. Èyí sábà máa ń gba pé kí wọ́n kọ́ àwọn àṣà tó lè ṣàjèjì sí àwọn aláwọ̀ funfun. Bí àpẹẹrẹ, láwọn àgbègbè kan tó wà lábẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Guam, wọ́n máa ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ṣàjèjì sáwọn kan. Àmọ́ àwọn míṣọ́nnárì kan ti kọ́ àwọn àṣà náà, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí sì lè kọ́ ọ pẹ̀lú.

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sìn ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “Jẹ́ Olóòótọ́ sí ‘Ìjọba Olúwa Wa.’” Ó rán àwọn tó wà níjòókó létí pé: “Kò sí nǹkan kan tí Jèhófà ṣèèṣì dá. Ó nídìí tó fi dá gbogbo ohun tó dá. Ohun tó sì fẹ́ ṣe sí ilẹ̀ ayé wa kò yí padà. Kò sóhun tó lè ṣèdíwọ́ fáwọn nǹkan náà kí wọ́n má nímùúṣẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Arákùnrin Pierce rọ gbogbo àwọn tó pésẹ̀ láti fi gbogbo ọkàn wọn fara mọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ láìka àwọn ìṣòro tó ti yọjú sí nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. Arákùnrin Pierce wá rọ gbogbo wọn pé: “Wákàtí ìdájọ́ là ń gbé báyìí. Àkókò díẹ̀ ló sì kù fún wa láti wá àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn rí ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Ẹ lo àkókò yín dáadáa láti sọ ìhìn rere nípa Ìjọba náà fáwọn èèyàn.” Kí àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn ní ìdánílójú pé, Ọlọ́run ò ní fi wọ́n sílẹ̀.—Sáàmù 18:25.

Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ti ń parí lọ, alága ka àwọn lẹ́tà ìkíni tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ kárí ayé. Lẹ́yìn náà ló fún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà ní ìwé ẹ̀rí, ọ̀kan lára wọn sì ka lẹ́tà tí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ náà kọ, èyí tí wọ́n fi dúpẹ́ gidigidi fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Lẹ́tà ìdúpẹ́ yìí ni wọ́n fi kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó pinminrin náà, èyí tí gbogbo àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà ò ní gbàgbé bọ̀rọ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 11

Iye orílẹ̀-èdè tá a rán wọn lọ: 22

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 34.8

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́:18.3

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13.4

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kíláàsì Kẹtàdínlọ́gọ́fà [117] Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan

(1) Thompson, E.; Norvell, G.; Powell, T.; Kozza, M.; McIntyre, T. (2) Reilly, A.; Clayton, C.; Allan, J.; Blanco, A.; Muñoz, L.; Rustad, N. (3) Guerrero, Z.; Garcia, K.; McKerlie, D.; Ishikawa, T.; Blanco, G. (4) McIntyre, S.; Cruz, E.; Guerrero, J.; Ritchie, O.; Avellaneda, L.; Garcia, R. (5) Powell, G.; Fiskå, H.; Muñoz, V.; Baumann, D.; Shaw, S.; Brown, K.; Brown, L. (6) Shaw, C.; Reilly, A.; Peloquin, C.; Münch, N.; McKerlie, D.; Ishikawa, K. (7) Münch, M.; Peloquin, J.; Kozza, T.; Avellaneda, M.; Allan, K.; Ritchie, E.; Norvell, T. (8) Cruz, J.; Baumann, H.; Clayton, Z.; Fiskå, E.; Thompson, M.; Rustad, J.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́