ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 8-ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 11
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sítérì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sítérì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • AYABA GBỌ́DỌ̀ DÁ SÍ Ọ̀RÀN NÁÀ
  • (Ẹ́sítérì 1:1–5:14)
  • ÀYÍPADÀ BURÚKÚ DÉ BÁ ÀWỌN ỌLỌ̀TẸ̀
  • (Ẹ́sítérì 6:1–10:3)
  • Jèhófà Yóò Pèsè “Ìtùnú àti Ìdáǹdè”
  • Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Ó sì Yọ̀ǹda Ara Rẹ̀ Tinútinú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 8-ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 11

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sítérì

ÓDÀ bíi pé ohun tí wọ́n ti wéwèé láti ṣe náà ò lè kùnà. Ohun náà ni pé wọ́n fẹ́ pa gbogbo àwọn Júù run yán-ányán-án. Wọ́n ti yan ọjọ́ kan tí wọn máa pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ ọba náà run, ìyẹn láti Íńdíà títí dé Etiópíà. Ohun tẹ́ni tó dìtẹ̀ náà rò lọ́kàn nìyẹn. Àmọ́, ó ti gbàgbé ohun pàtàkì kan. Ó gbàgbé pé Ọlọ́run ọ̀run lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbàkigbà tí ẹ̀mí wọn bá wà nínú ewu. Ìtàn bí Ọlọ́run ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là yìí ló wà nínu ìwé Ẹ́sítérì inú Bíbélì.

Bàbá àgbàlagbà Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ló kọ ìwé Ẹ́sítérì. Ìwé náà sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín nǹkan bí ọdún méjìdínlógún lákòókò tí Ahasuwérúsì ọba Páṣíà tàbí Sásítà Kìíní wà lórí oyè. Ìtàn yìí jẹ́ ká rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà yọ àwọn èèyàn rẹ̀ nínú ewu táwọn ọ̀tá wọn gbìmọ̀ rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé káàkiri ilẹ̀ ọba gbígbòòrò gan-an yìí làwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ń fún ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn Jèhófà lókun gan-an lóde òní, ìyẹn àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Ẹ́sítérì tún jẹ́ ká rí irú àwọn èèyàn tó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn àtàwọn mìíràn tá ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Láìsí àní-àní, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.

AYABA GBỌ́DỌ̀ DÁ SÍ Ọ̀RÀN NÁÀ

(Ẹ́sítérì 1:1–5:14)

Ahasuwérúsì Ọba se àsè kan tó jẹ́ àkànṣe fún gbogbo àwọn ọmọ aládé ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀ (ọdún 493 ṣáájú Sànmánì Kristẹni). Fáṣítì Ayaba tó lẹ́wà gan-an mú ọba bínú gan-an, ọba sì gba ipò náà lọ́wọ́ rẹ̀. Hádásà obìnrin Júù kan ni wọ́n wá yàn láti rọ́pò ayaba náà láàárín gbogbo àwọn òrékelẹ́wà wúńdíá tó wà ní ilẹ̀ náà. Gẹ́gẹ́ bí Módékáì tó jẹ́ ìbátan rẹ̀ ṣe darí rẹ̀, kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Júù lóun, kàkà bẹ́ẹ̀ orúkọ Páṣíà tó ń jẹ́, ìyẹn Ẹ́sítérì, ni wọ́n fi ń pè é.

Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n gbé ọkùnrin onígbèéraga kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hámánì sí ipò olórí ìjọba. Inú ń bí Hámánì gan-an nítorí pé Módékáì kọ̀ láti ‘tẹrí ba mọ́lẹ̀ tàbí láti wólẹ̀ fún un.’ Hámánì wá wéwèé láti pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo àgbègbè tí Ilẹ̀ Páṣíà ń ṣàkóso lé lórí. (Ẹ́sítérì 3:2) Hámánì pàrọwà sí Ahasuwérúsì Ọba pé kó fọwọ́ sí ohun tóun fẹ́ ṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọba fọwọ́ sí àṣẹ kan tó máa mú kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù. Módékáì wá fi “aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú bora.” (Ẹ́sítérì 4:1) Ẹ́sítérì gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀ràn náà wàyí. Ó wá se àsè kan tó jẹ́ pé ọba àti Hámánì olórí ìjọba rẹ̀ nìkan ló pè síbẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi inú dídùn wá síbi àsè náà, Ẹ́sítérì tún bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá síbi àsè mìíràn lọ́jọ́ kejì. Ńṣe ni inú Hámánì ń dùn ṣìnkìn. Àmọ́, inú ń bí i pé Módékáì kì í tẹrí ba fóun. Hámánì wá pinnu láti pa Módékáì ṣáájú àsè ọjọ́ kejì náà.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

