ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/15 ojú ìwé 3
  • Ikú Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ Tó Ń Pa Tàgbàtèwe!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ikú Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ Tó Ń Pa Tàgbàtèwe!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Máa Wá Ipò Ńlá!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìgbéraga Mú Kí Ábúsálómù Ṣọ̀tẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ìgbọ́kànlé Kíkún Nínú Jèhófà Ń Mú Ká Ní Ìgboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Máa Sin Ọlọ́run Tí Ń sọni Di Òmìnira
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/15 ojú ìwé 3

Ikú Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ Tó Ń Pa Tàgbàtèwe!

NÍNÚ ìwé tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Arnold Toynbee kọ, ó sọ pé: “Látìgbà tí wọ́n bá ti bí ẹnì kan sáyé ló ti ṣeé ṣe kí ẹni náà kú nígbàkigbà. Kò sì síbi tá a lè yẹ̀ ẹ́ sí, ó máa padà ṣẹlẹ̀ náà ni.” Ẹ ò rí i bó ṣe máa ń dunni tó nígbà téèyàn wa kan tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan bá kú!

Láti ìjímìjí ni ikú ti ń dá ọmọ èèyàn lóró. Téèyàn wa kan bá kú, ó máa ń dunni gan-an débi pé ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń tojú sú wa. Kò sì sẹ́ni tí ikú ò lè mú lọ. Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń kọ àròkọ kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ pé: “Ọ̀fọ̀ máa ń mú kí gbogbo wa ṣe bí ọmọdé, àtọ̀mọ̀wé àti púrúǹtù, kò sẹ́ni tọ́rọ̀ ikú yé. Àní ẹni tó gbọ́n jù lọ ò lè rí àlàyé kankan ṣe.” Tẹ́nì kan bá kú ńṣe la máa ń dà bí ọmọ àná, a kì í mọ ohun tá a lè ṣe, a kì í lè jí ẹni náà padà. Kódà àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn alágbára pàápàá kì í lè jí i. Ọ̀rọ̀ náà tiẹ̀ tojú sú àwọn ọlọ́gbọ́n àtàwọn olóye. Kódà àwọn tó jẹ́ akíkanjú pàápàá máa ń sunkún bí àwọn èèyàn míì.

Irú ọ̀fọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣẹ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì nígbà tí ọmọ rẹ̀ Ábúsálómù kú. Nígbà tó gbọ́ pé ọmọ òun kú, ńṣe ló bú sẹ́kún tó sì bẹ̀rẹ̀ sí kédàárò pé: “Ọmọkùnrin mi Ábúsálómù, ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi Ábúsálómù! Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ, Ábúsálómù ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi!” (2 Sámúẹ́lì 18:33) Àbẹ́ẹ̀rí nǹkan, ọba alágbára tó ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá alágbára kò rí nǹkan kan ṣe àfi bó kàn ṣe ń sọ pé òun ni “ọ̀tá ìkẹyìn [náà], ikú” ì bá mú lọ dípò ọmọ òun.—1 Kọ́ríńtì 15:26.

Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó máa fòpin sí ikú? Tó bá wà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Ǹjẹ́ a ṣì tún máa rí àwọn èèyàn wa tó ti kú? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa fi Ìwé Mímọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́