Jèhófà Mọ Iye ‘Irun Orí Rẹ’
“Kò sí ọ̀kan nínú [àwọn ológoṣẹ́] tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.”—MÁTÍÙ 10:29, 30.
1, 2. (a) Kí nìdí tí Jóòbù fi ronú pé Ọlọ́run ti pa òun tì? (b) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ yìí túmọ̀ sí pé ó ti kẹ̀yìn sí Jèhófà? Ṣàlàyé.
“MO KÍGBE sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; mo dúró, kí o bàa lè fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí mi. Ìwọ yí ara rẹ padà láti ṣe mí níkà; ìwọ fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ rẹ ṣe kèéta sí mi.” Ìbànújẹ́ ńlá ló dorí ọkùnrin yìí kodò, ìdí nìyẹn tó sì fi sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ohun tó ní ti pa rẹ́, jàǹbá kan tó ṣeni ní kàyéfì ti gbẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀, àìsàn búburú kan sì tún wá dá òun fúnra rẹ̀ gúnlẹ̀. Jóòbù lorúkọ ọkùnrin yìí, ìpọ́njú ńlá tó rí sì wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì fún àǹfààní wa.—Jóòbù 30:20.
2 Gbólóhùn tó tẹnu Jóòbù jáde yìí lè mú kó dà bíi pé ó ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Jóòbù wulẹ̀ ń sọ bí ọkàn rẹ̀ ṣe bàjẹ́ tó ní. (Jóòbù 6:2, 3) Kò mọ̀ rárá pé Sátánì ló ń fa gbogbo àdánwò tó dé bá òun, ló bá fàṣìṣe sọ pé Ọlọ́run ti fi òun sílẹ̀. Jóòbù tiẹ̀ sọ fún Jèhófà nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dójú ẹ̀ pé: “Èé ṣe tí o fi ojú rẹ gan-an pa mọ́, tí o sì kà mí sí ọ̀tá rẹ?”a—Jóòbù 13:24.
3. Nígbà táwọn nǹkan búburú bá ṣẹlẹ̀ sí wa, kí ló lè máa wá sọ́kàn wa?
3 Lónìí, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ló wà nínú ìṣòro táwọn ìṣòro náà kò sì níyanjú. Lára àwọn ohun tó ń fà á ni ogun, rúkèrúdò nítorí ìṣèlú tàbí ti àwọn èèyàn tó ń dàlú rú, jàǹbá, irú bí omíyalé tàbí ìsẹ̀lẹ̀, ọjọ́ ogbó, àìsàn, àìríjẹ àìrímu, àti òfin táwọn ìjọba máa ń ṣe pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà máa dojú kọ àdánwò kan tàbí òmíràn lọ́wọ́lọ́wọ́. Nígbà míì, o lè máa ronú pé Jèhófà ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ọ, pé kò fẹ́ rí ọ. Lóòótọ́, o mọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 3:16 tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.” Síbẹ̀, tó o bá wà nínú ìṣòro, tí kò sì sí àmì pé ìṣòro ọ̀hún máa yanjú, o lè máa bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ rí gbogbo ìnira tó ń bá mi yìí? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kà mí sí rárá?’
4. Ìṣòro tí kò dópin wo ni Pọ́ọ̀lù ní láti fara dà, kí ló sì lè máa wá sí wa lọ́kàn táwa náà bá wà nirú ipò yẹn?
4 Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ọ̀nà tó gbà ṣàpèjúwe rẹ̀ rèé, ó ní: “A fi ẹ̀gún kan sínú ẹran ara mi, áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá.” Ó tún sọ pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo pàrọwà sí Olúwa pé kí ó lè kúrò lára mi.” Jèhófà gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀bẹ̀ fún yìí. Àmọ́, ohun tó sọ fún Pọ́ọ̀lù ni pé òun ò ní mú ìṣòro náà kúrò lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù ní láti gbára lé agbára Ọlọ́run, èyí tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti fara da ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ rẹ̀ náà.b (2 Kọ́ríńtì 12:7-9) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìwọ náà lè ní àdánwò kan tí kò níyanjú. Bóyá o tiẹ̀ ti ń sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Bó ṣe dà bíi pé Jèhófà ò ṣe nǹkan kan nípa àdánwò mi yìí, ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pé kò mọ ohun tí mò ń dojú kọ tàbí pé kò tiẹ̀ bìkítà nípa mi?’ Rárá o! Ohun tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kété lẹ́yìn tó yàn wọ́n jẹ́ ká rí i gbangbagbàǹgbà pé Jèhófà bìkítà gan-an nípa gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Jẹ́ ká wo bí ohun tó sọ fún wọn ṣe lè jẹ́ ìṣírí fún wa lónìí.
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Bẹ̀rù?
5, 6. (a) Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ láti má ṣe bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà bìkítà fún òun?
5 Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní agbára tó kàmàmà, lára rẹ̀ ni “ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́, láti lé àwọn wọ̀nyí jáde àti láti ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara.” Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé wọn ò ní rí àdánwò àti ìnira rárá bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́, ó wá rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ má sì bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.”—Mátíù 10:1, 16-22, 28.
6 Káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lè rí ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n bẹ̀rù, Jésù sọ àkàwé méjì fún wọn. Ó ní: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Kíyè sí i pé, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà bìkítà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kò ní jẹ́ ká bẹ̀rù nígbà tá a bá ń dójú kọ àtakò. Kò sí àní-àní pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa? Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?” (Róòmù 8:31, 32) Irú ìṣòro tó wù kí ìwọ náà ní, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà bìkítà fún ọ níwọ̀n ìgbà tó o bá ti jẹ́ olóòótọ́ sí i. Wàá túbọ̀ rí i pé òótọ́ ló bìkítà fún ọ bá a ti ń ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀.
Iye Owó Ológoṣẹ́
7, 8. (a) Irú ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo ẹyẹ ológoṣẹ́ nígbà ayé Jésù? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ológoṣẹ́ wẹ́wẹ́” ni wọ́n dìídì lò nínú Mátíù 10:29?
7 Àwọn àpèjúwe tí Jésù lò jẹ́ ká rí i pé Jèhófà bìkítà fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. Jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ yẹ̀ wò ná. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn máa ń jẹ ẹyẹ ológoṣẹ́, àmọ́ nítorí pé wọ́n máa ń ba irè oko jẹ́, ọ̀tá àgbẹ̀ ni wọ́n kà wọ́n sí. Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí pọ̀ gan-an nígbà yẹn, iye tí wọ́n sì ń tà wọ́n kéré débi pé, tá a bá ṣírò rẹ̀ lówó òde òní, iye téèyàn á fi ra méjì kò tó náírà mẹ́fà. Téèyàn bá wá ní ìlọ́po méjì owó yẹn lọ́wọ́, ológoṣẹ́ márùn-ún ni wọ́n máa kó fún un kì í ṣe mẹ́rin. Èènì ni wọ́n fi ọ̀kan tó lé lórí rẹ̀ yẹn ṣe, bíi pé ẹyọ kan yẹn kò níye lórí rárá!—Lúùkù 12:6.
8 Tún ronú lórí bí ẹyẹ tó wọ́pọ̀ gan-an yìí ṣe kéré tó. Tá a bá fi ológoṣẹ́ wé àwọn ẹyẹ mìíràn, ológoṣẹ́ tó tiẹ̀ ti dàgbà dáadáa pàápàá kéré gan-an. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ológoṣẹ́” nínú Mátíù 10:29 dìídì tọ́ka sí ológoṣẹ́ wẹ́wẹ́. Kò sí àní-àní pé ìdí tí Jésù fi fi ológoṣẹ́ ṣàpèjúwe ni pé ó fẹ́ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ronú nípa ẹyẹ kan tí kò tiẹ̀ níye lórí rárá.
9. Kókó tó ṣe pàtàkì gan-an wo ni àkàwé Jésù nípa àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ gbé yọ?
9 Bí Jésù ṣe lo ẹyẹ ológoṣẹ́ láti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé kókó kan tó ṣe pàtàkì gan-an yọ. Kókó náà ni pé, ohun tó lè dà bíi pé kò jẹ́ nǹkan kan lójú ẹ̀dá èèyàn ṣe pàtàkì gan-an lójú Jèhófà Ọlọ́run. Jésù túbọ̀ gbé kókó yìí yọ nígbà tó sọ pé, ẹyẹ ológoṣẹ́ tó kéré gan-an kò lè “jábọ́ lulẹ̀” kí Jèhófà má mọ̀.c Ẹ̀kọ́ tó fẹ́ ká kọ́ níbẹ̀ ṣe kedere. Bí Jèhófà Ọlọ́run bá ń kíyè sí ẹyẹ tó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹyẹ, èyí tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó dájú pé yóò kíyè sí ìṣòro àwọn ẹ̀dá èèyàn tó pinnu láti sìn ín!
10. Kí nìdí tí gbólóhùn náà: “Gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà” fi ṣe pàtàkì?
10 Yàtọ̀ sí àpèjúwe ẹyẹ ológoṣẹ́ tí Jésù lò, ó tún sọ pé: “Gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.” (Mátíù 10:30) Gbólóhùn tó ṣe ṣókí àmọ́ tí ọ̀rọ̀ ki sínú rẹ̀ yìí túbọ̀ wá gbé kókó inú àkàwé ológoṣẹ́ tí Jésù ṣe yọ dáadáa. Rò ó wò ná: Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún fọ́nrán irun ló wà lórí èèyàn kan. Àwọn irun yìí kì í sábà yàtọ̀ síra, bákan náà gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe máa ń rí lójú, kò sì jọ pé èèyàn ń kíyè sí ẹyọ irun kan ju àwọn tó kù lọ. Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run kíyè sí ẹyọ irun kọ̀ọ̀kan ó sì kà á mọ́ àwọn tó kù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé báyìí lọ̀rọ̀ rí, ǹjẹ́ ohun kan lè máa ṣẹlẹ̀ sí wa kí Jèhófà má mọ̀? Dájúdájú, Jèhófà mọ ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan dáadáa. Láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n, ó “ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
11. Kí ni Dáfídì sọ tó fi hàn pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun?
11 Dáfídì jẹ́ ẹnì kan tó rí ìpọ́njú gan-an láyé rẹ̀, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà ń kíyè sí òun. Ó kọ̀wé pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré.” (Sáàmù 139:1, 2) Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. (Jeremáyà 17:10) Má kàn gbà pé o ò já mọ́ nǹkan kan débi tí ojú Jèhófà tó ń rí ohun gbogbo ò fi ní rí ọ!
“Fi Omijé Mi Sínú Ìgò Awọ Rẹ”
12. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ ohun tójú àwọn èèyàn rẹ̀ ń rí?
12 Kì í ṣe pé Jèhófà mọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan nìkan ni, ó tún mọ gbogbo ìpọ́njú tó ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn fínra. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìgbà táwọn ará Íjíbítì ń pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú tí wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe ẹrú. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹ́kísódù 3:7) Ẹ ò rí i pé ohun ìtùnú ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé Jèhófà ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa ó sì ń gbọ́ igbe wa nígbà tá a bá ń fara da àdánwò! Ó dájú pé kò dágunlá sáwọn ìṣòro wa.
13. Kí ló fi hàn pé àánú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣe é gan-an?
13 Pé Jèhófà bìkítà fáwọn tó ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀ la túbọ̀ rí nínú bí àánú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń ṣe é. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí kunkun wọn ló máa ń fa ìpọ́njú tó dé bá wọn lọ́pọ̀ ìgbà, síbẹ̀ Aísáyà kọ̀wé nípa Jèhófà pé: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9) Níwọ̀n bí ìwọ sì ti jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, nígbà náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé tí ohun kan bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ, ó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jèhófà náà. Ǹjẹ́ èyí kò túbọ̀ mú kó o fẹ́ láti kojú ìṣòro rẹ láìbẹ̀rù kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa sìn ín nìṣó?—1 Pétérù 5:6, 7.