1:3-5—Ṣé ọgọ́sàn-án [180] ọjọ́ ni àsè náà gbà? Ẹsẹ Bíbélì yìí ò sọ pé àsè náà pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ yẹn, ohun tó kàn sọ ni pé ọba fi ọrọ̀ àti ẹwà ìjọba rẹ̀ ológo han àwọn ìjòyè rẹ̀ fún odindi ọgọ́sàn-án ọjọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ọba náà lo àkókò gígùn yìí láti fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn kó lè mórí àwọn ìjòyè rẹ̀ wú kí wọ́n sì lè mọ̀ dájú pé ó lágbára láti ṣe àwọn ohun tó wéwèé láti ṣe. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àsè ọlọ́jọ́ méje tó wáyé lẹ́yìn ọgọ́sàn-án ọjọ́ tí wọ́n fi kóra jọ ni ẹsẹ kẹta àti ìkarùn-ún ń tọ́ka sí.

1:8—Kí ló túmọ̀ sí pé ‘kò sẹ́ni tó ń múni lọ́ranyàn láti mu iye ọtí kan pàtó gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí’? Níbi àsè yìí, Ahasuwérúsì Ọba ṣe ohun kan tó jọ pé ó yàtọ̀ sí ohun tó jẹ́ àṣà àwọn ará Páṣíà. Àṣà ọ̀hún ni kí wọ́n máa rọ èèyàn láti mu ọtí tó pọ̀ tó iye kan pàtó nírú àwọn àpèjẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ níbi àsè yìí, ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Wọ́n lè mu ọtí tó pọ̀, wọ́n sì lè mu ìwọ̀nba díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti fẹ́.”

1:10-12—Kí nìdí tí Fáṣítì Ayaba fi ń kọ̀ ṣáá láti wá sọ́dọ̀ ọba? Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ohun tó mú kí ayaba náà kọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ ọba ni pé kò fẹ́ fi ara rẹ̀ wọ́lẹ̀ níwájú àwọn àlejò ọba tí wọ́n ti mutí yó kẹ́ri. Tàbí kó jẹ́ pé ayaba tó lẹ́wà gan-an yìí kì í ṣe ẹni tó nítẹríba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ohun tó fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ àwọn amòye ayé ìgbà yẹn gbà pé àìgbọràn tó ṣe sí ọkọ rẹ̀ yẹn kì í ṣe ohun táwọn gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àti pé àpẹẹrẹ búburú tí Fáṣítì fi lélẹ̀ yìí yóò nípa lórí gbogbo àwọn aya tó wà ní ilẹ̀ Páṣíà.

2:14-17—Ṣé Ẹ́sítérì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọba ṣáájú kó tó fẹ́ ọba ni? Rárá o. Ìtàn náà sọ fún wa pé ní òwúrọ̀, wọ́n dá àwọn obìnrin yòókù tí wọ́n mú wá sí ọ̀dọ̀ ọba padà sí ilé kejì lábẹ́ àbójútó ìwẹ̀fà ọba tó jẹ́ “olùṣètọ́jú àwọn wáhàrì.” Àwọn obìnrin tó sùn ti ọba mọ́jú yìí sì tipa bẹ́ẹ̀ di wáhàrì ọba, tàbí àwọn aya mìíràn tí ọba ní. Àmọ́ ṣá o, wọn ò mú Ẹ́sítérì lọ sí ilé àwọn wáhàrì lẹ́yìn tó rí ọba tán. Nígbà tí wọ́n mú Ẹ́sítérì wá síwájú Ahasuwérúsì Ọba, ó “nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jèrè ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i níwájú rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù.” (Ẹ́sítérì 2:17) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe jèrè “ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́” Ahasuwérúsì? Lọ́nà kan náà tó gbà jèrè ojú rere àwọn èèyàn yòókù ni. “Ọ̀dọ́bìnrin náà dára lójú [Hégáì], tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jèrè inú-rere-onífẹ̀ẹ́ níwájú rẹ̀.” (Ẹ́sítérì 2:8, 9) Hégáì fi ojú rere hàn sí i gan-an nítorí ohun tó kíyè sí, ìyẹn ni ìrísí rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rere tó ní. Àní sẹ́, “Ẹ́sítérì ń bá a lọ ní jíjèrè ojú rere ní ojú gbogbo àwọn tí ó bá rí i.” (Ẹ́sítérì 2:15) Bákan náà, ohun tí ọba rí lára Ẹ́sítérì ló wú u lórí, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.

3:2; 5:9—Kí nìdí tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? Kò sóhun tó burú nínú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọyì ipò gíga tí ẹnì kan wà kí wọ́n sì wólẹ̀ fún un. Àmọ́, ohun tó wà lẹ́yìn ọ̀fà ju òje lọ nínú ọ̀ràn ti Hámánì. Ọmọ Ágágì ni Hámánì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ará Ámálékì, Jèhófà sì ti sọ pé pípa ni a ó pa Ámálékì run pátápátá. (Diutarónómì 25:19) Lójú Módékáì, títẹríba fún Hámánì yóò túmọ̀ sí pé òun kò jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó kọ̀ jálẹ̀, ó ní Júù lòun.—Ẹ́sítérì 3:3, 4.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

2:10, 20; 4:12-16. Ẹ́sítérì gba ìtọ́sọ́nà àti ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ olùjọsìn Jèhófà kan tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Ó bọ́gbọ́n mu káwa náà “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín [wa], kí [a] sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.”—Hébérù 13:17.

2:11; 4:5. Kò yẹ ká ‘máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ká mójú tó ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—Fílípì 2:4.

2:15. Ẹ́sítérì fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn ní ti pé kò tún béèrè àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mìíràn tàbí aṣọ tó lẹ́wà ju èyí tí Hégáì fún un. Jíjẹ́ tí Ẹ́sítérì jẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,” ló mú kó rí ojú rere ọba.—1 Pétérù 3:4.

2:21-23. Ẹ́sítérì àti Módékáì jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa ní ti kéèyàn “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.”—Róòmù 13:1.

3:4. Nínú àwọn ipò kan, ó lè jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé ká má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tá a jẹ́, bí Ẹ́sítérì ò ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tóun jẹ́ gan-an. Àmọ́ tọ́ràn náà bá dá lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì, irú bíi jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ apá ibi tá a wà nínú ọ̀rọ̀ jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ àti ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.

4:3. Nígbà tá a bá wà nínú àdánwò, ó yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní okun àti ọgbọ́n.

4:6-8. Ọ̀nà tó bófin mu ni Módékáì gbà wá ojútùú sí ìbẹ̀rùbojo tí ọ̀tẹ̀ Hámánì dá sílẹ̀.—Fílípì 1:7.

4:14. Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Módékáì ní nínú Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé.

4:16. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, Ẹ́sítérì fi ìṣòtítọ́ àti ìgboyà kojú ọ̀ràn kan tí ì bá mú kó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì ká kẹ́kọ̀ọ́ láti máa gbára lé Jèhófà, ká má máa gbára lé ara wa.

5:6-8. Kí Ẹ́sítérì lè rí ojú rere Ahasuwérúsì, ó tún pè é sí àsè mìíràn. Ó fi ọgbọ́n hùwà, bó sì ṣe yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.—Òwe 14:15.

ÀYÍPADÀ BURÚKÚ DÉ BÁ ÀWỌN ỌLỌ̀TẸ̀

(Ẹ́sítérì 6:1–10:3)

Bí nǹkan ṣe wá ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé ara wọn, ibi tí Hámánì fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Hámánì ni wọ́n wá gbé kọ́ òpó igi tó ṣe sílẹ̀ fún Módékáì, bí ẹni tí wọ́n fẹ́ pa tẹ́lẹ̀ sì ṣe wá di olórí ìjọba nìyẹn! Pípa tí wọ́n wéwèé àtipa gbogbo àwọn Júù run wá ńkọ́? Ńṣe nìyẹn náà yí padà lọ́nà tó jọni lójú.

Ẹ́sítérì olóòótọ́ tún sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nípa wíwá síwájú ọba tó sì bẹ̀bẹ̀ kó lè rí ọ̀nà kan ṣáá láti yí ọ̀tẹ̀ tí Hámánì ti dì padà. Ahasuwérúsì mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Nítorí náà, nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n pinnu láti pa àwọn Júù nípakúpa pé, dípò kí wọ́n pa àwọn Júù, àwọn tó fẹ́ pa wọ́n ni wọ́n wá pa dípò wọn. Módékáì wá gbé òfin kalẹ̀ pé káwọn máa ṣe Àjọyọ̀ Púrímù lọ́dọọdún ní ìrántí ìdáǹdè ńlá yìí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Módékáì ni igbákejì Ahasuwérúsì Ọba, ó ‘ṣiṣẹ́ fún ire àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún gbogbo ọmọ wọn.’—Ẹ́sítérì 10:3.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

