Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ Wednesday, August 24, 2005, ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Amẹ́ríkà àti ti ilẹ̀ Kánádà gbọ́ ìfilọ̀ ayọ̀ kan látorí ẹ̀rọ fídíò alátagbà tí wọ́n fi ń wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ tí wọ́n ń ṣe ní orílé-iṣẹ́. Ìfilọ̀ yẹn sọ pé láti September 1, 2005, wọn yóò fi àwọn arákùnrin méjì kún Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn méjèèjì ni Geoffrey W. Jackson àti Anthony Morris Kẹta.
Oṣù February ọdún 1971 ni arákùnrin Jackson bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Tasmania tó jẹ́ erékùṣù kan ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ó fẹ́ Jeanette (Jenny) ní oṣù June ọdún 1974. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà làwọn méjèèjì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Wọ́n ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Tuvalu, Samoa, àti Fiji láti ọdún 1979 sí 2003. Erékùṣù ni orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ní gúúsù Òkun Pàsífíìkì. Arákùnrin àti arábìnrin Jackson ṣe bẹbẹ lórí iṣẹ́ ìtumọ̀ àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì ní àwọn erékùṣù yìí. Ọdún 1992 ni arákùnrin Jackson di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Samoa, ó sì di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Fiji lọ́dún 1996. Ní April 2003, òun àti Jenny di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Amẹ́ríkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni arákùnrin Jackson di ara àwọn tó ń ran Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ara àwọn ẹ̀ka Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́.
Ọdún 1971 náà ni arákùnrin Morris bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Amẹ́ríkà. Oṣù December ọdún yẹn ló fẹ́ Susan, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ fọ́dún mẹ́rin kí wọ́n tó bí Jesse ọmọ wọn àkọ́kọ́. Nígbà tó yá, wọ́n tún bí ọmọkùnrin mìíràn tó ń jẹ́ Paul. Arákùnrin Morris padà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún 1979. Aya rẹ̀ náà padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà táwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ iléèwé. Ìdílé wọn lápapọ̀ lọ sìn láwọn àgbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ Rhode Island ati ìpínlẹ̀ North Carolina ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Arákùnrin Morris ṣe adelé alábòójútó àyíká ní North Carolina, nígbà táwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Jesse àti Paul, ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà táwọn ọmọ rẹ̀ yìí pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, wọ́n di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Amẹ́ríkà. Láàárín àkókò yìí, arákùnrin Morris bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà tó sì di ọdún 2002, a pe òun àti Susan pé kí wọ́n wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù August. Arákùnrin Morris ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti Patterson, nígbà tó sì yá ó di ọ̀kan lára àwọn tó ń ran Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn tó jẹ́ ara àwọn ẹ̀ka Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́.
Yàtọ̀ sí àwọn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí yìí, àwọn yòókù tó wà nínú Ìgbìmọ̀ yìí ni C. W. Barber; J. E. Barr; S. F. Herd; M. S. Lett; G. Lösch; T. Jaracz; G. H. Pierce; A. D. Schroeder; D. H. Splane; àti D. Sydlik. Kristẹni ẹni àmì òróró ni gbogbo àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí.