À Ń rìn Ní Ọ̀nà Ìmọ́lẹ̀ Tó Túbọ̀ Ń mọ́lẹ̀ Sí I
“Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.”—ÒWE 4:18.
1, 2. Báwo ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí Jèhófà ń tàn sórí àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà gbogbo ṣe ń ṣe wọ́n láǹfààní?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN, ẹni tó jẹ́ Orísun ìmọ́lẹ̀, nìkan ló lè ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí oòrùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń là ṣe ń borí òkùnkùn, àbí ẹlòmíì tún wà? (Sáàmù 36:9) Ọlọ́run sọ pé: ‘Nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ bá di àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé mú, ilẹ̀ ayé á pa ara rẹ̀ dà bí amọ̀ lábẹ́ èdìdì, àwọn nǹkan á sì mú ìdúró wọn bí ẹni pé nínú aṣọ.’ (Jóòbù 38:12-14) Bí oòrùn bá ṣe túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i, la máa ń rí àwọn ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé dáadáa, gẹ́gẹ́ bí ìrísí amọ̀ rírọ̀ ṣe máa ń yí padà téèyàn bá fi èdìdì tàbí òǹtẹ̀ lù ú.
2 Jèhófà tún ni Orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. (Sáàmù 43:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé wà nínú òkùnkùn biribiri, Ọlọ́run tòótọ́ ò yéé tan ìmọ́lẹ̀ sórí àwọn èèyàn rẹ̀. Kí ni àbájáde èyí? Bíbélì dáhùn pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Ìmọ́lẹ̀ tí Jèhófà ń pèsè tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i ń mú kí ọ̀nà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń tọ̀ ṣe kedere sí i. Ó ń mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò àwọn nǹkan dára sí i, ó ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ síwájú sí i, ó sì ń jẹ́ kí ìwà wọn dára sí i.
Ìmọ́lẹ̀ Tẹ̀mí Tó Ń Mọ́lẹ̀ Sí I Ń Mú Kí Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Ṣètò Àwọn Nǹkan Dára Sí I
3. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nínú Aísáyà 60:17?
3 Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin.” (Aísáyà 60:17) Ìtẹ̀síwájú ni kéèyàn fi nǹkan tó jẹ́ ojúlówó rọ́pò èyí tí kì í ṣe ojúlówó. Lọ́nà kan náà, ìtẹ̀síwájú ti dé bá ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń ṣètò àwọn nǹkan ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tàbí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá à ń gbé yìí.—Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1.
4. Ètò wo la ṣe lọ́dún 1919, báwo ló sì ṣe ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní?
4 Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ńṣe làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń dìbò yan àwọn alàgbà àtàwọn díákónì, ìyẹn àwọn tí a mọ̀ sí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lónìí. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lorúkọ tí à ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásìkò yẹn. Àmọ́ o, àwọn alàgbà ìjọ kan kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìjíhìnrere. Wọn ò fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì tún ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó fẹ́ ṣe é. Ìdí nìyí tá a fi ṣètò tuntun kan lọ́dún 1919, a bẹ̀rẹ̀ sí yan olùdarí iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ìjọ kì í dìbò yan olùdarí iṣẹ́ ìsìn, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn èèyàn Ọlọ́run ló máa ń yàn án sípò. Lára iṣẹ́ olùdarí iṣẹ́ ìsìn ni pé, kó máa ṣètò iṣẹ́ ìwàásù, kó máa sọ ìpínlẹ̀ táwọn ará á ti lọ wàásù, kó sì máa fún àwọn ará níṣìírí láti lọ sóde ẹ̀rí. Ètò Ọlọ́run túbọ̀ fún àwọn ará níṣìírí gan-an láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 1919.
5. Ètò tuntun wo la ṣe láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929?
5 Níbi àpéjọ àgbègbè táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún 1922 ní ìlú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ ìṣírí náà, “Ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀,” èyí tó túbọ̀ fún tọmọdé tàgbà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan lókun láti tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tó fi máa di 1927, a ti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù dáadáa débi pé a yan ọjọ́ Sunday gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tó dára jù lọ fún ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Kí nìdí tá a fi mú ọjọ́ Sunday? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í lọ ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí ní ti pé a máa ń sapá láti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láwọn àkókò tá a lè bá wọn nílé, irú bí òpin ọ̀sẹ̀ àti ìrọ̀lẹ́.