14. Ipò wo ni Dáfídì bá ara rẹ̀ tó mú un kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù Kẹrìndínlọ́gọ́ta?
14 Ó dá ọba Dáfídì lójú pé Jèhófà bìkítà fún òun, ó sì dùn ún pé òun wà nínú ìṣòro. Èyí hàn kedere nínú Sáàmù Kẹrìndínlọ́gọ́ta tí Dáfídì kọ nígbà tó ń sá lọ nítorí Ọba Sọ́ọ̀lù tó fẹ́ pà á. Dáfídì sá lọ sílùú Gátì, àmọ́ ẹ̀rù bà á pé àwọn Filísínì yóò mú òun tí wọ́n bá dá òun mọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀tá mi ń kù gìrì mọ́ mi ṣáá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń fi ọkàn gíga bá mi jagun.” Nítorí ipò eléwu tí Dáfídì bá ara rẹ̀ yìí, ó yíjú sí Jèhófà. Ó wá sọ pé: “Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni wọ́n ń ṣe àwọn àlámọ̀rí tèmi lọ́ṣẹ́. Gbogbo ìrònú wọn ni ó lòdì sí mi fún búburú.”—Sáàmù 56:2, 5.
15. (a) Kí ni Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé kí Jèhófà rọ omijé òun sínú ìgò awọ tàbí kó kọ ọ́ sínú ìwé? (b) Tá a bá ń fara da ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò, kí ló yẹ kó dá wa lójú?
15 Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Sáàmù 56:8, Dáfídì wá sọ gbólóhùn tó fani mọ́ra gan-an yìí pé: “Jíjẹ́ tí mo jẹ́ ìsáǹsá ni ìwọ alára ti ròyìn. Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ. Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?” Ẹ ò rí i pé bí Dáfídì ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí wọni lọ́kàn gan-an! Tá a bá wà nínú ìdààmú, a tiẹ̀ lè máa sunkún bá a ti ń ké pe Jèhófà. Ṣebí Jésù tó jẹ́ ẹni pípé pàápàá sunkún. (Hébérù 5:7) Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà ń kíyè sí òun àti pé yóò rántí ìnira òun, bí ẹni pé ó tọ́jú omi ojú òun sínú ìgò awọ tàbí pé ó kọ ọ́ sínú ìwé.d Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé omijé tìrẹ á fẹ́rẹ̀ẹ́ kún ìgò awọ náà tàbí pé yóò kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ojú ìwé bẹ́ẹ̀. Bó bá jẹ́ pé bí ìbànújẹ́ rẹ ṣe pọ̀ tó nìyẹn, ìtùnú wà. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
Bá A Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
16, 17. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kò dágunlá sáwọn ìṣòro táwọn èèyàn rẹ̀ ń kojú? (b) Kí ni Jèhófà ti ṣe láti mú káwọn èèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀?
16 Bí Jèhófà ṣe ka ‘irun orí wa’ tó sì mọ iye rẹ̀ jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run tó ń kíyè sí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ tó sì bìkítà fún wọn la ní àǹfààní láti máa sìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dìgbà tá a bá dénú ayé tuntun tó ṣèlérí kí gbogbo ìrora àti ìpọ́njú tóó pòórá, síbẹ̀ Jèhófà ń ṣe ohun kan tó jọni lójú gan-an fáwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú, láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.”—Sáàmù 25:14.
17 “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” Lójú ẹ̀dá aláìpé, èyí lè dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe rárá! Síbẹ̀, Jèhófà ń ké sáwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ pé kí wọ́n wá jẹ́ àlejò nínú àgọ́ òun. (Sáàmù 15:1-5) Kí sì ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn àlejò rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe sọ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ májẹ̀mú òun. Jèhófà máa ń sọ ohun tó ní lọ́kàn fún wọn, ó máa ń sọ “ọ̀ràn àṣírí” rẹ̀ fáwọn wòlíì kí wọ́n lè mọ àwọn ète rẹ̀ àtohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti gbé níbàámu pẹ̀lú wọn.—Ámósì 3:7.
18. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun?
18 Ká sòótọ́, inú wa dùn gan-an láti mọ̀ pé àwa tá a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ. Àní ohun tó tiẹ̀ ń rọ̀ wá pé ká ṣe gan-an nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Jèhófà fẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Ó tiẹ̀ ti ṣe àwọn nǹkan kan láti mú kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe. Ẹbọ ìràpadà Jésù ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa ká bàa lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run alágbára gbogbo. Bíbélì sọ pé: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 Jòhánù 4:19.