7:4—Báwo ni pípa àwọn Júù run yóò ṣe já sí “ìpalára ọba”? Nípa fífọgbọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ta àwọn Júù bí ẹrú, ohun tí Ẹ́sítérì ń sọ ni pé yóò jẹ́ ìpalára fún ọba tí wọ́n bá pa wọn run. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó fàdákà tí Hámánì ṣèlérí láti san kéré gan-an lẹ́gbẹ́ owó tí ọba máa rí tó bá jẹ́ pé ńṣe ni Hámánì sọ pé kí wọ́n ta àwọn Júù bí ẹrú. Tó bá sì jẹ́ pé wọ́n pa wọ́n run bí Hámánì ṣe sọ ni, á jẹ́ pé ayaba ì bá pàdánù ẹ̀mí tirẹ̀ náà.

7:8—Kí nìdí táwọn òṣìṣẹ́ ààfin ṣe fi nǹkan bo ojú Hámánì? Ó ṣeé ṣe kí èyí túmọ̀ sí ìtìjú tàbí ìparun tó ń dúró dè é. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, “nígbà mìíràn, àwọn ará ìgbàanì máa ń fi nǹkan borí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa.”

8:17—Ọ̀nà wo ni ‘púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà gbà polongo ara wọn ní Júù’? Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Páṣíà ló di aláwọ̀ṣe Júù, wọ́n rò pé yíyí tí ọba yí òfin tó ṣe láti pa àwọn Júù padà yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn Júù rí ojú rere Ọlọ́run. Ìlànà kan náà ló wà nínú ohun táwọn ará Páṣíà ṣe yìí àti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Sekaráyà. Èyí tó kà pé: “Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’”—Sekaráyà 8:23.

9:10, 15, 16—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fàyè gba kéèyàn kó àwọn ìkógun, kí nìdí táwọn Júù fi kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ fì hàn kedere pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n fẹ́ dáàbò bò, kì í ṣe pé wọ́n fẹ di ọlọ́rọ̀.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:

6:6-10. “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18.

7:3, 4. Ǹjẹ́ a máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá láìbẹ̀rù, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ máa jẹ́ kí wọ́n ṣenúnibíni sí wa?

8:3-6. A lè ké gbàjarè sáwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kódà, nǹkan tó yẹ ká máa ṣe nìyẹn.

8:5. Ẹ́sítérì lo ọgbọ́n, kò mẹ́nu kan ipa tí ọba kó nínú àṣẹ tí wọ́n fọwọ́ sí láti pa àwọn èèyàn òun run. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa lo ọgbọ́n nígbà tá a bá ń jẹ́rìí fáwọn aláṣẹ onípò gíga.

9:22. Kò yẹ ká gbàgbé àwọn òtòṣì tí ń bẹ láàárín wa.—Gálátíà 2:10.

Jèhófà Yóò Pèsè “Ìtùnú àti Ìdáǹdè”

Ọ̀rọ̀ tí Módékáì sọ fi hàn pé dídé tí Ẹ́sítérì dé ipò ọlá láàfin yìí jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n sọ pé wọ́n máa pa àwọn Júù run, wọ́n gbààwẹ̀ wọ́n sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́. Ayaba pàápàá ń wá síwájú ọba nígbà tí ọba kò pè é, gbogbo ìgbà tó ṣe bẹ́ẹ̀ ló sì rí ojú rere ọba. Ọba kò rí oorun sùn lóru ọjọ́ tí nǹkan le gan-an yẹn. Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe yí ipò nǹkan padà fún àǹfààní àwọn èèyàn rẹ̀ ló wà nínú ìwé Ẹ́sítérì.

Ìtàn amọ́kànyọ̀ tó wà nínú ìwé Ẹ́sítérì ń fúnni níṣìírí gan-an, àgàgà fún àwa tá à ń gbé ní “àkókò òpin” yìí. (Dáníẹ́lì 12:4) “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” tàbí ní apá ìparí àkókò òpin, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìyẹn Sátánì Èṣù yóò gbé àtakò líle koko dìde sáwọn èèyàn Jèhófà. Ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ni pé kóun pa àwọn olùjọsìn tòótọ́ run pátápátá. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Ẹ́sítérì, Jèhófà yóò pèsè “ìtura àti ìdáǹdè” fún àwọn olùjọsìn rẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 38:16-23; Ẹ́sítérì 4:14.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹ́sítérì àti Módékáì wá síwájú Ahasuwérúsì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́