6. Ìpinnu wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lọ́dún 1931, báwo nìyẹn sì ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?
6 Ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ Sunday, July 26, 1931, tó mú káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́jọ́ náà, àwọn tó wà ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní ìlú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ìpinnu kan, èyí táwọn ará wọn jákèjádò ayé ṣe lẹ́yìn náà. Lára ohun tí wọ́n pinnu ni pé: “Ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni wá, ó sì ti gbé iṣẹ́ kan fún wa láti ṣe ní orúkọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bó sì ti pàṣẹ, a óò máa jẹ́rìí nípa Jésù Kristi, a ó sì kéde fún àwọn èèyàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, òun sì ni Olódùmarè; nípa báyìí tayọ̀tayọ̀ la fi gbà láti máa jẹ́ orúkọ ti Olúwa Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ sọ, a sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ náà mọ́ wa, kí wọ́n sì máa fi orúkọ náà pè wá, ìyẹn ẹlẹ́rìí Jèhófà.” (Aísáyà 43:10) Ẹ ò rí i pé kedere kèdèrè ni orúkọ tuntun náà sọ olórí iṣẹ́ àwọn tó ń jẹ́ orúkọ ọ̀hún! Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà gbéṣẹ́ kan fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ làwọn ará lápapọ̀ fi tẹ́wọ́ gba orúkọ náà!
7. Àyípadà wo ló wáyé lọ́dún 1932, kí nìdí tí èyí sì fi rí bẹ́ẹ̀?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Àmọ́ láwọn ibì kan, àwọn alàgbà tí wọ́n dìbò yàn ṣe àtàkò gidigidi nígbà tí wọ́n gbọ́ pé gbogbo ẹni tó wà nínú ìjọ ni yóò máa ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n, àwọn àyípadà kan máa tó wáyé. Lọ́dún 1932, ètò Ọlọ́run lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti fi sọ fún gbogbo ìjọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ dìbò yan àwọn alàgbà àti díákónì mọ́. Dípò ìyẹn, ńṣe ni kí wọ́n máa yan ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn, àwọn ọkùnrin tẹ̀mí tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ló sì máa wà nínú ìgbìmọ̀ náà. Lọ́nà yìí, àwọn tó ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló wá ń ṣe àbójútó, ìtẹ̀síwájú sì bá iṣẹ́ náà.
Ìmọ́lẹ̀ Tí Ń Mọ́lẹ̀ Sí I Mú Kí Ọ̀pọ̀ Nǹkan Dára Sí I
8. Ìtẹ̀síwájú wo ló wáyé lọ́dún 1938?
8 Ńṣe ni ìmọ́lẹ̀ “ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i.” Lọ́dún 1938, a fagi lé gbogbo ìdìbò pátápátá. A ṣètò pé ìlànà Ìwé Mímọ́ ni a óò máa lò láti yan gbogbo àwọn ìránṣẹ́ nínú ìjọ, èyí á sì jẹ́ lábẹ́ àbójútó “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló fi tinútinú tẹ́wọ́ gba ètò tuntun yìí, iṣẹ́ ìjẹ́rìí sì ń so èso nìṣó.
9. Ètò wo la ṣe lọ́dún 1972, kí ló sì mú kí ìyẹn jẹ́ ìtẹ̀síwájú?
9 Bẹ̀rẹ̀ láti October 1, 1972, a bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ̀ lé ìlànà tuntun kan nínú ọ̀nà tá a gbà ń bójú tó nǹkan nínú ìjọ. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, alábòójútó kan ṣoṣo tí wọ́n ń pè ní ìránṣẹ́ ìjọ ló máa ń wà, àmọ́ lábẹ́ ètò tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ yìí, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ni yóò máa ṣe àbójútó nínú gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Ètò tuntun yìí mú kí àwọn ọkùnrin tó lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ fẹ́ láti dẹni tó tóótun fún ṣíṣe àbójútó nínú ìjọ. (1 Tímótì 3:1-7) Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló ti mọ bí wọ́n ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ wọn nínú ìjọ. Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n sì ti ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ pọ̀ gan-an ni!