19. Báwo ni ìfaradà ṣe lè mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i?
19 Àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí máa ń lágbára sí i tá a bá ń fara da àwọn ipò tí kò bára dé. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:4) “Iṣẹ́” wo ni fífara da ìṣòro máa ń ṣe? Rántí ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ Pọ́ọ̀lù. Kí ni ìfaradà ṣe nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀? Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn àdánwò rẹ̀ rèé, ó ní: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́. Nítorí náà, mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:9, 10) Ẹ̀kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni pé, bó bá pọn dandan, Jèhófà yóò pèsè agbára tí òun nílò, ìyẹn “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” kó bàa lè fara dà á. Èyí sì mú kó túbọ̀ sún mọ́ Kristi àti Jèhófà Ọlọ́run gan-an.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:11-13.
20. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn yóò sì tù wá nínú nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro?
20 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà fàyè sílẹ̀ káwọn àdánwò rẹ máa bá a nìṣó. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, máa fi ìlérí tó ṣe fáwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ sọ́kàn, ìyẹn ni pé: “Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Ìwọ náà lè rí irú ìtìlẹ́yìn àti ìtùnú bẹ́ẹ̀ gbà. Jèhófà mọ iye ‘gbogbo irun orí rẹ.’ Ó ń rí ìfaradà rẹ. Ó mọ ìrora tí ò ń jẹ. Ó bìkítà gan-an nípa rẹ. Kò sì ní ‘gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀’ láé.—Hébérù 6:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Dáfídì tó jẹ́ olódodo èèyàn àtàwọn ọmọkùnrin Kórà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sọ gbólóhùn tó fara jọ èyí.—Sáàmù 10:1; 44:24.
b Bíbélì kò sọ ohun tí ‘ẹ̀gún inú ẹran ara’ Pọ́ọ̀lù jẹ́ gan-gan. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìlera ara kan ni, irú bí àìsàn ojú. Gbólóhùn náà, ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ sì tún lè tọ́ka sáwọn èké àpọ́sítélì àtàwọn mìíràn tí wọn ò fara mọ́ jíjẹ́ tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpọ́sítélì, tínú wọn ò sì dùn sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń ṣe.—2 Kọ́ríńtì 11:6, 13-15; Gálátíà 4:15; 6:11.
c Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun tí àpèjúwe náà dá lé lórí tiẹ̀ lè nítumọ̀ mìíràn tó ju pé ẹyẹ ológoṣẹ́ náà kú nígbà tó jábọ́ lulẹ̀. Wọ́n ni ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí ẹyẹ náà ṣe máa ń fò wálẹ̀ láti jẹun ni ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò fún gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé Ọlọ́run ń kíyè sí ẹyẹ yìí ó sì ń bójú tó o lójoojúmọ́, kì í ṣe pé ó ń mọ̀ nígbà tó bá kú nìkan.—Mátíù 6:26.
d Láyé ọjọ́un, awọ àgùntàn, awọ ewúrẹ́ àti ti màlúù tí wọ́n ti sá gbẹ nínú oòrùn ni wọ́n fi máa ń ṣe irú àwọn ìgò awọ bẹ́ẹ̀. Inú wọn ni wọ́n máa ń rọ mílíìkì, bọ́tà, wàrà tàbí omi sí. Kódà wọ́n lè rọ òróró tàbí wáìnì sínú àwọn tí wọ́n bá sá gbẹ dáadáa.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn nǹkan wo ló lè mú kẹ́nì kan máa rò pé Ọlọ́run ti pa òun tì?
• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àwọn àkàwé Jésù nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ àti nípa bí Ọlọ́run ṣe mọ iye irun orí wa?
• Kí ló túmọ̀ sí pé a rọ omijé ẹnì kan sínú “ìgò awọ” Jèhófà tàbí pé ó wà nínú “ìwé” rẹ̀?
• Báwo la ṣe lè dẹni tó ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Kí nìdí tí Jèhófà kò fi mú ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ Pọ́ọ̀lù kúrò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú àkàwé tí Jésù ṣe nípa ẹyẹ ológoṣẹ́?
[Credit Line]
© J. Heidecker/VIREO
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, a ó rí i dájú pé Ọlọ́run bìkítà fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan