ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 11/1 ojú ìwé 15
  • “Ọ̀kan Lára Ọjọ́ Tínú Mi Dùn Jù Lọ Láyé Mi”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọ̀kan Lára Ọjọ́ Tínú Mi Dùn Jù Lọ Láyé Mi”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ọmọ Rẹ Máa Sọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Tọ́kì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mo Dúpẹ́ Pé Ìrìn Mi Ò Já Sásán
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 11/1 ojú ìwé 15

“Ọ̀kan Lára Ọjọ́ Tínú Mi Dùn Jù Lọ Láyé Mi”

ÀJỌ kan tí wọ́n ń pè ní Beyondblue nílẹ̀ Ọsirélíà tíjọba ń ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, èyí tó wà fún ríran àwọn ọ̀dọ́ tí ilé ayé ti sú lọ́wọ́, sọ pé: “Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn làwọn èèyàn sábà máa ń dárúkọ jù pé ó jẹ́ ìṣòro àwọn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni olórí ohun tó ń dààmú ọpọlọ àwọn ọ̀dọ́ jù.” Ìwádìí fi hàn pé lọ́dọọdún, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Ọsirélíà ló máa ń ní ìdààmú ọkàn.

Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ náà ò bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn o. Àmọ́, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́wọ́ láti borí èrò òdì tí wọ́n máa ń ní nípa ara wọn ó sì ń jẹ́ kí wọ́n gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ wọn gan-an. Lọ́nà yìí, ìwúrí ńlá ni wọ́n jẹ́ fáwọn èèyàn. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Claire, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nílùú Melbourne lòun àti màmá rẹ̀ ń lọ. Nígbà tí bàbá rẹ̀ fi ìdílé wọn sílẹ̀, ilé ayé sú Claire pátápátá. Àmọ́ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà baba rẹ̀ ọ̀run kò yẹ̀ rárá. Lọ́jọ́ kan, Lydia, ìyẹn dókítà tó ń tọ́jú ìdílé àwọn Claire wá sílé wọn, láti wá wo bí màmá Claire tí ara rẹ̀ kò yá ṣe ń ṣe sí. Lẹ́yìn náà, ó gbé Claire sínú ọkọ̀, wọ́n sì jọ lọ síbi táwọn ṣọ́ọ̀bù ìtajà pọ̀ sí. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, dókítà náà béèrè lọ́wọ́ Claire bóyá ó ní ọ̀rẹ́kùnrin. Claire ṣàlàyé fún un pé níwọ̀n bí òun ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun kì í bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin dọ́rẹ̀ẹ́ báyẹn. Èyí ya dókítà náà lẹ́nu. Lẹ́yìn náà ni Claire ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí Bíbélì ti gbà ran òun lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nígbèésí ayé òun. Níparí àlàyé rẹ̀, ó sọ pé òun á fẹ́ láti mú ìwé kan tó dá lórí Bíbélì tó ti ran òun lọ́wọ́ gan-an wá fún dókítà náà. Orúkọ ìwé náà ni Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.

Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Lydia gba ìwé náà ló pe màmá Claire lórí fóònù láti sọ bí òun ṣe gbádùn ìwé náà tó nígbà tí òun kà á. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé kí wọ́n bá òun wá ẹ̀dà mẹ́fà ìwé náà sí i kóun lè fún àwọn táwọn jọ ń ṣiṣẹ́. Nígbà tí Claire kó ìwé náà lọ fún dókítà náà, ó sọ fún Claire pé ìgbàgbọ́ Claire wú òun lórí gan-an. Claire wá sọ fún un pé òun á fẹ́ láti máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dókítà náà sì gbà.

Fún oṣù bíi mélòó kan ni Claire fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lákòókò ìsinmi oúnjẹ ọ̀sán dókítà náà. Nígbà tó yá, Lydia béèrè lọ́wọ́ Claire bóyá yóò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ níbi àpérò kan tó dá lórí ìdààmú ọkàn láàárín àwọn ọ̀dọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyà Claire ń já, síbẹ̀ ó gbà láti sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà. Ó lé lọ́gọ́ta èèyàn tó pésẹ̀ síbi àpérò náà. Ògúnná gbòǹgbò nínú ìwòsàn ọpọlọ ni mẹ́rin lára wọn, àgbàlagbà sì ni wọ́n, àwọn ló bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà ni ọpọ́n wá sún kan Claire láti sọ̀rọ̀. Ó sọ nípa bó ṣe ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn ọ̀dọ́ ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọ̀dọ́ gan-an ó sì máa ń dúró ti àwọn tó bá yíjú sí i fún ìrànwọ́ àti ìtùnú. Bákan náà ló tún sọ pé ó dá òun lójú gan-an pé Jèhófà máa tó mú gbogbo àìsàn kúrò, títí kan àwọn ìṣòro tó máa ń kó ìdààmú bá ọpọlọ. (Aísáyà 33:24) Kí ni àbájáde ìwàásù tó dára gan-an yìí?

Claire sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ló wá bá mi lẹ́yìn àpérò náà tí wọ́n sì sọ fún mi pé orí àwọn wú gan-an báwọn ṣe rí ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Ẹ̀dà mẹ́tàlélógún ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé làwọn èèyàn gbà lọ́wọ́ mi. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mẹ́ta lára àwọn tó wá sí àpérò náà fún mi ní nọ́ńbà tẹlifóònù wọn. Ọ̀kan nínú wọn sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Ọ̀kan lára ọjọ́ tínú mi dùn jù lọ láyé mi ni ọjọ́ náà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́