10. Ètò wo la bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé láti ọdún 1976?
10 A pín àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí sí ẹ̀ka mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Láti January 1, 1976 làwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sì ti ń mójú tó ìgbòkègbodò ètò Ọlọ́run lápapọ̀ àti ti inú ìjọ kọ̀ọ̀kan kárí ayé. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni pé “ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn” ló ń darí gbogbo ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run!—Òwe 15:22; 24:6.
11. Ìtẹ̀síwájú wo ló wáyé nínú ètò Ọlọ́run lọ́dún 1992, kí sì nìdí tó fi wáyé?
11 Ìtẹ̀síwájú mìíràn tún wáyé lọ́dún 1992, èyí tá a lè fi wé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn mìíràn padà dé láti ìgbèkùn tí wọ́n wà ní Bábílónì. Lásìkò náà lọ́hùn-ún, àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣiṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì kò pọ̀ tó. Èyí ló mú kí wọ́n fún àwọn Nétínímù níṣẹ́ púpọ̀ sí i láti ṣe kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ Léfì. Àwọn Nétínímù yìí kì í sì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Lọ́nà kan náà, a fún àwọn kan lára “àwọn àgùntàn mìíràn” ní àfikún iṣẹ́ lọ́dún 1992 kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. A yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹ̀ka tá a pín Ìgbìmọ̀ Olùdarí sí.—Jòhánù 10:16.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe yan àlàáfíà ṣe alábòójútó wa?
12 Kí ni àbájáde gbogbo èyí? Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:17) “Àlàáfíà” wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí “òdodo” sì ni ‘ohun tí ń pínṣẹ́’ fún wọn, ìyẹn ni pé ìfẹ́ tí wọ́n ní láti ṣe òdodo yìí ló ń sún wọn láti máa sin Ọlọ́run. Wọ́n ti ṣe àwọn ètò tó yẹ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Jèhófà Ń Tànmọ́lẹ̀ Sórí Àwọn Ẹ̀kọ́ Wa
13. Láàárín ọdún 1920 àti 1929, báwo ni Jèhófà ṣe tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn ẹ̀kọ́ táwọn èèyàn rẹ̀ ń kọ́?
13 Jèhófà tún ń fún wa ní ìlàlóye síwájú àti síwájú sí i lórí àwọn ẹ̀kọ́ wa. A lè rí àpẹẹrẹ èyí nínú Ìṣípayá 12:1-9. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa àwọn ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n dúró fún àwọn nǹkan kan: “obìnrin kan” tó lóyún tó sì bímọ, “dírágónì” kan, àti “ọmọkùnrin kan, akọ.” Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún? Àpilẹ̀kọ kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Birth of the Nation [Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà],” nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925 [Gẹ̀ẹ́sì], sọ ohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ. Àpilẹ̀kọ yẹn jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ìbí Ìjọba Ọlọ́run, ìlàlóye yìí sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé ètò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà, ètò Jèhófà àti ètò Sátánì. Láàárín ọdún 1927 àti 1928, ó yé àwọn èèyàn Ọlọ́run yékéyéké pé ọdún Kérésìmesì àtàwọn ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, àtìgbà náà ni wọn ò sì ti ṣe é mọ́.
14. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló túbọ̀ yé wa láàárín ọdún 1930 àti 1939?
14 Láàárín ọdún 1930 àti 1939, Jèhófà túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì mẹ́ta. Ọjọ́ pẹ́ táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mọ̀ pé ògìdìgbó ńlá, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí Ìṣípayá 7:9-17 mẹ́nu kàn yàtọ̀ sí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó máa bá Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-5) Àmọ́, àwọn tó jẹ́ ògìdìgbó ńlá kò tíì ṣe kedere sí wọn. Ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i máa ń jẹ́ kí gbogbo nǹkan ṣe kedere. Bákan náà, lọ́dún 1935, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wá rí i pé àwọn ògìdìgbó ńlá náà ni àwọn tó máa rí ìgbàlà nígbà “ìpọ́njú ńlá,” tí wọn yóò sì láǹfààní láti gbé orí ilẹ̀ ayé títí láé. Lọ́dún yẹn kan náà, ìlàlóye kan wáyé tó kan àwọn ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lọ ilé ẹ̀kọ́ ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Lásìkò yẹn, kárí ayé làwọn èèyàn ti ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn lọ́nà tó bùáyà, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ní tiwọn lóye pé jíjúbà àsíá tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kì í wulẹ̀ ṣe ayẹyẹ kan lásán. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn, ìyẹn ni pé orí òpó igi ni Kristi kú sí, kì í ṣe orí àgbélébùú.—Ìṣe 10:39.
15. Ìgbà wo ni ètò Ọlọ́run tẹnu mọ́ bí ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ ohun mímọ́ tó, báwo ni wọ́n sì ṣe tẹnu mọ́ ọn?
15 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àṣà tó wọ́pọ̀ ni pé kí wọ́n máa fa ẹ̀jẹ̀ sára àwọn sójà tó fara gbọgbẹ́ lójú ogun, àmọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ rí ìlàlóye nípa bí ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ ohun mímọ́ tó. Ilé Ìṣọ́ July 1, 1945 [Gẹ̀ẹ́sì], rọ “gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìyè ayérayé nínú ayé tuntun rẹ̀ níbi tí òdodo yóò ti gbilẹ̀, pé kí wọ́n mọyì bí ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ ohun mímọ́ tó, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ òdodo tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí.”
16. Ìgbà wo la tẹ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì, kí sì ni méjì lára àwọn ohun tó mú kó dára gan-an?
16 Lọ́dún 1946, ètò Ọlọ́run rí i pé ó yẹ kí wọ́n tún Bíbélì túmọ̀ látòkèdélẹ̀, kí wọ́n fi òye ìtẹ̀síwájú tó ti wà nínú ìmọ̀ Bíbélì lóde òní túmọ̀ rẹ̀, kó má sì ní àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látinú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nínú. Ọdún 1947 ni iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ìtumọ̀ Bíbélì yìí. Nígbà tó di ọdún 1950, a tẹ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Apá márùn-ún la ṣe Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tá a tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì sí, ọ̀kọ̀ọ̀kan la sì ń mú wọn jáde bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1953. Ọdún 1960 la mú apá tó gbẹ̀yìn jáde, ìyẹn sì lé díẹ̀ lọ́dún méjìlá lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì náà bẹ̀rẹ̀. Lọ́dún 1961, a tẹ odindi Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bíbélì yìí ti wà ní ọ̀pọ̀ èdè báyìí, àwọn nǹkan kan sì wà nínú rẹ̀ tó mú kó dára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó tú u lo Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, láwọn ibi tó yẹ kó wà. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà tí kò lábùlà ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ máa lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síwájú àti síwájú sí i.
17. Ìmọ́lẹ̀ wo ló túbọ̀ mọ́lẹ̀ lọ́dún 1962?
17 Lọ́dún 1962, a wá mọ àwọn tó jẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga” tí Róòmù 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní kedere àti ibi tó yẹ kí àwa Kristẹni ṣègbọràn sí wọn dé. Fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Róòmù orí kẹtàlá àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Títù 3:1, 2 àti 1 Pétérù 2:13, 17 jẹ́ kó hàn gbangba pé kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ni ọ̀rọ̀ náà “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ń tọ́ka sí, bí kò ṣe àwọn alákòóso tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn.
18. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a túbọ̀ lóye sí i láàárín ọdún 1980 àti 1989?
18 Ọ̀nà àwọn olódodo kàn ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i ni láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e. Lọ́dún 1985, Jèhófà jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìtumọ̀ jíjẹ́ ẹni tí a polongo ní olódodo “fún ìyè” àti jíjẹ́ olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 5:18; Jákọ́bù 2:23) A ṣàlàyé ìtumọ̀ Júbílì àwọn Kristẹni lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́dún 1987.
19. Báwo ni Jèhófà ṣe túbọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí sí ọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí?
19 Lọ́dún 1995, a túbọ̀ lóye ọ̀ràn yíya “àwọn àgùntàn” sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ewúrẹ́.” Lọ́dún 1998, a ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, èyí tó ti ń ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Lọ́dún 1999, a rí ìlàlóye nípa ìgbà tí ‘ohun ìríra dúró ní ibi mímọ́’ àti bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀. (Mátíù 24:15, 16; 25:32) Nígbà tó sì di ọdún 2002, a túbọ̀ lóye ohun tí jíjọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” túmọ̀ sí.—Jòhánù 4:24.
20. Àwọn ìtẹ̀síwájú mìíràn wo ló wáyé láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run?
20 Yàtọ̀ sí àwọn ìtẹ̀síwájú tó ti wáyé nínú ọ̀nà tí a gbà ń ṣètò àwọn nǹkan àti nínú àwọn ẹ̀kọ́ wa, a tún ti ṣe àwọn àtúnṣe kan nípa irú ìwà tó yẹ káwọn Kristẹni máa hù. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1973, a rí i pé lílo tábà jẹ́ “ẹ̀gbin ti ẹran ara,” a sì gbà pé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìyẹn, Ilè-iṣọ Naa ti January 15, 1984 ṣe àlàyé yékéyéké lórí ọ̀rọ̀ ìbọn lílò. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ìmọ́lẹ̀ tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i lásìkò tiwa.
Máa Rìn ní Ọ̀nà Ìmọ́lẹ̀ Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
21. Èrò wo ló yẹ ká ní, tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i?
21 Arákùnrin kan tó ti jẹ́ alàgbà tipẹ́tipẹ́ sọ pé: “Nígbà tí àyípadà tuntun bá dé, kì í rọrùn láti gbà á.” Kí ló ti ràn án lọ́wọ́ láti fara mọ́ ọ̀pọ̀ àyípadà tó ti wáyé láti nǹkan bí ọdún méjìdínláàádọ́ta tó ti ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run? Ó ní: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn ní èrò tó tọ́ nípa àyípadà náà. Béèyàn bá kọ̀ tí kò fara mọ́ àyípadà kan, ńṣe ni ètò Ọlọ́run máa já onítọ̀hún jù sílẹ̀. Bí mo bá rí i pé kò rọrùn fún mi láti fara mọ́ àwọn àyípadà kan, mo máa ń ronú lórí ohun tí Pétérù sọ fún Jésù pé: ‘Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.’ Èmi yóò wá bi ara mi pé, ‘Ibo ni mo fẹ́ lọ ná, ṣé inú ayé tó ṣókùnkùn biribiri ni?’ Èyí ló ń ràn mí lọ́wọ́ láti fara mọ́ ètò Ọlọ́run tímọ́tímọ́.”—Jòhánù 6:68.
22. Àǹfààní wo là ń jẹ bá a ṣe ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀?
22 Láìsí àní-àní, inú òkùnkùn biribiri làwọn èèyàn tó wà nínú ayé wà. Bí Jèhófà ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn èèyàn rẹ̀, ńṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn àtàwọn èèyàn ayé ń pọ̀ sí i. Àǹfààní wo ni ìmọ́lẹ̀ yìí ń ṣe fún wa ná? Òótọ́ ni pé bá a bá tanná síbi tí kòtò wà nínú òkùnkùn, ìyẹn ò ní kí kòtò náà kúrò, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń jẹ́ ká rí àwọn ìdẹkùn, àmọ́ kì í mú àwọn ìdẹkùn náà kúrò. Ńṣe ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti yàgò fún wọn ká lè máa rìn ní ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé à ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà, “gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn.”—2 Pétérù 1:19.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí ọ̀nà táwọn èèyàn rẹ̀ gbà ń ṣètò àwọn nǹkan túbọ̀ dára sí i?
• Àwọn àyípadà wo nínú ẹ̀kọ́ wa ni ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i ti mú kó ṣeé ṣe?
• Àwọn àyípadà wo lo ti fojú ara rẹ rí, kí ló sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara mọ́ wọn?
• Kí nìdí tí o fi fẹ́ máa rìn nìṣó ní ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìpàdé àgbègbè táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún 1922 ní ìlú Cedar Point, ìpínlẹ̀ Ohio fún wọn lókun láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Arákùnrin N. H. Knorr ń kéde ìmújáde “Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun” [Gẹ̀ẹ́sì] lọ́dún 1950
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
© 2003 BiblePlaces.com